Ìdìde àti Ìṣubú Ère Arabarìbì Kan
Orí Kẹrin
Ìdìde àti Ìṣubú Ère Arabarìbì Kan
1. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí Nebukadinésárì Ọba kó Dáníẹ́lì àti àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn?
ỌDÚN mẹ́wàá ti kọjá lẹ́yìn ìgbà tí Nebukadinésárì Ọba kó Dáníẹ́lì àti àwọn mìíràn “tí ó wà ní ipò iwájú ní ilẹ̀” Júdà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. (2 Àwọn Ọba 24:15) Dáníẹ́lì ọ̀dọ́ ń sìn ní ààfin ọba nígbà tí ipò kan tí ń fẹ̀mí ẹni wewu yọjú. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí èyí gbàfiyèsí wa? Nítorí pé kì í ṣe pé ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run gbà dá sí ọ̀ràn náà gba ẹ̀mí Dáníẹ́lì àti àwọn yòókù là nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ kí a rí bí àwọn agbára ayé ti inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe tò tẹ̀ léra wọn títí dé ìgbà tiwa.
ỌBA KAN KO ÌṢÒRO LÍLEKOKO KAN
2. Ìgbà wo ni Nebukadinésárì lá àlá alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́?
2 Wòlíì Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Ní ọdún kejì ìgbà àkóso Nebukadinésárì, Nebukadinésárì lá àwọn àlá; ṣìbáṣìbo sì bá ẹ̀mí rẹ̀, oorun rẹ̀ sì di èyí tí ó fò lọ.” (Dáníẹ́lì 2:1) Nebukadinésárì ọba Ilẹ̀ Ọba Bábílónì ni ó lá àlá náà. Ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run gbà á láyè kí ó pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, ni ó di olùṣàkóso ayé láìsí àní-àní. Ní ọdún kejì ìṣàkóso Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé (ọdún 606 sí 605 ṣááju Sànmánì Tiwa), Ọlọ́run rán àlá akó-jìnnìjìnnì-báni kan sí i.
3. Àwọn wo ni kò lè túmọ̀ àlá ọba, báwo sí ni Nebukadinésárì ṣe fèsì?
3 Àlá yìí kó ìdààmú bá Nebukadinésárì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi lè sùn. Bí a ṣe lè retí, ó hára gàgà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ọba alágbára náà ti gbàgbé àlá náà! Nítorí náà, ó ké sí àwọn pidánpidán, alálùpàyídà àti àwọn oṣó Bábílónì, Dáníẹ́lì 2:2-14.
ó sì ní dandan ni kí wọ́n rọ́ àlá náà kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Iṣẹ́ yìí kọjá agbára wọn. Kíkùnà tí wọ́n kùnà láti ṣe èyí mú inú Nebukadinésárì ru tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi pàṣẹ pé “kí wọ́n pa gbogbo ọlọ́gbọ́n Bábílónì run.” Àṣẹ yìí ni ó gbé wòlíì Dáníẹ́lì pàdé ẹni tí a ní kí ó pa wọ́n. Èé ṣe? Nítorí pé a ka òun àti àwọn Hébérù alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà—mọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì.—DÁNÍẸ́LÌ YỌ WỌ́N NÍNÚ EWU
4. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe mọ ohun tí àlá Nebukadinésárì jẹ́ àti ìtumọ̀ rẹ̀? (b) Kí ni Dáníẹ́lì sọ láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run?
4 Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti mọ ìdí tí Nebukadinésárì fi pàṣẹ lílekoko yìí, ó “wọlé, ó sì béèrè pé kí ọba fún òun ní àkókò kan ní pàtó láti fi ìtumọ̀ náà gan-an han ọba.” A yọ̀ǹda èyí fún un. Dáníẹ́lì padà sí ilé rẹ̀, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó jẹ́ Hébérù sì gbàdúrà, wọ́n sì béèrè “fún àánú lọ́wọ́ Ọlọ́run ọ̀run nípa àṣírí yìí.” Nínú ìran kan ní òru yẹn gan-an, Jèhófà ṣí àṣírí àlá yẹn payá. Ní fífi ìmoore hàn, Dáníẹ́lì sọ pé: “Kí a fi ìbùkún fún orúkọ Ọlọ́run láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí ọgbọ́n àti agbára ńlá—wọ́n jẹ́ tirẹ̀. Ó sì ń yí ìgbà àti àsìkò padà, ó ń mú àwọn ọba kúrò, ó sì ń fi àwọn ọba jẹ, ó ń fi ọgbọ́n fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó mọ ìfòyemọ̀. Ó ń ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ àti àwọn ohun tí ó pa mọ́ payá, ó mọ ohun tí ó wà nínú òkùnkùn; ìmọ́lẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” Dáníẹ́lì fìyìn fún Jèhófà nítorí irú òye inú bẹ́ẹ̀.—Dáníẹ́lì 2:15-23.
5. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe gbé ògo fún Jèhófà nígbà tí ó dé iwájú ọba? (b) Èé ṣe tí a fi nífẹ̀ẹ́ sí àlàyé Dáníẹ́lì lónìí?
5 Lọ́jọ́ kejì, Dáníẹ́lì lọ bá Áríókù, olórí ẹ̀ṣọ́ tí a yàn láti pa àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì run. Bí Áríókù ṣe gbọ́ pé Dáníẹ́lì lè túmọ̀ àlá náà, kíá ni ó mú un lọ sọ́dọ̀ ọba. Láìgbé ògo fún ara rẹ̀, Dáníẹ́lì sọ fún Nebukadinésárì pé: “Ọlọ́run Dáníẹ́lì 2:24-30.
kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀ fún Ọba Nebukadinésárì.” Kì í ṣe kìkì ọjọ́ iwájú Ilẹ̀ Ọba Bábílónì nìkan ni Dáníẹ́lì ti ṣe tán láti ṣí payá, ó tún ṣe tán láti la ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé lẹ́sẹẹsẹ láti ọjọ́ Nebukadinésárì títí dé ìgbà tiwa àti ré kọjá ìgbà tiwa.—ÀLÁ NÁÀ—Ó WÁ SÍ ÌRÁNTÍ
6, 7. Kí ni àlá tí Dáníẹ́lì mú wá sí ìrántí ọba?
