Ìtùnú fún Àwọn Tó Ní Ìbànújẹ́ Ọkàn
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ìtùnú fún Àwọn Tó Ní Ìbànújẹ́ Ọkàn
‘JÈHÓFÀ kò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé.’ Kristẹni ni obìnrin tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ló fi ní ìdààmú ọkàn. Èrò rẹ̀ ni pé, Jèhófà ti jìnnà sí òun. Ṣé òótọ́ ni pé Jèhófà jìnnà sí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn? Ìdáhùn tó ń tuni nínú wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí onísáàmù náà Dáfídì láti kọ, ó wà nínú ìwé Sáàmù 34:18.
Dáfídì mọ ipa tí ìdààmú ọkàn tó lékenkà lè ní lórí ẹnì kan tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. Nígbà tí Dáfídì wà ní ọ̀dọ́, ńṣe ló ń sá káàkiri, nítorí pé Sọ́ọ̀lù òjòwú ọba fẹ́ pa á, kò sì dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. Dáfídì sá lọ sí ìlú Gátì, ìyẹn àgbègbè àwọn Filísínì tó jẹ́ ọ̀tá Sọ́ọ̀lù, èrò rẹ̀ sì ni pé Sọ́ọ̀lù kò ní wá òun wá síbẹ̀. Àmọ́, nígbà tí àwọn ará Gátì dá Dáfídì mọ̀, ńṣe ló díbọ́n bíi pé orí òun ti yí. Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún bó ṣe dáàbò bo òun, ìyẹn ló sì mú kó kọ Sáàmù 34.
Ǹjẹ́ Dáfídì gbà pé Ọlọ́run jìnnà sí àwọn èèyàn tí ìdààmú ọkàn bá tí ìyẹn sì mú kí wọ́n soríkọ́ tàbí tí wọ́n rò pé àwọn kò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run lè ràn lọ́wọ́? Dáfídì sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Ẹsẹ 18) Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣe jẹ́ ká ní ìtùnú tó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ìrètí ń bẹ.
“Jèhófà sún mọ́.” Ìwé kan tí wọ́n ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, gbólóhùn yìí jẹ́ “ọ̀nà kan láti sọ pé Olúwa ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn èèyàn rẹ̀, ó ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ àti láti gbà wọ́n nígbà gbogbo.” Ó fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé Jèhófà ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn èèyàn rẹ̀. Ó mọ ohun tí ojú wọn ń rí ní “àwọn àkókò lílekoko” yìí, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn.—2 Tímótì 3:1; Ìṣe 17:27.
“Àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà.” Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan àmọ́ tí onítọ̀hún kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “ìròbìnújẹ́ ọkàn” fún. Àmọ́ ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí ní í ṣe pẹ̀lú “onírúurú ìbànújẹ́ àti ìdààmú ọkàn.” Nígbà míì, ìṣòro tó lékenkà lè bá àwọn olùjọsìn Ọlọ́run pàápàá, tó sì máa ń bà wọ́n lọ́kàn jẹ́.
“Àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀.” Àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá lè wo ara wọn pé àwọn kò já mọ́ nǹkan kan, tíyẹn á sì mú kí wọ́n rò pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan. Ìwé kan tó wà fún àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè míì sọ pé, ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí “àwọn tí kò ní nǹkan rere tí wọ́n ń retí.”
Kí ni Jèhófà máa ń ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ní “ìròbìnújẹ́ ọkàn” àti “àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀”? Ṣé ó máa ń jìnnà sí wọn, tí ó sì máa ń wò wọ́n pé wọn kò yẹ lẹ́ni tóun ń fiyè sí tóun sì ń fi ìfẹ́ hàn sí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Bí òbí onífẹ̀ẹ́ tó gbá ọmọ tí ìdààmú ọkàn bá mọ́ra tó sì tù ú nínú, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe wà nítòsí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó ń wojú rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ó ń fẹ́ tu ọkàn àwọn oníròbìnújẹ́ àtàwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ lára. Ó lè fún wọn ní ọgbọ́n àti okun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wọn.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Jákọ́bù 1:5.
O ò ṣe wá bí wàá ṣe túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Ọlọ́run aláàánú yìí ṣèlérí pé: “Mo ń gbé . . . pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí, láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.”—Aísáyà 57:15.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún June: