Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
Orí Kìíní
Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
1, 2. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò àrà ọ̀tọ̀ tí a fi hàn nínú ìwé Dáníẹ́lì inú Bíbélì? (b) Ní àwọn àkókò òde òní, kí ni àwọn ìbéèrè tí a béèrè nípa ìwé Dáníẹ́lì?
ỌBA alágbára kan kéde pé òun yóò pa àwọn amòye òun nítorí pé wọn kò lè rọ́ àdììtú àlá tí òun lá kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. A ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn ère gìrìwò kan sínú iná ìléru kan tí a mú gbóná ré kọjá ààlà, síbẹ̀ wọ́n là á já. Bí àjọyọ̀ kan ṣe ń lọ lọ́wọ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn rí ọwọ́ kan tí ń kọ àwọn àdììtú ọ̀rọ̀ sára ògiri ààfin. Àwọn olubi ọlọ̀tẹ̀ kan mú kí wọ́n ju àgbàlagbà ọkùnrin kan sínú ihò kìnnìún, ṣùgbọ́n ó jáde wá láìfarapa rárá. Wòlíì Ọlọ́run kan rí ẹranko mẹ́rin nínú ìran, ohun tí wọ́n sì dúró fún nasẹ̀ dé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lọ́jọ́ iwájú.
2 Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ mélòó kan lára àwọn ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a rí nínú ìwé Dáníẹ́lì inú Bíbélì. Wọ́n ha yẹ fún àgbéyẹ̀wò dan-indan-in kan bí? Kí ni ògbólógbòó ìwé yìí lè ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ wa? Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ṣàníyàn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá [2,600] ọdún sẹ́yìn?
DÁNÍẸ́LÌ—ÌWÉ TÍ A KỌ NÍGBÀANÌ FÚN ỌJỌ́ ÒNÍ
3, 4. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń ṣàníyàn lọ́nà ẹ̀tọ́ nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé?
3 Apá tí ó pọ̀ jù nínú ìwé Dáníẹ́lì dá lórí ọ̀ràn ìṣàkóso ayé, kókó kan tí a ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ jù lọ lónìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ènìyàn ni yóò gbà pé a ń gbé ní àkókò lílekoko. Lójoojúmọ́, léraléra ni a ń gba àwọn ìròyìn tí ń rán wa létí, lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, pé àwùjọ ènìyàn túbọ̀ ń rì sínú irà àwọn ìṣòro tí ó kani láyà—tí ìwọ̀nyí sì ń ṣẹlẹ̀ láìka
àwọn àṣeyọrí ńláǹlà tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ṣe sí.4 Ro èyí wò ná: Ènìyàn ti rìn lórí òṣùpá, ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi kò lè gbafẹ́ káàkiri láwọn òpópónà nínú pílánẹ́ẹ̀tì tirẹ̀ láìbẹ̀rù. Ó lè pèsè onírúurú nǹkan amúlé-tura ìgbàlódé sínú ibùgbé kan, ṣùgbọ́n kò lè dáwọ́ títú tí àwọn ìdílé ń tú ká dúró. Ó lè mú kí ayé kan tí ìsọfúnni ti gbilẹ̀ wà, ṣùgbọ́n kò lè kọ́ àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe lè gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Hugh Thomas, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn, kọ̀wé nígbà kan rí pé: “Bí ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ ṣe ń tàn kálẹ̀, ohun kékeré ni aráyé tí ì kọ́ nípa ìkóra-ẹni-níjàánu, ohun tí ó sì mọ̀ nípa ọgbọ́n bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn gbé pọ̀ kéré jọjọ.”
