Ayé Yìí Kò Lè Ranni Lọ́wọ́
Orí Kẹrìnlélógún
Ayé Yìí Kò Lè Ranni Lọ́wọ́
1, 2. (a) Èé ṣe tí jìnnìjìnnì fi bo àwọn ará Jerúsálẹ́mù? (b) Lójú ìṣòro tí Jerúsálẹ́mù dojú kọ, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè?
JÌNNÌJÌNNÌ bo àwọn ará Jerúsálẹ́mù, kò sì lè ṣe kó máà rí bẹ́ẹ̀ o! Ásíríà, ilẹ̀ ọba tó lágbára jù lọ lásìkò yẹn, ti kọ lu “gbogbo ìlú ńlá olódi Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbà wọ́n.” Àwọn erìkìnà tó sì ń jagun fún Ásíríà yìí ló ti wá ń fẹjú mọ́ olú ìlú Júdà báyìí. (2 Àwọn Ọba 18:13, 17) Kí ni Hesekáyà Ọba àti àwọn ará Jerúsálẹ́mù yòókù yóò ṣe?
2 Níwọ̀n bí àwọn ìlú ńláńlá ní ilẹ̀ náà ti ṣubú, Hesekáyà mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù ò lè bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà alágbára figẹ̀ wọngẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, òṣìkà àti oníjàgídíjàgan tó burú jù lọ làwọn èèyàn mọ àwọn ará Ásíríà sí. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè yẹn sì jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé nígbà mìíràn, àní àwọn alátakò ò tiẹ̀ ní dúró jà rárá kí wọ́n tó kán lùgbẹ́! Bí ewu yìí sì ṣe wá dojú kọ Jerúsálẹ́mù, ibo làwọn ará ibẹ̀ wá fẹ́ yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Ǹjẹ́ ọ̀nà kankan wà tí wọ́n fi lè bọ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà? Kí ló sì gbé àwọn èèyàn Ọlọ́run dé irú ipò yẹn? Láti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a ní láti ṣàyẹ̀wò ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, kí a sì wo ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá orílẹ̀-èdè tí ó bá dá májẹ̀mú lò ní àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá.
Ìpẹ̀yìndà ní Ísírẹ́lì
3, 4. (a) Ìgbà wo ni wọ́n pín orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sí ìjọba méjì, báwo ni wọ́n sì ṣe pín in? (b) Ohun burúkú wo ni Jèróbóámù fi bẹ̀rẹ̀ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá?
3 Orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni ẹ̀yà méjèèjìlá Ísírẹ́lì para pọ̀ jẹ́ láti
ìgbà tí Ísírẹ́lì ti kúrò ní Íjíbítì títí dìgbà ikú Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, díẹ̀ sì ni àkókò yẹn fi ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún péré. Bí Sólómọ́nì ṣe kú tán, ni Jèróbóámù bá kó ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá sòdí, láti ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì, láti ìgbà yẹn lọ lorílẹ̀-èdè yẹn sì ti pín sí ìjọba méjì. Èyí wáyé lọ́dún 997 ṣááju Sànmánì Tiwa.4 Jèróbóámù ló kọ́kọ́ jọba nínú ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá, bẹ́ẹ̀ ló sì mú kí àwọn èèyàn ìjọba rẹ̀ di apẹ̀yìndà ní ti pé ó lọ dá ẹgbẹ́ àlùfáà tí kò bófin mu àti ètò ìjọsìn ọmọ màlúù sílẹ̀ dípò ipò àlùfáà ti ìdílé Áárónì àti ìjọsìn Jèhófà tó bófin mu. (1 Àwọn Ọba 12:25-33) Ìríra gbáà lèyí jẹ́ lójú Jèhófà. (Jeremáyà 32:30, 35) Ìdí yìí àti àwọn ìdí mìíràn ló fi yọ̀ǹda kí Ásíríà tẹ Ísírẹ́lì lórí ba. (2 Àwọn Ọba 15:29) Hóséà Ọba gbìyànjú láti ṣẹ́ àjàgà Ásíríà, ó lọ bá Íjíbítì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, ṣùgbọ́n ìpètepèrò yẹn kùnà.—2 Àwọn Ọba 17:4.