6 Nebukadinésárì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe ń ṣàlàyé pé: “Ìwọ ọba, ó ṣẹlẹ̀ pé o rí i, sì kíyè sí i! ère arabarìbì kan. Ère yẹn, tí ó tóbi, tí ìtànyòò rẹ̀ sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, dúró ní iwájú rẹ, ìrísí rẹ̀ sì múni kún fún ìbẹ̀rùbojo. Ní ti ère yẹn, orí rẹ̀ jẹ́ wúrà dáradára, igẹ̀ àti apá rẹ̀ jẹ́ fàdákà, ikùn àti itan rẹ̀ sì jẹ́ bàbà, ojúgun rẹ̀ jẹ́ irin, ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin, apá kan amọ̀ tí a ṣù. Ìwọ wò ó títí a fi gé òkúta kan jáde tí kì í ṣe nípasẹ̀ ọwọ́, ó sì kọlu ère náà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ irin àti amọ̀ tí a ṣù, ó sì fọ́ wọn túútúú. Ní àkókò yẹn, irin, amọ̀ tí a ṣù, bàbà, fàdákà àti wúrà, lápapọ̀, ni a fọ́ túútúú bí ìyàngbò láti ilẹ̀ ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹ̀fúùfù sì gbé wọn lọ tí ó fi jẹ́ pé a kò rí ipasẹ̀ wọn rárá. Àti ní ti òkúta tí ó kọlu ère náà, ó di òkè ńlá tí ó tóbi, ó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Dáníẹ́lì 2:31-35.
7 Ẹ wo bí inú Nebukadinésárì ṣe máa dùn tó bí ó ṣe ń gbọ́ bí Dáníẹ́lì ṣe ń ṣí àlá náà payá! Ṣùgbọ́n dúró ná! Àyàfi bí Dáníẹ́lì bá tún sọ ìtumọ̀ àlá yẹn nìkan ni a fi lè dá àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì sí. Ní ṣíṣojú fún ara rẹ̀ àti àwọn Hébérù ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Dáníẹ́lì polongo pé: “Èyí ni àlá náà, a ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ níwájú ọba.”—Dáníẹ́lì 2:36.
ÌJỌBA TÍ ÒGO RẸ̀ TAYỌ
8. (a) Ta ni tàbí kí ni Dáníẹ́lì túmọ̀ orí wúrà sí? (b) Ìgbà wo ni orí wúrà náà di èyí tí ó wà?
8 “Ìwọ ọba, ọba àwọn ọba, ìwọ ẹni tí Ọlọ́run ọ̀run ti fún ní ìjọba, agbára ńlá, okun àti iyì, tí ó sì fi àwọn Dáníẹ́lì 2:37, 38) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀ fún Nebukadinésárì lẹ́yìn tí Jèhófà ti lò ó láti pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ọba tí ń gorí ìtẹ́ ní Jerúsálẹ́mù ń wá láti ìlà Dáfídì, ọba tí Jèhófà fòróró yàn. Jerúsálẹ́mù jẹ́ olú ìlú Júdà, ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, tí ń ṣojú fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Bí a ṣe pa ìlú ńlá náà run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ yìí kò sí mọ́. (1 Kíróníkà 29:23; 2 Kíróníkà 36:17-21) Àwọn agbára ayé, ní ìtòtẹ̀léra, tí àwọn apá onírúurú irin ara ère náà dúró fún, lè wá máa ṣàkóso ayé lọ láìsí pé kí ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ dá sí i. Gẹ́gẹ́ bí orí wúrà, ohun bí irin tí a mọ̀ pé ó níye lórí jù lọ nígbàanì, Nebukadinésárì ti tayọ ní ti pé òun ni ó dojú ìjọba yẹn dé nípa pípa tí ó pa Jerúsálẹ́mù run.—Wo “Ọba Ajagun Kan Gbé Ilẹ̀ Ọba Kan Ró,” ní ojú ewé kẹtàlélọ́gọ́ta.
ẹranko inú pápá àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá ojú ọ̀run lé lọ́wọ́, tí ó sì ti fi ṣe olùṣàkóso lórí gbogbo wọn ní ibikíbi tí ọmọ aráyé ń gbé, ìwọ alára ni orí wúrà náà.” (9. Kí ni orí wúrà náà dúró fún?
9 Nebukadinésárì, tí ó ṣàkóso fún ọdún mẹ́tàlélógójì, ni ó jẹ́ olórí ìlà ìdílé tí ọba tí ń ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì ti ń wá. Nábónídọ́sì tí ó jẹ́ ọkọ ọmọ rẹ̀, àti ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí, Efili-méródákì, wà nínú èyí. Ìlà ìdílé tí ọba ti ń wá náà ṣì ń bá a lọ fún ọdún mẹ́tàlélógójì sí i, títí dìgbà ikú Bẹliṣásárì ọmọ Nábónídọ́sì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. (2 Àwọn Ọba 25:27; Dáníẹ́lì 5:30) Nípa báyìí, kì í ṣe Nebukadinésárì nìkan ni orí wúrà ti ère inú àlá yẹn dúró fún bí kò ṣe gbogbo ìlà àwọn ọba tí ń ṣàkóso Bábílónì.
10. (a) Báwo ni àlá Nebukadinésárì ṣe fi hàn pé Agbára Ayé Bábílónì kì yóò wà pẹ́ títí? (b) Kí ni wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹni tí ó ṣẹ́gun Bábílónì? (d) Lọ́nà wo ni Mídíà òun Páṣíà fi rẹlẹ̀ sí Bábílónì?
