Ọgbọ́n
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tòótọ́?
Ibo la ti lè rí ọgbọ́n tòótọ́?
Ṣó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Kr 1:8-12—Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì wà lọ́dọ̀ọ́, ó sọ pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n kóun lè jẹ́ ọba tó dáa. Inú Jèhófà dùn sí nǹkan tó béèrè, ó sì fún un
-
Owe 2:1-5—Bíbélì fi ọgbọ́n, òye, àti ìfòyemọ̀ wé ìṣura tó ṣeyebíye tó yẹ kéèyàn wá, ó sì jẹ́ kó da wá lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fara balẹ̀ wá a
-
Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa ní ọgbọ́n?
Ais 11:2; 1Kọ 1:24, 30; 2:13; Ef 1:17; Kol 2:2, 3
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Owe 8:1-3, 22-31—Bíbélì ṣàpèjúwe ọgbọ́n bíi pé èèyàn ni, àpèjúwe náà sì bá Jésù mú torí pé òun ni àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá
-
Mt 13:51-54—Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ti mọ̀ ọ́n láti kékeré, torí náà ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń sọ
-
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ọgbọ́n Ọlọ́run?
Tá a bá ní ọgbọ́n, báwo ló ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ tó sì tún máa dáàbò bò wá?
Tún wo Owe 7:2-5; Onw 7:12
Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ṣeyebíye tó?
Tún wo Job 28:18
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Job 28:12, 15-19—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ń jìyà gan-an tó sì ti pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan, ó ṣì ń yin Jèhófà torí ọgbọ́n rẹ̀
-
Sm 19:7-9—Ọba Dáfídì sọ pé tẹ́nì kan bá tiẹ̀ jẹ́ aláìmọ̀kan, tó bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Jèhófà àtàwọn ìránnilétí rẹ̀, ó máa di ọlọ́gbọ́n
-
Tá a bá ń tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé yìí, àkóbá wo ló lè ṣe fún wa?