Ísírẹ́lì Yíjú sí Ààbò Irọ́
5. Ta ni Ísírẹ́lì yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?
5 Jèhófà fẹ́ mú kí Ísírẹ́lì ronú wò. * Ìyẹn ló fi fi ìkìlọ̀ yìí rán wòlíì Aísáyà sí wọn pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì fún ìrànwọ́, àwọn tí ó gbójú lé ẹṣin lásán-làsàn, tí wọ́n sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun, nítorí tí wọ́n pọ̀ níye, àti sínú ẹṣin ogun, nítorí tí wọ́n jẹ́ alágbára ńlá gan-an, ṣùgbọ́n tí wọn kò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, tí wọn kò sì wá Jèhófà tìkára rẹ̀.” (Aísáyà 31:1) Èyí mà burú o! Ísírẹ́lì lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun dípò Jèhófà Ọlọ́run alààyè. Èrò Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara ni pé ẹṣin àwọn ará Íjíbítì pọ̀ rẹpẹtẹ, wọ́n sì lágbára. Áà, ó dájú pé Íjíbítì á ṣeé bá lẹ̀dí àpò pọ̀ gan-an ni láti dojú ìjà kọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà! Àmọ́, láìpẹ́, Ísírẹ́lì yóò rí i pé ìmúlẹ̀mófo ni àjọṣe tóun lọ bá Íjíbítì ẹlẹ́ran ara wọ̀.
6. Èé ṣe tí yíyíjú tí Ísírẹ́lì yíjú sí Íjíbítì fi fi hàn pé wọn ò gba Jèhófà gbọ́ rárá?
Ẹ́kísódù 24:3-8; 1 Kíróníkà 16:15-17) Yíyíjú tí Ísírẹ́lì sì yíjú sí Íjíbítì fún ìrànlọ́wọ́, ńṣe ló ń fi hàn pé òun ò gba Jèhófà gbọ́, àti pé òun ò ka àwọn òfin tó jẹ́ ara májẹ̀mú mímọ́ yẹn sí. Èé ṣe? Nítorí pé, ara ohun tó wà nínú májẹ̀mú tí wọ́n jọ dá ni pé, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò dáàbò bo àwọn èèyàn òun bí wọ́n bá ń fún òun ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Léfítíkù 26:3-8) Lóòótọ́, bí Jèhófà sì ṣe ṣèlérí, léraléra ló ti jẹ́ “odi agbára wọn ní àkókò wàhálà.” (Sáàmù 37:39; 2 Kíróníkà 14:2, 9-12; 17:3-5, 10) Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà ti gbẹnu Mósè, ẹni tó jẹ́ alárinà májẹ̀mú Òfin, sọ fún àwọn tí yóò bá jọba ní Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe kó ẹṣin jọ fún ara wọn. (Diutarónómì 17:16) Bí àwọn ọba wọ̀nyí bá ṣègbọràn sí ìlànà yìí, yóò fi hàn pé ààbò “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì” ni wọ́n gbójú lé. Ó wá ṣeni láàánú pé àwọn ọba Ísírẹ́lì ò ní irú ìgbàgbọ́ yẹn.
6 Ipasẹ̀ májẹ̀mú Òfin làwọn ará Ísírẹ́lì àti ti Júdà fi wọ àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, èyí tó ń béèrè ìyara-ẹni-sọ́tọ̀. (7. Ẹ̀kọ́ wo ni ìwà àìnígbàgbọ́ Ísírẹ́lì kọ́ àwọn Kristẹni lóde òní?
7 Àwọn Kristẹni òde òní lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí. Ísírẹ́lì lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹyìn tó ṣeé fojú rí lọ́dọ̀ Íjíbítì dípò gbígbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹyìn Jèhófà, èyí tó lágbára gidigidi ju ìyẹn lọ. Bákan náà ni lóde òní, àwọn Kristẹni lè fẹ́ fi àwọn ohun ti ara, ìyẹn owó tí wọ́n ní ní báńkì, ipò wọn láwùjọ, jíjẹ́ ojúlùmọ̀ àwọn ẹni kàǹkà-kàǹkà nínú ayé, ṣe ààbò ti wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé dípò kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Lóòótọ́, àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé a máa fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn láti pèsè àwọn nǹkan ti ara fún ìdílé wọn. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́, wọn kì í gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wọn karí àwọn ohun ti ara. Wọ́n sì máa ń ṣọ́ra fún “gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:13-21) Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni “ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.”—Sáàmù 9:9; 54:7.
