Kí Ni Màá Fayé Mi Ṣe?
ORÍ 38
Kí Ni Màá Fayé Mi Ṣe?
“Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ò kọ́kọ́ jọ mí lójú. Àmọ́ bó ṣe kù díẹ̀ kí n jáde níléèwé ni mo wá rí i pé inú ayé lèmi náà mà ń lọ yìí, níbi tí màá ti máa ṣiṣẹ́ gidi, tí màá sì wá dẹni tó ń gbọ́ bùkátà ara mi.”—Alex.
JẸ́ KÁ sọ pé o fẹ́ rìnrìn àjò lọ síbì kan tó jìnnà síbi tó ò ń gbé. Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ wá ẹni tó máa júwe ọ̀nà fún ẹ kó o lè mọ ọ̀nà tó máa dáa jù lọ láti gbà. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn téèyàn bá ń ronú nípa ọjọ́ iwájú. Michael, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè yàn láti ṣe.” Báwo lo ṣe máa yan ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà fún ẹ láti yàn yẹn? Michael sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ sinmi lórí nǹkan tó o bá fi ṣe àfojúsùn ẹ.”
Máa wo àfojúsùn ẹ bí ibi tó ò ń lọ gan-an lẹ́nu ìrìn àjò ayé ẹ. Kò dájú pé wàá débẹ̀ tó o bá kàn ń rìn káàkiri lásán. Ohun tí ì bá sàn jù ni pé kó o rẹ́ni tó máa fọ̀nà hàn ẹ́, kó o sì pinnu ibi tó o fẹ́ gbà. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú ìwé Òwe 4:26 nìyẹn, níbi tó ti sọ pé: “Mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀.” Bíbélì Contemporary English Version túmọ̀ gbólóhùn yìí sí: “Mọ ibi tó o forí lé.”
Bọ́dún bá ṣe ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ ìpinnu pàtàkì lo máa ṣe nípa ìjọsìn, iṣẹ́, ìgbéyàwó, ìdílé, àtàwọn nǹkan pàtàkì míì. Ó máa rọrùn fún ẹ láti ṣàwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání tó o bá kọ́kọ́ mọ ibi tó ò ń lọ. Bó o sì ṣe ń ronú ohun tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe, nǹkan kan wà tó ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.
“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ”
Bó o bá fẹ́ láyọ̀ lóòótọ́, àfi kó o fọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ́kàn pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tó o ṣì wà ní ọ̀dọ́.” (Oníwàásù 12:1, ìtúmọ̀ Today’s English Version) Ìyẹn ni pé, fífẹ́ láti ṣe ohun tó wu Ọlọ́run ló yẹ kó pinnu nǹkan tó o máa fayé ẹ ṣe.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa fi ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo? Bíbélì sọ nínú Ìṣípayá 4:11 pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé àtọ̀run ló jẹ Ẹlẹ́dàá ní gbèsè ọpẹ́. Ṣó ò ń ṣọpẹ́ pé ó fún ẹ ní “ìyè àti èémí àti ohun gbogbo”? (Ìṣe 17:25) Ṣéyẹn ò wá mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pó yẹ kó o san nǹkan kan pa dà fún Jèhófà Ọlọ́run láti fi hàn pó o mọrírì gbogbo ohun tó ti ṣe fún ẹ?
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fi Ẹlẹ́dàá wọn sọ́kàn dáadáa, tí wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ yan iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Ṣàyẹ̀wò oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn tó o lè ṣe.
Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń lo wákàtí tó pọ̀ láti fi wàásù. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìrírí wọn máa ń sọ wọ́n di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ fífi Bíbélì kọ́ni.
Sísìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn kan ti kó lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn míì ti kọ́ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ tó ń sọ èdè àjèjì ládùúgbò wọn nígbà táwọn míì ti kó lọ sílẹ̀ àjèjì láti lọ wàásù níbẹ̀. *
Iṣẹ́ míṣọ́nnárì. A máa ń fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó bá kúnjú ìwọ̀n, tára wọn dá ṣáṣá, tí agbára wọn sì gbé iṣẹ́ ìsìn nílẹ̀ òkèèrè ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ìgbésí ayé wọn máa ń lárinrin, ó sì máa ń nítumọ̀.
Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń sìn láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lára iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe láwọn ilẹ̀ kan ni pé wọ́n máa ń tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, wọ́n sì máa ń kó wọn ránṣẹ́ sáwọn ìjọ.
Iṣẹ́ ìsìn kárí ayé. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn kárí ayé máa ń lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì láti lọ ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí la ti máa ń dá àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí kò tíì gbéyàwó, tó sì kúnjú ìwọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ àbójútó àti bá a ṣe ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀. Àwọn kan lára àwọn tó bá jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí máa ń lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè.
Ronú Bó O Ṣe Máa Ṣe É
Iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún gbayì lọ́pọ̀lọpọ̀, ìbùkún tó sì máa ń tibẹ̀ wá ò lóǹkà. Àmọ́, ó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ ronú nípa bó ṣe máa ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé, ‘Kí lohun tí mo lè ṣe, iṣẹ́ ọwọ́ wo ni mo sì mọ̀ tí mo lè máa fi gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ náà?’
