KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?
Báwo La Ṣe Ń Rówó Bójú Tó Iṣẹ́ Wa?
Lọ́dọọdún, a máa ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àti àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, a sì máa ń pín in fún àwọn èèyàn. A máa ń kọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti àwọn ibi ìtẹ̀wé, a sì ń bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ níbẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìjọ sì tún máa ń ṣe ìpàdé ní àwọn ibi ìjọsìn tó bójú mu, tó sì mọ níwọ̀n, èyí tí à ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Báwo la ṣe ń rówó ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí?
Ọrẹ tí àwọn èèyàn fínnú fíndọ̀ ṣe la fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ yìí. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Lọ́dún 1879, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tá à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí sọ pé: “A gbà pé JÈHÓFÀ ni alátìlẹyìn ‘Zion’s Watch Tower,’ torí náà, ìwé ìròyìn yìí kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn fáwọn.” Ìlànà yẹn náà la ṣì ń tẹ̀ lé di báyìí.
A máa ń fi ọrẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní tààràtà tàbí ká fi sínú àpótí ọrẹ tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, a kì í gba ìdámẹ́wàá, a kì í gbégbá ọrẹ, a ò sì ń díye lé àwọn ìwé wa. A kì í gba owó fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìpàdé wa kì í gba owó, a ò sì ń gba owó tá a bá lọ kọ́ àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ títí kan àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í gba owó oṣù fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
“Ọrẹ táwọn èèyàn fínnú fíndọ̀ ṣe láwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń bójú tó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ń pinnu iye tó máa fi ‘ṣètọrẹ’ fún iṣẹ́ Ọlọ́run àti ìgbà tó máa mú un wá.”
A tún máa ń fi ọrẹ táwọn èèyàn ṣe ran àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Inú àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń dùn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní. (Róòmù 15:26) A máa ń bá àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí tún ilé àti ibi ìjọsìn wọn ṣe. A máa ń fún wọn lóúnjẹ àti aṣọ, a sì tún máa ń tọ́jú àwọn tó fara pa.