Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Nípa Gbèsè
Giannis: * “Nígbà tí ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Gíríìsì dẹnu kọlẹ̀, òwò tí mò ń ṣe fọ́, a kò lè san owó tí a yá fi kọ́lé pa dà déédéé mọ́, a kò sì lè san gbèsè orí káàdì tá a fi ń ra ọjà àwìn mọ́. Ìdààmú bá mi, mi ò tiẹ̀ lè sùn.”
Katerina: “Gbogbo ohun tó gbà la ṣe ká tó lè kọ́ ilé wa, ilé náà sì tù wá lára gan-an, ìyẹn ni mi ò ṣe fẹ́ gbọ́ ọ sétí rárá pé ó máa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Àìmọye ìgbà ni èmi àti Giannis ti bá ara wa fa ọ̀rọ̀ bá a ṣe máa san gbèsè wa.”
GBÈSÈ lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé tàbí kó tiẹ̀ tú ìdílé ká pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, olùwádìí kan tí ó ń jẹ́ Jeffrey Dew rí i pé àwọn tọkọtaya tó bá jẹ gbèsè kì í sábà rójú ráyè gbọ́ ti ara wọn, wọ́n máa ń jà lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀. Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí tọkọtaya máa ń jiyàn lé lórí, ìjiyàn nípa ọ̀rọ̀ owó àti gbèsè ló máa ń pẹ́ nílẹ̀ jù. Òun ló máa ń fa ariwo jù tàbí kó mú wọn yọwọ́ ìjà sí ara wọn tàbí kó tiẹ̀ fa wàhálà míì. Abájọ tó fi jẹ́ pé ìjà lórí ọ̀rọ̀ owó ni ohun tó ń fa ìkọ̀sílẹ̀ jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Tí gbèsè bá pọ̀, ó máa ń ṣàkóbá fún ìlera ẹni pàápàá. Ó lè fa àìrí oorun sùn, ẹ̀fọ́rí, inú rírun, àrùn ọkàn, àti ìdààmú ọkàn. Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Marta sọ pé: “Àárẹ̀ ọkàn tó bá ọkọ mi torí gbèsè wa pọ̀ débi pé ṣe ló kàn ń sùn ṣáá bí olókùnrùn. Gbogbo nǹkan wá dojú rú fún ọkọ mi akíkanjú tó jẹ́ aláfẹ̀yìntì mi.” Ìdààmú gbèsè tiẹ̀ máa ń jẹ́ kí ẹlòmíràn ro ayé ara rẹ̀ pin. Bí àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn BBC News, ròyìn pé obìnrin kan ní ilẹ̀ Íńdíà pa ara rẹ̀ torí pé owó tó yẹ kó máa san díẹ̀díẹ̀ lórí gbèsè kan tó jẹ ti ṣẹ́ jọ sí i lọ́rùn. Tí a bá ṣírò iye tó ṣẹ́ jọ sí i lọ́rùn ní náírà, ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà ààbọ̀ ó lé igba [130,200] náírà. Ṣe ló yá owó tó di gbèsè sí i lọ́rùn yìí láti fi sanwó ìtọ́jú ìṣègùn àwọn ọmọ rẹ̀.
Tí gbèsè bá wá di wàhálà sí ìdílé kan lọ́rùn, kí ni wọ́n lè ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìṣòro kan tó sábà máa ń bá tọkọtaya tó bá jẹ gbèsè, a ó sì wo àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n á fi lè yanjú àwọn ìṣòro náà.
ÌṢÒRO KÌÍNÍ: Àwa méjèèjì ń dẹ́bi fún ara wa.
Lukasz sọ pé: “Mo dá ìyàwó mi lẹ́bi pé òun ló máa ń náwó ní ìnákúnàá, òun náà sì ń ṣàròyé pé ká ní mo níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ ni owó kò ní wọ́n wa.” Kí ni tọkọtaya lè ṣe tí gbèsè kò fi ní da àárín wọn rú?
Bí ẹ ṣe lè ṣàṣeyọrí: Ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ọ̀rọ̀ gbèsè náà.
Kò ní dáa kó o máa kanra mọ́ ẹnì kejì rẹ ká tiẹ̀ sọ pé ìwọ kọ́ lo fa gbèsè náà, torí ariwo ẹnu kò san gbèsè. Àsìkò yìí gan-an ló tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì pé kí ẹ fi ìmọ̀ràn inú Éfésù 4:31 sílò. Ó ní: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”
Gbèsè ni kẹ́ ẹ bá jà, ẹ má ṣe bára yín jà. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Stephanos sọ bí òun àti aya rẹ̀ ṣe jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó ní: “Ṣe ni a ka gbèsè náà sí ọ̀tá àwa méjèèjì.” Irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni Òwe 13:10 dámọ̀ràn, ó ní: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” Dípò kí o gbìyànjú láti fi ìkùgbù dá yanjú ọ̀rọ̀ náà, ṣe ni kí ẹ jọ fi òótọ́ inú bá ara yín sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ìnáwó yín, kí ẹ sì jọ wá nǹkan ṣe sí wọn.
