Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá 4

Ọlọ́run Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú

Ọlọ́run Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú

Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní mú kó ṣègbọràn sí Ọlọ́run, Jèhófà sì ṣèlérí pé òun máa bù kún un, òun sì máa sọ irú-ọmọ rẹ̀ di púpọ̀

NǸKAN bí àádọ́ta-dín-nírínwó [350] ọdún ti kọjá látìgbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà. Ábúráhámù ìgbàanì ń gbé nínú ìlú aláásìkí tó ń jẹ́ Úrì, èyí tó wà níbi tí ìlú Ìráàkì òde òní wà. Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó tayọ lọ́lá. Àmọ́, ní báyìí, Ọlọ́run fẹ́ dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò.

Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kó fi ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kó sì lọ sí ilẹ̀ àjèjì, èyí tá a wá mọ̀ sí ilẹ̀ Kénáánì. Ábúráhámù ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìjáfara. Ó gbéra tòun ti agbo ilé ẹ̀, tó fi mọ́ ìyàwó ẹ̀ Sérà, àti Lọ́ọ̀tì, ọmọ ẹ̀gbọ́n ẹ̀, lẹ́yìn ìrìn-àjò gígùn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú àgọ́ ní ilẹ̀ Kénáánì. Nínú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá, ó ṣèlérí pé, Òun máa sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, pé òun máa bù kún gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ rẹ̀, àti pé àwọn ọmọ rẹ̀ máa jogún ilẹ̀ Kénáánì.

Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì láásìkí, wọ́n ní agbo àgùntàn àti agbo màlúù tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Ábúráhámù ò fàgbà yan Lọ́ọ̀tì jẹ, ó jẹ́ kó yan apá ibi tó wù ú láti máa gbé. Lọ́ọ̀tì yan àgbègbè ẹlẹ́tùlójú tó wà níbi Odò Jọ́dánì ó sì ń gbé nítòsí ìlú Sódómù. Àmọ́, oníṣekúṣe làwọn ọkùnrin ìlú Sódómù, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ bíburú jáì sí Jèhófà.

Nígbà tó ṣe, Jèhófà Ọlọ́run mú un dá Ábúráhámù lójú pé irú-ọmọ rẹ̀ máa pọ̀ rẹpẹtẹ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. Ábúráhámù nígbàgbọ́ nínú ìlérí yẹn. Síbẹ̀, Sérà, tó jẹ́ ààyò olùfẹ́, ìyàwó Ábúráhámù, ò rọ́mọ bí. Nígbà tí Ábúráhámù wá di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99], tí Sérà sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé òun àti Sérà máa bí ọmọkùnrin kan. Bí Ọlọ́run ṣe sọ, Sérà bí Ísáákì. Ábúráhámù tún bí àwọn ọmọ míì, àmọ́ ọ̀dọ̀ Ísáákì ni Olùdáǹdè tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú ọgbà Édẹ́nì máa gbà wá.

Ní àgbègbè ibi tí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ń gbé ní Sódómù, Lọ́ọ̀tì jẹ́ olódodo, kò sì sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn oníṣekúṣe tó ń gbé nínú ìlú náà. Nígbà tí Jèhófà pinnu láti mú ìdájọ́ wá sórí ìlú Sódómù, ó kọ́kọ́ rán àwọn áńgẹ́lì wá láti kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì nípa ìparun tó ń bọ̀ wá. Àwọn áńgẹ́lì náà rọ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ láti sá kúrò nílùú Sódómù kí wọ́n má sì ṣe bojú wẹ̀yìn. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run mú kí òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti ìlú búburú tó wà nítòsí ibẹ̀, ìyẹn Gòmórà, ó sì pa gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ run. Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì la ìparun náà já. Àmọ́, aya Lọ́ọ̀tì bojú wẹ̀yìn, bóyá nípa yíyán hànhàn fáwọn nǹkan tó fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Nítorí ìwà àìgbọràn rẹ̀ yìí, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ dí i.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì 11:10–19:38.