8, 9. (a) Bí àwọn ète Ísírẹ́lì tiẹ̀ dà bí ẹní bójú mu, kí ni yóò yọrí sí, èé sì ti ṣe? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìlérí ọmọ aráyé àti ìlérí Jèhófà?
Aísáyà 31:2) Àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì lè rò pé àwọn gbọ́n. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé kò borí tẹni gbogbo? Lóòótọ́, bí a bá fojú ti èèyàn wò ó, ó bójú mu bí Ísírẹ́lì ṣe pète láti wá ìrànlọ́wọ́ Íjíbítì. Àmọ́, bíbá tó bá orílẹ̀-èdè yẹn wọ irú àjọṣe yẹn jẹ́ ìwà panṣágà nípa tẹ̀mí lójú Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 23:1-10) Nípa bẹ́ẹ̀, Aísáyà sọ pé Jèhófà yóò “mú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù wá.”
8 Nípa báyìí, Aísáyà wá ń fi àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì tó lọ bá Íjíbítì ṣe àdéhùn yẹn ṣẹlẹ́yà, ó ní: “Òun sì gbọ́n pẹ̀lú, yóò sì mú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù wá, kì yóò sì kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ; ṣe ni òun yóò sì dìde sí ilé àwọn aṣebi àti lòdì sí ìrànwọ́ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.” (9 Ìlérí ọmọ aráyé kò ṣeé gbára lé rárá, bẹ́ẹ̀ ni ààbò láti ọ̀dọ̀ ọmọ ènìyàn kò lágbẹ̀ẹ́kẹ̀lé. Ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, kò sóhun tó lè mú un “kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ.” Yóò ṣe àwọn ohun tó bá ṣèlérí dandan ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í padà sọ́dọ̀ rẹ̀ láìṣẹ.—Aísáyà 55:10, 11; 14:24.
10. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì àti Ísírẹ́lì?
10 Ṣé àwọn ará Íjíbítì yóò jẹ́ ààbò tí Ísírẹ́lì lè gbára lé? Rárá o. Aísáyà sọ fún Ísírẹ́lì pé: “Àmọ́ ṣá o, ará ayé ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í sì í ṣe Ọlọ́run; ẹran ara sì ni àwọn ẹṣin wọn, wọn kì í sì í ṣe ẹ̀mí. Jèhófà alára yóò sì na ọwọ́ rẹ̀, ṣe ni ẹni tí ń fúnni ní ìrànlọ́wọ́ yóò sì kọsẹ̀, ẹni tí a ń ràn lọ́wọ́ yóò sì ṣubú, lẹ́ẹ̀kan náà gbogbo wọn yóò sì wá sí òpin.” (Aísáyà 31:3) Ṣe ni ẹni tó ń fúnni ní ìrànlọ́wọ́ (Íjíbítì) àti ẹni tí a ń ràn lọ́wọ́ (Ísírẹ́lì) yóò jọ kọsẹ̀, wọn yóò ṣubú, wọn yóò sì wá sópin nígbà tí Jèhófà bá na ọwọ́ rẹ̀, nípa lílo Ásíríà láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ.