Ẹ lè pe àwọn ọmọ yín mọ́ra kí àwọn náà lè kọ́wọ́ ti ìsapá yín. Bàbá kan tó ń jẹ́ Edgardo, ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ̀, ó ní: “Ọmọ mi ọkùnrin fẹ́ ká ra kẹ̀kẹ́ tuntun fún òun. Àmọ́ a ṣàlàyé ìdí tí a ò fi ní lè rà á fún un. A wá gbé kẹ̀kẹ́ tí bàbá àgbà lò fún un, ó sì wá fẹ́ràn kẹ̀kẹ́ náà gan-an. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó kí ìdílé máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ wá àsìkò kan tí ẹ̀yin méjèèjì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ nípa gbèsè yín, ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ pa mọ́ fún ara yín. Kí kálukú yín sì gba àṣìṣe rẹ̀ láṣìṣe. Dípò tí ẹ ó fi ránnu mọ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ṣe ni kí ẹ jọ fẹnu kò lórí àwọn ìlànà tí ẹ ó máa tẹ̀ lé báyìí lórí ọ̀rọ̀ ìnáwó tí ẹ bá máa ṣe.—Sáàmù 37:21; Lúùkù 12:15.
ÌṢÒRO KEJÌ: Tí gbèsè bá fẹ́ di àsantì.
Ọ̀gbẹ́ni Enrique sọ pé: “Gbèsè tí mo jẹ nídìí òwò mi pọ̀ gan-an, ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Ajẹntínà tó dẹnu kọlẹ̀ sì tún bọ̀rọ̀ jẹ́. Wọ́n tún wá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún ìyàwó mi. Ó wá dà bíi pé mi ò ní lè bọ́ nínú gbèsè, àfi bí ìgbà tí eṣinṣin kó sínú okùn aláǹtakùn.” Gbogbo owó ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Roberto ní ilẹ̀ Brazil, run sórí òwò kan tó tọrùn bọ̀. Ó sì jẹ báńkì méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní gbèsè. Ó ní: “Ojú tì mí débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa sá fún àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé arungún ni mí.”
Kí ni ẹ lè ṣe tí gbèsè bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì, ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìtìjú bá yín?
Bí ẹ ṣe lè ṣàṣeyọrí: Ẹ fi ètò sí bí ẹ ó ṣe máa náwó. *
1. Ẹ mọ iye tó ń wọlé fún yín àti iye tí ẹ̀ ń ná. Ẹ kọ gbogbo iye owó tó ń wọlé fún ìdílé yín àti bí ẹ ṣe ń náwó láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tàbí kó tiẹ̀ tó oṣù kan tó bá jẹ́ pé ìyẹn ló máa pé yín jù. Ẹ tún ṣírò àwọn ìnáwó tí ẹ máa ń ṣe ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan, irú bí owó orí, owó ìbánigbófò tàbí owó aṣọ, kí ẹ wá pín in sí ọ̀nà méjìlá láti fi mọ iye tí gbogbo rẹ̀ kú sí lóṣooṣù. Ẹ wá fi ìyẹn náà kún àkọsílẹ̀ tí ẹ kọ́kọ́ ṣe.
2. Ẹ wá bí owó tó ń wọlé fún yín ṣe máa pọ̀ sí i. Ẹ lè wá iṣẹ́ kún iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe báyìí, ẹ lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló máa ń yọ, ẹ lè wá ẹni tí ẹ lè máa kọ́ níwèé tàbí tí ẹ lè kọ́ ní iṣẹ́ tí á sì sanwó, ẹ lè máa ta àwọn nǹkan àlòkù, ẹ sì lè kúkú sọ iṣẹ́ tẹ́ ẹ sábà máa fi ń pawọ́ nínú ilé di òwò. Àkíyèsí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ gba àsìkò àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì mọ́ yín lọ́wọ́, irú bí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ti ìjọsìn Ọlọ́run tí ẹ máa ń ṣe.
3. Ẹ dín ìnáwó yín kù. Ẹ má kàn máa ra ohun tí ẹ bá ti rí lórí igbá, kìkì ohun tí ẹ bá nílò ni kẹ́ ẹ máa rà. (Òwe 21:5) Ọ̀gbẹ́ni Enrique tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó dáa kéèyàn máa ní sùúrù dáadáa kó tó ra nǹkan, èyí máa jẹ́ kó lè mọ̀ bóyá òótọ́ ló nílò rẹ̀ àbí ṣe ló kàn wù ú pé kó ní in.” Àwọn nǹkan míì tí ẹ tún lè ṣe nìyí.