Kelly fi ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà ṣe àfojúsùn rẹ̀, torí náà ó ti ronú irú iṣẹ́
tóun lè ṣe. Ó ní: “Àfi kí n kọ́ iṣẹ́ tí màá lè fi máa gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.”Kelly kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ kan nílé ẹ̀kọ́. Ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ kọ́wọ́ ẹ̀ tẹ àfojúsùn ẹ̀. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ló wù mí ṣe. Ipò kejì ni gbogbo nǹkan yòókù wà.” Kelly ò kábàámọ̀ pé òun yan iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Ó ní: “Mo mọ̀ pé kò sí ìpinnu míì tí mo lè ṣe tó máa dáa jùyẹn lọ.”
Béèrè Ìmọ̀ràn
Bó o bá ń rìnrìn àjò lọ síbi tó ò mọ̀ dáadáa, àfi kó o béèrè ọ̀nà. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú nígbà tó o bá ń ronú ohun tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe. Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Òwe 20:18 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”
Ọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ wà lára ibi pàtàkì tó o ti lè rí ìtọ́sọ́nà.
O sì tún lè gbàmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù. Roberto, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27], tó ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ yín tàbí láwọn ìjọ míì ládùúgbò ni kó o máa fi ṣe àwòkọ́ṣe.”Ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o bàa lè ṣe ìpinnu tó máa mú kó o láyọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbèésí ayé ẹ. Torí náà, sọ fún un pé kó jẹ́ kó o ‘máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́’ nípa ọjọ́ iwájú rẹ. (Éfésù 5:17) Nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, máa fọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 3:5, 6 sọ́kàn pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”
Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo DVD wa tó dá lórí ohun táwọn ọ̀dọ́ lè fayé wọn ṣe, ìyẹn, “Young People Ask—What Will I Do With My Life?” Ó lé ní ọgbọ̀n [30] èdè tá a fi ṣe é jáde
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“‘Dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’”—Málákì 3:10.
ÌMỌ̀RÀN
Bá àwọn tó ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ̀rọ̀. Béèrè ìdí tí wọ́n fi yàn láti máa ṣe irú iṣẹ́ yẹn àtàwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí lẹ́nu iṣẹ́ náà.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Bí agbára iná mànàmáná ṣe lè mú káwọn nǹkan abánáṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè mú kó o ṣàṣeyọrí ohun tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Ìṣe 1:8.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Kí n bàa lè túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ẹni tí màá bá sọ̀rọ̀ ni․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí làwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe?
● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fàwọn ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe wọ̀nyí yin Jèhófà?
● Èwo ló wù ẹ́ jù lọ nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tá a mẹ́nu kàn nínú orí yìí?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 313]
“Mo mọyì àwọn òbí mi gan-an ni. Bí iná ìtara wọn ò ṣe jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bí wọ́n ṣe fara da ipò ìṣúnná owó tí kò rọgbọ àti bí wọ́n ṣe fún mi níṣìírí láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”—Jarrod
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 314]
Tí mo kọ èrò mi sí
Àwọn Àfojúsùn Mi
Fàmì sáwọn ohun tó o bá fẹ́ fi ṣe àfojúsùn ẹ. Kọ ọ̀rọ̀ sáwọn àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí kó bàa lè bá ohun tó o fẹ́ mu tàbí kó o kúkú kọ àwọn nǹkan míì tó o fẹ́ fojú sùn.
Àfojúsùn Tó Jẹ Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù
□ Wákàtí ․․․․․ ni mo fẹ́ máa fi wàásù lóṣooṣù
□ Mo fẹ́ máa fi ìwé ․․․․․ sóde lóṣooṣù
□ Mo fẹ́ máa lo Bíbélì nígbà tí mo bá ń sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn èèyàn
□ Mo fẹ máa ṣe ìpadàbẹ̀wò ․․․․․ lóṣooṣù
□ Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Àwọn àfojúsùn míì: ․․․․․
Àfojúsùn Tó Jẹ Mọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́
□ Mo fẹ́ máa ka ojú ìwé ․․․․․ nínú Bíbélì lójoojúmọ́
□ Mo fẹ́ máa múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀
□ Mo fẹ́ ṣèwádìí lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ Bíbélì wọ̀nyí: ․․․․․
Àfojúsùn Nínú Ìjọ
□ Mo fẹ́ máa dáhùn nípàdé, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo
□ Mo fẹ́ bá àgbàlagbà kan tó wù mí kí n sún mọ́ sọ̀rọ̀
□ Mo fẹ́ lọ kí ará ìjọ wa kan tó jẹ́ àgbàlagbà tàbí aláìlera
Àwọn àfojúsùn míì:
Déètì Òní ․․․․․
Pa dà yẹ àwọn nǹkan tó o kọ síbí yìí wo lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, kó o lè mọ bó o ṣe ṣe sí. Kó o ṣàwọn àtúnṣe tó bá yẹ tàbí kó o fi kún àwọn àfojúsùn rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 312]
Bó o bá ní àfojúsùn, o ò kàn ní máa sáré láìkúrò lójú kan