ILÉ ÌṢỌ́ April 2013 |

Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí ìgbésí ayé wa tó ládùn. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Wa Lè Ládùn Lóòótọ́?

Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ̀ bóyá ìgbésí ayé wa lè ládùn, pàápàá tí a bá wà nínú wàhálà tàbí ìbànújẹ́.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Ló Mú Kí Ìgbésí Ayé Jésù Ládùn?

“Wo mẹ́rin lára ohun tó mú kí ìgbésí ayé Jésù ládùn.”

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Jésù Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìgbésí Ayé Wa Ṣe Lè Ládùn

Ìrírí àwọn èèyàn fi hàn pé tí a bá ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè sílò, ìgbésí ayé wa máa ládùn.

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Esa rọ́wọ́ mú láàárín àwọn olórin, ó mọ̀ pé ìgbé ayé ire kọ́ ni òun ń gbé. Wo bí olórin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan ṣe rí ojúlówó ayọ̀.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Bíbélì fi pe ìlú Nínéfè ìgbàanì ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀”? Kí nìdí tí àwọn Júù fi máa ń ṣe ìgbátí yí òrùlé ilé wọn ká?

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbéèrè, A Ó sì Fi Í fún Yín”

Wo bí àpèjúwe méjì tí Jésù sọ nínú Lúùkù 11 ṣe ṣàlàyé bí ó ṣe lè dá ọ lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà rẹ.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

Kí ni a lè kọ́ lára Nóà, aya rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí o mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè lóye Bíbélì.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?

Ìtumọ̀ Bíbélì èyíkéyìí tó bá wù ẹ́ lo lè lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. O sì lè pe gbogbo ìdílé ẹ tàbí kó o pe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.