10 Dáníẹ́lì sọ fún Nebukadinésárì pé: “Lẹ́yìn rẹ, ìjọba Dáníẹ́lì 2:39) Ìjọba tí igẹ̀ àti apá fàdákà ère náà ṣàpẹẹrẹ ni yóò gba àkóso tẹ̀ lé ìlà ìdílé Nebukadinésárì tí ń jọba. Ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú, Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìjọba yìí, kódà, ó dárúkọ ọba ibẹ̀ tí yóò ṣẹ́gun—Kírúsì. (Aísáyà 13:1-17; 21:2-9; 44:24–45:7, 13) Èyí ni Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mídíà òun Páṣíà gbé ọ̀làjú ńlá tí kò rẹ̀yìn sí ti Ilẹ̀ Ọba Bábílónì kalẹ̀, a fi ìjọba yẹn wé fàdákà, ohun bí irin tí kò níye lórí tó wúrà. Ìjọba yẹn rẹlẹ̀ sí ti Agbára Ayé Bábílónì ní ti pé kò ní àmì ìtayọ ti dídojú Júdà, tí ó jẹ́ ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, tí olú ìlú rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù dé.
mìíràn yóò dìde, èyí tí ó rẹlẹ̀ sí ọ.” (11. Ìgbà wo ni ìlà ìdílé Nebukadinésárì tí ń jọba dópin?
11 Dáníẹ́lì fojú rí òpin ìlà ìdílé Nebukadinésárì tí ń jọba ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí ó túmọ̀ àlá náà. Dáníẹ́lì wà níbẹ̀ ní òru October 5 tàbí 6, 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà gba Bábílónì tí ó dà bí èyí tí a kò lè borí, tí wọ́n sì pa Bẹliṣásárì Ọba. Ní kíkú tí Bẹliṣásárì kú, orí wúrà ère inú àlá náà—Ilẹ̀ Ọba Bábílónì—kò sí mọ́.
ÌJỌBA KAN DÁ ÀWỌN ÌGBÈKÙN SÍLẸ̀
12. Báwo ni àṣẹ tí Kírúsì pa ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ṣe ṣe àwọn Júù tí ó wà nígbèkùn láǹfààní?
12 Mídíà òun Páṣíà gbapò Ilẹ̀ Ọba Bábílónì gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tí ń ṣàkóso ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ní ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta, Dáríúsì ará Mídíà di olùṣàkóso àkọ́kọ́ ní ìlú Bábílónì tí a ṣẹ́gun. (Dáníẹ́lì 5:30, 31) Òun àti Kírúsì ará Páṣíà jùmọ̀ ṣàkóso lórí Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà fún ìgbà kúkúrú. Nígbà tí Dáríúsì kú, Kírúsì nìkan wá di olórí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Abẹ́ ìṣàkóso Kírúsì ni a ti dá àwọn Júù tí ó wà ní Bábílónì sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn. Ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Kírúsì gbé àṣẹ kan jáde, èyí ni ó yọ̀ǹda fún àwọn Júù tí ó wà nígbèkùn ní Bábílónì láti padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn kí wọ́n sì tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. Àmọ́, a kò tún ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ gbé kalẹ̀ ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.—2 Kíróníkà 36:22, 23; Ẹ́sírà 1:1–2:2a.
13. Kí ni igẹ̀ àti apá ère inú àlá Nebukadinésárì dúró fún?
13 Igẹ̀ àti apá fàdákà ère inú àlá náà dúró fún ìlà àwọn ọba Páṣíà bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kírúsì Ńlá. Ìlà àwọn ọba náà wà pẹ́ tó igba ọdún. Kírúsì ni a gbà gbọ́ pé ó kú nígbà tí ó ń jagun ní ọdún 530 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lára àwọn ọba méjìlá tí ó jẹ tẹ̀ lé e lórí ìtẹ́ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, ó kéré tán, méjì hùwà tí ó dára sí àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ àyànfẹ́ Jèhófà. Ọ̀kan ni Dáríúsì Kìíní (ará Páṣíà), òmíràn sì ni Atasásítà Kìíní.
14, 15. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Dáríúsì Ńlá àti Atasásítà Kìíní ṣe fún àwọn Júù?
14 Dáríúsì Kìíní ni ìkẹta ní ìlà àwọn ọba Páṣíà lẹ́yìn Kírúsì Ńlá. Àwọn méjì tí ó ṣáájú rẹ̀ ni Kambáísísì Kejì àti arákùnrin rẹ̀ Bádíyà (tàbí àlùfáà Mídíà òun Páṣíà kan tí ó fèrú jọba tí ń jẹ́ Gáúmátà). Nígbà tí Dáríúsì Kìíní, tí a tún mọ̀ sí Dáríúsì Ńlá, fi gorí ìtẹ́ ní ọdún 521 ṣááju Sànmánì Tiwa, abẹ́ ìfòfindè ni iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù wà. Nígbà tí Dáríúsì ṣàwárí àkọsílẹ̀ kan tí àṣẹ Kírúsì wà nínú rẹ̀ ní ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní Ekibátánà, ohun tí ó ṣe ní ọdún 520 ṣááju Sànmánì Tiwa ju mímú ìfòfindè náà kúrò lọ. Ó tún pèsè owó láti inú ìṣúra ọba pé kí wọ́n fi tún tẹ́ńpìlì náà kọ́.—Ẹ́sírà 6:1-12.
15 Olùṣàkóso Páṣíà mìíràn tí ó tún ran àwọn Júù lọ́wọ́ nínú ìsapá wọn láti ṣe ìmúbọ̀sípò ni Atasásítà Kìíní, tí ó gbapò baba rẹ̀ Ahasuwérúsì (Sásítà Kìíní) ní ọdún 475 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àpèlé Atasásítà ni Longimanus nítorí pé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gùn ju ti òsì. Ní ọdún ogún ìṣàkóso rẹ̀, ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó fi Nehemáyà, Dáníẹ́lì 9:24-27; Nehemáyà 1:1; 2:1-18.
Júù kan tí ó jẹ́ agbọ́tí rẹ̀, jẹ gómìnà Júdà, ó sì ní kí ó tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́. Ìgbésẹ̀ yìí ni ó jẹ́ àmì ìbẹ̀rẹ̀ ‘àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún’ tí a là lẹ́sẹẹsẹ nínú orí kẹsàn-án ìwé Dáníẹ́lì, ó sì tọ́ka ìgbà tí ìfarahàn àti ikú Mèsáyà, tàbí Kristi, Jésù ti Násárétì yóò jẹ́.—16. Ìgbà wo ni Agbára Ayé Mídíà òun Páṣíà dópin, ọba wo sì ni ó jẹ kẹ́yìn níbẹ̀?
