Òtítọ́
Ibo lo ti lè rí i?
Báwo ni òtítọ́ ṣe lè ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ láǹfààní?
A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ kí o wá gbọ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní àpéjọ ọlọ́jọ́-mẹ́ta tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe lọ́dún yìí.
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀:
‘Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!’
a gbé e ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 17:17.
ÀWỌN OHUN TÍ A MÁA GBÁDÙN:
Àsọyé alárinrin kan tó máa ṣàlàyé ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àkòrí rẹ̀ ni “Kí Ni Òtítọ́?”
A máa wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ méjì tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ìṣojú wa ni àwọn ìtàn Bíbélì ṣe ṣẹlẹ̀, tá á sì tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́.
ÀWỌN WO LA PÈ:
Gbogbo èèyàn la pè. Ọ̀fẹ́ ni, kò sí owó ìwọlé, a kì í sì í gbégbá ọrẹ.
ÀKÓKÒ ÀTI IBI TÍ A TI MÁA ṢE É:
Wá àpéjọ kan tó bá sún mọ́ ẹ, kí o sì wo fídíò tó dá lórí àwọn àpéjọ wa lórí ìkànnì www.isa4310.com. (Wo abẹ́ NÍPA WA/ÀWỌN ÀPÉJỌ)
Lọ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ yìí lórí ìkànnì www.isa4310.com. (Wo Àbẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE/ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ)