Ọkùnrin Kan Tí Ó Tẹ́ Ọkàn Jèhófà Lọ́rùn
Ọkùnrin Kan Tí Ó Tẹ́ Ọkàn Jèhófà Lọ́rùn
NÍGBÀ tí o bá ń ronú nípa Dáfídì tí ìtàn rẹ̀ wà nínú Bíbélì, kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé bó ṣe ṣẹ́gun òmìrán Filísínì tó ń jẹ́ Gòláyátì ni? Ṣé bó ṣe ń sá kiri nínú aginjù nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba gbógun tì í ni? Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ìṣòro tó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ náà ni? Àbí ewì tí Ọlọ́run mí sí tí ó kọ, èyí tó wà nínú ìwé Sáàmù inú Bíbélì ni?
Lákòókò tí Dáfídì gbé láyé, ó ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó ja àjàṣẹ́gun, àjálù sì tún dé bá a. Síbẹ̀, ohun tó fà wá mọ́ra jù lọ nípa Dáfídì ni àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Sámúẹ́lì sọ nípa rẹ̀ pé, ó máa jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [Jèhófà] lọ́rùn.”—1 Sámúẹ́lì 13:14.
Àsọtẹ́lẹ̀ tí Sámúẹ́lì sọ yìí ṣẹ nígbà tí Dáfídì ṣì wà ní ọ̀dọ́. Ṣé ìwọ náà fẹ́ jẹ́ ẹni tó tẹ́ ọkàn Jèhófà lọ́rùn? Kí ni ohun tí Dáfídì fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, pàápàá nígbà èwe rẹ̀, èyí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
Ìdílé àti Iṣẹ́ Rẹ̀
Ọmọ ọmọ Bóásì àti Rúùtù ni Jésè tó jẹ́ bàbá Dáfídì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni Jésè. Láti kékeré ni Jésè ti kọ́ Dáfídì àtàwọn arákùnrin rẹ̀ méje pẹ̀lú àwọn arábìnrin rẹ̀ méjì ní Òfin Mósè. Nínú ọ̀kan lára àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ, ó pe ara rẹ̀ ní ọmọ “ẹrúbìnrin” Jèhófà. (Sáàmù 86:16) Èyí ló mú kí àwọn kan rò pé ìyá Dáfídì tún ní ipa tó dára lórí ìjọsìn Dáfídì sí Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ orúkọ obìnrin náà. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, “Ó lè jẹ́ pé látẹnu ìyá rẹ̀ ló kọ́kọ́ ti gbọ́ ìtàn àgbàyanu nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀,” títí kan ìtàn nípa Rúùtù àti Bóásì.
Ohun tá a kọ́kọ́ mọ̀ nípa Dáfídì ni pé, ó jẹ́ ọmọdékùnrin kan tó ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. Iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí lè gba pé kó máa wà lóun nìkan fún àkókò gígun lọ́sàn-án àti lóru nínú pápá. Fojú inú wo bó ṣe rí.
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú kékeré tó wà ní orí òkè àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kéékèèké Júdà ni Dáfídì àtàwọn ará ilé rẹ̀ ń gbé. Àwọn nǹkan ọ̀gbìn oníhóró máa ń méso jáde dáadáa láwọn pápá olókùúta tó wà yí ká Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àwọn igi eléso, àwọn igi ólífì àtàwọn ọgbà àjàrà ló wà ní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àti àfonífojì ibẹ̀. Nígbà ayé Dáfídì, ó jọ pé àwọn ilẹ̀ tí wọn kì í dáko sí tó wà láàárín àwọn òkè náà ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹran jẹko. Ní ìkọjá àwọn ilẹ̀ yẹn ni aginjù Júdà wà.
Iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí Dáfídì ń ṣe kò ṣàìní ewu nínú. Ní àárín àwọn òkè yìí ló ti gbéjà ko kìnnìún àti béárì tó gbé àgùntàn nínú agbo ẹran. * Ọ̀dọ́kùnrin onígboyà yìí lé àwọn ẹranko ajẹranjeegun yìí, ó pa wọ́n, ó sì gba àwọn àgùntàn náà lẹ́nu wọn. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Ó lè jẹ́ pé ní àkókò yìí ni Dáfídì kọ́ bí ó ṣe lè lo kànnàkànnà. Ibi tí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wà kò jìnnà sí ìlú ìbílẹ̀ Dáfídì. Àwọn tó jẹ́ atamátàsé nínú ẹ̀yà yìí lè fi kànnàkànnà gbọn òkúta ba “fọ́nrán irun tí kò sì ní tàsé.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Dáfídì ṣe máa ń gbọn kànnàkànnà bá nǹkan láìtàsé.—Àwọn Onídàájọ́ 20:14-16; 1 Sámúẹ́lì 17:49.
