Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Kan Láti Orílẹ̀-èdè Benin

Ṣé Apá Mi Á Lè Ká Ohun Tí Mo Dáwọ́ Lé Yìí?

Ṣé Apá Mi Á Lè Ká Ohun Tí Mo Dáwọ́ Lé Yìí?

BÍ WỌ́N ṣe máa ń ṣe ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà ní òròòwúrọ̀ ni nǹkan rí gẹ́lẹ́ ní àárọ̀ ọjọ́ yìí. Òórùn ata ọbẹ̀ tí wọ́n ń sè àti ti ìrẹsì gba ilẹ̀ kan. Àwọn obìnrin ń kọjá pẹ̀lú ẹrù ńláńlá lórí wọn. Ariwo àti ẹ̀rín àwọn tó ń ná ọjà gbalẹ̀ kan. Oòrùn tètè yọ, kò sì pẹ́ rárá ti ibi gbogbo fi móoru.

Bí àwọn ọmọ kéékèèké kan ṣe rí mi pé mo jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí wọ́n máa ń pè ní Yovo, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin wọ́n sì ń jó kí wọ́n lè fi pàfiyèsí mi. Wọ́n fi “Yovo, Yovo, bon soir” bẹ̀rẹ̀ orin náà, ọ̀rọ̀ tó sì parí ni pé “ẹ̀bùn wo ni ẹ máa fún wa bí a ṣe dá yín lára yá?” Àmọ́ mo kíyè sí ọ̀kan nínú wọn tó jẹ́ ọkùnrin pé kò kọrin. Bí mo sì ṣe ń bá tèmi lọ, ló ń tẹ̀ lé mi, ó sì ń fi ọwọ́ ṣàpèjúwe. Ohun tí ó ń fọwọ́ ṣe jọ èdè àwọn adití. Nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi ọwọ́ ṣàpèjúwe ABD ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà (ASL), àmọ́ Faransé ni wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Benin tí mo wà.

Mo gbìyànjú láti fi ọwọ́ ṣàpèjúwe orúkọ mi. Ọmọkùnrin náà rẹ́rìn-ín múṣẹ́. Ó di ọwọ́ mi mú, ó sì mú mi gba inú àwọn horo kan lọ sí ilé wọn. Yàrá méjì ni ilé wọn yìí, búlọ́ọ̀kù ni wọ́n fi kọ́ ọ. Àwọn ará ilé ọmọ náà wá. Gbogbo wọn ń fi èdè adití bá ara wọn sọ̀rọ̀. Kí ni màá ṣe báyìí o? Mo wá fi ọwọ́ ṣàpèjúwe orúkọ mi, mo sì kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé pélébé kan láti sọ fún wọn pé, míṣọ́nnárì ni mí, pé mo máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, àti pé màá pa dà wá láti kọ́ wọn. Àwọn aládùúgbò míì tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ wá bá wa níbẹ̀, gbogbo wọn sì mi orí láti fi hàn pé àwọn náà nífẹ̀ẹ́ sí i. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn ara mi pé, ‘Ṣé apá mi á lè ká ohun tí mo dáwọ́ lé yìí?’

