Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Peshitta Lédè Síríákì—Bíbélì kan Tó Jẹ́ Ká Mọ Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Bíbélì Láyé Àtijọ́

Bíbélì Peshitta Lédè Síríákì—Bíbélì kan Tó Jẹ́ Ká Mọ Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Bíbélì Láyé Àtijọ́

Ní ọdún 1892, àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ ìbejì gun ràkúnmí la àárín aginjù lọ sí St. Catherine’s Monastery, ìyẹn ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Sínáì. Ìrìn àjò yẹn gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́sàn. Orúkọ àwọn obìnrin náà ni Agnes Smith Lewis àti Margaret Dunlop Gibson. Kí nìdí táwọn obìnrin méjèèjì tọ́jọ́ orí wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún fi rìnrìn-àjò eléwu yìí lọ sí apá Ìlà Oòrùn ayé? Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé làwọn àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì.

Agnes Smith Lewis àti ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n ń pè ní St. Catherine’s Monastery

KÍ Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́rìí nípa òun “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ìtara àti ìgboyà jíṣẹ́ tó rán wọn yìí. Àmọ́ àwọn ará ìlú Jerúsálẹ́mù ta kò wọ́n, wọ́n sì pa ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń jẹ́ Sítéfánù. Èyí ló mú kí púpọ̀ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn náà sá lọ sí ìlú Áńtíókù tó wà nílẹ̀ Síríà. Ìlú yìí wà lára àwọn ìlú tó tóbi jù lọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ó sì jìnnà tó nǹkan bí àádọ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [550] kìlómítà sí ìhà àríwá Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 11:19.

Ńṣe làwọn ọmọlẹ́yìn ń bá ìwàásù “ìhìn rere” nípa Jésù nìṣó nílùú Áńtíókù, ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù sì di onígbàgbọ́. (Ìṣe 11:20, 21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Gíríìkì ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nínú ìlú náà ń sọ, èdè Síríákì làwọn tó ń gbé ní ẹnubodè àti àwọn àgbègbè tó yí ìlú náà ká ń sọ.

“ÌHÌN RERE” NÍ ÈDÈ SÍRÍÁKÌ

Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì, iye àwọn Kristẹni tó ń sọ èdè Síríákì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi túmọ̀ “ìhìn rere” sí èdè ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, ó dà bíi pé èdè Síríákì ni èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí, kì í ṣe èdè Látìn.

 Ní nǹkan bí ọdún 170 Sànmánì Kristẹni, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Síríà kan tó ń jẹ́ Tatian (tó gbáyé ní ọdún 120 sí 173 Sànmánì Kristẹni) ṣe àpapọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní èdè Gíríìkì tàbí èdè Síríákì. Àpapọ̀ ìwé tó ṣe yìí ló pè ní Diatessaron, ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “látinú [àwọn ìwé Ìhìn Rere] mẹ́rin.” Nígbà tó yá, ọmọ ilẹ̀ Síríà míì tó ń jẹ́ Ephraem (tó gbáyé láti ọdún 310 sí 373 Sànmánì Kristẹni) ṣe ìwé kan tó fi ṣàlàyé ìwé Diatessaron, èyí fi hàn pé àwọn Kristẹni tó ń sọ èdè Síríákì ń lo ìwé Diatessaron dáadáa nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

Kí nìdí tí ìwé Diatessaron fi gba àfiyèsí wa lónìí? Ìdí ni pé, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣàríwísí pé nǹkan bí ọdún 130 sí 170 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere, torí náà, wọn kò lè sọ òkodoro òtítọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù. Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ tó jẹ́ ti Diatessaron tí wọ́n ṣàwárí fi hàn pé àwọn èèyàn ti ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù ní gbogbo àwọn ọdún 130 sí 170 Sànmánì Kristẹni. Èyí fi hàn pé, wọ́n ti kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere náà ṣáájú àkókò yẹn. Láfikún sí i, nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Tatian ń ṣe àpapọ̀ ìwé Diatessaron, àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni ó lò tó sì tẹnu mọ́ dáadáa, ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló mẹ́nu ba àwọn ohun tó wà nínú ayédèrú ìwé kan tí wọ́n ń pè ní ìwé ìhìn rere ti àpókírífà. Èyí jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn ò ka àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà sí apá kan Ìwé Mímọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

Ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì Peshitta lédè Síríákì tí wọ́n kọ lọ́dún 464 Sànmánì Kristẹni, ló ṣìkejì nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ, déètì tí wọ́n kọ ọ́ sì wà níbẹ̀

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún, àwọn tó ń gbé ní àríwá Mesopotámíà bẹ̀rẹ̀ sí í lo Bíbélì kan tó ń jẹ́ Peshitta, tí wọ́n kọ ní èdè Síríákì. Ọ̀rọ̀ náà Peshitta túmọ̀ sí “Rọrùn” tàbí “ṣeé lóye,” ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìkẹta Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́. Gbogbo ìwé Bíbélì ló wà nínú rẹ̀ àyàfi Pétérù kejì, Jòhánù kejì àti ìkẹta, Júúdà àti Ìṣípayá. Bíbélì Peshitta yìí wà lára àwọn Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe ń da Bíbélì kọ nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

Wọ́n tún ṣàwárí ọ̀kan lára àwọn ìwé àfọwọ́kọ Peshitta tí wọ́n kọ déètì tí wọ́n ṣe é sí lára, ìyẹn ọdún 459 tàbí 460 Sànmánì Kristẹni. Àdàkọ tí wọ́n ṣàwárí yìí ni ẹ̀dà tó ti pẹ́ jù lọ nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tí wọ́n kọ déètì tí wọ́n ṣe é sí i lára. Ní nǹkan bí ọdún 508 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ṣe àtúnṣe sí Bíbélì Peshitta kó lè ní àwọn ìwé Bíbélì márùn-ún tí kò sí lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ̀dà tuntun yìí ni wọ́n pè ní Bíbélì Philoxenian Version.

WỌ́N ṢÀWÁRÍ ÀWỌN ÌWÉ ÀFỌWỌ́KỌ MÍÌ NÍ ÈDÈ SÍRÍÁKÌ

Ṣáájú ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n dà kọ wá látinú àwọn ẹ̀dà tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì fi pàfiyèsí sáwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n ti kọ ṣáájú ìgbà yẹn, irú bíi Bíbélì Vulgate lédè Látìn àti Bíbélì Peshitta lédè Síríákì. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé Bíbélì Peshitta jẹ́ àtúnṣe Bíbélì míì lédè Síríákì tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mọ Bíbélì náà. Wọ́n mọ̀ pé láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ni wọ́n ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí èdè Síríákì, tí ọwọ́ wọ́n bá tẹ irú Bíbélì tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ bẹ́ẹ̀, á ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe kọ ọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ṣé irú Bíbélì tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ bẹ́ẹ̀ lè wà ní èdè Síríákì? Tó bá tiẹ̀ wà, ṣé wọ́n á rí i?

Ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n ń pè ní Sinaitic Syriac. Ìwé Ìhìn Rere ń fara hàn lábẹ́lẹ̀ nínú àmì róbótó

Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n rí i! Kódà oríṣi méjì pàápàá ni wọ́n rí. Èyí àkọ́kọ́ ni wọ́n kọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún. Ó sì wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Síríákì tó wà ní Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé sí ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún 1842 ni wọ́n rí i nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà nínú aginjù Nitrian nílẹ̀ Íjíbítì. Wọ́n pe orúkọ ẹ̀dà yìí ní Curetonian Syriac nítorí pé ọ̀gbẹ́ni William Cureton tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ẹni tó ń bójú tó àwọn ìwé àfọwọ́kọ níbi ìkóhun ìṣẹ̀ǹbáyé sí náà, ló ṣàwárí rẹ̀. Àpapọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló wà nínú rẹ̀, bí wọ́n sì ṣe tò ó rèé, Mátíù, Máàkù, Jòhánù àti Lúùkù.

