SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
“Wò ó! Mo Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ kí ìwọ àti ìdílé rẹ ní ìlera tó dáa àti ẹ̀mí gígùn? Ṣé ó wù ẹ́ láti gbé nínú ayé tí ìrora, ìyà àti ikú á ti di ohun àtijọ́? Àwọn ohun àgbàyanu yìí kì í ṣe àlá lásán. Kódà, Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí pé ayé tuntun òdodo kò ní pẹ́ dé mọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí ìlérí yìí ṣe máa ní ìmúṣẹ, èyí wà nínú Ìṣípayá 21:3-5.—Kà á.
“[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 21:4) Irú omijé wo ni Ọlọ́run máa nù kúrò? Kì í ṣe omijé ayọ̀ tàbí omijé tó ń fọ ìdọ̀tí kúrò ní ẹyinjú wa ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Omijé tí ìyà àti ìbànújẹ́ máa ń fà ni Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa nù kúrò. Kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn máa nu omijé yẹn kúrò lójú wa nìkan, ṣùgbọ́n ìyà àti ìbànújẹ́ tó ń fa omijé gan-an ló máa mú kúrò pátápátá.
“Ikú kì yóò sì sí mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Ikú ni ọ̀tá ọmọ aráyé, òun sì ni ó máa ń fa ọ̀pọ̀ omijé. Àmọ́, Jèhófà máa dá gbogbo ẹ̀dá onígbọràn sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Lọ́nà wo? Ó máa mú ohun tó ń fa ikú kúrò, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù, Jèhófà máa sọ àwọn onígbọràn di ẹ̀dá pípé. * Lẹ́yìn náà, ikú tí ó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn “ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àwọn ẹ̀dá olóòótọ́ máa gbádùn ìlera pípé títí láé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣètò láti ìbẹ̀rẹ̀.
“Kì yóò sì sí . . . ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Irú ìrora wo ni kò ní sí mọ́? Gbogbo àròdùn, ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti fà tó ti jẹ́ kí ayé nira fún àìmọye èèyàn kò ní sí mọ́.
Láìpẹ́, aráyé á máa gbé nínú ayé tí kò sí omijé, ikú àti ìrora mọ́. O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘níbo nìyẹn á ti ṣẹlẹ̀?’ ‘Ṣé ọ̀run ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí ti máa nímùúṣẹ?’ Rárá o. Kí nìdí? Àkọ́kọ́, ìlérí yẹn sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé,” bẹ́ẹ̀ sì rèé ilẹ̀ ayé ni aráyé ń gbé. (Ìṣípayá 21:3) Èkejì, ìlérí yìí sọ nípa ayé kan tí kò ní ‘sí ikú mọ́,’ ìyẹn ayé tí àwọn èèyàn ti ń kú tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọn kò ní kú mọ́. A ò gbọ́ rí pé ikú ṣẹlẹ̀ lọ́run, àmọ́ ọjọ́ pẹ́ tí ikú ti ń fojú aráyé rí màbo láyé. Ó ṣe kedere báyìí pé, orí ilẹ̀ ayé níbí ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ti máa ní ìmúṣẹ.
Tí Ọlọ́run bá ti mú ìyà àti ìbànújẹ́ kúrò, gbogbo orísun omijé ló máa gbẹ dànù
Jèhófà fẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí tó ṣe nípa ayé tuntun òdodo tó ń bọ̀. Lẹ́yìn tó ṣàlàyé àwọn ìbùkún tó ń bọ̀, ó wá fìdí ìlérí rẹ̀ múlẹ̀, ó ní: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Ó wá fi kún un pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.” (Ìṣípayá 21:5) Á dáa kí ìwọ náà kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe lè wà lára àwọn tó ń fi ayọ̀ sin Ọlọ́run, tí wọ́n máa rí bí ìlérí àgbàyanu Ọlọ́run ṣe máa ní ìmúṣẹ.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún December
1 Pétérù 1-5; 2 Pétérù 1-3; 1 Jòhánù 1-5; 2 Jòhánù 1-13; 3 Jòhánù 1-14; Júúdà 1-25–Ìṣípayá 1-22
^ ìpínrọ̀ 5 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹbọ ìràpadà Kristi, wo orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.