Nígbà tí mo délé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tó máa kọ́ àwọn èèyàn yìí ní ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé: “Etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.”’ (Aísáyà 35:5) Mo ṣe àwọn ìwádìí kan, ìyẹn ni mo fi mọ̀ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, iye àwọn tí wọ́n rí kà pé wọ́n jẹ́ adití tàbí tí wọn kò gbọ́ran dáadáa ní orílẹ̀-èdè Benin tó ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000]. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé ni mo rò pé wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn adití, àmọ́ ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí i pé Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ni wọ́n fi ń kọ́ wọn. Àmọ́ ó dùn mí gan-an pé kò tiẹ̀ wá sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbí yìí tó mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé fún Ẹlẹ́rìí kan tó wà ní àdúgbò yẹn pé, “Ó wù mí pé kí ẹnì kan tí ó mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà wá sí àdúgbò yìí kí ó lè ran àwọn odi tó wà níbí lọ́wọ́.” Àmọ́ èsì tó fún mi ni pé, “Ṣebí ìwọ wà níbí?” Òótọ́ ọ̀rọ̀ ló sì sọ! Mo bá kọ̀wé béèrè pé kí wọ́n fi ìwé tí mo lè fi kọ́ èdè náà fúnra mi àti àwọn àwo DVD ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà èyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ránṣẹ́ sí mi. Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́. Ó sì gbọ́. Ẹlẹ́rìí kan tó mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà dáadáa kó wá sí orílẹ̀-èdè Benin láti orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́ pé mò ń kọ́ èdè àwọn adití. Àwọn kan ní kí n dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brice. Iṣẹ́ ayàwòrán ló ń ṣe. Abẹ́ àtíbàbà kan ló ti ń ṣiṣẹ́, ibẹ̀ sì máa ń tutù láìka bí ojú ọjọ́ bá ṣe gbóná sí. Torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ló ti ń fi ọ̀dà tó wà lára búrọ́ọ̀ṣì nu ògiri tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, gbogbo ara ògiri náà ti di bálabàla. Ó nu orí àwọn àpótí kan, ó jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wò mí bíi pé kí n máa sọ ohun tí mo bá wá. Mo bá fi àwo DVD kan sínú ẹ̀rọ kékeré kan tí wọ́n fi ń wo DVD. Òun náà sì sún àpótí tó fi jókòó mọ́ ojú ẹ̀rọ yìí dáadáa, ó wá ń fi ọwọ́ ṣàpèjúwe pé “Ó yé mi! Ó yé mi!” Ká tó pajú pẹ́, àwọn ọmọ tó wà ládùúgbò ti ṣùrù bò wá, wọ́n sì ń na ọrùn kí wọ́n ṣáà lè rí ohun tí à ń wò. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ yẹn bá pariwo pé: “Kí ló dé tí wọ́n ń wo fíìmù tí kò sí ẹnì kankan tó ń sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀?”

Gbogbo ìgbà tí mo bá ti lọ sọ́dọ̀ Brice ni àwọn tó ń ṣùrù bo ẹ̀rọ DVD náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nígbà tó yá Brice àti àwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí mo ṣe ń gbìyànjú láti túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ ní ìpàdé fún wọn ní èdè àwọn adití jẹ́ kí n tètè mọ èdè náà dáadáa. Àwọn adití tí mò ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, kódà ṣe ni àwọn kan fúnra wọn wá mi wá. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo torí bí mo ṣe ń já sí kòtò àti gegele níbi tí mo ti ń gbìyànjú láti yà fún àwọn ewúrẹ́ àti ẹlẹ́dẹ̀ tó ń rìn gbéregbère lójú títì. Àfìgbà tí mo tún dédé gbọ́ gbì-gbì-gbì látẹ̀yìn. Mo kọ́kọ́ rò pé nǹkan míì ló tún bà jẹ́ lára ọkọ̀ mi, àṣé ọkùnrin odi kan tó ń sáré tẹ̀ lé ọkọ̀ mi ló fọwọ́ lu ara ọkọ̀ náà gbì-gbì-gbì kí n lè fi mọ̀ pé òun ń pè mí!

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà gbèrú láwọn ìlú ńlá tó kù. Nígbà àpéjọ ńlá tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún, mo wà lára àwọ́n tí wọ́n ṣètò pé ó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ tó bá ń lọ lọ́wọ́ sí èdè àwọn adití. Bí mo ṣe bọ́ sórí pèpéle, tí mò ń retí kí ẹni tó máa sọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo rántí ìgbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Mo máa ń rò ó pé, ‘Kí ni mo tún lè ṣe gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nárì ní ilẹ̀ Áfíríkà?’ Bí mo ti ń wo ọ̀pọ̀ èèyàn tó jókòó látorí pèpéle, mo mọ̀ pé mo ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè mi. Ìdáhùn náà sì ni pé ó yẹ kí n di míṣọ́nnárì tó ń ran àwọn adití lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mi ò tún bi ara mi mọ́ pé ‘Ṣé apá mi á lè ká ohun tí mo dáwọ́ lé yìí?’