Ìjọba
Ìjọba wo làwa Kristẹni jẹ́ adúróṣinṣin sí, tá a sì ń fi gbogbo ọkàn wa ṣègbọràn sí?
Tún wo Da 7:13, 14
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 89:18-29—Jèhófà fi Mèsáyà jọba lórí gbogbo ayé
-
Ifi 12:7-12—Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ó sì lé Sátánì kúrò lọ́run
-
Kí làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe tó fi hàn pé aṣojú Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n?
Àwa Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ
Kí nìdí tá a fi ń pa òfin ìjọba mọ́, tá a sì ń san owó orí?
Ro 13:1-7; Tit 3:1; 1Pe 2:13, 14
Tún wo Iṣe 25:8
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 22:15-22—Jésù fọgbọ́n dáhùn nígbà tí wọ́n bi í pé ṣé ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa san owó orí
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbẹ̀san táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa?
Tún wo “Inúnibíni”
Àwa Kristẹni kì í dá sí ogun àti ọ̀rọ̀ òṣèlú
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, kí nìdí tá ò fi ní ṣègbọràn sí wọn tí wọ́n bá ní ká ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí?
Kí ni Jésù ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Báwo ni òfin Ọlọ́run nípa ìbọ̀rìṣà ṣe lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ kó má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Táwọn aláṣẹ bá sọ pé káwa Kristẹni jagun tàbí ká ti àwọn tó fẹ́ lọ jagun lẹ́yìn, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe?
Tún wo Sm 11:5
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 26:50-52—Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ogun
-
Jo 13:34, 35—Kristẹni kan lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé máa fi hàn pé mo ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù yìí tí mo bá lọ jagun lórílẹ̀-èdè míì, bóyá tí mo tiẹ̀ pa àwọn arákùnrin àti arábìnrin tá a jọ ń sin Jèhófà?’
-
Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ sí ìwọ́de nígbà táwọn ìjọba bá ṣe nǹkan tí kò tẹ́ wa lọ́rùn?
Kí nìdí tí kò fi yẹ kó ya àwa Kristẹni lẹ́nu táwọn èèyàn bá parọ́ mọ́ wa pé a fẹ́ dojú ìjọba dé tàbí pé à ń da ìlú rú?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Iṣe 16:19-23—Àwọn èèyàn fìyà jẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà torí pé wọ́n ń wàásù
-