KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ǸJẸ́ A NÍLÒ ỌLỌ́RUN?
Ìdí Tá A Fi Nílò Ọlọ́run
Àwọn oníṣègùn ọpọlọ sọ pé ojúlówó ayọ̀ ju kéèyàn jẹun, kó mu tàbí kó wọṣọ lọ. Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn máa ń fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó nítumọ̀ tàbí kí wọ́n ní ẹnì kan tí wọ́n á máa sìn. Àwọn kan máa ń lo àkókò tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀ láti kọrin tàbí ronú nípa ìṣẹ̀dá tàbí kí wọ́n ya àwòrán, torí wọ́n gbà pé àwọn nǹkan yìí lè fún wọn láyọ̀. Síbẹ̀ àwọn nǹkan yẹn kọ́ ló ń fúnni láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó wà pẹ́ títí.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa láyọ̀ nísinsìnyí àti títí láé
Àwọn tó bá ka Bíbélì jinlẹ̀ á ti mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá láti jọ́sìn rẹ̀. Àwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ó máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé, ìyẹn ló mú kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-10) Ọlọ́run ò dá wa pé ká kàn máa ṣe bó ṣe wù wá láìsí ìtọ́sọ́nà rẹ̀, torí náà ó yẹ ká máa bá Ẹlẹ́dàá wa sọ̀rọ̀ déédéé. Léraléra ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù5:3) A lè rí kókó pàtàkì kan fà yọ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ìyẹn ni pé, tí a bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa láyọ̀ ká sì ní ìfọkànbalẹ̀, àfi ká sún mọ́ Ọlọ́run. Báwo ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù sọ ohun tá a lè ṣe, ó sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ, ìyẹn èrò rẹ̀ àtàwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì à pàtàkì mẹ́ta kan yẹ̀ wò.
A Nílò Ìtọ́sọ́nà Tó Dára
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ni wọ́n ṣe tán láti fúnni ní ìmọ̀ràn nípa àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ ìfẹ́, ọ̀rọ̀ ìdílé, bí èèyàn ṣe lè yanjú aáwọ̀, bí èèyàn ṣe lè láyọ̀ àti ìdí tí a fi wà láàyè. Àmọ́, ta ni ìmọ̀ràn rẹ̀ gbéṣẹ́ jù lọ nípa àwọn ohun tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, bí kò ṣe Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa?
Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé o ra kámẹ́rà tuntun kan, wàá retí pé kí ìwé atọ́nà bá ohun èlò tuntun
yìí wá, torí ìwé yẹn ló máa ṣàlàyé gbogbo ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa ohun èlò tuntun náà àti bó ṣe yẹ kó o lò ó. Lọ́nà kàn náà, Bíbélì dà bí ìwé atọ́nà tí Ọlọ́run fi ń tọ́ wa sọ́nà nípa ìgbésí ayé. Bíbélì sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo wa. Ìwé atọ́nà tó máa ń bá ohun èlò tuntun wá sábà máa ń ṣàlàyé ohun tí ohun èlò náà ń ṣiṣẹ́ fún àti ọ̀nà tó dáa jù láti lò ó.Bí ìwé atọ́nà ṣe máa ń sọ àwọn ohun tó lè ba ohun èlò náà jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe máa ń kìlọ̀ nípa àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fún ayé wa. Ìmọ̀ràn tí àwọn míì bá fún wa lè dà bí èyí tó rọrùn tí kò sì léwu, àmọ́ ohun tó yẹ ká mọ̀ ni pé tí a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ẹlẹ́dàá wa nìkan ni a lè láyọ̀ tí a ò sì ní kó sínú ìṣòro.
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:17, 18
Òótọ́ ni pé Jèhófà Ọlọ́run ń fún wa ní ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà, síbẹ̀ kì í fipá mú ẹni kankan pé kó tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ ló ṣe fi ìfẹ́ rọ̀ wá pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:17, 18) Lọ́rọ̀ kan, tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, ìgbésí ayé wa máa dára. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí a bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa ládùn ká sì máa láyọ̀, a nílò Ọlọ́run.
A Nílò Ojútùú Sí Àwọn Ìṣòro Ìgbésí Ayé
Àwọn èèyàn kan gbà pé àwọn kò nílò Ọlọ́run, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ń rú wọn lójú, wọ́n wò ó pé tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, kò yẹ kó fàyè gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè béèrè pé: ‘Kí nìdí tí ìyà fi ń jẹ àwọn èèyàn rere?’ ‘Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi ń bí ọmọ abirùn?’ ‘Kí ló dé tí ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ láyé?’ Àwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an, tí a bá sì rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sí wọn, ó lè ní ipa tó jinlẹ̀ láyé wa. Àmọ́ dípò ká kàn máa dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí irú àwọn ìṣòro yìí, jẹ́ ká wo bí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí.
Nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta, a rí àkọsílẹ̀ nípa bí Sátánì ṣe dọ́gbọ́n lo ejò láti mú kí àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run pa fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Sátánì sọ fún Éfà pé “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:4, 5.
Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé òpùrọ́ ni Ọlọ́run àti pé bó ṣé ń ṣàkóso wa kò dáa. Èṣù wá ń jiyàn pé tí àwọn èèyàn bá tẹ́tí sí òun, nǹkan máa lọ dáadáa fún wọn. Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ yanjú ọ̀ràn yìí? Jèhófà mọ̀ọ́mọ̀ fi àkókò tó pọ̀ sílẹ̀ káwọn èèyàn lè rí i kedere bóyá ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun
jẹ́ òótọ́ tàbí irọ́. Ṣe ni Ọlọ́run fún Sátánì àti gbogbo àwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ láyè láti fi hàn bóyá èèyàn lè gbé ìgbé ayé tó dáa láì sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.Kí ni èrò rẹ nípa àwọn ohun tí Sátánì sọ? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn lè gbé ìgbé ayé tó dáa, kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí bí wọ́n ṣe ń ṣàkóso ara wọn láì sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run? Àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé aráyé kò lè ṣàkóso ara wọn láì sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Lára àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ ni ìyà, ìrẹ́jẹ, àìsàn, ikú àti ìwà ọ̀daràn. Ìṣekúṣe gbòde kan, ogun ń jà kiri, ìpẹ̀yàrun àti ìwà ìkà tó burú jáì kò gbẹ́yìn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa gbogbo nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Ó jẹ́ ká mọ olórí ohun tó fà á, Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí yìí, ṣé ẹ̀yin náà ti wá rí i pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ni a ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìṣòro tó ń dojú kọ ẹ̀dá àti ojútùú sí àwọn ìṣòro náà? Àmọ́ kí ni Ọlọ́run máa ṣe?
A Nílò Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń sapá kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú. Ọ̀pọ̀ ti lo àkókò àti okun wọn kí èyí lè ṣeé ṣe, wọ́n ti náwó nára, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn ń já sí. Kódà àwọn kan ti lo oríṣiríṣi oògùn ajẹ́bíidán tí kì í jẹ́ kéèyàn kú tàbí omi àjídèwe àtàwọn nǹkan míì kí wọ́n máà bàa darúgbó, kí ẹ̀mí wọn sì lè gùn. Àmọ́ gbogbo ibi tí wọ́n fojú sí yìí, ọ̀nà ò gba ibẹ̀.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa láyọ̀ ká sì gbé ìgbé ayé tó dáa. Ohun tó ní lọ́kàn gan-an nìyẹn tó fi dá wa, kò sì tíì gbàgbé ohun tó pinnu láti ṣe yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Aísáyà 45:18) Jèhófà Ọlọ́run fi dá wa lójú pé, ohunkóhun tí òun bá ti pinnu ni òun máa ṣe. (Aísáyà 55:10, 11) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti mú kí ilẹ̀ ayé padà di Párádísè, èyí tí àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ pàdánù. Ìwé Ìṣípayá tó kẹ́yìn Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “[Jèhófà Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí àgbàyanu yìí ṣẹ, báwo sì ni ìlérí yìí ṣe máa ṣe wá láǹfààní?
Jésù Kristi, ọmọ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ àdúrà yẹn, èyí tí àwọn kan ń pè ní Àdúrà Olúwa, wọ́n sì máa ń kà á lákàtúnkà. Bí àdúrà náà ṣe lọ rèé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Jèhófà Ọlọ́run máa lo ìjọba rẹ̀ láti mú gbogbo láabi tí ìjọba èèyàn ti fà kúrò, á sì mú kí aráyé máa gbé nínú ayé tuntun òdodo tó ṣèlérí. * (Dáníẹ́lì 2:44; 2 Pétérù 3:13) Kí ni a lè ṣe ká lè jàǹfààní nínú ìlérí Ọlọ́run?
Jòhánù 17:3) Nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ni ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí ó ṣèlérí fi máa ṣeé ṣe. Ìrètí àgbàyanu yìí jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé a nílò Ọlọ́run lóòótọ́.
Jésù Kristi sọ ìgbésẹ̀ tí a gbọ́dọ̀ gbé, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Àkókò Nìyí Láti Ronú Nípa Ọlọ́run
Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, Pọ́ọ̀lù bá àwọn ará ìlú Áténì sọ̀rọ̀ lórí Òkè Máàsì tàbí Áréópágù nípa Ọlọ́run. Ó mọ̀ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tiwọn, síbẹ̀ wọn kì í rin kinkin mọ́ nǹkan, ó wá sọ fún wọn pé: “Òun [Ọlọ́run] fúnra rẹ̀ ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo. Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn kan lára àwọn akéwì láàárín yín ti wí pé, ‘Nítorí àwa pẹ̀lú jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.’”—Ìṣe 17:25, 28.
Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Áténì ṣì jóòótọ́ títí dòní. Ẹlẹ́dàá wa ló pèsè oúnjẹ tí à ń jẹ, omi tí à ń mu àti atẹ́gùn tí à ń mí símú. Kò sí bí a ṣe lè wà láàyè tí Jèhófà kò bá pèsè àwọn ohun rere yìí kó lè dá ẹ̀mí wa sí. Àmọ́, kí nìdí tí Ọlọ́run ṣì fi ń bá a lọ láti pèsè àwọn nǹkan yìí fún gbogbo èèyàn yálà wọ́n ronú nípa rẹ̀ tàbí wọn kò ronú nípa rẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé torí kí wọ́n lè “máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.
Ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ mọ Ọlọ́run dáadáa, kí o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe àti ìmọ̀ràn tó fún wa nípa bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè sọ fún ẹni tó fún ẹ ní ìwé ìròyìn yìí tàbí kí o kàn sí àwọn tó ṣe ìwé yìí. Inú wọn á dùn láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
^ ìpínrọ̀ 20 Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Ìjọba yìí ṣe máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, wo orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. O sì tún lè kà á tàbí kí o wà á jáde lórí www.isa4310.com/yo.