Ṣé Póòpù Ló “Rọ́pò Pétérù Mímọ́”?
Ṣé Póòpù Ló “Rọ́pò Pétérù Mímọ́”?
LỌ́DÚN 2002, Póòpù John Paul Kejì kọ lẹ́tà sí bíṣọ́ọ̀bù ìlú Limburg, lórílẹ̀-èdè Jámánì, láti gbá ìpinnu tí bíṣọ́ọ̀bù náà ṣe lórí ọ̀ràn ìṣẹ́yún dà nù. Póòpù yìí sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ojúṣe òun ni láti rí sí bí “nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ ìfẹ́ Jésù Kristi.” Ó ní òun láṣẹ láti gbá ìpinnu bíṣọ́ọ̀bù náà dà nù, nítorí gẹ́gẹ́ bíi póòpù, òun lòun “rọ́pò Pétérù Mímọ́.”
Ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni pé, “Kristi fi Pétérù Mímọ́ ṣe olórí àwọn àpọ́sítélì yòókù.” Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tún sọ pé, “Kristi fi lélẹ̀ pé lẹ́yìn Pétérù, àwọn kan wà tí wọ́n á máa bọ́ sí ipò Pétérù, àwọn bíṣọ́ọ̀bù Róòmù ló sì máa bọ́ sí ipò náà.”—New Catholic Encyclopedia (2003), Ìdìpọ̀ 11, ojú ìwé 495 sí 496.
Àwọn nǹkan tí wọ́n sọ nìyẹn. Ǹjẹ́ o ti ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n sọ yìí fúnra rẹ? Ẹ jẹ́ ká wo ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Ǹjẹ́ Bíbélì jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n sọ pé Pétérù ni póòpù àkọ́kọ́? (2) Ibo ni ọ̀rọ̀ nípa ipò póòpù ti bẹ̀rẹ̀? (3) Ṣé ìwà àti ẹ̀kọ́ tí àwọn póòpù ń kọ́ni fi hàn lóòótọ́ pé àwọn ló rọ́pò Pétérù?
Ṣé Pétérù ni Póòpù Àkọ́kọ́?
Láti jẹ́rìí sí i pé Pétérù ni ìpìlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, tipẹ́tipẹ́ ni ẹ̀sìn Kátólíìkì ti ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 16:18 pé: “Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta ràbàtà yìí sì ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú.” Kódà, wọ́n tiẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ yìí lédè Látìn sí abẹ́ òrùlé ribiti ti ilé ìjọsìn St. Peter’s Basilica tó wà ní Róòmù.
Ọ̀gbẹ́ni Augustine táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún dáadáa, tó jẹ́ Bàbá Ìjọ sọ nígbà kan pé, Pétérù ni ìpìlẹ̀ ìjọ. Àmọ́ kí ọ̀gbẹ́ni yìí tó kú, ó yí èrò rẹ̀ nípa ohun tí Jésù sọ yìí pa dà. Nínú ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Retractations, Augustine jẹ́ kó yé àwọn èèyàn pé Jésù ni ìpìlẹ̀ Ìjọ Kristẹni kì í ṣe Pétérù. *
Òótọ́ ni pé, àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nǹkan tó pọ̀ gan-an nípa Pétérù. Àwọn ìgbà kan wà tí Jésù pe àpọ́sítélì Jòhánù, Jákọ́bù àti Pétérù pé kí wọ́n wà pẹ̀lú òun láwọn ibi tí nǹkan pàtàkì ti ṣẹlẹ̀. (Máàkù 5:37, 38; 9:2; 14:33) Jésù fún Pétérù ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run,” èyí tí Pétérù lò láti fi ṣí ọ̀nà Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù, lẹ́yìn náà fún àwọn ará Samáríà àti ní ìkẹyìn fún àwọn kèfèrí. (Mátíù 16:19; Ìṣe 2:5, 41; 8:14-17; 10:45) Nítorí pé ara Pétérù yá mọ́ èèyàn, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé òun ló máa ń gbẹ́nu sọ fún àwọn àpọ́sítélì yòókù. (Ìṣe 1:15; 2:14) Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan yìí wá fi hàn pé Pétérù ni orí ìjọ Kristẹni lákòókò yẹn?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kọ̀wé pé Pétérù ni Jésù yàn pé kó máa ṣe “iṣẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn tí ó dádọ̀dọ́.” (Gálátíà 2:8) Àmọ́, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kò fi hàn pé Pétérù ló ń darí ìjọ. Ipa tí Pétérù máa kó nínú wíwàásù fún àwọn Júù ni Pọ́ọ̀lù ń sọ.
