Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ìrètí wo ló wà fún àwọn tó ti kú?
Ikú dà bí oorun tẹ́nì kan sùn, tí kò mọ nǹkan kan, tí kò sì lè ṣe ohunkóhun. Àmọ́, Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti gbé àwọn òkú dìde nípasẹ̀ àjíǹde. Ẹ̀rí yìí túbọ̀ dájú nígbà tí Jésù wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára láti jí ọ̀pọ̀ òkú dìde.—Ka Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11, 43, 44.
Báwo ni ikú ṣe dà bí oorun?
Ọlọ́run kò ní gbàgbé gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ tí wọ́n ti kú, ó máa jí wọn dìde sínú ayé tuntun òdodo. Òun nìkan ló ní agbára láti jí àwọn tó wà ní ipò òkú dìde, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. Ó wu Ọlọ́run Olódùmarè pé kí ó lo agbára rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde.—Ka Jóòbù 14:14, 15.
Báwo ni àjíǹde ṣe máa rí?
Gbogbo àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde ṣì máa dá àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wọn mọ̀. Tí ara ẹnì kan bá tiẹ̀ ti jẹrà mọ́lẹ̀, Ọlọ́run ṣì lè jí ẹni náà pa dà pẹ̀lú ara tuntun.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:35, 38.
Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6) Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde ni yóò wà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí á bẹ̀rẹ̀ ayé wọn lákọ̀tun, wọn yóò sì máa wà láàyè títí láé.—Ka Sáàmù 37:29; Ìṣe 24:15.