5. Ní èyí tí ó pọ̀ jù lọ, kí ní ti jẹ́ àbájáde ìṣàkóso ènìyàn?
5 Kí ènìyàn lè gbìyànjú láti mú kí ètò wà ní àwùjọ dé ìwọ̀n kan, wọ́n ṣètò ara wọn sábẹ́ onírúurú ìjọba tí ó pọ̀ lọ jàra. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí ohun tí Sólómọ́nì Ọba sọ kò ṣẹ mọ́ lára pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 4:1; 8:9) Lóòótọ́, àwọn ọba kan ti ní àwọn ète tí ó dára. Ṣùgbọ́n, kò sí ọba, ààrẹ, tàbí apàṣẹwàá kan tí ó lè mú àìsàn àti ikú kúrò. Kò sí ènìyàn tí ó lè mú ilẹ̀ ayé wa padà sí ipò Párádísè tí Ọlọ́run pète pé kí ó wà.
6. Èé ṣe tí Jèhófà kò fi nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìṣàkóso ènìyàn kí ó tó lè mú ètè rẹ̀ ṣẹ?
6 Síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá ń fẹ́ ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, ó sì lè ṣe wọ́n. Kò nílò ìyọ̀ǹda láti ọwọ́ ìjọba ènìyàn láti lè ṣàṣeparí ète rẹ̀, nítorí pé, lójú tirẹ̀, “àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí.” (Aísáyà 40:15) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, Olùṣàkóso àgbáyé. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní àṣẹ tí ó ju ti àwọn ìjọba ènìyàn lọ fíìfíì. Ìjọba Ọlọ́run ni yóò rọ́pò ìṣàkóso ènìyàn, fún ìbùkún ayérayé ti aráyé. Ó ṣeé ṣe kí ó máà sí ibòmíràn tí a ti túbọ̀ mú kí èyí ṣe kedere ju inú ìwé Dáníẹ́lì nínú Bíbélì.
DÁNÍẸ́LÌ—ÀÀYÒ OLÙFẸ́ GIDI LÓJÚ ỌLỌ́RUN
7. Ta ni Dáníẹ́lì, ojú wo sì ni Jèhófà fi wò ó?
7 Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ràn Dáníẹ́lì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, gidigidi. Ní tòótọ́, áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣàpèjúwe Dáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.” (Dáníẹ́lì 9:23) Ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a túmọ̀ sí “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” lè túmọ̀ sí “ààyò olùfẹ́ gidi,” “ẹni tí a pọ́nlé gidigidi” àní “àyànfẹ́” pàápàá. Dáníẹ́lì ṣeyebíye lọ́nà àkànṣe lójú Ọlọ́run.
8. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe dé Bábílónì?
8 Ní ṣókí, ẹ jẹ́ kí a gbé ipò àrà ọ̀tọ̀ tí ó yí wòlíì tí ó jẹ́ ààyò olùfẹ́ yìí ká yẹ̀ wò. Ní ọdún 618 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nebukadinésárì Ọba, ará Bábílónì, sàga ti Jerúsálẹ́mù. (Dáníẹ́lì 1:1) Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà ni a fipá kó àwọn èwe Júù kan, tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Ara wọn ni Dáníẹ́lì wà. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀dọ́langba ni nígbà yẹn.
9. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni a fún Dáníẹ́lì àti àwọn Hébérù alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀?
9 Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà wà lára àwọn Hébérù tí a yàn láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́ta nínú “ìkọ̀wé àti ahọ́n àwọn ará Kálídíà.” (Dáníẹ́lì 1:3, 4) Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí èyí ju kìkìdá ẹ̀kọ́ èdè. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n C. F. Keil sọ pé: “Ńṣe ni a máa fi ọgbọ́n àwọn àlùfáà àti àwọn ìjìmì Kálídíà, tí a fi ń kọ́ni ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ Bábílónì, kọ́ Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” Nítorí náà, ṣe ni a ń dá Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àkànṣe láti lò wọ́n fún iṣẹ́ ìjọba.
10, 11. Ìpèníjà wo ni Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dojú kọ, ìrànlọ́wọ́ wo sì ni Jèhófà fi fún wọn?
