Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
Orí 9
Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
1. Kí ni ó máa ń jẹ́ ìmọ̀lára àwọn ènìyàn nígbà tí olólùfẹ́ kan bá kú?
“ÌYÀ máa ń jẹni nígbà tí olólùfẹ́ ẹni kan bá kú nítorí pé ikú jẹ́ àdánù kan tí ó rékọjá ohun tí a lè lóye.” Ohun tí ọmọkùnrin kan sọ nìyẹn nígbà tí màmá rẹ̀ kú kété lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Ìrora àti ìmọ̀lára àdánù jíjinlẹ̀ tí ó ní mú kí ó nímọ̀lára pé “ìmí-ẹ̀dùn ti bo òun mọ́lẹ̀.” Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti jìyà ní irú ọ̀nà kan náà. O lè ti ṣe kàyéfì nípa ibi tí àwọn olólùfẹ́ rẹ wà àti bóyá ìwọ yóò tún rí wọn mọ́.
2. Àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí wo ni ó ń dìde nípa àwọn òkú?
2 Àwọn òbí kan tí ń ṣọ̀fọ̀ ni a sọ fún pé, “Ọlọrun ń mú àwọn òdòdó tí ó lẹ́wà jùlọ láti wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ha rí nítòótọ́ bí? Àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú ha lọ sí ilẹ̀-ọba ẹ̀mí bí? Òun ha ni àwọn kan ń pè ní Nirvana, tí a ṣàpèjúwe bí ipò aláyọ̀ pípé kan níbi tí kò sí ìrora àti ìfẹ́-ọkàn? Àwọn tí a nífẹ̀ẹ́ ha ti gba ẹnu-ọ̀nà ìwàláàyè àìlèkú nínú paradise kọjá bí? Tàbí bí àwọn kan ti sọ, ikú ha jẹ́ ìjìyà ìdálóró aláìlópin fún àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe láìfí sí Ọlọrun bí? Àwọn òkú ha lè nípa lórí ìgbésí-ayé wa bí? Láti rí àwọn ìdáhùn tí ó jóòótọ́ sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, a níláti tọ Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lọ.
KÍ NI “Ẹ̀MÍ” TÍ Ó WÀ NÍNÚ Ẹ̀DÁ ÈNÌYÀN?
3. Èrò wo ni Socrates àti Plato ní nípa àwọn òkú, báwo sì ni èyí ṣe nípa lórí àwọn ènìyàn lónìí?
3 Àwọn ọ̀mọ̀ràn ilẹ̀ Griki náà Socrates àti Plato di ojú-ìwòye náà mú pé ohun kan gbọ́dọ̀ wà tí ó jẹ́ àìlèkú tí a jogúnbá nínú ọkùnrin àti obìnrin—ẹ̀mí kan tí ó la ikú já tí kì í sì í kú níti gidi. Yíká ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ gba èyí gbọ́ lónìí. Ìgbàgbọ́ yìí sì ti fa ìbẹ̀rù àwọn òkú bí ó ti ń fa ìdàníyàn fún ire àlàáfíà àwọn òkú. Bibeli kọ́ wa ní ohun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá nípa àwọn òkú.
4. (a) Kí ni ohun tí Genesisi sọ fún wa nípa ọkàn? (b) Kí ni ohun tí Ọlọrun fi sínú Adamu tí ó mú kí ó wàláàyè?
4 Ní gbígbé ipò àwọn òkú yẹ̀wò, a gbọ́dọ̀ rántí pé bàbá wa ìpilẹ̀ṣẹ̀, Adamu, kò ní ọkàn kan. Ó jẹ́ ọkàn kan. Nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, Ọlọrun mọ ènìyàn—ọkàn náà—láti inú àwọn èròjà inú ilẹ̀ tí ó sì mí “[èémí] ìyè” sínú rẹ̀. Genesisi 2:7 sọ fún wa pé: “OLUWA Ọlọrun sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn; ó sì mí [èémí] ìyè sí ihò imú rẹ̀; ènìyàn sì di alààyè ọkàn.” Ìwàláàyè Adamu ni èémí gbé dúró. Síbẹ̀, ohun tí ó ju fífẹ́ afẹ́fẹ́ sínú ẹ̀dọ̀fóró ènìyàn ni ó ní nínú nígbà tí Ọlọrun mí èémí ìyè sínú Adamu. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “ipá ìwàláàyè” tí ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀dá alààyè lórí ilẹ̀-ayé.—Genesisi 7:22, NW.
5, 6. (a) Kí ni “ipá ìwàláàyè”? (b) Kí ní ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí “ẹ̀mí” tí a mẹ́nukàn nínú Orin Dafidi 146:4 bá dẹ́kun pípèsè agbára fún ara?