Ìṣubú Samáríà
11. Kí ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ísírẹ́lì dá jọ, kí ló sì yọrí sí?
11 Nítorí àánú Jèhófà, léraléra ló ń rán àwọn wòlíì láti lọ rọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì padà wá máa ṣe ìsìn mímọ́ gaara. (2 Àwọn Ọba 17:13) Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni Ísírẹ́lì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ màlúù tó ń sìn, ó lọ ń woṣẹ́, ó ń ṣe ìsìn oníṣekúṣe ti Báálì, ó ń lo òpó ọlọ́wọ̀, ó sì ṣe àwọn ibi gíga. Àní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ ń mú “àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn la iná kọjá,” ní fífi ọmọ bíbí tiwọn fúnra wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà ẹ̀mí èṣù. (2 Àwọn Ọba 17:14-17; Sáàmù 106:36-39; Ámósì 2:8) Láti mú kí ìwà burúkú Ísírẹ́lì wá sópin, Jèhófà pàṣẹ pé: “Samáríà àti ọba rẹ̀ ni a ó pa lẹ́nu mọ́ dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí ó ti dá gbọ́n-ún sí ojú omi.” (Hóséà 10:1, 7) Lọ́dún 742 ṣááju Sànmánì Tiwa, agbo ọmọ ogun Ásíríà kọ lu Samáríà, olú ìlú Ísírẹ́lì. Wọ́n sàga ti Samáríà fún ọdún mẹ́ta kó tó ṣubú, bí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá sì ṣe pa rẹ́ nìyẹn lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa.
12. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà pa láṣẹ lónìí, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ṣàìka ìkìlọ̀ yẹn sí?
12 Lọ́jọ́ tiwa yìí, Jèhófà pàṣẹ pé kí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé di ṣíṣe, láti fi kìlọ̀ “fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà.” (Ìṣe 17:30; Mátíù 24:14) Àwọn tó bá kọ ohun tí Ọlọ́run ń lò láti fi gbani là, yóò dà bí “ẹ̀ka igi tí ó ti dá gbọ́n-ún,” wọn yóò sì pa run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà. Àmọ́ o, àwọn tó bá nírètí nínú Jèhófà “yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Nígbà náà, ó mà bọ́gbọ́n mu o, pé ká yàgò fún àwọn àṣìṣe ìjọba Ísírẹ́lì àtijọ́! Ẹ jẹ́ ká gbára lé Jèhófà pátápátá fún ìgbàlà.
Agbára Tí Jèhófà Fi Ń Gbani Là
13, 14. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Jèhófà sọ fún Síónì?
13 Kìlómítà mélòó kan péré ni Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Júdà, wà sí ààlà Ísírẹ́lì níhà gúúsù. Kedere sì ni àwọn ará Jerúsálẹ́mù mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Samáríà. Wàyí o, wọ́n wá rí i pé ọ̀tá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan náà tó pa ìkejì wọn níhà àríwá run ló ti ń fẹjú mọ́ àwọn náà báyìí. Ṣé wọ́n á fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Samáríà ṣàríkọ́gbọ́n?
14 Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e tu àwọn ará Jerúsálẹ́mù nínú. Ó mú un dá wọn lójú pé Jèhófà ṣì fẹ́ràn àwọn èèyàn tí ó bá dá májẹ̀mú, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ti ń kùn hùn-ùn, àní ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀, lórí Aísáyà 31:4) Bí ìgbà tí ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún bá dúró ti ẹran tó pa, ni Jèhófà yóò ṣe dáàbò bo Síónì ìlú mímọ́ rẹ̀ lójú méjèèjì. Kò sí irú ẹnu tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà lè fọ́n, kò sí ìhàlẹ̀ tàbí arukutu kankan tí wọ́n lè fà tí yóò mú kí Jèhófà yẹhùn lórí ète rẹ̀.
ẹran ọdẹ rẹ̀, nígbà tí a bá pe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn olùṣọ́ àgùntàn jáde sí i, láìka ohùn wọn sí, kì yóò jáyà, láìka arukutu wọn sí, kì yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; bákan náà ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ja ogun ní tìtorí Òkè Ńlá Síónì àti ní tìtorí òkè kékeré rẹ̀.’” (15. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìyọ́nú mú àwọn ará Jerúsálẹ́mù?
15 Wàyí o, ṣàkíyèsí ọwọ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú tí Jèhófà yóò fi mú àwọn ará Jerúsálẹ́mù, ó ní: “Bí àwọn ẹyẹ tí ń fò, bákan náà ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò gbèjà Jerúsálẹ́mù. Ní gbígbèjà rẹ̀, dájúdájú, òun yóò dá a nídè pẹ̀lú. Ní dídá a sí, òun yóò mú kí ó sá àsálà pẹ̀lú.” (Aísáyà 31:5) Ìyá ẹyẹ a máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà láti lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀. A máa rà bàbà lókè orí àwọn ọmọ rẹ̀, a sì máa wò yíká wọn léraléra láti lè ṣàkíyèsí ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ àmì ewu. Bí ohunkóhun bá sì fẹ́ gbé ọmọ rẹ̀, kíá ni yóò já ṣòòròṣò wálẹ̀ láti wá gbèjà àwọn ọmọ rẹ̀. Bákan náà ni Jèhófà yóò ṣe bójú tó àwọn ará Jerúsálẹ́mù lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ nítorí àwọn ará Ásíríà tó ṣígun tọ̀ wọ́n wá.