Òótọ́ ni pé wọ́n fún Pétérù ní ọ̀pọ̀ nǹkan 1 Pétérù 1:1; 5:1.
láti máa bójú tó, àmọ́ kò sí ibì kankan tó ti sọ nínú Bíbélì pé òun ni orí ìjọ Kristẹni, pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣe ìpinnu fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Ohun tó sọ nípa ara rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ ni pé, òun jẹ́ “àpọ́sítélì” àti “àgbà ọkùnrin,” kò sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Ibo Ni Ọ̀rọ̀ Nípa Ipò Póòpù Ti Bẹ̀rẹ̀?
Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ nípa ipò póòpù bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìgbà tí àwọn àpọ́sítélì ṣì wà láyé ni àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ó yẹ kí ọkùnrin kan jẹ́ ọ̀gá lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Ojú wo làwọn àpọ́sítélì fi wo èrò yìí?
Pétérù fúnra rẹ̀ sọ fún àwọn ọkùnrin tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ pé, wọn kò gbọ́dọ̀ “jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí,” àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi ìrẹ̀lẹ̀ àtọkànwá hùwà sí àwọn èèyàn. (1 Pétérù 5:1-5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé, àwọn ọkùnrin kan máa dìde láàárín ìjọ tí wọ́n á máa “sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30) Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń parí lọ, àpọ́sítélì Jòhánù kọ lẹ́tà kan tó fi bá ọmọ ẹ̀yìn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dìótíréfè wí lọ́nà tó múná. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, ọkùnrin yìí ‘ń fẹ́ ipò àkọ́kọ́’ nínú ìjọ. (3 Jòhánù 9) Ọ̀rọ̀ tí àwọn àpọ́sítélì sọ yìí ni kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn tó ń fẹ́ ipò ọ̀gá nínú ìjọ láti rọ́wọ́ mú.—2 Tẹsalóníkà 2:3-8.
Àmọ́, kété lẹ́yìn tí àpọ́sítélì tó kẹ́yìn kú, àwọn tó ń fẹ́ ipò ọ̀gá nínú ìjọ wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́wọ́ mú. Ìwé kan tó ń jẹ́, The Cambridge History of Christianity sọ pé: “Ó jọ pé lápá ìdajì ọgọ́rùn-ún ọdún kejì, kò sí bíṣọ́ọ̀bù kan tó lè máa ṣe olórí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.” Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta, bíṣọ́ọ̀bù Róòmù sọ pé òun ni olórí, òun sì láṣẹ, ó kéré tán lórí apá kan ṣọ́ọ̀ṣì. * Láti ṣàtìlẹ́yìn fún ọ̀rọ̀ tí bíṣọ́ọ̀bù Róòmù yìí sọ pé òun ni olórí, àwọn kan ti ṣàkójọ orúkọ àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n rọ́pò Pétérù.
Àmọ́ ṣá o, àkọsílẹ̀ àwọn orúkọ náà kò fi hàn pé òótọ́ ló sọ. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé, àwọn kan lára orúkọ náà ni kò sí ẹ̀rí pé wọ́n wà lóòótọ́. Èyí tó wá ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé, ohun tí wọ́n tìtorí rẹ̀ ṣe àkójọ àwọn orúkọ náà kì í ṣe òótọ́. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ká ní Pétérù tiẹ̀ wàásù ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé kan tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti ìkejì ṣe sọ, kò sí ẹ̀rí kankan tó sọ pé òun ni orí ìjọ Kristẹni tó wà ní Róòmù.
Ẹ̀rí kan tó fi hàn pé Pétérù kì í ṣe orí ìjọ Kristẹni tó wà ní Róòmù ni pé, nígbà tí Róòmù 16:1-23) Tó bá jẹ́ pé, Pétérù ni orí ìjọ Kristẹni náà lóòótọ́, ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù á gbójú fò ó dá tàbí kó má kà á sí?
àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn ará Róòmù, ó dárúkọ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. Àmọ́, kò dárúkọ Pétérù rárá. (Ẹ tún kíyè sí i pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àkókò kan náà tí Pétérù kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ tó kọ lábẹ́ ìmísí ni Pọ́ọ̀lù náà kọ lẹ́tà kejì sí Tímótì. Nínú lẹ́tà yẹn, Pọ́ọ̀lù dárúkọ ìlú Róòmù. Lẹ́tà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù kọ láti ìlú Róòmù, kò sì dárúkọ Pétérù nínú wọn.
Lẹ́yìn ọgbọ̀n [30] ọdún tí Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà tó kọ, àpọ́sítélì Jòhánù náà kọ lẹ́tà mẹ́ta àti ìwé Ìfihàn. Kò sí ibì kankan nínú àwọn ìwé tí Jòhánù kọ tó sọ pé ìjọ tó wà ní Róòmù ló ṣe pàtàkì jù tàbí kó dárúkọ olórí ìjọ kan tó sọ pé òun lòun rọ́pò Pétérù. Kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tàbí ìwé ìtàn tó jẹ́rìí sí i pé Pétérù sọ pé òun ni bíṣọ́ọ̀bù àkọ́kọ́ nínú ìjọ tó wà ní Róòmù.
