Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà”

“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà”
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1966

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: FINLAND

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: AJÀFẸ́TỌ̀Ọ́ ỌMỌNÌYÀN

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Láti kékeré ni mo ti fẹ́ràn láti máa wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Ìdílé wa sábà máa ń ṣeré lọ sí àwọn igbó tí igi tó rẹwà pọ̀ sí àti àwọn odò tó mọ́ lóló tó wà káàkiri ìlú wa, ìyẹn Jyväskylä, tó wà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Finland. Mo tún fẹ́ràn ẹranko gan-an. Nígbà tí mo wà ní kékeré, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n ṣáà máa gbé gbogbo ológbò àti ajá tí mo bá ti rí mọ́ra! Àmọ́ bí mo ṣe ń dàgbà, inú mi ò dùn sí bí àwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe àwọn ẹranko báṣubàṣu. Kò pẹ́ tí mo fi wọ ẹgbẹ́ àwọn tó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹranko, àwọn èèyàn tá a jọ ní èrò kan náà nípa àwọn ẹranko la sì jọ wà níbẹ̀.

Taratara la fi máa ń ṣe ìkéde nítorí ẹ̀tọ́ àwọn ẹranko. A máa ń tẹ èrò wa sínú ìwé, a sì máa ń pín in fún àwọn èèyàn. A tún máa ń ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń ta irun àti awọ ẹranko àti ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń fi ẹranko kọ́ṣẹ́ ìṣègùn. Kódà, a dá ẹgbẹ́ tuntun kan sílẹ̀ tó ń dáàbò bo àwọn ẹranko. Àmọ́ torí pé ọwọ́ líle la fi mú ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kó sí ìjọ̀ngbọ̀n lọ́dọ̀ ìjọba. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n mú mi, tí wọ́n sì gbé mi lọ sílé ẹjọ́.

Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn ẹranko tó ká mi lára, àwọn ìṣòro tó kún inú ayé tún ń kọ mí lóminú. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wọ ẹgbẹ́ kan tẹ̀ lé òmíràn, títí kan àjọ àgbáyé kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àwọn tó ń rí sí bí àwọn èèyàn ò ṣe ní ba àyíká jẹ́. Gbogbo ẹ̀mí mi ni mo fi ń ti àwọn ẹgbẹ́ yìí lẹ́yìn. Mo máa ń jà fún àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn tí ebi ń pa àti àwọn tí kò ní olùgbèjà.

Àmọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi díẹ̀díẹ̀ pé mi ò lè yí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé pa dà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àjọ yẹn gbìyànjú láti wá nǹkan ṣe sí àwọn ìṣòro kéékèèké kan, àwọn ìṣòro ńláńlá túbọ̀ ń fẹjú sí i ni. Ṣe ló wá dà bíi pé ìwà ibi kúkú ti gba gbogbo ayé kan, kò sì sẹ́ni tó fẹ́ wá nǹkan ṣe sí i. Mo wá rí i pé agbára mi ò gbé e.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Nígbà tí mo rí i pé kò sí nǹkan tí mo lè ṣe tí màá fi yí bí nǹkan ṣe ń lọ láyé pa dà, inú mi bàjẹ́ gan-an, mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Ọlọ́run àti Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan rí. Nígbà yẹn, mo mọrírì bí wọ́n ṣe ní ìwà jẹ́jẹ́, tí wọ́n sì fẹ́ràn mi, àmọ́ mi ò ṣe tán láti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, èrò mi ti yàtọ̀.

Mo wá Bíbélì mi jáde mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ṣe ló dà bí pé wọ́n fi oògùn sí ojú ọgbẹ́ mi, ó tù mí lára gan-an ni. Mo rí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ká máa ṣe àwọn ẹranko jẹ́jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 12:10 sọ pé: “Olódodo ènìyàn mọ̀ rírì ẹ̀mí ẹran rẹ̀.” (Bíbélì Mímọ́) Ó tún yé mi pé Ọlọ́run kọ́ ló fa àwọn ìṣòro tó kún inú ayé. Ṣùgbọ́n torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò pa òfin Ọlọ́run mọ́ ni àwọn ìṣòro wa ṣe túbọ̀ ń fẹjú sí i. Inú mi dùn nígbà tí mo wá mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé ó ní ìpamọ́ra.—Sáàmù 103:8-14.

Láàárín àkókò yìí, mo rí fọ́ọ̀mù lẹ́yìn ìwé kan, téèyàn lè fi béèrè ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, mo kọ ọ̀rọ̀ kún un mo sì fi ránṣẹ́. Láìpẹ́, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá kan ilẹ̀kùn mi, wọ́n ní àwọn fẹ́ máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì gbà. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ìyẹn sì jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jinlẹ̀ lọ́kàn mi.

Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì lára mi, òun ló jẹ́ kí n lè yí ọ̀pọ̀ nǹkan pa dà láyé mi. Mo jáwọ́ nínú sìgá àti ọtí àmujù. Mo ń múra bí ọmọlúwàbí, mi ò sì sọ ìsọkúsọ mọ́. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ. (Róòmù 13:1) Bákan náà, mo jáwọ́ nínú ìṣekúṣe tó ti wọ̀ mí lẹ́wù.

Ó nira gan-an fún mi láti yí èrò tí mo ní nípa àwọn ẹgbẹ́ tí mo wà pa dà. Kò rọrùn láti ṣàdédé jáwọ́ níbẹ̀. Mo kọ́kọ́ ń rò pé tí mo bá sọ fún àwọn àjọ yẹn pé mi ò ṣe ẹgbẹ́ mọ́, ṣe ló máa dà bíi pé mo dalẹ̀ wọn. Àmọ́, ó pa dà wá yé mi pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè tún ilẹ̀ ayé wa yìí ṣe. Mo wá pinnu pé màá fi gbogbo ẹ̀mí mi kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run, màá tún máa ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè mọ̀ nípa rẹ̀.—Mátíù 6:33.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Torí pé, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ni mí, mo máa ń tètè gbà pé èèyàn rere tàbí èèyàn burúkú lẹnì kan, mo sì máa ń ta ko àwọn tí mo bá kà sí ẹni burúkú. Àmọ́, Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ kí n má máa kórìíra àwọn èèyàn. Ṣe ni mo wá ń sapá láti máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn báyìí. (Mátíù 5:44) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí mo fi ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn ni bí mo ṣe máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Inú mi dùn bí iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣe túbọ̀ ń jẹ́ kí àwọn èèyàn ní àlàáfíà àti ayọ̀, tó sì ń jẹ́ kí ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.

Ọkàn mi ti wá balẹ̀ bí mo ṣe fi ohun gbogbo sọ́wọ́ Jèhófà. Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá kò ní gbà kí wọ́n máa fìyà jẹ ẹranko àti àwọn èèyàn títí láé, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ba ilẹ̀ ayé wa tó lẹ́wà yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe. Láìpẹ́, ó máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fi tún gbogbo ohun tó ti bàjẹ́ ṣe. (Aísáyà 11:1-9) Ayọ̀ kún inú ọkàn mi pé mo mọ àwọn òtítọ́ yìí, kì í ṣe ìyẹn nìkan o, inú mi tún dùn pé mo ń ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ nínú òtítọ́ yìí. Kò ṣe mí mọ́ bíi pé mo gbọ́dọ̀ yí ayé yìí pa dà.