“Ẹ Padà”
16. (a) Kí ni Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ àwọn èèyàn rẹ̀ láti ṣe? (b) Ìgbà wo ni ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ará Júdà kúkú wá hàn kedere? Ṣàlàyé.
16 Jèhófà wá rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé wọ́n ṣẹ̀, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, ó ní: “Ẹ padà sọ́dọ̀ Ẹni tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ jinlẹ̀ nínú ìdìtẹ̀ sí.” (Aísáyà 31:6) Ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá nìkan kọ́ ló ṣọ̀tẹ̀. Àwọn ará Júdà, tó jẹ́ “ọmọ Ísírẹ́lì” bákan náà, ti “lọ jinlẹ̀ nínú ìdìtẹ̀.” Èyí kúkú wá hàn kedere nígbà tí Mánásè ọmọ Hesekáyà jọba láìpẹ́ sí ìgbà tí Aísáyà parí iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “Mánásè sì ń bá a nìṣó ní sísún Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù dẹ́ṣẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (2 Kíróníkà 33:9) Áà, èyí mà burú o! Tìtorí ìwà ìbàjẹ́ akóni-nírìíra tí àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ń hù ni Jèhófà fi pa wọ́n rẹ́, síbẹ̀, ìwà àwọn ará Júdà tó bá Jèhófà wọ májẹ̀mú, tiẹ̀ tún burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lọ.
17. Ọ̀nà wo ni ipò ayé òde òní fi jọ ipò tó wà ní Júdà láyé ìgbà Mánásè?
17 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, onírúurú ọ̀nà ni ipò ayé fi jọ ipò tó wà ní Júdà láyé ìgbà Mánásè. Ìkórìíra nítorí pé ẹ̀sìn yàtọ̀ síra, nítorí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti nítorí pé ìran yàtọ̀ síra túbọ̀ ń ya ayé nípa síra wọn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti fara gbá nínú ọ̀nà tó burú jáì táráyé gbà ń hùwà ìṣìkàpànìyàn, ìdánilóró, ìfipábáni-lòpọ̀ àti ìwà kí ẹ̀yà kan dìde láti run àwọn tí wọ́n kà sí àdàmọ̀dì láàárín ẹ̀yà tiwọn. Láìsí àní-àní, àwọn èèyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè ti “lọ jinlẹ̀ nínú ìdìtẹ̀,” pàápàá àwọn orílẹ̀-èdè tó láwọn ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gba kí ìwà ibi máa bá a lọ gbére. Èé ṣe? Ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà Aísáyà ló fi hàn bẹ́ẹ̀.
Ó Gba Jerúsálẹ́mù Sílẹ̀
18. Ìkìlọ̀ wo ni Rábúṣákè fún Hesekáyà?
18 Àwọn ọba Ásíríà a máa gbógo ìṣẹ́gun wọn lójú ogun fún àwọn òrìṣà wọn. Àwọn ohun tí Aṣọbánípà kọ sílẹ̀ wà nínú ìwé Ancient Near Eastern Texts, òun ni ọba Ásíríà tó sọ pé atọ́nà òun ni “Áṣúrì, Bélì, Nébò, àwọn òrìṣà ńláńlá, àwọn olúwa [òun], tó ń bá [òun] rìn láìyẹsẹ̀, [nígbà tóun] ń ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun (tó gbówọ́) . . . lójú ìjà àjàkú-akátá.” Nígbà tí Rábúṣákè, tó jẹ́ aṣojú Senakéríbù ọba Ásíríà, ń bá Hesekáyà Ọba sọ̀rọ̀ nígbà ayé Aísáyà, ó fi hàn pé òun gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà a máa dá sí ogun táráyé bá ń jà. Ó kìlọ̀ fún ọba àwọn Júù yẹn pé kó ṣíwọ́ gbígbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ìgbàlà, ó sì sọ pé òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò rí ohunkóhun ṣe láti dáàbò bo àwọn èèyàn wọn lọ́wọ́ àwọn erìkìnà ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà alágbára.—2 Àwọn Ọba 18:33-35.
