Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni iṣẹ́ balógun ọgọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù?
Ó tó ìgbà bíi mélòó kan tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa àwọn balógun ọgọ́rùn-ún ti ilẹ̀ Róòmù. Ipò yìí ni Ọ̀gágun tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù wà. Ipò yẹn náà ni Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí àkọ́kọ́ tó di Kristẹni wà. Bákan náà, balógun ọgọ́rùn-ún ni ọ̀gágun tó bójú tó ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n fẹ́ nà án lọ́rẹ́ àti Júlíọ́sì tó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù lọ sí ìlú Róòmù.—Máàkù 15:39; Ìṣe 10:1; 22:25; 27:1.
Balógun ọgọ́rùn-ún sábà máa ń darí àádọ́ta sí ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn. Lára iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó máa dá àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, kó máa bá wọn wí tí wọ́n bá ṣẹ̀, kó máa yẹ aṣọ àti ohun ìjà wọn wò, kó sì máa darí wọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ sójú ogun.
Ipò balógun ọgọ́rùn-ún ni ipò tó ga jù lọ tí ọmọ ogun kan lè dé. Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ológun tí wọ́n sì jẹ́ aṣáájú tó pegedé ló máa ń wà ní ipò yìí. Àwọn ló wà nídìí bí wọ́n ṣe máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọ ogun tó bá ṣẹ̀ àti bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tó jẹ́ àkòtagìrì á ṣe máa já fáfá sí i. Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn balógun ọgọ́rùn-ún “ló ní ìrírí jù lọ tó sì máa ń mọ gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ sí láàárín ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”
Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú dígí tí wọ́n ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì àti tòde òní?
Àwọn dígí tí wọ́n ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì yàtọ̀ sí tòde òní. Nígbà yẹn, irin tí wọ́n dán dáadáa ni wọ́n fi ń ṣe dígí. Idẹ ni wọ́n sábà máa ń lò, àmọ́ wọ́n tún máa ń lo bàbà, fàdákà, wúrà tàbí fàdákà àti wúrà tí wọ́n yọ́ pọ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa dígí ni ìgbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ilé àkọ́kọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò fún ìjọsìn. Àwọn obìnrin dá dígí jọ kí wọ́n lè fi ṣe bàsíà bàbà àti ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀. (Ẹ́kísódù 38:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi iná yọ́ àwọn dígí yìí kí wọ́n tó lè fi ṣe bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀.
Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn wú àwọn dígí jáde ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti àgbègbè rẹ̀, wọ́n tún rí àwọn nǹkan bíi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn, ẹ̀gbà ọwọ́, yẹtí àtàwọn nǹkan míì táwọn obìnrin fi ń ṣara lóge. Àwọn dígí yìí sábà máa ń rí róbótó. Igi, irin tàbí eyín erin tí wọ́n fi gbẹ́ ère obìnrin ni wọ́n fi ń ṣe ibi tí wọ́n ti ń dì í mú. Wọ́n sábà máa ń fi ojú kejì dígí náà sílẹ̀ láì dán an.
Àwọn dígí ayé àtijọ́ kò lè gbé àwòrán kedere jáde bíi ti dígí onígíláàsì ti òde òní. Ó jọ pé ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Nísinsìnyí àwa ń ríran nínú àwòrán fírífírí nípasẹ̀ dígí tí a fi irin ṣe.”—1 Kọ́ríńtì 13:12.