Ó Lo Àkókò Náà Lọ́nà Rere
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, iṣẹ́ darandaran máa ń mú kéèyàn dá wà níbi tí kò sí ariwo. Àmọ́, Dáfídì kò jẹ́ kí ìyẹn mú nǹkan sú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìparọ́rọ́ ibi àdádó yẹn fún un ní àǹfààní láti máa ṣàṣàrò. Ó jọ pé àwọn kan lára àṣàrò tí Dáfídì ṣe nígbà tó wà ní ọ̀dọ́ wà Sáàmù 8:3-9; 19:1-6.
nínú àwọn sáàmù tó kọ. Àbí ìgbà tó wà ní àdádó yẹn ló ronú jinlẹ̀ lórí ipò tí èèyàn wà tá a bá fi wé bí Ọlọ́run ṣe ṣètò ayé àtọ̀run àtàwọn nǹkan ìyanu tó wà lójú ọ̀run, ìyẹn oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀, tí wọ́n jẹ́ “àwọn iṣẹ́ ìka [Jèhófà]”? Tàbí kẹ̀, ṣé ìgbà tó wà nínú pápá tó yí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ká yẹn ló ronú nípa ilẹ̀ eléso, ẹran ọ̀sìn àti màlúù, àwọn ohun abìyẹ́ àti “àwọn ẹranko pápá gbalasa”?—Kò sí àní-àní pé, ohun tí Dáfídì mọ̀ nígbà tó ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló mú kó túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi ń bójú tó àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn rẹ̀. Ìyẹn ló mú kí Dáfídì kọrin pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.”—Sáàmù 23:1, 2, 4.
O lè máa ṣe kàyéfì pé, báwo ni gbogbo nǹkan tá a ti ń sọ bọ̀ yìí ṣe kàn mí? Ìdáhùn náà ni pé ọ̀kan lára ìdí tí Dáfídì fi ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, tí ó sì pè é ní ‘ọkùnrin tí ó tẹ́ ọkàn òun lọ́rùn’ ni pé, Dáfídì máa ń ṣe àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí àwọn iṣẹ́ Jèhófà àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Lẹ́yìn tó o ti fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, ǹjẹ́ ìyẹn mú kó o fi ìyìn àti ògo fún Ẹlẹ́dàá? Ǹjẹ́ ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní fún Jèhófà kò túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tó o rí irú Ọlọ́run tó jẹ́ látinú bó ṣe ń ṣe sí aráyé? Àmọ́ ṣá o, kó o tó lè fi irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ hàn fún Jèhófà, o ní láti ya àkókò sọ́tọ̀ níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́ kó o sì fi tàdúràtàdúrà ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lórí àwọn ohun tó dá. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ Jèhófà dáadáa, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tàgbàtèwe ni àǹfààní yìí wà fún. Ó jọ pé ní gbogbo ọ̀nà, Dáfídì sún mọ́ Jèhófà láti ìgbà èwe rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
Ọlọ́run Fòróró Yan Dáfídì
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba sọ ara rẹ̀ di ẹni tí kò yẹ láti máa ṣe aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run, Jèhófà sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé èmi, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti kọ̀ ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì? Fi òróró kún ìwo rẹ, kí o sì lọ. Èmi yóò rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí pé mo ti pèsè ọba fún ara mi lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 16:1.
Nígbà tí Sámúẹ́lì dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó ní kí Jésè pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jọ. Èwo nínú wọn ni Sámúẹ́lì máa fòróró yàn láti di ọba? Nígbà tí Sámúẹ́lì rí bí Élíábù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n pátápátá ṣe rẹwà tó, ó ní: ‘Òun nìyí.’ Àmọ́, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan [ni 1 Sámúẹ́lì 16:7, 11.
Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan], nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” Bákan náà, Jèhófà kọ Ábínádábù, Ṣámáhì àtàwọn mẹ́rin míì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn. Ìtàn náà ń bá a lọ pé: “Níkẹyìn, Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: ‘Gbogbo àwọn ọmọdékùnrin náà ha nìyí bí?’ Ó fèsì pé: ‘Èyí àbíkẹ́yìn ni ó ṣẹ́ kù títí di ìsinsìnyí, sì wò ó! ó ń kó àwọn àgùntàn jẹ koríko.’”—Ó jọ pé ohun tí ìdáhùn Jésè túmọ̀ sí ni pé: ‘Dáfídì ti kéré jù, kò lè jẹ́ ẹni tó o máa fi òróró yàn.’ Nítorí pé Dáfídì ló kéré jù lọ, tí kò sì fí bẹ́ẹ̀ sí ní ipò pàtàkì nínú ìdílé, òun ni wọ́n ní kó máa lọ bójú tó àwọn àgùntàn. Àmọ́, òun lẹni tí Ọlọ́run yàn. Jèhófà mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn èèyàn, ó dájú pé ó ti rí ohun tó ṣeyebíye kan nínú Dáfídì. Nítorí náà, Jésè rán àwọn kan láti lọ mú Dáfídì wá, nígbà tí wọ́n dé, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “‘Dìde, fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì fòróró yàn án láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.”—1 Sámúẹ́lì 16:12, 13.
