Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Baba Ńlá Mi Tó ti Kú?

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Baba Ńlá Mi Tó ti Kú?

NÍNÚ ìwé ìròyìn ilẹ̀ Korea tí wọ́n ń pè ní The Chosun Ilbo, wọ́n gbé àkọlé kan tó gbàfiyèsí jáde. Àkọlé náà sọ pé: “‘Shim Cheong Wa Àtàtà,’ Tí Kò Mọ Nǹkan Kan Nípa Jésù, Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Ló Wà?”

Àkọlé náà ṣeni ní kàyéfì torí pé nínú ìtàn àròsọ àwọn ará Korea, ẹni ọ̀wọ́n ni Shim Cheong. Ọmọbìnrin yìí fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kó bàa lè ran bàbá rẹ̀ tó jẹ́ afọ́jú lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé, wọ́n ṣì ń rántí ohun ńlá tó ṣe. Kódà ní Korea, àwòfiṣàpẹẹrẹ ni “Shim Cheong” jẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin.

Ìdí nìyí tí ọ̀pọ̀ fi gbà pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin àtàtà yìí kò ṣe ìrìbọmi tàbí di Kristẹni, kì í ṣé irú ẹ̀ ló yẹ kó lọ sí ọ̀run àpáàdì níbi tá á ti máa joró. Kò tiẹ̀ tọ́ sí i rárá. Òótọ́ sì ni, torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé tipẹ́ kí àwọn èèyàn tó wàásù nípa Jésù Kristi dé abúlé tí ọmọbìnrin náà gbé dàgbà.

Nínú ìwé ìròyìn tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan. Wọ́n bíi pé ṣé ọ̀run àpáàdì ni àwọn tó kú láì mọ Jésù ń lọ ni? Ó dáhùn pé: “A ò lè sọ. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà àbáyọ wà [fun irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀] nípasẹ̀ Ìdarí Àtọ̀runwá.”

ṢÉ Ó YẸ KÉÈYÀN ṢE BATISÍ KÓ TÓ LÈ RÍ ÌGBÀLÀ?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Àfi kéèyàn ṣe batisí kó tó lè rí ìgbàlà. Ṣebí Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé, láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti Ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run (Jòhánù 3:5).” Ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi gbà pé tí ẹnì kan bá kú láì ṣe batisí, ọ̀run àpáàdì ló ń lọ tàbí kó jìyà lọ́nà míì tó kàmàmà.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ẹ̀kọ́ yìí kò mọ́gbọ́n dání. Ó ṣe tán, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti kú láì mọ nǹkan kan nípa Bíbélì. Ṣé ìdálóró ayérayé ló wá tọ́ sí wọn nítorí pé wọ́n kú láì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

BÍBÉLÌ FÚN WA NÍ ÌRÈTÍ

Àwọn kan ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí wọ́n fi kú, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ torí pé wọn ò mọ̀ nípa ìlànà rẹ̀. Ìṣe 17:30 jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀ bẹ́ẹ̀.” Ìrètí wo ló wá wà fún àwọn tí kò ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n tó kú?

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣèlérí pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”?

A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn méjì tó ń kú lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọkùnrin náà sọ fún Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù fún un lésì pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:39-43.

Ṣé ohun tí Jésù ń sọ fún ọ̀daràn yẹn ni pé ó máa tẹ̀ lé òun lọ sí ọ̀run? Rárá. Torí láì jẹ́ pé a fi omi àti ẹ̀mí ‘tún ọkùnrin náà bí,’ kò lè wọ Ìjọba ọ̀run. (Jòhánù 3:3-6) Ohun tí Jésù ń sọ fún ọ̀daràn yẹn ni pé á wà pẹ̀lú òun nínú Párádísè. Nítorí pé Júù ni ọkùnrin náà, ó ṣeé ṣe kí ó ti gbọ́ nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tẹ́lẹ̀, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì tí Bíbélì sọ́rọ̀ rẹ̀ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ìlérí tí Jésù ṣe fún ọkùnrin náà jẹ́ kó dá a lójú pé, Ọlọ́run máa jí òun dìde nígbà tó bá sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.

Kódà, Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) “Àwọn aláìṣòdodo” ni àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run torí pé wọn kò ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́. Jésù máa jí ọ̀daràn tó jẹ́ aláìṣòdodo yẹn dìde àti ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí wọ́n ti kú láì ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Nígbà yẹn, inú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n á máa gbé, wọ́n á sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. Bí wọ́n bá ṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé lóòótọ́ ni àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

 NÍGBÀ TÍ ÀWỌN ALÁÌṢÒDODO BÁ JÍǸDE

Tí àwọn aláìṣòdodo bá jíǹde, ṣé ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú ni Ọlọ́run á fi dá wọn lẹ́jọ́? Rárá o. Róòmù 6:7 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ọlọ́run ti pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn aláìṣòdodo yẹn rẹ́ nígbà tí wọ́n ti kú. Torí náà, ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde ni Ọlọ́run á fi dá wọn lẹ́jọ́, kì í ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe nígbà àìmọ̀. Àǹfààní wo ni àwọn èèyàn yìí máa rí?

Lẹ́yìn àjíǹde, àwọn aláìṣòdodo máa ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òfin Ọlọ́run nígbà tí Ọlọ́run bá ṣí àwọn àkájọ ìwé payá. Ọlọ́run yóò sì ṣèdájọ́ wọn “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn,” bóyá wọ́n ṣègbọràn sí i àbí wọn kò ṣègbọràn sí i. (Ìṣípayá 20:12, 13) Ní ti ọ̀pọ̀ àwọn aláìṣòdodo yẹn, kì í ṣe pé Ọlọ́run ń fún wọn láǹfààní ẹlẹ́ẹ̀kejì o, ńṣe ni Ọlọrun ń fún wọ́n ní àǹfààní pàtàkì fún igbà àkọ́kọ́ láti fi hàn pé àwọn fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n tún lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ọ̀kan lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Yeong Sug. Kátólíìkì paraku ni, ọ̀pọ̀ nínú ìdílé rẹ̀ sì jẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Ó kó lọ sí ilé ìsìn tí àwọn mọdá ń gbé kí òun náà lè di ara wọn. Àmọ́ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé àwọn ohun tó rí níbẹ̀ kò bá a lára mu. Kò tún fara mọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì torí pé kò gbà pé Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ tó sì jẹ́ onídàájọ́ òdodo lè máa dá àwọn èèyàn lóró nínú iná.

Nígbà tó yá, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pàdé Yeong Sug, ó sì fi ẹsẹ Bíbélì kan hàn án tó sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́.” (Oníwàásù 9:5) Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣàlàyé fún Yeong Sug pé àwọn baba ńlá rẹ̀ kò sí ní ọ̀run àpáàdì níbi tí wọ́n ti ń joró. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń sùn nínú oorun ikú, wọ́n sì ń retí àjíǹde.

Nígbà tó wá ṣe kedere sí Yeong Sug pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kíá ló fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò, èyí tó wà nínú Mátíù 24:14 pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àtìgbà yẹn ló ti ń wàásù Ìhìn Rere fún àwọn èèyàn kí àwọn náà lè ní ìrètí.

“ỌLỌ́RUN KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ”

Bíbélì sọ fún wa pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ọ̀rọ̀ yẹn ò yà wá lẹ́nu, nítorí Ọlọ́run “jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”—Sáàmù 33:5.