-
Ilé gbígbé: Tó bá ṣeé ṣe, ẹ kó lọ sí ilé míì tí owó rẹ̀ kò pọ̀ tó ibi tí ẹ wà báyìí. Ẹ dín ìnáwó yín lórí àwọn ohun amáyédẹrùn kù, irú bí iná mànàmáná, omi, ẹ̀rọ amúlétutù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
-
Oúnjẹ: Ẹ máa gbé oúnjẹ tàbí ìpápánu dání dípò tí ẹ ó fi jẹ́ kó mọ́ yín lára láti máa lọ ra oúnjẹ jẹ níta. Ẹ máa lọ rajà níbi tí ẹ ti lè rí i rà lọ́pọ̀ tàbí ibi tí wọ́n ti fẹ́ ta ọjà ní ẹ̀dínwó. Joelma ní ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Tí mo bá lọ sí ọjà lásìkò tí wọ́n fẹ́ máa palẹ̀ mọ́, mo máa ń rí èso àti ewébẹ̀ rà ní owó pọ́ọ́kú.”
-
Ohun Ìrìnnà: Ẹ ta ohun ìrìnnà tí ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ nílò. Ẹ tọ́jú èyí tí ẹ̀ ń lò dáadáa, dípò tí ẹ ó fi máa sáré bí ẹ ṣe máa ra àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Ẹ tún lè wọ ọkọ̀ èrò tàbí kí ẹ fi ẹsẹ̀ rìn nígbà tó bá ṣeé ṣe.
Tí ẹ bá ti wá dín ìnáwó yín kù, ẹ ó lè lo owó tí ẹ bá ní lọ́wọ́ lọ́nà tó dáa.
4. Ẹ ṣàyẹ̀wò gbèsè yín kí ẹ sì wá nǹkan ṣe sí i. Ẹ kọ́kọ́ wo iye èlé tí wọ́n sọ pé kí ẹ máa san lórí gbèsè kọ̀ọ̀kan, owó iṣẹ́ tí àwọn tó yáni lówó máa gbà, ohun tí àwọn tí ẹ jẹ ní gbèsè máa ṣe tí ẹ bá pẹ́ sanwó tàbí tí ẹ kò bá rí owó san rárá. Kí ẹ sì tún wò ó bóyá àsìkò tó yẹ kí ẹ san owó kan tiẹ̀ ti kọjá. Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí gbogbo ohun tí ayánilówó sọ nípa owó tí ẹ yá tàbí àlàyé inú ìwé tí ẹ fi ń sanwó ọjà àwìn tí ẹ rà, torí wọ́n lè fẹ̀tàn múni tọrùn bọ gbèsè. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tó ń yáni lówó ní Amẹ́ríkà sọ pé tí àwọn bá yá ẹnì kan ní ọgọ́rùn-ún náírà, ẹni yẹn yóò fi san náírà mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [124]. Àmọ́ ẹ̀tàn ni o, torí ó ju irínwó [400] náírà tí onítọ̀hún máa fi san pa dà!
Lẹ́yìn náà, ẹ wá pinnu èyí tí ẹ máa kọ́kọ́ gbájú mọ́ nínú àwọn gbèsè náà. Ọ̀nà kan ni pé kí ẹ kọ́kọ́ máa san gbèsè tí èlé orí rẹ̀ ga jù ná. Ọ̀nà míì ni pé kí ẹ kọ́kọ́ san àwọn gbèsè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, èyí á mú kí ọkàn yín balẹ̀ torí pé àwọn tí yóò máa sìn yín lówó lóṣooṣù yóò dín kù. Tí èlé orí àwọn gbèsè kan bá pọ̀ gan-an, ó lè ṣàǹfààní tí ẹ bá yá owó tí èlè orí rẹ̀ kéré níbòmíì, láti fi san àwọn gbèsè tí èlé orí rẹ̀ pọ̀ kúrò nílẹ̀.
Àmọ́, tó bá wá di pé apá yín kò fẹ́ ká gbèsè náà, ẹ lè lọ bá àwọn tí ẹ jẹ ní gbèsè, kí ẹ jọ tún àdéhùn ṣe nípa bí ẹ ṣe lè rí gbèsè náà san. Ẹ lè bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n fún yín ní àsìkò díẹ̀ sí i tàbí kí wọ́n bá yín dín èlé orí rẹ̀ kù. Àwọn kan tiẹ̀ lè gbà láti dín gbèsè tí ẹnì kan jẹ wọ́n kù, tó bá ti lè san iye tí wọ́n dín gbèsè rẹ̀ kù sí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Tí ẹ bá ń ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí fún yín báyìí, ẹ sòótọ́ fún wọn kí ẹ sì sọ̀rọ̀ lọ́nà ọmọlúwàbí. (Kólósè 4:6; Hébérù 13:18) Ẹ rí i dájú pé ẹ kọ ohun tí ẹ bá jọ fẹnu kò sí sílẹ̀. Ká tiẹ̀ wá sọ pé nígbà tí ẹ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ yìí lọ̀ wọ́n, wọn kò gbà, ẹ má fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ títí wọ́n á fi ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ náà.—Òwe 6:1-5.