16 Èyí tí ó kẹ́yìn nínú àwọn ọba mẹ́fà tí ó jẹ tẹ̀ lé Atasásítà Kìíní lórí ìtẹ́ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ni Dáríúsì Kẹta. Ìṣàkóso rẹ̀ dópin lójijì lọ́dún 331 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun rẹ̀ kanlẹ̀ ní Gaugamela, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Nínéfè ìgbàanì. Ìṣẹ́gun yìí ni ó fòpin sí Agbára Ayé ti Mídíà òun Páṣíà tí a fi apá tí ó jẹ́ fàdákà lára ère inú àlá Nebukadinésárì ṣàpẹẹrẹ. Agbára tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ tayọ ní àwọn ọ̀nà kan, síbẹ̀ ó rẹlẹ̀ ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Èyí ṣe kedere bí a ṣe ń gbọ́ bí Dáníẹ́lì ṣe túmọ̀ àlá Nebukadinésárì síwájú sí i.
ÌJỌBA KAN—Ó GBÒÒRÒ ṢÙGBỌ́N Ó RẸLẸ̀
17-19. (a) Agbára ayé wo ni ikùn àti itan bàbà ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni ìṣàkóso rẹ̀ ṣe gbòòrò tó? (b) Ta ni Alẹkisáńdà Kẹta? (d) Báwo ni èdè Gíríìkì ṣe di èdè tí a ń sọ láti orílẹ̀-èdè kan sí ìkejì, kí sì ni ìlò rẹ̀ dára fún?
17 Dáníẹ́lì sọ fún Nebukadinésárì pé ikùn àti itan ère arabarìbì náà pa pọ̀ jẹ́ “ìjọba mìíràn, ẹ̀kẹta, tí ó jẹ́ ti bàbà, tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Dáníẹ́lì 2:32, 39) Ìjọba kẹta yìí ni yóò tẹ̀ lé ti Bábílónì àti Mídíà òun Páṣíà. Bí bàbà ṣe rẹlẹ̀ sí fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba tuntun yìí yóò ṣe rẹlẹ̀ sí ti Mídíà òun Páṣíà ní ti pé a kò ní fi àǹfààní kankan, irú bí pé kí ó dá àwọn ènìyàn Jèhófà sílẹ̀, dá a lọ́lá. Àmọ́, ìjọba tí ó dà bí bàbà yìí yóò “ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,” tí ó fi hàn pé yóò gbòòrò ju yálà ti Bábílónì tàbí ti Mídíà òun Páṣíà lọ. Kí ni ẹ̀rí òkodoro ìtàn fi hàn nípa agbára ayé yìí?
18 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà Kẹta, olùlépa àṣeyọrí, jogún ìtẹ́ ọba Makedóníà, lọ́dún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa, ní ẹni ogún ọdún, tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí ja ogun àjàṣẹ́gun káàkiri. Nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀ lójú ogun, a wá ń pè é ní Alẹkisáńdà Ńlá. Bí ó ṣe ń ti inú ìṣẹ́gun kan bọ́ sí òmíràn, ó ń bá a lọ láti wọnú ilẹ̀ àwọn ará Páṣíà. Nígbà tí ó ṣẹ́gun Dáríúsì Kẹta nínú ìjà ogun Gaugamela lọ́dún 331 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ilẹ̀ Ọba Páṣíà bẹ̀rẹ̀ sí fọ́, Alẹkisáńdà sì wá fìdí Gíríìsì múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tuntun.
19 Lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà ṣẹ́gun ní Gaugamela, ó tẹ̀ síwájú láti gba Bábílónì, Súsà, Persepolis àti Ekibátánà tí wọ́n jẹ́ olú ìlú Páṣíà. Bí ó ṣe borí apá yòókù Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, ó nasẹ̀ ìṣẹ́gun rẹ̀ wọnú ìwọ̀ oòrùn Íńdíà. A dá àwọn ibi tí Gíríìkì ń tòkèèrè ṣàkóso sílẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí a ṣẹ́gun. Bí èdè Gíríìkì àti àṣà wọn ṣe tàn ká àgbègbè àkóso yẹn nìyẹn. Lóòótọ́, Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì di èyí tí ó pọ̀ ju èyíkéyìí tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìjọba tí ó jẹ́ bàbà náà “ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àbájáde kan tí èyí mú wá ni pé Gíríìkì (Koine) di èdè tí a ń sọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè. Níwọ̀n bí ó ti ṣeé lò láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó péye, ó wá di èyí tí ó dára láti lò fún kíkọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì àti fún títan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀.
20. Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà Ńlá?
20 Ọdún mẹ́jọ péré ni Alẹkisáńdà Ńlá fi wà láàyè gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ṣì ni Alẹkisáńdà tí ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, àìsàn kọlù ú lẹ́yìn àsè kan, ó sì kú gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà ní June 13, ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ó ṣe, ilẹ̀ ọba rẹ̀ tí ó pọ̀ lọ súà ni a pín sí àgbègbè ìpínlẹ̀ mẹ́rin, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀gágun rẹ̀ sì ń ṣàkóso ọ̀kọ̀ọ̀kan. Bí ìjọba mẹ́rin ṣe ti inú ìjọba ńlá kan ṣoṣo jáde nìyẹn, tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù sì wá gbé wọn mì ní
àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Agbára ayé tí ó dà bí bàbà yìí ń bá a lọ títí di kìkì nǹkan bí ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí èyí tí ó kẹ́yìn lára ìjọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí—ìlà àwọn ọba láti ìdílé Ptolemy tí ń ṣàkóso ní Íjíbítì—fi ṣubú sọ́wọ́ Róòmù níkẹyìn.ÌJỌBA TÍ Ń FỌ́ NǸKAN TÚÚTÚÚ TÍ Ó SÌ Ń RÚN NǸKAN WÓMÚWÓMÚ
21. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe “ìjọba kẹrin”?