10 Ẹ wo irú àyípadà ńláǹlà nínú ipò àwọn nǹkan tí èyí jẹ́ fún Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀! Ní Júdà, àárín àwọn olùjọsìn Jèhófà ni wọ́n ń gbé. Ní báyìí, àwọn
tí ń jọ́sìn àwọn akọ àti abo ọlọ́run inú ìtàn àròsọ ni ó wà yí wọn ká. Àmọ́, àwọn èwe náà, Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà kò mikàn. Wọ́n pinnu láti rọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́—láìka ipò tí ó jẹ́ ìpèníjà sí ìgbàgbọ́ wọn yìí sí.11 Èyí kò ní rọrùn. Ojúlówó olùfọkànsìn Mádọ́kì, olú ọlọ́run àjúbàfún àwọn ará Bábílónì, ni Nebukadinésárì Ọba jẹ́. Nígbà mìíràn, àwọn ohun tí ọba sọ pé kí wọ́n ṣe jẹ́ ohun tí olùjọsìn Jèhófà kò lè fara mọ́ rárá. (Bí àpẹẹrẹ, wo Dáníẹ́lì 3:1-7.) Síbẹ̀, Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí ìtọ́sọ́nà tí kì í yẹ̀ gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Nígbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́ta tí a ṣe fún wọn, Ọlọ́run fi “ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye nínú gbogbo ìkọ̀wé àti ọgbọ́n” bù kún wọn. Ní àfikún sí i, a fún Dáníẹ́lì ní agbára láti lóye ìtumọ̀ àwọn ìran àti àlá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọba dán àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin wọ̀nyí wò, ó rí i pé wọ́n fi “ìlọ́po mẹ́wàá sàn ju gbogbo àwọn àlùfáà pidánpidán àti alálùpàyídà tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 1:17, 20.
PÍPOLONGO ÀWỌN ÌHÌN IṢẸ́ ỌLỌ́RUN
12. Àkànṣe iṣẹ́ àyànfúnni wo ni a fún Dáníẹ́lì?
12 Ní gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí Dáníẹ́lì lò ní Bábílónì, ońṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí àwọn ènìyàn bí Nebukadinésárì Ọba àti Bẹliṣásárì Ọba. Iṣẹ́ tí a fún Dáníẹ́lì ṣe jẹ́ èyí tí ó ṣe pàtàkì gidigidi. Jèhófà gba Nebukadinésárì láàyè láti pa Jerúsálẹ́mù run, ní lílò ó gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ Rẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, Bábílónì pẹ̀lú ni a óò pa run. Ní tòótọ́, ìwé Dáníẹ́lì gbé Jèhófà Ọlọ́run ga gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ àti Olùṣàkóso nínú “ìjọba aráyé.”—Dáníẹ́lì 4:17.
13, 14. Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì lẹ́yìn ìṣubú Bábílónì?
13 Dáníẹ́lì ń bá iṣẹ́ lọ ní ààfin fún nǹkan bí àádọ́rin ọdún, títí tí Bábílónì fi ṣubú. Ó ṣì fojú rí bí púpọ̀ nínú
àwọn Júù ṣe ń padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ pé ó bá wọn lọ. Ó kéré tán, ó wà lẹ́nu iṣẹ́ títí di ọdún kẹta ìṣàkóso Kírúsì Ọba, olùdásílẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ní àkókò yẹn, ọjọ́ orí Dáníẹ́lì ti ní láti sún mọ́ ọgọ́rùn ún ọdún!14 Lẹ́yìn ìṣubú Bábílónì, Dáníẹ́lì kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣé pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀ sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wá jẹ́ apá pàtàkì kan nínú Bíbélì Mímọ́, a sì wá mọ̀ ọ́n sí ìwé Dáníẹ́lì. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ó fi yẹ kí a kíyè sí ìwé ìgbàanì yìí?