19. Kí ni ìṣarasíhùwà Hesekáyà sí ìṣáátá Rábúṣákè?
19 Kí ni Hesekáyà Ọba wá ṣe nípa rẹ̀? Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Hesekáyà Ọba gbọ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora, ó sì wá sínú ilé Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 19:1) Hesekáyà mọ̀ pé Ẹnì kan ṣoṣo ló lè ran òun lọ́wọ́ nínú ipò tó bani lẹ́rù yìí. Ló bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà.
20. Kí ni Jèhófà yóò ṣe fún àwọn ará Júdà, ẹ̀kọ́ wo ló sì yẹ kí èyí kọ́ wọn?
20 Jèhófà wá fún un ní ìtọ́sọ́nà tó ń wá. Jèhófà gbẹnu Aísáyà wòlíì sọ̀rọ̀, ó ní: “Ní ọjọ́ yẹn, olúkúlùkù yóò kọ àwọn Aísáyà 31:7) Nígbà tí Jèhófà bá gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ ni àṣírí àwọn òrìṣà Senakéríbù yóò wá tú pé aláìníláárí gbáà ni wọ́n. Fèyíkọ́gbọ́n ló yẹ kí ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ fáwọn ará Júdà. Pẹ̀lú gbogbo bí Hesekáyà Ọba ṣe jẹ́ olóòótọ́ yẹn náà, bámúbámú ni ilẹ̀ Júdà kún fún àwọn òrìṣà bí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Aísáyà 2:5-8) Kí àjọṣe àwọn ará Júdà pẹ̀lú Jèhófà tó lè padà máa lọ geerege, wọ́n ní láti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí “olúkúlùkù” wọn sì “kọ àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí” sílẹ̀.—Wo Ẹ́kísódù 34:14.
ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, èyí tí a fi fàdákà ṣe àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò níye lórí, èyí tí a fi wúrà ṣe, èyí tí ọwọ́ yín ti ṣe fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀.” (21. Báwo ni Aísáyà ṣe fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe èèmọ̀ tí Jèhófà máa fojú àwọn ará Ásíríà rí?
21 Aísáyà wá fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe èèmọ̀ tí Jèhófà máa fojú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ọ̀tá Júdà rí, ó ní: “Ará Ásíríà yóò sì ṣubú nípa idà, tí kì í ṣe ti ènìyàn; idà kan, tí kì í ṣe ti ará ayé sì ni yóò jẹ ẹ́ run. Yóò sì sá lọ nítorí idà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ yóò wá wà fún òpò àfipámúniṣe pàápàá.” (Aísáyà 31:8) Nígbà tí ìjà yìí bẹ́ sílẹ̀, àwọn ará Jerúsálẹ́mù ò tiẹ̀ ṣòpò yọ idà nínú àkọ̀ wọn rárá. Idà ti jẹ àwọn akọgun láàárín agbo ọmọ ogun Ásíríà run, idà tènìyàn kọ́ o, ti Jèhófà ni. Ní ti Senakéríbù ọba Ásíríà, sísá ni “yóò sì sá lọ nítorí idà.” Nígbà tó di pé áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára àwọn jagunjagun rẹ̀, ló bá kọrí sílé. Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń tẹrí ba fún Nísírọ́kì òrìṣà rẹ̀ lọ́wọ́, ni àwọn ọmọ òun fúnra rẹ̀ pa á.—2 Àwọn Ọba 19:35-37.
22. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Kristẹni òde òní lè rí kọ́ látinú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Hesekáyà àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà?