21 Dáníẹ́lì ń bá àlàyé rẹ̀ nípa ère inú àlá yẹn lọ pé: “Ní ti ìjọba kẹrin [lẹ́yìn Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, àti Gíríìsì], yóò le bí irin. Nítorí bí irin ti ń fọ́ ohun gbogbo mìíràn túútúú tí ó sì ń lọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni, bí irin tí ń rún nǹkan wómúwómú, yóò fọ́ àní gbogbo ìwọ̀nyí túútúú, yóò sì rún wọn wómúwómú.” (Dáníẹ́lì 2:40) Ní ti agbára àti ipá rẹ̀ láti fọ́ túútúú, agbára ayé yìí yóò dà bí irin—tí ó lágbára ju àwọn ilẹ̀ ọba tí a fi wúrà, fàdákà, tàbí bàbà ṣàpẹẹrẹ. Irú agbára bẹ́ẹ̀ ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù jẹ́.
22. Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe dà bí irin?
22 Róòmù fọ́ Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì túútúú, ó sì rún un wómúwómú, ó sì gbé àṣẹ́kù agbára ayé Mídíà òun Páṣíà àti Bábílónì mì. Láìkò bọ̀wọ̀ fún Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù Kristi polongo rẹ̀, ó fikú pa á lórí igi ìdálóró lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa. Nínú ìsapá Róòmù láti fọ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́ yángá, ó ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa.
23, 24. Ní àfikún sí Ilẹ̀ Ọba Róòmù, kí ni ẹsẹ̀ ère náà dúró fún?
23 Kì í ṣe kìkì Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ojúgun irin inú àlá Nebukadinésárì dúró fún, ó tún dúró fún àwọn ètò ìṣèlú tí ó tinú rẹ̀ jáde wá. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Ìṣípayá 17:10 pé: “Ọba méje ni ó sì ń bẹ: márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan tí ó kù kò tíì dé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.” Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílẹ̀, ó wà ní ìgbèkùn tí àwọn ará Róòmù gbé e sí ní erékùṣù kékeré ti Pátímọ́sì. Àwọn ọba tàbí agbára ayé márùn-ún tí ó ti ṣubú ni Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, àti Gíríìsì. Ìkẹfà—Ilẹ̀ Ọba Róòmù—ṣì wà lórí àlééfà nígbà náà. Ṣùgbọ́n òun pẹ̀lú yóò ṣubú, tí ọba keje yóò sì dìde láti inú ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ tí Róòmù ti gbà. Agbára ayé wo ni ìyẹn yóò jẹ́?
24 Tẹ́lẹ̀ rí, ilẹ̀ Britannia jẹ́ apá àríwá síhà ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ọdún 1763, ó di Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì—ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó ṣàkóso òkun méje. Ní nǹkan bí ọdún 1776, àwọn ilẹ̀ mẹ́tàlá ní Àríwá Amẹ́ríkà, tí ó jẹ́ ilẹ̀ àtòkèèrè-ṣàkóso fún un, polongo pé àwọn gba òmìnira, láti bàa lè dá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀. Àmọ́ ní àwọn ọdún ẹ̀yìn ìgbà náà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà di alájọṣepọ̀ nínú ogun àti àlàáfíà. Bí àpapọ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, ìyẹn agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ṣe wáyé nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ó jẹ́ èyí tí ó “le bí irin,” tí ó ń lo ọlá àṣẹ lọ́nà líle bí irin. Nípa báyìí, Ilẹ̀ Ọba Róòmù àti àpapọ̀ agbára ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni ó para pọ̀ jẹ́ ojúgun irin tí ère inú àlá náà ní.
ÀDÀPỌ̀ KAN TÍ Ó GBẸGẸ́
25. Kí ni Dáníẹ́lì sọ nípa ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà?
25 Dáníẹ́lì sọ fún Nebukadinésárì síwájú sí i pé: “Níwọ̀n bí ìwọ . . . ti rí ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ apá kan amọ̀ tí a ṣù ti amọ̀kòkò àti apá kan irin, ìjọba náà yóò pínyà, ṣùgbọ́n ohun kan bí líle ti irin yóò wà nínú rẹ̀, níwọ̀n bí ìwọ ti rí irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírin. Ní ti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀ tí a ṣù, ìjọba náà yóò ní agbára lápá kan, yóò sì jẹ́ èyí tí ó gbẹgẹ́ lápá kan. Níwọ̀n bí ìwọ ti rí irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírin, wọn yóò wá dà pọ̀ mọ́ ọmọ aráyé; ṣùgbọ́n wọn kì yóò lẹ̀ Dáníẹ́lì 2:41-43.
mọ́ra, èyí pẹ̀lú ìyẹn, gan-an gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè dà pọ̀ mọ́ amọ̀ tí a ṣù.”—26. Ìgbà wo ni ìṣàkóso tí ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ dúró fún yọjú?
26 Láti orí ni àwọn agbára ayé tí onírúurú ẹ̀yà ara ère inú àlá Nebukadinésárì dúró fún ti bẹ̀rẹ̀ sí tò tẹ̀ léra lọ sísàlẹ̀ títí dé ẹsẹ̀. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ “irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírin” yóò jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìṣàkóso ìkẹyìn ti aráyé, èyí tí yóò wà nígbà “àkókò òpin,” yóò ṣe rí.—Dáníẹ́lì 12:4.
27. (a) Irú ipò wo nínú ayé ni ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ dúró fún? (b) Kí ni àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́wàá tí ère náà ní dúró fún?
27 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ìdámẹ́rin àwọn olùgbé ayé ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso. Àwọn tí ilẹ̀ ọba mìíràn ní Yúróòpù ń ṣàkóso fi àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ju èyí lọ. Ṣùgbọ́n àbáyọrí Ogun Àgbáyé Kìíní ni pé àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ sí yọjú dípò àwọn ilẹ̀ ọba. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìtẹ̀sí yìí túbọ̀ yá kánkán sí i. Bí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ṣe ga sí i, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn orílẹ̀-èdè inú ayé ṣe pọ̀ sí i lọ́nà tí ó bùáyà. Ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti ère náà dúró fún gbogbo irú àwọn agbára àti ìjọba tí ó jùmọ̀ wà bẹ́ẹ̀, nítorí nínú Bíbélì, nígbà mìíràn, iye náà, mẹ́wàá, máa ń dúró fún ìpé pérépéré ní ti ohun ti ilẹ̀ ayé.—Fi wé Ẹ́kísódù 34:28; Mátíù 25:1; Ìṣípayá 2:10.
