Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Gbé Ẹ̀yà Ìran Kan Ga Ju Òmíràn Lọ?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Gbé Ẹ̀yà Ìran Kan Ga Ju Òmíràn Lọ?
▪ Rárá o, Ọlọ́run kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn náà yàtọ̀ gan-an sí ojú tí ẹ̀dá èèyàn aláìpé fi ń wò ó. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ẹ̀yà ìran kan (tó sábà jẹ́ tiwọn) ga ju àwọn yòókù lọ. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò yàtọ̀ sí èrò ọ̀gbẹ́ni Charles Darwin, tó sọ pé: “Ní ìgbà kan lọ́jọ́ iwájú, . . . àwọn ẹ̀yà ìran tó lajú yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ẹ̀yà ìran tí kò lajú run tán, tí wọ́n á sì rọ́pò wọn.” Ó ṣeni láàánú pé, àwọn ẹ̀yà ìran kan tí wọ́n rò pé àwọn ga ju àwọn yòókù lọ ti fìyà jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn.
Ǹjẹ́ èrò pé ẹ̀yà ìran kan ga ju àwọn yòókù lọ tiẹ̀ ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi ẹ̀rí hàn pé àbùdá àwọn ẹ̀yà ìran kan ṣàrà ọ̀tọ̀ ju tí àwọn ẹ̀yà ìran míì lọ? Rárá. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bryan Sykes ará Oxford tó jẹ́ onímọ̀ nípa àbùdá èèyàn sọ pé: “Kò sí àbùdá kan tó ti èrò náà lẹ́yìn pé ẹ̀yà tàbí ìran kan ga ju òmíràn lọ. . . . Wọ́n máa ń bi mí bóyá àbùdá kan wà tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Gíríìsì tàbí àbùdá kan wà tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ítálì, àmọ́, ká sòótọ́, kò sí o. . . . Ọ̀kan náà ni gbogbo wa.”
Ohun tí ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbé jáde yìí bá ohun tá a kà nínú Ìwé Mímọ́ mu. Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run dá ọkùnrin kan àti obìnrin kan, ara wọn sì ni gbogbo èèyàn yòókù ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:20; Ìṣe 17:26) Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, ọ̀kan náà ni gbogbo ìran èèyàn jẹ́.
Bí àwọ̀ tàbí ojú àwọn èèyàn ṣe rí kò ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun kan tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ló jẹ Jèhófà lógún, ìyẹn ohun téèyàn jẹ́ ní inú. Ó sọ pé: “Ìrísí àwọn èèyàn ni èèyàn fi ń ṣèdájọ́ wọn, àmọ́ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn ni èmi fi ń ṣèdájọ́ wọn.” (1 Sámúẹ́lì 16:7, Contemporary English Version) Tí a bá ń rántí òtítọ́ yẹn, ó máa ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà ìran tí a ti wá yàtọ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú wa ni kò nífẹ̀ẹ́ sí bí àwọn ẹ̀yà ara wọn kan ṣe rí, àmọ́ a kò fí bẹ́ẹ̀ ní agbára láti yí wọn pa dà. Ṣùgbọ́n a lè mú kí èrò ọkàn wa dára sí i, èyí sì ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. (Kólósè 3:9-11) Tí a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ara wa, a ó rí i pé ó máa ń ṣe wá bíi pé a lọ́lá ju àwọn ẹ̀yà míì lọ tàbí pé a rẹlẹ̀ jù wọ́n lọ. Nítorí pé èrò méjèèjì yẹn kò bá èrò Ọlọ́run mu, ó yẹ ká sapá gan-an láti mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn wa.—Sáàmù 139:23, 24.
Bí a ti ń sapá láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wò wá wo ara wa àti àwọn ẹlòmíì, ó dájú pé Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán wa létí pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, láìka ẹ̀yà tàbí ìran tí a ti wá sí.