5 Kí ni “ipá ìwàláàyè”? Ó jẹ́ ohun ṣíṣekókó tí ó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe tí Ọlọrun fi sínú ara aláìlẹ́mìí ti Adamu. Ipá yìí ni ọ̀nà tí a ń gbà mí èémí tì lẹ́yìn. Síbẹ̀, kí ni “ẹ̀mí” tí Orin Dafidi 146:4 tọ́ka sí? Ẹsẹ̀ yẹn sọ nípa ẹni tí ó kú pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.” Nígbà tí àwọn òǹkọ̀wé Bibeli lò ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” ní ọ̀nà yìí, wọn kò ní ẹ̀mí tí ó fi ara sílẹ̀ tí ó sì ń bá a lọ láàyè lẹ́yìn òde ara tí ó ti kú lọ́kàn.
6 “Ẹ̀mí” tí ó fi ara ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ nígbà ikú ni ipá ìwàláàyè tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa. (Orin Dafidi 36:9; Ìṣe 17:28) Ipá ìwàláàyè yìí kò ní èyíkéyìí lára àwọn àmì ànímọ́ ẹ̀dá tí ó ń gbé ṣiṣẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí iná mànàmáná kì í tií gbà lára àwọn irin-iṣẹ́ tí ó ń fún lágbára. Bí ẹnì kan bá kú, ẹ̀mí (ipá ìwàláàyè) dẹ́kun mímú àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara ṣiṣẹ́, bí iná ti máa ń kú nígbà tí a bá pa iná mànàmáná. Nígbà tí ipá ìwàláàyè kò bá ti ara ẹ̀dá ènìyàn lẹ́yìn mọ́, ènìyàn—ọkàn náà—yóò kú.—Orin Dafidi 104:29; Oniwasu 12:1, 7.
“ÌWỌ ÓÒ SÌ PADÀ DI ERÙPẸ̀”
7. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Adamu bí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọlọrun?
7 Ní kedere ni Jehofa ṣàlàyé ohun tí ikú yóò túmọ̀ sí fún Adamu ẹlẹ́ṣẹ̀. Ọlọrun sọ pé: “Ní òógùn ojú rẹ ni ìwọ óò máa jẹun, títí ìwọ óò fi padà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” (Genesisi 3:19) Níbo ni Adamu yóò padà sí? Sínú ilẹ̀, sí erùpẹ̀ láti ibi tí a ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Nígbà ikú Adamu yóò wulẹ̀ dẹ́kun wíwà ni!
8. Bí ọkàn, ọ̀nà wo ni àwọn ènìyàn kò fi lọ́lá ju ẹranko lọ?
8 Nínú ọ̀ràn yìí, ikú ẹ̀dá ènìyàn kò yàtọ̀ sí ti àwọn ẹranko. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ ọkàn, ẹ̀mí kan náà, tàbí ipá ìwàláàyè, ni ó sì ń fún wọn lókun. (Genesisi 1:24) Nínú Oniwasu 3:19, 20, ọlọ́gbọ́n ọkùnrin náà Solomoni sọ fún wa pé: “Bí èkínní ti ń kú bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; nítòótọ́ ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kò ní ọlá ju ẹran lọ [nígbà ikú]: . . . láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tún padà di erùpẹ̀.” Ènìyàn lọ́lá ju ẹranko lọ níti pé a dá a ní àwòrán Ọlọrun, ní gbígbé àwọn ànímọ́ Jehofa yọ. (Genesisi 1:26, 27) Síbẹ̀, nígbà ikú ẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko bákan náà ń padà di erùpẹ̀.
9. Kí ni ipò tí àwọn òkú wà, ibo sì ni wọ́n ń lọ?
9 Solomoni ṣàlàyé ohun tí ikú túmọ̀ sí síwájú síi, ní sísọ pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn òkú kò mọ ohun kankan páàpáà. Nítorí èyí, Solomoni rọ̀ wá pé: “Ohunkohun tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é; nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní [Ṣìọ́ọ̀lù, NW] níbi tí ìwọ ń rè.” (Oniwasu 9:5, 10) Níbo ni àwọn òkú ń lọ? Ṣìọ́ọ̀lù (Heberu, sheʼohlʹ) ni, àpapọ̀ isà-òkú aráyé. Àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú kò mọ ohunkóhun. Wọn kò jìyà, wọn kò sì lè nípa lórí wa lọ́nà èyíkéyìí.
10. Èéṣe tí a fi lè sọ pé kò yẹ kí ikú jẹ́ òpin rẹ̀?
10 Gbogbo wa àti àwọn olólùfẹ́ wa ha gbọ́dọ̀ wàláàyè fún kìkì ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà kí a ṣíwọ́ wíwàláàyè títí láé bí? Bibeli kò sọ bẹ́ẹ̀. Ní ìgbà ìṣọ̀tẹ̀ Adamu, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jehofa Ọlọrun ti gbé ìṣètò kan dìde láti yí abáyọrí bíbanilẹ́rù nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn padà. Ikú kì í ṣe apá kan ète Ọlọrun fún aráyé. (Esekieli 33:11; 2 Peteru 3:9) Nítorí náà, ikú kò níláti jẹ́ òpin rẹ̀ fún wa tàbí fún àwọn olólùfẹ́ wa.
‘Ó LỌ SINMI’
11. Báwo ni Jesu ṣe ṣàpèjúwe ipò Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó kú?
11 Ète Jehofa ni láti gba awa àti àwọn olólùfẹ́ wa tí ó ti kú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú tí a jogún láti ọ̀dọ̀ Adamu. Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tọ́ka sí àwọn tí ó kú bí ẹni pé wọ́n sùn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó gbọ́ pé Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kú, Jesu Kristi sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé: “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣugbọn mo ń rìnrìn-àjò lọ sí ibẹ̀ lati jí i kúrò lójú oorun.” Níwọ̀n bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò ti tètè lóye ìtumọ̀ gbólóhùn yìí, Jesu sọ ní tààràtà pé: “Lasaru ti kú.” (Johannu 11:11, 14) Lẹ́yìn náà Jesu lọ sí ìlú Betani, níbi tí Marta àti Maria àwọn arábìnrin Lasaru ti ń ṣọ̀fọ̀ ikú arákùnrin wọn. Nígbà tí Jesu sọ fún Marta pé, “Arákùnrin rẹ yoo dìde,” ó sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ jáde nínú ète Ọlọrun láti yí ipa tí ikú ní lórí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn padà. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé yoo dìde ninu àjíǹde ní ìkẹyìn ọjọ́.”—Johannu 11:23, 24.
12. Ìrètí wo ni Marta ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ní nípa àwọn òkú?
12 Marta kò sọ ohunkóhun nípa àìlèkú ọkàn tí ń wàláàyè nìṣó ní ibì kan lẹ́yìn ikú. Kò gbàgbọ́ pé Lasaru ti lọ sí ilẹ̀-ọba ẹ̀mí kan láti máa bá ìwàláàyè rẹ̀ nìṣó. Marta ní ìgbàgbọ́ nínú ìrètí àgbàyanu ti àjíǹde kúrò nínú ikú. Ó lóye pé arákùnrin rẹ̀ tí ó kú kò sí láàyè mọ́, kì í ṣe pé ọkàn àìlèkú kan ti fi ara Lasaru sílẹ̀. Ojútùú náà yóò jẹ́ jíjí arákùnrin rẹ̀ dìde.
13. Agbára wo tí Ọlọrun fifúnni ni Jesu ní, báwo ni ó sì ṣe fi agbára yìí hàn?
13 Jesu Kristi ni Jehofa Ọlọrun fún lágbára láti tún aráyé rà padà. (Hosea 13:14) Nítorí náà, ní ìdáhùnpadà sí ohun tí Marta sọ, Jesu sọ pé: “Emi ni àjíǹde ati ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu mi, bí ó tilẹ̀ kú, yoo yè.” (Johannu 11:25) Jesu fi agbára tí Ọlọrun fi fún un hàn ní ìhà yìí nígbà tí ó lọ sí ibojì Lasaru, ẹni tí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin, ó sì dá a pada sí ààyè. (Johannu 11:38-44) Wulẹ̀ ronú nípa ìdùnnú-ayọ̀ tí àwọn wọnnì tí wọ́n rí àjíǹde yìí àti àwọn mìíràn tí Jesu Kristi ṣe yóò ní!—Marku 5:35-42; Luku 7:12-16.
14. Èéṣe tí èrò àjíǹde àti ọkàn àìlèkú kò fi báramu?
14 Dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ kí o sì ronú jinlẹ̀ lórí èyí: Kì yóò sí ìdí láti jí ẹnikẹ́ni dìde, tàbí mú un padà sí ìwàláàyè, bí ọkàn àìlèkú kan bá wà lẹ́yìn ikú. Ní tòótọ́, kì yóò jẹ́ inúrere láti jí ẹnì kan bíi Lasaru dìde padà sí ìwàláàyè aláìpé nínú ayé bí ó bá jẹ́ pé ó ti rékọjá lọ sínú àgbàyanu èrè ọ̀run kan. Níti gàsíkíá, Bibeli kò fìgbà kan lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn àìlèkú.” Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ sọ pé ọkàn ènìyàn tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń kú. (Esekieli 18:4, 20) Nítorí náà, Bibeli fi ìpèsè àjíǹde hàn gẹ́gẹ́ bí ojútùú gidi kan fún ikú.
“GBOGBO AWỌN WỌNNÌ TÍ WỌ́N WÀ NINU AWỌN IBOJÌ ÌRÁNTÍ”
15. (a) Kí ni èdè ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” túmọ̀ sí? (b) Èéṣe tí àjíǹde àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan kò fi lè jẹ́ ìṣòro fún Jehofa Ọlọrun?
15 Ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lò fún “àjíǹde” túmọ̀ lóréfèé sí “gbígbé sókè” tàbí “dídìde sókè.” Èyí jẹ́ gbígbé sókè láti inú ipò àìlẹ́mìí ti ikú—dídìde sókè láti inú àpapọ̀ isà-òkú aráyé, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó rọrùn fún Jehofa Ọlọrun láti jí ẹnì kan dìde. Èéṣe? Nítorí pé Jehofa ni Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè. Lónìí, àwọn ènìyàn lè gba ohùn àti àwòrán àwọn ọkùnrin àti obìnrin sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì fídíò kí wọ́n sì gbé àwọn ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ wọ̀nyí jáde àní lẹ́yìn ikú ẹni náà pàápàá. Nígbà náà, ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa alágbára ńlá lè gba kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ kí ó sì jí ẹni náà gan-an dìde, ní fífún un ní ara mìíràn tí a túndá.
16. (a) Ìlérí wo ni Jesu ṣe nípa gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ibojì ìrántí? (b) Kí ni yóò pinnu bí àjíǹde ẹnì kan yóò ṣe yọrí sí?
16 Jesu Kristi wí pé: “Wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ [ti Jesu] wọn yoo sì jáde wá, awọn wọnnì tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, awọn wọnnì tí wọ́n sọ ohun bíburú jáì dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Johannu 5:28, 29) Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìrántí Jehofa ni a óò jí dìde tí a óò sì kọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Fún àwọn tí wọ́n gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun, èyí yóò yọrí sí àjíǹde ìyè. Bí ó ti wù kí ó rí, yóò yọrí sí àjíǹde ìdájọ́ ẹ̀bi fún àwọn wọnnì tí wọ́n kọ ẹ̀kọ́ àti ìṣàkóso Ọlọrun.
17. Àwọn wo ni a óò jí dìde?
17 Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn wọnnì tí wọ́n ti tọ ipa-ọ̀nà òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ni a óò jí dìde. Ní tòótọ́, ìrètí àjíǹde fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lókun láti dojúkọ ikú, àní nínú àwọn ọ̀ràn inúnibíni oníwà-ipá. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun yóò dá wọn padà sí ìwàláàyè. (Matteu 10:28) Ṣùgbọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti kú láìfihàn bóyá wọ́n yóò faramọ́ àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n òdodo Ọlọrun. A óò jí àwọn náà dìde pẹ̀lú. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú ète Jehofa nínú ọ̀ràn yìí, aposteli Paulu sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.”—Ìṣe 24:15.
18. (a) Ìran wo ni aposteli Johannu gbà nípa àjíǹde? (b) Kí ni a parun nínú “adágún iná náà,” kí sì ni “adágún” yìí ṣàpẹẹrẹ?
18 Aposteli Johannu rí ìran tí ń ru ìmọ̀lára sókè gbà nípa àwọn tí a jí dìde tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọrun. Johannu kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ awọn òkú wọnnì tí ń bẹ ninu rẹ̀ lọ́wọ́, ikú ati Hédíìsì sì jọ̀wọ́ awọn òkú wọnnì tí ń bẹ ninu wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹlu awọn iṣẹ́ wọn. A sì fi ikú ati Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná naa.” (Ìṣípayá 20:12-14) Wulẹ̀ ronú nípa ìyẹn! Gbogbo àwọn òkú tí ó wà nínú ìrántí Ọlọrun ni a tú sílẹ̀ kúrò nínú Hédíìsì (Griki, haiʹdes), tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, àpapọ̀ isà-òkú aráyé. (Orin Dafidi 16:10; Ìṣe 2:31) Wọn yóò ní àǹfààní láti fi hàn nípa ìṣe wọn bóyá wọn yóò jọ́sìn Ọlọrun. Lẹ́yìn náà, “ikú ati Hédíìsì” ni a óò fi sọ̀kò sínú ohun tí a pè ní “adágún iná,” tí ó ṣàpẹẹrẹ ìparun pátápátá, bí èdè ọ̀rọ̀ náà “Gẹ̀hẹ́nà” ti fi hàn. (Luku 12:5) Àpapọ̀ isà-òkú aráyé fúnra rẹ̀ ni a óò ti sọ dòfo tí yóò sì dẹ́kun wíwà nígbà tí àjíǹde náà bá ti parí. Ẹ wo bí ó ti ń tuni nínú tó láti kọ́ láti inú Bibeli pé Ọlọrun kì í dá ẹnikẹ́ni lóró!—Jeremiah 7:30, 31.
