Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Ó Dìgbà Téèyàn Bá Lọ́kọ Tàbí Téèyàn Bá Láya Kó Tó Lè Láyọ̀?
Ṣé Bíbélì fi kọ́ni pé èèyàn gbọ́dọ̀ níyàwó tàbí kí ó lọ́kọ kó tó lè kógo já kó sì máa láyọ̀? Tí a bá kọ́kọ́ wo inú Bíbélì, ó lè fẹ́ dà bíi pé èrò tó ń gbìn sọ́kàn ẹni nìyẹn. Lọ́nà wo?
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Ọlọ́run rí i pé “kò dára” kí Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ wà ní òun nìkan. Ó sì dá Éfà gẹ́gẹ́ bí “àṣekún” fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ọ̀rọ̀ náà “àṣekún” túmọ̀ sí ohun kan tó mú kí ohun mìíràn pé tàbí kó kún rẹ́rẹ́. Àkọsílẹ̀ yìí lè jẹ́ kí á wá rò pé tí ẹnì kan kò bá tíì lọ́kọ tàbí láya, kò tíì pé. Yàtọ̀ sí èyí, ọ̀pọ̀ ìtàn inú Bíbélì ló fi hàn pé ìgbéyàwó máa ń yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún àti ayọ̀. Ìtàn Rúùtù jẹ́ àpẹẹrẹ kan.
Ṣé a wá lè sọ pé ohun tí irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń kọ́ wa ni pé àwọn Kristẹni òde òní kò lè láyọ̀, kí wọ́n jẹ́ ẹni tó kógo já tàbí ẹni tó pé àfi tí wọ́n bá lọ́kọ tàbí láya kí wọ́n sì bímọ? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tó pé jù tó sì kógo já jù nínú gbogbo ẹni tó tíì gbé láyé ni Jésù Kristi. Síbẹ̀, àpọ́n ni títí tó fi kú. Jésù tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n jù láyé yìí sì tún jọ Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀” pátápátá láìkù síbì kan. (1 Tímótì 1:11; Jòhánù 14:9) Jésù sọ àwọn ohun tó lè mú kéèyàn jẹ́ aláyọ̀ tàbí ẹni ìbùkún nínú ayé yìí. (Mátíù 5:1-12) Kò sọ pé ìgbéyàwó wà lára nǹkan wọ̀nyẹn.
Ṣé Bíbélì wá ta ko ara rẹ̀ lórí kókó yìí ni? Rárá o. Ṣe ló yẹ ká máa wo ìgbéyàwó pa pọ̀ mọ́ gbogbo ohun tó jẹ́ ète Jèhófà. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run ṣe ètò ìgbéyàwó lọ́nà táá fi lè mú kí tọkọtaya máa láyọ̀, kí wọ́n máa ní àjọṣepọ̀ lọ́kọláya, kí wọ́n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí tún kó ipa pàtàkì nínú mímú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ ní àwọn ọ̀nà kan. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá Ádámù àti Éfà ni pé kí wọ́n “máa so èso, kí [wọ́n] sì di púpọ̀, kí [wọ́n] sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Kò sí ìkankan nínú Ádámù àti Éfà tó lè dá ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, kálukú wọn nílò ẹnì kejì, ṣe ni ìkíní sì mú kí ìkejì pé lọ́nà tó ṣe rẹ́gí.
Lọ́nà kan náà, nígbà tí orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ṣì jẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó lo ìgbéyàwó àti ìdílé láàárín wọn láti fi mú àwọn ète rẹ̀ pàtàkì ṣẹ. Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tó yàn yìí pọ̀, kí àwọn ọ̀tá wọn má bàa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ó tún jẹ́ ète Ọlọ́run pé inú ẹ̀yà Júdà ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà, ẹni tó máa gba àwọn èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì gan-an lójú àwọn obìnrin olóòótọ́ ní Ísírẹ́lì pé kí wọ́n lọ́kọ kí wọ́n sì bímọ, ìdí sì tún nìyẹn tó fi máa ń jẹ́ ìtìjú àti ìbànújẹ́ gbáà fún ẹni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Lóde òní ńkọ́? Ṣé àṣẹ tí Ọlọ́run pa láyé ìgbà yẹn pé kí àwọn èèyàn “kún ilẹ̀ ayé,” wá kàn án nípá fún àwọn Kristẹni tó wà nínú ayé tí èèyàn ti kún fọ́fọ́ báyìí, pé wọ́n ṣáà gbọ́dọ̀ gbéyàwó kí wọ́n sì bímọ? Rárá. (Mátíù 19:10-12) Bákan náà, kò tún sí pé Ọlọ́run ń dáàbò bo ìlà ìdílé kan tí Mèsáyà ti máa wá mọ́ tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti máa bí Olùgbàlà. Irú ojú wo ló wá yẹ kí àwọn Kristẹni máa fi wo níní ọkọ tàbí aya àti wíwà láìní ọkọ tàbí aya?
Ní tòdodo, ipò méjèèjì la lè sọ pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bí ẹ sì ṣe mọ̀, ẹ̀bùn kan tó wúlò gan-an fún ẹnì kan lè máà wúlò rárá fún ẹlòmíì. Ìgbéyàwó jẹ́ ètò mímọ́ kan tó jẹ́ ibi tí ìfẹ́ tí lè jọba, ibi téèyàn ti lè ní ẹnì kejì tó jẹ́ alábàárò rẹ̀, àti ibi tó fini lọ́kàn balẹ̀ láti tọ́jú ìdílé. Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, Bíbélì sojú abẹ níkòó fún wa pé àwọn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó nínú ayé búburú yìí yóò ní àwọn ìṣòro tàbí “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Ní ti wíwà láìní ọkọ tàbí aya, Jèhófà kò ka ìyẹn sí nǹkan ìtìjú tàbí ìbànújẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé wíwà láì ṣègbéyàwó ní àwọn àǹfààní pàtàkì kan nínú ju ṣíṣe ìgbéyàwó lọ.—1 Kọ́ríńtì 7:28, 32-35.
Gbogbo èyí fi hàn pé Bíbélì kò fì sí apá kan jùkan lọ lórí ọ̀rọ̀ níní ọkọ tàbí aya àti wíwà láìní ọkọ tàbí aya. Jèhófà tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó àti ìdílé fẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ òun jẹ́ aláyọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó kógo já yálà wọ́n ní ọkọ tàbí aya tàbí wọn kò ní.