28, 29. (a) Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe wí, kí ni amọ̀ ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni a lè sọ nípa àdàpọ̀ irin àti amọ̀?
28 Bí a ti wà ní “àkókò òpin” nísinsìnyí, àkókò ìṣàkóso tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún ni a wà. Àwọn kan lára àwọn ìjọba tí ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà, tí ó jẹ́ irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀, dúró fún, le bí irin—abàṣẹwàá tàbí ti òṣìkà agbonimọ́lẹ̀. Àwọn mìíràn rí bí amọ̀. Lọ́nà wo? “Ọmọ aráyé” ni Dáníẹ́lì so amọ̀ pọ̀ mọ́. (Dáníẹ́lì 2:43) Láìka bí amọ̀ ṣe gbẹgẹ́ tó, èyí tí a fi dá ọmọ aráyé, ó ti di dandan fún àwọn ìjọba tí ó le bí irin látilẹ̀wá láti túbọ̀ fetí sí àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n ń fẹ́ máa lóhùn sí ohun tí ìjọba tí ń ṣàkóso lé wọn lórí ń ṣe. (Jóòbù 10:9) Ṣùgbọ́n àwọn ìjọba abàṣẹwàá àti àwọn mẹ̀kúnnù kò lẹ̀ mọ́ra—kò ju bí irin ṣe lè dà pọ̀ mọ́ amọ̀ lọ. Ní àkókò tí ère náà yóò parẹ́, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni ìṣèlú ayé máa pín sí ní ti tòótọ́!
29 Ṣé ìpínyà ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà ni yóò mú kí ère náà wó lulẹ̀ látòkè délẹ̀? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ère náà?
ÒTÉŃTÉ KAN TÍ Ó KÀMÀMÀ!
30. Ṣàpèjúwe òtéńté àlá Nebukadinésárì.
30 Gbé òtéńté àlá náà yẹ̀ wò. Dáníẹ́lì sọ fún ọba náà pé: “Ìwọ wò ó títí a fi gé òkúta kan jáde tí kì í ṣe nípasẹ̀ ọwọ́, ó sì kọlu ère náà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ irin àti amọ̀ tí a ṣù, ó sì fọ́ wọn túútúú. Ní àkókò yẹn, irin, amọ̀ tí a ṣù, bàbà, fàdákà àti wúrà, lápapọ̀, ni a fọ́ túútúú bí ìyàngbò láti ilẹ̀ ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹ̀fúùfù sì gbé wọn lọ tí ó fi jẹ́ pé a kò rí ipasẹ̀ wọn rárá. Àti ní ti òkúta tí ó kọlu ère náà, ó di òkè ńlá tí ó tóbi, ó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Dáníẹ́lì 2:34, 35.
31, 32. Kí ni a sọ tẹ́lẹ̀ ní ti apá tí ó kẹ́yìn nínú àlá Nebukadinésárì?
31 Láti ṣàlàyé èyí, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin; níwọ̀n bí ìwọ sì ti rí i tí òkúta kan gé kúrò lára òkè ńlá náà tí kì í ṣe nípasẹ̀ ọwọ́, tí ó sì fọ́ irin, bàbà, amọ̀ tí a ṣù, fàdákà àti wúrà túútúú. Ọlọ́run Atóbilọ́lá fúnra rẹ̀ ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí di mímọ̀ fún ọba. Àlá náà ṣeé fọkàn tẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”—Dáníẹ́lì 2:44, 45.
32 Ní rírí i pé a mú àlá òun wá sí ìrántí tí a sì ti ṣàlàyé Dáníẹ́lì 2:46-49) Àmọ́, lóde òní, kí ni ìjẹ́pàtàkì ‘ìtumọ̀ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé’ tí Dáníẹ́lì ṣe?
rẹ̀, Nebukadinésárì gbà pé Ọlọ́run Dáníẹ́lì nìkan ni “Olúwa àwọn ọba, ó sì jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.” Ọba yẹn tún gbé Dáníẹ́lì àti àwọn Hébérù alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sí ipò gíga. (‘ÒKÈ KAN KÚN AYÉ’
33. Láti inú “òkè ńlá” wo ni a ti gé “òkúta” náà, ìgbà wo àti báwo sì ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?
33 Nígbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin ní October 1914, “Ọlọ́run ọ̀run” gbé Ìjọba rẹ̀ ọ̀run kalẹ̀ nípa gbígbé Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi tí a fòróró yàn, sórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” * (Lúùkù 21:24; Ìṣípayá 12:1-5; 19:16) Bí ó ṣe jẹ́ nìyẹn, pé nípa agbára àtọ̀runwá ni, kì í ṣe nípa ọwọ́ ènìyàn, ni a fi gé “òkúta” Ìjọba Mèsáyà jáde láti ara “òkè ńlá” ipò ọba aláṣẹ àgbáyé ti Jèhófà. Ìjọba ọ̀run náà wà lọ́wọ́ Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run ti fi àìkú jíǹkí. (Róòmù 6:9; 1 Tímótì 6:15, 16) Nípa báyìí, “ìjọba Olúwa [Ọlọ́run] wa àti ti Kristi rẹ̀” yìí—ìfihàn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà—ni a kì yóò tún gbé fún ẹlòmíràn mọ́. Yóò dúró títí láé.—Ìṣípayá 11:15.