ÀJÍǸDE SÍ IBO?
19. Èéṣe tí a óò fi jí díẹ̀ lára aráyé dìde sí ọ̀run, irú ara wo sì ni Ọlọrun yóò fún wọn?
19 Àwọn ọkùnrin àti obìnrin kéréje kan ni a óò jí dìde sí ìwàláàyè ní ọ̀run. Bí àwọn ọba àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú Jesu, wọn yóò ṣàjọpín nínú yíyí gbogbo ìyọrísí ikú tí aráyé jogún láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Adamu, padà. (Romu 5:12; Ìṣípayá 5:9, 10) Àwọn mélòó ni Ọlọrun yóò mú lọ sí ọ̀run láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli, kìkì 144,000 péré ni. (Ìṣípayá 7:4; 14:1) Jehofa yóò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí a jí dìde wọ̀nyí ní ara ẹ̀mí kí wọ́n ba lè gbé ní ọ̀run.—1 Korinti 15:35, 38, 42-45; 1 Peteru 3:18.
20. Kí ni aráyé onígbọràn, títí kan àwọn tí a jí dìde, yóò nírìírí rẹ̀?
20 Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú yóò ní àjíǹde sí orí paradise ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 37:11, 29; Matteu 6:10) Apá kan lára ìdí fún jíjí àwọn kan dìde sí ọ̀run ni láti ṣe àṣeparí ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé. Jesu Kristi àti àwọn 144,000 ní ọ̀run ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yóò mú aráyé onígbọràn padàbọ̀ sí ìjẹ́pípé tí àwọn òbí wa ìpilẹ̀ṣẹ̀ sọnù. Èyí yóò ní nínú àwọn tí a jí dìde, bí a ti fi hàn nípa ohun tí Jesu sọ nígbà tí ó sọ fún ọkùnrin tí ń kú lọ tí a kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé: “Iwọ yoo wà pẹlu mi ní Paradise.”—Luku 23:42, 43.
21. Ní ìbámu pẹ̀lú wòlíì Isaiah àti aposteli Johannu, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ikú?
21 Lórí ilẹ̀-ayé tí a ti sọ di Paradise, ikú, tí ń fa irú ìmúlẹ̀mófo bẹ́ẹ̀ lónìí, ni a óò ti mú kúrò. (Romu 8:19-21) Wòlíì Isaiah polongo pé Jehofa Ọlọrun “óò gbé ikú mì láéláé.” (Isaiah 25:8) A fi ìran kan han aposteli Johannu nípa àkókò náà nígbà tí aráyé onígbọràn yóò nírìírí òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìrora àti ikú. Bẹ́ẹ̀ni, “Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu wọn. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:1-4.
22. Ipa wo ni ìmọ̀ nípa àjíǹde ní lórí rẹ?
22 Àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ṣe kedere láti inú Bibeli mú ìdàrúdàpọ̀ kúrò nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú. Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere pé ikú ni “ọ̀tá ìkẹyìn” tí a óò parun. (1 Korinti 15:26) Wo okun àti ìtùnú tí a lè rí fàyọ láti inú ìmọ̀ nípa ìrètí àjíǹde! Sì wo bí inú wa ti dùn tó pé àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọrun yóò jí láti inú oorun ikú láti gbádùn gbogbo àwọn ohun rere tí ó ní ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! (Orin Dafidi 145:16) Irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ ni Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe ní àṣeparí. Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni ìṣàkóso rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á wò ó.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Kí ni ẹ̀mí tí ó wà nínú àwọn ènìyàn?
Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe ipò tí àwọn òkú wà?
Àwọn wo ni a óò jí dìde?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 85]
Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti pe Lasaru láti inú ibojì, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 86]
Ìdùnnú-ayọ̀ yóò gbilẹ̀ nígbà tí ‘Ọlọrun bá gbé ikú mì láéláé’