Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | OHUN TÍ ỌLỌ́RUN TI ṢE FÚN Ẹ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Kan Tó Yẹ Kó Ṣojú Ẹ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Kan Tó Yẹ Kó Ṣojú Ẹ

Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí ó tó kú, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé kí wọ́n máa rántí ẹbọ tí òun rú. Jésù lo búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì láti dá Ìrántí Ikú rẹ̀ tàbí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀. Ó wá pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.

Lọ́dọọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń pé jọ láti ṣe ìrántí ikú Jésù ní àyájọ́ ọjọ́ tó kú gan-an. Lọ́dún yìí, ọjọ́ náà bọ́ sí Monday, April 14, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀.

A fi tayọ̀tayọ̀ pè ọ́ wá sí ìpàdé yìí kó o lè wá gbọ́ àlàyé sí i nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún wa. Ọ̀fẹ́ ni ìjókòó, a kì í sì gbégbá ọrẹ. Ẹni tó fún ẹ ní ìwé ìròyìn yìí máa sọ àkókò àti ibi tá a ti máa ṣe é ní àdúgbò rẹ, tàbí kó o wo orí ìkànnì jw.org/yo. Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn. À ń retí rẹ níbẹ̀.