Kí Nìdí Tó Fi Jọ Pé Ìgbésí Ayé Yìí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?
Kí Nìdí Tó Fi Jọ Pé Ìgbésí Ayé Yìí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?
KÍ NÌDÍ tó fi yẹ kó o gbà pé, ìgbésí ayé ṣì máa dára gan-an, kò sì ní rí bí “ìwàláàyè kúkúrú tó jẹ́ asán,” tí a máa ń gbé fúngbà díẹ̀ tí a ó sì kọjá lọ “bí òjìji,” gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì Ọba ti sọ? (Oníwàásù 6:12, The New English Bible) Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ orísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé, ṣèlérí pé ìgbésí ayé lọ́jọ́ iwájú máa dára gan-an.—2 Tímótì 3:16, 17.
Bíbélì sọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí. Ó tún ṣàlàyé ìdí tí ayé fi kún fún àìṣẹ̀tọ́, ìnilára àti ìjìyà. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn nǹkan yìí? Ìdí pàtàkì táwọn èèyàn fi rò pé ìgbésí ayé yìí kò já mọ́ nǹkan kan ni pé, wọn kò mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí àtàwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé wọn kò fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀.
Kí ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ayé?
Jèhófà Ọlọ́run * dá ayé pé kó jẹ́ Párádísè níbi táwọn ẹ̀dá èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé á máa gbé, tí wọ́n á sì máa gbádùn títí láé. Èyí ta ko èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní pé Ọlọ́run dá ayé kó lè jẹ́ ibi tí á ti máa dán àwọn èèyàn wò láti rí i bóyá wọ́n yóò lè kúnjú ìwọ̀n láti gbé ìgbésí ayé tó dára jù lọ ní ọ̀run.—Wo àpótí náà, “Ṣé Ó Dìgbà Tá A Bá Kúrò Láyé Kí Ìgbésí Ayé Wa Tó Lè Dára?” ní ojú ìwé 6.
Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin ní àwòrán ara rẹ̀, ó sì fún wọn ní agbára láti máa ṣàgbéyọ àwọn ìwà òun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Ó dá wọn ní pípé. Wọ́n ní gbogbo nǹkan tí ó lè mú kí wọ́n máa gbádùn ìgbésí ayé wọn títí láé. Ìyẹn sì kan pé kí wọ́n bí ọmọ tó pọ̀ sí ayé, kí wọ́n bójú tó ayé, kí wọ́n sì sọ ayé di Párádísè bí ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-31; 2:8, 9.
Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Tó Kù Díẹ̀ Káàtó?
Kò sí àní-àní pé, ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn kò gbé ìwà Ọlọ́run yọ lọ́nà tó tọ́. Ayé yìí kò di Párádísè. Kí ló fà á? Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ òbí wa, ṣi òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn lò. Wọ́n fẹ́ “dà bí Ọlọ́run,” kí wọ́n lè máa pinnu ohun tó jẹ́ “rere àti búburú” fúnra wọn. Nípa báyìí, wọ́n tẹ̀ lé Sátánì Èṣù nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.
Nítorí náà, àwọn ohun búburú kò sí lára ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. Ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run. Àbájáde ìṣọ̀tẹ̀ wọn ni pé, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pàdánù Párádísè àti ìjẹ́pípé, wọ́n sì fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú bá ara wọn àtàwọn ọmọ wọn, ìyẹn ìran èèyàn lápapọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12) Èyí ló fa àwọn nǹkan tó mú kó jọ pé ìgbésí ayé yìí kò já mọ́ nǹkan kan.
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Mú Ibi Kúrò Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?
Àwọn kan ṣe kàyéfì pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi mú ibi kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípa pípa Sátánì àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ yòókù run, kí ó sì dá àwọn èèyàn míì?’ Ǹjẹ́ ìyẹn á bọ́gbọ́n mu? Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá gbọ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni ìjọba alágbára kan máa ń pa ẹnikẹ́ni tó bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò dùn mọ́ ọn nínú? Ǹjẹ́ irú ìwà yìí kò ní kó ìbànújẹ́ bá àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere, tí èyí á sì sọ ìjọba náà di òǹrorò lójú àwọn ará ìlú?
Ọlọ́run kò ṣe nǹkan kan fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, ọgbọ́n Ọlọ́run ga, ó fi àyè sílẹ̀ kí àtakò tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì nípa bí òun ṣe ń ṣàkóso lè yanjú pátápátá.
Ọlọ́run Máa Mú Ibi Kúrò
Ohun pàtàkì kan tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé, Ọlọ́run ti fàyè gba ìwà ibi fún àwọn àkókò kan. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé òun lè mú ìbànújẹ́ tó burú jáì tí ibi ti fà kúrò, tí àtakò tó wáyé sí bí òun ṣe ń ṣàkóso bá ṣáà ti yanjú pátápátá.