Wọn kò sọ ọjọ́ orí Dáfídì nígbà tí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn ìgbà yẹn, Élíábù, Ábínádábù àti Ṣámáhì tí wọ́n dàgbà jù lára ẹ̀gbọ́n Dáfídì di ara ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Ó lè jẹ́ nítorí pé àwọn márùn-ún yòókù kéré gan-an ni wọn kò ṣe bá wọn lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò sí èyí tó ti pé ogún ọdún lára wọn, ìyẹn ọdún tí àwọn ọkùnrin máa ń wọ iṣẹ́ ológun nílẹ̀ Ísírẹ́lì. (Númérì 1:3; 1 Sámúẹ́lì 17:13) Ohun yòówù kó jẹ́, Dáfídì kéré gan-an nígbà tí Jèhófà yàn án. Àmọ́ nígbà yẹn, Dáfídì ti fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa. Ó dájú pé ríronú jinlẹ̀ lórí ohun tó mọ̀ nípa Jèhófà ló mú kó ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú rẹ̀.
Ó yẹ kí a gba àwọn ọ̀dọ́ òde òní níyànjú láti máa ṣe bíi ti Dáfídì. Nítorí náà, ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀ ń gba àwọn ọmọ yín níyànjú pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ìjọsìn Ọlọ́run, ṣé ẹ̀ ń gbà wọ́n níyànjú láti máa mọyì àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àti pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ẹlẹ́dàá? (Diutarónómì 6:4-9) Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ̀ ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? A ti ṣe àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì irú bí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! * láti ràn yín lọ́wọ́.
Ó Mọ Háàpù Ta Dáadáa
Bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ọ̀pọ̀ sáàmù tí Dáfídì kọ sílẹ̀ ṣe sọ fún wa nípa bí Dáfídì ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà lórin tún sọ fún wa nípa rẹ̀. Àmọ́, a kò mọ ohùn tó fi kọ àwọn orin mímọ́ náà lónìí. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ẹni tó kọ àwọn orin náà jẹ́ kọrinkọrin tó ta yọ. Kódà, ìdí tí wọ́n fi pe Dáfídì láti inú pápá pé kó wá máa ṣèránṣẹ́ fún Sọ́ọ̀lù Ọba ni pé, ó mọ háàpù ta dáadáa.—1 Sámúẹ́lì 16:18-23. *
Ibo ni Dáfídì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan yìí, ìgbà wo ló sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn? Ó lè jẹ́ láwọn àkókò tí ó ń bójú tó àwọn àgùntàn nínú pápá. Kò sídìí láti ṣiyè méjì pé, ìgbà tí Dáfídì wà ní ọ̀dọ́ ló ti ń kọ àwọn orin ìyìn àtọkànwá sí Ọlọ́run. Ó ṣe tán Jèhófà yàn án, ó sì gbé iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ nítorí ìfọkànsìn rẹ̀ àti ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run.
Ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tó dàgbà tán tún kọ yọyọ. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àròjinlẹ̀ tó ṣe nígbà tó wà nínú pápá ní àyíká Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà èwe rẹ̀ ló nípa lórí àwọn ìwà tó hù jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Fojú inú wo Dáfídì bó ṣe ń kọrin sí Jèhófà pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 143:5) Bí sáàmù yìí àti ọ̀pọ̀ sáàmù míì tí Dáfídì kọ ṣe múni lára yá jẹ́ ìṣírí gidi fún gbogbo àwọn tó fẹ́ tẹ́ ọkàn Jèhófà lọ́rùn.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Béárì aláwọ̀ ilẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Síríà, tí wọ́n máa ń rí ní Palẹ́sìnì nígbà kan, wúwo tó ogóje [140] kìlógíráàmù, ó sì lè fi ọwọ́ rẹ̀ pàǹpà tó ní èékánná pa èèyàn àti ẹranko. Ìgbà kan wà tí kìnnìún pọ̀ lágbègbè yẹn. Aísáyà 31:4 sọ pé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn olùṣọ́ àgùntàn” kò ní lè lé “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀” kúrò nídìí ẹran tó fẹ́ jẹ.
^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
^ Olùgbani nímọ̀ràn ọba tó dábàá Dáfídì fún iṣẹ́ ọba tún sọ pé Dáfídì jẹ́ “olùbánisọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ onílàákàyè àti ọkùnrin tí ó dára délẹ̀, Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 16:18.