Ẹ̀KA MÉJÌ, ÌHÌN IṢẸ́ KAN ṢOṢO
15. (a) Ẹ̀ka méjì wo ni ó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì inú Bíbélì? (b) Báwo ni ẹ̀ka tí ó jẹ́ ìsọ̀tàn nínú Dáníẹ́lì ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
15 Ìwé Dáníẹ́lì aláìlẹ́gbẹ́ ní ẹ̀ka méjì tí ó yàtọ̀ síra pátápátá nínú—ọ̀kan jẹ́ ìsọ̀tàn, èkejì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka méjèèjì ìwé Dáníẹ́lì ni ó lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Báwo? Àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ ti ìsọ̀tàn—tí ó wà lára àwọn tí ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ jù lọ nínú Bíbélì—fi hàn wá pé Jèhófà Ọlọ́run yóò bù kún àwọn tí ó bá pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí i, yóò sì tọ́jú wọn. Gbọn-in gbọn-in ni Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dúró lójú àwọn àdánwò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wọn. Lónìí, gbígbé àpẹẹrẹ wọn yẹ̀ wò kínníkínní yóò fún gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lókun.
16. Ẹ̀kọ́ wo ni a kọ́ láti inú àwọn ẹ̀ka ti àsọtẹ́lẹ̀ nínú ìwé Dáníẹ́lì?
16 Àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì gbé ìgbàgbọ́ ró nípa fífihàn pé Jèhófà ti mọ bí ìtàn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún—àní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún—síwájú ṣe máa rí. Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí àwọn agbára ayé yóò ṣe máa dìde tí wọn yóò sì máa ṣubú látorí Bábílónì ìgbàanì títí dé “àkókò òpin.” (Dáníẹ́lì 12:4) Dáníẹ́lì pe àfiyèsí wa sí Ìjọba Ọlọ́run ní ọwọ́ Ọba tí Ó yàn àti “àwọn ẹni mímọ́” alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ó sì tọ́ka sí i pé òun nìkan ni ìjọba tí yóò wà títí láé. Ìjọba yìí yóò mú ète Jèhófà fún ilẹ̀ ayé wa ṣẹ ní kíkún yóò sì yọrí sí ìbùkún fún gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ láti sin Ọlọ́run.—Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14, 22.
17, 18. (a) Báwo ni àyẹ̀wò kínníkínní nínú ìwé Dáníẹ́lì yóò ṣe fún ìgbàgbọ́ wa lókun? (b) Ọ̀ràn wo ni ó yẹ kí a jíròrò kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí nínú Bíbélì?
17 A dúpẹ́ pé Jèhófà kò fi ìmọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ “Olùṣí àwọn àṣírí payá.” (Dáníẹ́lì 2:28) Bí a ṣe ń gbé ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú ìwé Dáníẹ́lì yẹ̀ wò, a óò fún ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run lókun. Yóò túbọ̀ dá wa lójú hán-ún hán-ún sí i pé Ọlọ́run yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ ní àkókò rẹ̀ gẹ́lẹ́ àti ní ọ̀nà tí ó yàn gan-an.
18 Gbogbo àwọn tí ó bá fi ọkàn tí ó dára kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Dáníẹ́lì nínú Bíbélì ni ìgbàgbọ́ wọn yóò túbọ̀ pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n kí a tó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò jinlẹ̀jinlẹ̀ nínú ìwé yìí, ó yẹ kí a gbé àwọn ẹ̀rí yẹ̀ wò ní ti bóyá ìwé yìí ṣeé gbà gbọ́ lóòótọ́. Àwọn olùṣelámèyítọ́ kan ti gbógun ti ìwé Dáníẹ́lì, wọ́n sọ pé lẹ́yìn tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ti ní ìmúṣẹ ni a kọ wọ́n. Ohun tí àwọn oníyèméjì yìí ń sọ ha lẹ́sẹ̀-ń-lẹ̀ bí? Àkòrí tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò ọ̀ràn yìí.
KÍ LO LÓYE?
• Èé ṣe tí Dáníẹ́lì fi jẹ́ ìwé kan tí ó wà fún àkókò òde òní?
• Báwo ni Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe dé ẹnú iṣẹ́ ìjọba Bábílónì?
• Kí ni iṣẹ́ àkànṣe tí a fún Dáníẹ́lì ṣe ní Bábílónì?
• Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]