22 Títí kan Hesekáyà, kò sí ẹnikẹ́ni tó mọ ọ̀nà tí Jèhófà yóò gbà gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Ásíríà. Síbẹ̀síbẹ̀, ọwọ́ tí Hesekáyà fi mú ìṣòro yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún àwọn tó bá dojú kọ àdánwò lóde òní. (2 Kọ́ríńtì ) Lóòótọ́, ẹ̀rù ba Hesekáyà o, nítorí ìwà ìkà burúkú táwọn èèyàn mọ̀ mọ àwọn ará Ásíríà tó ń fẹjú mọ́ Jerúsálẹ́mù. ( 4:16-182 Àwọn Ọba 19:3) Síbẹ̀síbẹ̀, ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ìtọ́sọ́nà Rẹ̀ ló sì wá, kì í ṣe tènìyàn. Ohun tó ṣe yìí mà sì ṣe Jerúsálẹ́mù lóore ńláǹlà o! Ìdààmú ọkàn gidi lè bá àwọn Kristẹni olùbẹ̀rù Ọlọ́run lóde òní pẹ̀lú, bí wọ́n bá kó sí pákáǹleke. Ní tòdodo, lábẹ́ àwọn ipò kan, ẹ̀rù ò ní ṣàìbani. Síbẹ̀, bí a bá ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà,’ yóò bójú tó wa. (1 Pétérù 5:7) Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù wa, yóò sì fún wa lókun láti kojú àwọn ipò tó ń kó pákáǹleke bá wa.
23. Ọ̀nà wo ló fi jẹ́ pé Senakéríbù ni ìdààmú ọkàn bá dípò tí ì bá fi jẹ́ Hesekáyà?
23 Níkẹyìn, Senakéríbù ló wá kó sí ìdààmú ọkàn dípò tí ì bá fi jẹ́ Hesekáyà. Ta ló wá fẹ́ yíjú sí báyìí? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “‘Àpáta gàǹgà rẹ̀ yóò sì kọjá lọ nítorí jìnnìjìnnì tí ó bùáyà, àti nítorí àmì àfiyèsí, àwọn ọmọ aládé rẹ̀ yóò jáyà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ẹni tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ wà ní Síónì, tí ìléru rẹ̀ sì wà ní Jerúsálẹ́mù.” (Aísáyà 31:9) Ńṣe làwọn òrìṣà Senakéríbù, ìyẹn “àpáta gàǹgà” rẹ̀, tó jẹ́ ibi ààbò tó gbẹ́kẹ̀ lé, já a kulẹ̀. Àfi bíi ká sọ pé wọ́n “kọjá lọ nítorí jìnnìjìnnì tí ó bùáyà.” Ẹ̀wẹ̀, àní àwọn ọmọ aládé tí Senakéríbù ní pàápàá kò rí ìrànlọ́wọ́ tó ṣe gúnmọ́ ṣe. Jìnnìjìnnì bá àwọn náà.
24. Ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere wo ni a lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará Ásíríà?
24 Ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere ni ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ alátakò Ọlọ́run. Kò sí ohun ìjà kankan, kò sí agbára tẹ́nikẹ́ni lè sà, kò sọ́gbọ́n tó lè ta, tó lè dabarú àwọn ète Jèhófà. (Aísáyà 41:11, 12) Bákan náà, ẹnikẹ́ni tó bá lóun ń sin Ọlọ́run tó sì tún lọ ń fi àwọn nǹkan nípa ti ara ṣe ibi ààbò rẹ̀, yóò rí ìjákulẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí “kò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,” yóò rí i pé Jèhófà á “mú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù wá” bá òun. (Aísáyà 31:1, 2) Ní tòdodo, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ibi ààbò gidi tó wà pẹ́ títí.—Sáàmù 37:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Ó jọ pé Ísírẹ́lì ni Aísáyà darí ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí kọkànlélọ́gbọ̀n sí ní pàtàkì. Ó dà bí ẹni pé Júdà ni Ais 31:4-9ẹsẹ mẹ́fà tó gbẹ̀yìn kàn.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 319]
Ìjákulẹ̀ yóò bá àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn nǹkan ti ara
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 322]
Bí kìnnìún tó dúró ti ẹran tó pa, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò ṣe dáàbò bo ìlú mímọ́ rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 324]
Ìkórìíra nítorí pé ẹ̀sìn yàtọ̀ síra, nítorí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti ìran yíyàtọ̀ síra ti ya ayé nípa síra wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 326]
Hesekáyà wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ilé Jèhófà