Èyí èkejì tí wọ́n ṣàwárí tó sì wà títí dòní ni wọ́n pè ní Sinaitic Syriac. Àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ìbejì tá a sọ̀rọ̀ wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ àkòrí yìí ló ṣàwárí rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Agnes kò lọ sí yunifásítì, èdè mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló gbọ́ títí kan èdè Síríákì. Ọdún 1892 ni Agnes ṣàwárí ìwé yìí ní St. Catherine Monastery nílẹ̀ Íjíbítì.

 Nígbà tí Agnes wọ inú yàrá kékeré kan, ó rí ìwé kan tí wọ́n kọ ní èdè Síríákì. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ó dọ̀tí, ó sì rí wúruwùru, gbogbo ojú ìwé rẹ̀ pátá ló ti lẹ̀ pọ̀ torí kò sẹ́ni tó ṣí i” láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá. Ìwé tó rí náà jẹ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n máa ń pa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ rẹ́ kí wọ́n lè kọ ọ̀rọ̀ míì lé e lórí. Agnes rí i pé wọ́n pa ọ̀rọ̀ kan rẹ́ nínú ìwé náà, wọ́n wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ míì lédè Síríákì nípa obìnrin kan tí wọ́n kà sí ẹni mímọ́ sínú rẹ̀. Síbẹ̀ nígbà tí Agnes wo ìwé náà dáadáa, ó ri àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n pa rẹ́ náà, ó rí “ti Mátíù,” “ti Máàkù,” tàbí “ti Lúùkù” lọ́wọ́ òkè ìwé náà. Ohun tí Agnes ṣàwárí yìí jẹ́ àpapọ̀ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní èdè Síríákì! Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ni wọ́n kọ ọ́.

Ìwé Sinaitic Syriac tó wà ní èdè Síríákì, ìwé Codex Sinaiticus àti Codex Vaticanus tó wà ní èdè Gíríìkì wà lára àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ táwọn ọ̀mọ̀wé kà sí pàtàkì jù lọ lára àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n ṣàwárí. Wọ́n gbà pé ìwé Curetonian Syriac àti ìwé Sinaitic Syriac tó ṣì wà títí dòní jẹ́ àdàkọ àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n kọ lédè Síríákì ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta.

“Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN WA YÓÒ WÀ FÚN ÀKÓKÒ TÍ Ó LỌ KÁNRIN”

Ǹjẹ́ àwọn Bíbélì tí wọ́n ṣàwárí yìí wúlò fáwa tí à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ìwé Ìhìn Rere Máàkù parí sí orí 16:8, apá kan wà táwọn kan fi kún un, wọ́n pè apá yìí ní ìparí gígùn. Àfikún yìí wà nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì irú bíi, Greek Codex Alexandrinus tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún, Bíbélì Vulgate ní èdè Látìn àti nínú àwọn Bíbélì míì pẹ̀lú. Àmọ́ àfikún náà kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì méjì tí wọ́n kọ ní èdè Gíríìkì tó sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ gan-an, ìyẹn Codex Sinaiticus àti Codex Vaticanus tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin. Bákan náà, Bíbélì Sinaitic Syriac náà kò ní ìparí gígùn yìí, èyí fi hàn pé ìparí gígùn náà kò sí lára ìwé Ìhìn Rere tí Máàkù fúnra rẹ̀ kọ, àwọn kan ló fi àfikún náà sí.

Àpẹẹrẹ míì tún ni ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 5:7. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ló ní ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ìyẹn ayédèrú ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n fi kún ẹsẹ Bíbélì yẹn. Àmọ́ àfikún yìí kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tó wà ní èdè Gíríìkì. Bákan náà, Bíbélì Peshitta tó wà ní èdè Síríákì kò ní àfikún yìí, èyí fi hàn pé awúrúju gbáà ni àfikún tí wọ́n ṣe sí ìwé 1 Jòhánù 5:7.

Gbogbo ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé Jèhófà ti pa Ọ̀rọ̀ Mímọ́ rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 40:8; 1 Pétérù 1:25) Ká sòótọ́, Bíbélì Peshitta ti kó ipa tó jọjú gan-an nínú títan òkodoro òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.