Ọlọ́run kò tíì yí ohun tó ní lọ́kàn fún ayé àtàwọn èèyàn pa dà. Jèhófà mú un dá wa lójú nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà pé, Òun lẹni to dá ayé, òun kò “dá a lásán,” ńṣe ni òun “ṣẹ̀dá rẹ̀ . . . kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Láìpẹ́, ó máa mú kí ayé pa dà sí ipò pípé tó fẹ́ kó wà nígbà tó dá ayé. Nígbà tó bá ti hàn kedere pé ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan ló tọ̀nà, kò sí ẹni tó máa sọ pé kí ló dé tí Ọlọ́run fi lo agbára rẹ̀ tí kò ní ààlà láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ tó sì mú gbogbo ibi kúrò títí láé. (Aísáyà 55:10, 11) Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù Kristi gbà, ó bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe nǹkan yìí. Jésù kọ́ wa ká gbàdúrà pé: “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?
Ohun Tí Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ayé
Lára rẹ̀ ni pé, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:9-11, 29; Òwe 2:21, 22) Jésù Kristi máa “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, [àti] ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.” Ó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ “ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 72:12-14) Kò ní sí ogun, ikú, ẹkún, ìrora tàbí ìjìyà mọ́. (Sáàmù 46:9; Ìṣípayá 21:1-4) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tí wọ́n ti kú lákòókò tí Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì láǹfààní láti gbádùn ìbùkún yìí àtàwọn míì.—Jòhánù 5:28, 29.
Kódà, Jèhófà máa mú gbogbo aburú tí ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì fà kúrò. Ó máa mú gbogbo aburú náà kúrò pátápátá débi pé, “àwọn ohun àtijọ́ [ìyẹn gbogbo nǹkan tó ń fa ìbànújẹ́ àti ìrora lónìí] ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí.” (Aísáyà 65:16-19) Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la yìí dájú. Ọlọ́run kò lè purọ́. Gbogbo ìlérí rẹ̀ ló máa ń ṣẹ. Ìgbésí ayé kò ní jẹ́ “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù” mọ́. (Oníwàásù 2:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé yóò dára gan-an.
Àmọ́, ní báyìí ńkọ́? Ǹjẹ́ mímọ ohun tí Bíbélì kọ́ni àtohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé lè mú kí ìgbésí ayé èèyàn dára gan-an ní báyìí? Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí dáhùn ìbéèrè yẹn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣé Ó Dìgbà Tá A Bá Kúrò Láyé Kí Ìgbésí Ayé Wa Tó Lè Dára?
Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún sẹ́yìn làwọn èèyàn tí kò mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé ti máa ń kọ́ni pé, a ní láti kúrò láyé yìí ká tó lè gbádùn ìgbésí ayé tó dára.
Àwọn kan sọ pé, ọkàn “ti gbádùn ìwàláàyè tó dára gan-an kó tó di pé ó wọ inú ara èèyàn.” (New Dictionary of Theology) Àwọn míì sọ pé, Ọlọ́run fi ọkàn “sínú ara èèyàn kí ọkàn yẹn lè wá jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó dá nígbà tó wà ní ọ̀run.”—Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature.
Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì bíi Socrates àti Plato ń kọ́ni pé: Ìgbà tí ọkàn bá kúrò nínú ara èèyàn “ló tó bọ́ lọ́wọ́ ìrònú asán, ìwà òmùgọ̀ àti ìbẹ̀rù, lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti onírúurú ìṣòro tó máa ń fa ìfàsẹ́yìn fún èèyàn” tí á sì máa gbé “pẹ̀lú àwọn ọlọ́run títí láé.”—Plato’s Phaedo, 81, A.
Nígbà tó yá, àwọn tó pe ara wọn ní aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni tẹ́wọ́ gba èrò àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì, pé “ọkàn kì í kú,” wọ́n sì fi sínú ẹ̀kọ́ wọn.—Christianity—A Global History.
Ẹ jẹ́ ká wá fi àwọn èrò yìí wéra pẹ̀lú ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́ta nínú Bíbélì:
1. Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé ni pé kó jẹ́ ilé táwọn èèyàn á máa gbé títí láé, kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run ti ń dán àwọn èèyàn wò láti mọ̀ bóyá wọ́n lè gbé ní ọ̀run. Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run ni, wọn ì bá ṣì wà láàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Sáàmù 115:16.
2. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ti kọ́ni pé èèyàn ní ọkàn, ìyẹn ohun kan tí kò lè kú tó wà nínú èèyàn, àmọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ni rọrùn láti lóye. Ó ní, èèyàn jẹ́ “alààyè ọkàn,” “ekuru ilẹ̀” sì ni Ọlọ́run fi dá wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé ọkàn kò lè kú. Bíbélì sọ pé, wọ́n lè pa ọkàn, tí kò sì ní sí mọ́. (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20) Ádámù tó jẹ́ ọkàn àkọ́kọ́ kú, ó sì pa dà sí ekuru tí Ọlọ́run fi dá a. Ó pa dà di ẹni tí kò sí níbì kankan.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:19.
3. Bí àwọn èèyàn tó ti kú ṣe máa wà láàyè lọ́jọ́ iwájú ni pé, Ọlọ́run máa jí wọn dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe pé, ọkàn àwọn tó ti kú máa kúrò lára wọn lọ máa gbé ní ọ̀run.—Dáníẹ́lì 12:13; Jòhánù 11:24-26; Ìṣe 24:15.