Àmọ́ ṣá o, ó máa dáa kí ẹ tún fi sọ́kàn pé ètò ìnáwó tí ẹ ṣe lè yí pa dà. Torí àwọn nǹkan téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀ ṣì lè mú kí ètò ìnáwó tó dáa jù pàápàá dà rú mọ́ni lọ́wọ́. Ìdí ni pé owó sábà “máa ń ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bí ti idì, a sì fò lọ sí ojú ọ̀run.”—Òwe 23:4, 5.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tí ẹ bá ti parí iṣẹ́ lórí ètò ìnáwó ìdílé yín, ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo yín ṣe
lè dín ìnáwó kù tàbí ohun tí ẹ máa ṣe tí owó tó ń wọlé fún ìdílé yín á fi pọ̀ sí i. Tí ẹ bá ń rí ìsapá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín, èyí lè mú kí ẹ túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí gbèsè má bàa wáyé mọ́.ÌṢÒRO KẸTA: Gbèsè gbà wá lọ́kàn pátápátá.
Téèyàn bá ń sáré bó ṣe máa yanjú gbèsè, ó lè máà ráyè láti ṣe àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì gan-an. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Georgios sọ pé: “Ohun tó wá burú jù ni pé a ò tiẹ̀ ráyè nǹkan míì mọ́ ju gbèsè tí a jẹ lọ. Ṣe la kúkú wá pa àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì ju gbèsè yẹn lọ tì.”
Bí ẹ ṣe lè ṣàṣeyọrí: Ẹ fi owó sí àyè tó yẹ ẹ́.
Pẹ̀lú gbogbo ìsapá yín, ó ṣì lè gbà yín ní ọ̀pọ̀ ọdún kí ẹ tó san gbèsè yín tán. Ṣùgbọ́n láàárín àsìkò yẹn, ẹ̀yin lẹ máa pinnu irú ojú tí ẹ ó máa fi wo ipò tí ẹ wà. Ohun tó tiẹ̀ dáa ni pé, dípò tí a ó fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ níní owó tàbí àìlówó lọ́wọ́ gbà wá lọ́kàn, ṣe ló yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:8.
Tí ẹ kò bá ti dààmú jù nípa ipò tí ẹ wà, ẹ ó lè ráyè láti “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Ara “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” yìí ni àjọṣe ẹ̀yin àti Ọlọ́run àti àjọṣe tó wà láàárín ẹ̀yin àti ìdílé yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kó bà jẹ́. Ọ̀gbẹ́ni Georgios, tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lóòótọ́, a ò tíì san gbogbo gbèsè wa tán, ṣùgbọ́n a kò jẹ́ kó gbà wá lọ́kàn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. À ń láyọ̀ báyìí, torí pé a túbọ̀ ń ráyè ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run dáadáa, a sì ń ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wa àti ara wa dáadáa.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ kọ àwọn nǹkan tí ẹ kà sí pàtàkì jù, àmọ́ tí kò ṣeé fowó rà. Ẹ wá pinnu bí ẹ ṣe lè túbọ̀ fi kún àkókò tí ẹ n lò àti ìsapá tí ẹ ń ṣe lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Gbèsè máa ń kóni láyà sókè, ó sì máa ń gba kéèyàn ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti lè san án; àmọ́ téèyàn bá lè bọ́ níbẹ̀ àǹfààní rẹ̀ pọ̀ jọjọ. Baálé ilé kan tó ń jẹ́ Andrzej ní ilẹ̀ Poland, sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé ìyàwó mi ló ṣe onídùúró fún ẹnì kan níbi iṣẹ́ wọn tó lọ yá owó tó sì gbé owó náà sá lọ, nǹkan kò rọgbọ nínú ilé wa rárá.” Àmọ́ nígbà tó ń sọ bí òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe wá yanjú ọ̀rọ̀ náà, ó ní: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbèsè yẹn dà wá láàmú, bí a ṣe jọ pawọ́ pọ̀ ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà mú ká túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan.”
^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ Tí o bá ń fẹ́ ìmọ̀ràn síwájú sí i lórí èyí, wo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí náà “Bí O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná” nínú Jí! January–March 2012. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
BI ARA RẸ PÉ . . .
-
Kí ni mo lè ṣe tí ìdílé wa á fi lè bọ́ nínú gbèsè?
-
Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ gbèsè jẹ wá lógún ju ara wa lọ, tàbí kí ó ba àárín wa jẹ́?