34. Báwo ni ó ṣe ṣẹlẹ̀ pé a bí Ìjọba Ọlọ́run “ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn”?
34 Ìbí Ìjọba náà ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn ọba tí a fi ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́wàá ère náà ṣàpẹẹrẹ nìkan kọ́ ni àwọn wọ̀nyí, àwọn ẹ̀yà tí a fi irin, bàbà, fàdákà àti wúrà rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ náà wà nínú wọn pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ilẹ̀ ọba Bábílónì, Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù ti ré kọjá gẹ́gẹ́ bí agbára ayé, àṣẹ́kù wọn ṣì wà ní ọdún 1914. Ní ìgbà yẹn, Ilẹ̀ Ọba Ottoman ti Turkey wà ní ibi tí Bábílónì wà, ìjọba ti orílẹ̀-èdè sì wà ní Páṣíà (Iran) àti Gíríìsì àti Róòmù, Ítálì.
35. Ìgbà wo ni “òkúta” náà yóò kọlu ère náà, báwo sì ni pípalẹ̀ ère náà mọ́ yóò ṣe mọ́ féfé tó?
Ìṣípayá 16:14, 16) Lẹ́yìn náà, bí òkúta náà tí ó tóbi títí ó fi rí bí òkè ńlá tí ó sì kún ilẹ̀ ayé, Ìjọba Ọlọ́run yóò di òkè ìjọba ńlá tí yóò nípa lórí “gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Dáníẹ́lì 2:35.
35 Láìpẹ́, Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run yóò kọlu ère ìṣàpẹẹrẹ yìí ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Nípa báyìí, gbogbo àwọn ìjọba tí a fi ère náà ṣàpẹẹrẹ ni a óò fọ́ túútúú, tí a óò sì mú wọn wá sí òpin. Ní tòótọ́, nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” bí agbára ìfọ́túútúú “òkúta” yẹn yóò ṣe ba ère náà yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi lọ̀ ọ́ kúnná bí ìyẹ̀fun, afẹ́fẹ́ ti ìjì Ọlọ́run yóò sì gbá a lọ bí ìyàngbò ilẹ̀ ìpakà. (36. Èé ṣe tí a fi lè pe Ìjọba Mèsáyà ní ìjọba tí ó dúró gbọin?
36 Bí Ìjọba Mèsáyà yìí tilẹ̀ jẹ́ ti ọ̀run, yóò nasẹ̀ agbára rẹ̀ síhà ayé wa fún ìbùkún gbogbo àwọn onígbọràn olùgbé ayé. Ìjọba tí ó dúró gbọin yìí ni “a kì yóò run láé” tàbí kí a “gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn.” Láìdàbí ìjọba àwọn alákòóso ènìyàn tí ó jẹ́ ẹni kíkú, “òun fúnra rẹ̀ yóò . . . dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin,” títí láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Ǹjẹ́ kí àǹfààní jíjẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ jẹ́ tìrẹ títí láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 33 Wo Orí Kẹfà ìwé yìí.
KÍ LO LÓYE?
• Àwọn agbára ayé wo ni onírúurú ẹ̀yà ara ère arabarìbì inú àlá Nebukadinésárì dúró fún?
• Irú ipò wo nínú ayé ni ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́wàá tí ó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ dúró fún?
• Ìgbà wo àti láti inú “òkè ńlá” wo ni a ti gé “òkúta” náà?
• Ìgbà wo ni “òkúta” náà yóò kọlu ère náà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwés 63-67]
ỌBA AJAGUN KAN GBÉ ILẸ̀ ỌBA KAN RÓ
ỌMỌ aládé Bábílónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Íjíbítì ti Fáráò Nékò yángá ní Kákémíṣì, ní Síríà. Àwọn ará Íjíbítì tí a ṣẹ́gun náà sá gba apá gúúsù lọ sí ọ̀nà Íjíbítì, àwọn ará Bábílónì bá lépa wọn. Ṣùgbọ́n ìhìn iṣẹ́ kan láti Bábílónì mú kí ó di dandan pé kí ọmọ aládé tí ó ṣẹ́gun náà jáwọ́ nínú ìlépa rẹ̀. Ìhìn náà ni pé baba rẹ̀, Nabopolassar, ti kú. Bí Nebukadinésárì ṣe fi iṣẹ́ kíkó àwọn òǹdè àti ẹrù àkótogunbọ̀ síkàáwọ́ àwọn ọ̀gágun rẹ̀ tán, ó padà sílé kíákíá, ó sì jókòó sórí ìtẹ́ tí baba rẹ̀ ti kúrò.
Bí Nebukadinésárì ṣe gorí ìtẹ́ Bábílónì ní ọdún 624 ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn, ó sì di olùṣàkóso kejì ní Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Tuntun. Nígbà ìṣàkóso rẹ̀ tí ó gba ọdún mẹ́tàlélógójì, ó gba àwọn ìpínlẹ̀ tí Agbára Ayé Ásíríà ti wà tẹ́lẹ̀ rí,
ó mú ilẹ̀ ọba rẹ̀ gbòòrò sí i, ó nasẹ̀ dé Síríà níhà àríwá àti Palẹ́sìnì níhà ìwọ̀-oòrùn títí dé ààlà Íjíbítì.—Wo àwòrán ilẹ̀.Ní ọdún kẹrin ìṣàkóso Nebukadinésárì (ọdún 620 ṣááju Sànmánì Tiwa), ó sọ Júdà di ìjọba tí ó wà ní abẹ́ àkóso rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 24:1) Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìṣọ̀tẹ̀ Júdà mú kí Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù. Nebukadinésárì mú Jèhóákínì, Dáníẹ́lì, àti àwọn mìíràn lóǹdè lọ sí Bábílónì. Ọba náà kó lára àwọn ohun èlò tẹ́ńpìlì Jèhófà dání lọ pẹ̀lú. Ó sọ Sedekáyà, arákùnrin òbí Jèhóákínì, di ọba Júdà lábẹ́ àkóso rẹ̀.—2 Àwọn Ọba 24:2-17; Dáníẹ́lì 1:6, 7.
Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn náà, Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, ní sísowọ́pọ̀ pẹ̀lú Íjíbítì. Nebukadinésárì bá tún sàga ti Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ó sì di ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó dá àlàfo sí odi rẹ̀, ó jó tẹ́ńpìlì, ó sì pa ìlú náà run. Ó pa gbogbo àwọn ọmọ Sedekáyà, ó sì wá fọ́ Sedekáyà lójú, ó dè é, kí ó lè mú un bí ẹlẹ́wọ̀n lọ sí Bábílónì. Èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn náà ni Nebukadinésárì mú lóǹdè, ó sì ru àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́ kù ní tẹ́ńpìlì lọ sí Bábílónì. “Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.”—Nebukadinésárì tún ṣẹ́gun Tírè nípa sísàga ti ìlú náà—ìsàgatì náà gba ọdún mẹ́tàlá. Nígbà ìsàgatì náà, orí àwọn ọmọ ogun “ni a mú pá” bí àṣíborí wọn ṣe ń rin wọn lórí, èjìká wọn ni a sì “mú bó” nípasẹ̀ ríru ẹrù àwọn ohun èlò tí wọ́n fi kọ́ ìsàgatì. (Ìsíkíẹ́lì 29:18) Níkẹyìn, Tírè túbá fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì.
Dájúdájú, ọba Bábílónì mọ bí a ti ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ jagun. Àwọn ìtọ́kasí inú àwọn àkọsílẹ̀, pàápàá èyí tí ó ti Bábílónì wá, tún ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba onídàájọ́ òdodo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ kò sọ ní ṣàkó pé Nebukadinésárì jẹ́ onídàájọ́ òdodo, wòlíì Jeremáyà sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀, wọn yóò hùwà dáadáa sí i ‘bí ó bá jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ aládé ọba Bábílónì.’ (Jeremáyà 38:17, 18) Àti pé lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, ìwà ọ̀wọ̀ ni Nebukadinésárì hú sí Jeremáyà. Ọba pàṣẹ nípa Jeremáyà pé: “Mú un, kí o sì fojú sí i lára, má sì ṣe nǹkan kan tí ó burú sí i rárá. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí òun bá ṣe wí fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe fún un.”—Jeremáyà 39:11, 12; 40:1-4.
Gẹ́gẹ́ bí olùṣàbójútó, kíá ni Nebukadinésárì rí àwọn ànímọ́ àti ohun tí Dáníẹ́lì lè ṣe àti ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì 1:6, 7, 19-21; 2:49.
rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò—tí orúkọ Hébérù wọn ń jẹ́ Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà. Nípa bẹ́ẹ̀, ọba lò wọ́n nínú ipò tí ó ní láárí nínú ìjọba rẹ̀.—Ní ti ìsìn, Mádọ́kì, olú ọlọ́run àwọn ará Bábílónì, ni Nebukadinésárì ń fún ní ìfọkànsìn rẹ̀ ní pàtàkì. Mádọ́kì ni ọba ń gbé ògo gbogbo ìṣẹ́gun rẹ̀ fún. Ní Bábílónì, ó kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì, ó sì ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́ fún Mádọ́kì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́run àjúbàfún mìíràn ní Bábílónì. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Mádọ́kì ni ó ya ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà sí mímọ́ fún. Ó sì dà bí pé Nebukadinésárì gbára lé iṣẹ́ wíwò gidigidi nígbà tí ó bá ń wéwèé àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ nínú ogun.
Ó tún jẹ́ ohun ìyangàn fún Nebukadinésárì pé ó mú Bábílónì, ìlú ńlá olódi tí ó tayọ ní ìgbà náà, padà bọ̀ sípò. Ní ti pé ó parí odi onílọ̀ọ́po méjì tí baba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Nebukadinésárì mú kí olú ìlú yìí dà bí ohun tí a kò lè borí. Ọba náà tún ògbólógbòó ààfin kan tí ó wà ní àárín gbùngbùn ìlú ńlá náà ṣe, ó sì kọ́ ààfin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan sí nǹkan bí kìlómítà
méjì síhà àríwá. A ròyìn rẹ̀ pé, láti lè tẹ́ ayaba rẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ Mídíà, tí ó ń yán hànhàn fún àwọn òkè àti igbó ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ́rùn, Nebukadinésárì kọ́ àwọn ọ̀gbà tí a so rọ̀—tí a kà sí ọ̀kan lára àwọn ohun ìyanu méje ayé ìgbàanì.Lọ́jọ́ kan, bí ọba ṣe ń rìn kiri ààfin Bábílónì, ó yangàn pé: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi? Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ṣì wà lẹ́nu ọba,” orí rẹ̀ dàrú. Kò lè ṣàkóso fún ọdún méje, ó sì ń jẹ ewéko, bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Ní òpin àkókò náà, a dá ìjọba padà fún Nebukadinésárì, ó sì ṣàkóso títí ó fi kú ní ọdún 582 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Dáníẹ́lì 4:30-36.
KÍ LO LÓYE?
Kí ni a lè sọ nípa Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bíi
• ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ nípa ogun jíjà?
• olùṣàbójútó?
• olùjọsìn Mádọ́kì?
• kọ́lékọ́lé?
[Àwòrán ilẹ̀]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ILẸ̀ ỌBA BÁBÍLÓNÌ
ÒKUN PUPA
Jerúsálẹ́mù
Odò Yúfírétì
Odò Tígírísì
Nínéfè
Súsà
Bábílónì
Úrì
[Àwòrán]
Bábílónì, ìlú ńlá olódi tí ó tayọ ní ìgbà náà lọ́hùn-ún
[Àwòrán]
Dírágónì ni àmì Mádọ́kì
[Àwòrán]
Àwọn ọgbà àsorọ̀ tí ó lókìkí ní Bábílónì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 56]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀWỌN AGBÁRA AYÉ INÚ ÀSỌTẸ́LẸ̀ DÁNÍẸ́LÌ
Ère arabarìbì náà (Dáníẹ́lì 2:31-45)
BABILÓNÍÀ láti ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa
MÍDÍÀ ÒUN PÁṢÍÀ láti ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa
GÍRÍÌSÌ láti ọdún 331 ṣááju Sànmánì Tiwa
RÓÒMÙ láti ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa
AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI AMẸ́RÍKÀ láti ọdún 1763 Sànmánì Tiwa
AYÉ TÍ Ó PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ NÍ TI Ọ̀RÀN ÌṢÈLÚ ní àkókò òpin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 47]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 58]