Ẹ̀KỌ́ 20
Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń ṣe nǹkan létòlétò. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Torí náà, ó yẹ káwọn èèyàn rẹ̀ wà létòlétò. Báwo la ṣe ṣètò ìjọ Kristẹni? Kí la lè ṣe tí nǹkan á fi máa lọ létòlétò nínú ìjọ?
1. Ta ni olórí ìjọ Kristẹni?
‘Kristi ni orí ìjọ.’ (Éfésù 5:23) Láti ọ̀run ni Kristi ti ń darí ìjọ àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó jẹ́ àwùjọ àwọn alàgbà tí wọ́n ti ń sin Jèhófà bọ̀ tipẹ́, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì yé wọn dáadáa. A tún mọ̀ wọ́n sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí. (Ka Mátíù 24:45-47.) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù ló máa ń tọ́ àwọn Kristẹni sọ́nà. Bákan náà lóde òní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń tọ́ àwọn ìjọ wa sọ́nà kárí ayé. (Ìṣe 15:2) Àmọ́, àwọn ọkùnrin yìí kì í ṣe olórí ẹ̀sìn wa o. Àṣẹ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n sì ń jẹ́ kí Jésù máa darí àwọn.
2. Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà?
Àwọn alàgbà ni àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tí wọ́n ti ń sin Ọlọ́run bọ̀ tipẹ́. Wọ́n máa ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n máa ń bójú tó wọn, wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń fún wọn níṣìírí. Wọn kì í gbowó nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ‘tinútinú níwájú Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ wọ́n ń fi ìtara ṣe é látọkàn wá.’ (1 Pétérù 5:1, 2) Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló máa ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́, tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.
Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń yan àwọn alàgbà kan láti di alábòójútó àyíká. Àwọn alábòójútó àyíká yìí máa ń bẹ àwọn ìjọ wò kí wọ́n lè tọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin sọ́nà, kí wọ́n sì fún wọn lókun. Wọ́n tún máa ń yan àwọn arákùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ láti di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.—1 Tímótì 3:1-10, 12; Títù 1:5-9.
3. Kí ni ojúṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan?
Gbogbo wa nínú ìjọ máa ń “yin orúkọ Jèhófà.” Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń dáhùn ìbéèrè nípàdé, a sì máa ń fi iṣẹ́ ìwàásù dánra wò, a máa ń gbọ́ àsọyé, a máa ń kọrin, a sì máa ń wàásù fáwọn èèyàn bí agbára kálukú wa bá ṣe mọ.—Ka Sáàmù 148:12, 13.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa irú aṣáájú tí Jésù jẹ́, bí àwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àti bá a ṣe lè máa ṣègbọràn sí Jésù ká sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà.
4. Aṣáájú tó lójú àánú ni Jésù
Jésù ń fìfẹ́ pè wá pé ká sún mọ́ òun. Ka Mátíù 11:28-30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Irú aṣáájú wo ni Jésù? Kí ló sọ pé òun máa ṣe fún wa?
Báwo làwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé apẹẹrẹ Jésù? Wo FÍDÍÒ yìí.
Bíbélì jẹ́ káwọn alàgbà mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wọn.
Ka Àìsáyà 32:2 àti 1 Pétérù 5:1-3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé àwọn alàgbà máa ń mára tu àwọn èèyàn bíi ti Jésù?
-
Àwọn ọ̀nà míì wo làwọn alàgbà máa ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
5. Ìwà àwọn alàgbà bá ohun tí wọ́n ń kọ́ni mu
Ojú wo ni Jésù fẹ́ káwọn alàgbà máa fi wo iṣẹ́ wọn? Wo FÍDÍÒ yìí.
Jésù fi ìlànà lélẹ̀ fáwọn alábòójútó nínú ìjọ. Ka Mátíù 23:8-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Ìlànà wo ló wà nínú Bíbélì tó yẹ káwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni máa tẹ̀ lé? Ṣé o rò pé àwọn olórí ẹ̀sìn ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí?
-
A. Àwọn alàgbà máa ń mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára, wọ́n sì ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀
-
B. Àwọn alàgbà máa ń bójú tó gbogbo àwọn ará ìjọ
-
D. Àwọn alàgbà máa ń wàásù déédéé
-
E. Àwọn alàgbà máa ń kọ́ni nínú ìjọ. Wọ́n tún máa ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó àtàwọn iṣẹ́ míì
6. Máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà
Bíbélì sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà. Ka Hébérù 13:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Ṣé o rò pé ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣègbọràn sáwọn alábòójútó nínú ìjọ, ká sì máa tẹrí ba fún wọn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ka Lúùkù 16:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà kódà nínú àwọn ohun tá a rò pé kò tó nǹkan?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò pọn dandan kí n dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan kí n tó lè sin Ọlọ́run”
-
Àǹfààní wo lo rò pé ẹnì kan máa rí tó bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jésù ni orí ìjọ. À ń fayọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà tí Jésù ń darí, torí pé wọ́n máa ń mára tù wá, ìwà wọn sì bá ohun tí wọ́n ń kọ́ni mu.
Kí lo rí kọ́?
-
Ta ni orí ìjọ?
-
Báwo làwọn alàgbà ṣe ń ran ìjọ lọ́wọ́?
-
Kí ni ojúṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn alàgbà tó kù fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni òde òní.
A Fún Àwọn Ará Wa Lókun Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa (4:22)
Wo fídíò yìí kó o lè mọ iṣẹ́ táwọn alábòójútó àyíká ń ṣe.
Ìgbésí Ayé Alábòójútó Àyíká Tó Lọ Sìn ní Ìgbèríko Kan (4:51)
Ka àpilẹ̀kọ yìí, kó o lè mọ ipa táwọn obìnrin ń kó nínú ìjọ.
“Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run?” (Ilé Ìṣọ́, September 1, 2012)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níṣìírí.
“Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’” (Ilé Ìṣọ́, January 15, 2013)