Ṣé Ìwà Àwọn Póòpù àti Ẹ̀kọ́ Tí Wọ́n Ń Kọ́ni Bá Ohun Tí Wọ́n Ń Sọ Mu?
Ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí ẹni tó pe ara rẹ̀ ní arọ́pò Pétérù Mímọ́ àti Aṣojú Kristi tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà Pétérù àti ti Kristi, kí ó sì tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ Pétérù gbà pé kí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa gbé òun gẹ̀gẹ̀? Rárá. Kò gbà kí ẹnikẹ́ni lo ọ̀rọ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti máa fi ṣàpọ́nlé òun. (Ìṣe 10:25, 26) Jésù ńkọ́? Ó sọ pé, òun wá láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì ni kì í ṣe pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ sin òun. (Mátíù 20:28) Àmọ́, báwo lọ̀rọ̀ àwọn póòpù ṣe rí? Ǹjẹ́ wọ́n kọ ipò ọ̀gá, orúkọ oyè àti fífi ọrọ̀ àti agbára ṣe ṣekárími?
Pétérù àti Jésù ní ìwà tó dáa, wọ́n sì rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Ẹ jẹ́ ká wá fi àwọn ohun tí Pétérù àti Jésù ṣe wéra pẹ̀lú ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Kátólíìkì náà, Lexicon for Theology and Church sọ nípa Póòpù Leo Kẹwàá, ó ní: “Ó lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, ó sì sábà máa ń ṣojúsàájú tọ́rọ̀ bá kan àwọn ará ilé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó tún fẹ́ràn afẹ́ ayé, Leo Kẹwàá kò ka ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run sí nǹkan pàtàkì.” Ọ̀gbẹ́ni Karl Amon, tó jẹ́ àlùfáà Kátólíìkì tó tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé, ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa Póòpù Alexander Kẹfà fi hàn pé, “ọ̀pọ̀ ìwà àìṣòótọ́ ló wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa ń ṣi agbára lò, ó ń gba owó láti ta ipò, ó sì jẹ́ oníṣekúṣe.”
Ẹ̀kọ́ àwọn póòpù ńkọ́? Ǹjẹ́ wọ́n bá ẹ̀kọ́ Pétérù àti ti Kristi mu? Pétérù kò gbà pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sí ọ̀run. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Dáfídì tó jẹ́ Ọba rere, Pétérù sọ ní kedere pé: “Dáfídì kò gòkè lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Bákan náà, Pétérù kò kọ́ni pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé, ìrìbọmi jẹ́ nǹkan àtọkànwá tí ẹni tó gbà gbọ́ máa ń ṣe.—1 Pétérù 3:21.
Jésù kọ́ni pé, ìkankan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kò gbọ́dọ̀ máa rò pé òun wà nípò tó ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, kí ó jẹ́ ẹni ìkẹyìn nínú gbogbo yín àti òjíṣẹ́ gbogbo yín.” (Máàkù 9:35) Ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ ní kedere nípa ohun tó ń fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe, ó ní: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.” (Mátíù 23:1, 8-10) Ǹjẹ́ o lè sọ pé, ohun tí Pétérù àti Kristi kọ́ni làwọn póòpù náà ń kọ́ni?
Àwọn kan sọ pé, ipò póòpù ṣì wà, bí ẹni tí wọ́n yàn síbẹ̀ kò bá tiẹ̀ ní ìwà tó yẹ Kristẹni. Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí wọ́n sọ yìí mọ́gbọ́n dání? Jésù sọ pé: “Gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde.” Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí yìí, ǹjẹ́ o rò pé Pétérù tàbí Kristi á fara mọ́ irú ìwà táwọn póòpù ń hù yẹn?—Mátíù 7:17, 18, 21-23.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Báwọn èèyàn ṣe máa dá Kristi àti ipa tó ń kó mọ̀ ni Jésù ń bá Pétérù sọ, kì í ṣe ipò tí Pétérù máa wà nínú ìjọ Kristẹni. (Mátíù 16:13-17) Nígbà tó yá, Pétérù pàápàá sọ pé Jésù ni àpáta tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. (1 Pétérù 2:4-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí i pé, Jésù ni “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé” ìjọ Kristẹni kì í ṣe Pétérù.—Éfésù 2:20.
^ Jésù àtàwọn àpọ́sítélì sọ pé àwọn ọkùnrin kan máa dìde nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n á sì máa kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èké. (Mátíù 13:24-30, 36-43; 2 Tímótì 4:3; 2 Pétérù 2:1; 1 Jòhánù 2:18) Ọ̀rọ̀ yìí wá rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì ọgọ́rùn-ún ọdún kejì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba àṣà àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n sì ń da ẹ̀kọ́ Bíbélì pọ̀ mọ́ ọgbọ́n orí ilẹ̀ Gíríìsì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ǹjẹ́ ẹ̀rí fi hàn pé àwọn póòpù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù?