Kọ́ Ọmọ Rẹ
Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Dá Wà Tí Ẹ̀rù sì Ń Bà Ẹ́?
Ó MÁA ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí bíi pé wọ́n dá wà, wọ́n máa ń rò pé kò sí ẹnì kankan tó bìkítà nípa àwọn. Àwọn àgbàlagbà ló sábà máa ń ní èrò yìí. Àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ ọmọdé títí kan ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sin Ọlọ́run ló ní èrò pé àwọn dá wà tí ẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?— *
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó rí bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó gbé láyé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan kí wọ́n tó bí Jésù. Orúkọ rẹ̀ ni Èlíjà. Ó gbé láyé nígbà táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti fi ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Báálì, ọlọ́run èké. Èlíjà sọ pé: “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù.” Àmọ́, ṣé o rò pé Èlíjà nìkan ṣoṣo ló ṣẹ́ kù lóòótọ́ tó ń jọ́sìn Jèhófà?—
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà kò mọ̀, àwọn míì ní Ísírẹ́lì ṣì ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Àmọ́ wọ́n ti lọ fara pa mọ́. Ẹ̀rù ń bà wọ́n. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi ń bẹ̀rù?—
Áhábù ọba Ísírẹ́lì kò jọ́sìn Jèhófà, Báálì ọlọ́run èké tí Jésíbẹ́lì obìnrin búburú tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ ń jọ́sìn, ni Áhábù náà ń jọ́sìn. Ìdí nìyẹn tí obìnrin yìí àti Áhábù fi ń sapá láti wá gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n sì pa wọ́n, ní pàtàkì Èlíjà. Ìyẹn ló mú kí Èlíjà sá lọ. Ó sá lọ sí Hórébù tó jìn tó nǹkan bíi kìlómítà irínwó àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta [483], ọ̀nà aṣálẹ̀ ló sì gbà débẹ̀, wọ́n tún ń pe ibẹ̀ ní Sínáì nínú Bíbélì.
Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn kí wọ́n tó bí Èlíjà, ibí yìí ni Ọlọ́run ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Òfin Mẹ́wàá àtàwọn Òfin rẹ̀ yòókù. Èlíjà sá pa mọ́ sí ihò kan ní Hórébù. Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ kí Èlíjà bẹ̀rù?—Bíbélì fi hàn pé, ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà lo Èlíjà láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá. Nígbà kan, Jèhófà dáhùn àdúrà tí Èlíjà gbà pé kí Jèhófà rán iná láti ọ̀run kó lè jó ẹbọ kan tí Èlíjà rú. Jèhófà fi hàn lọ́nà yìí pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́ kì í ṣe Báálì. Wàyí o, nígbà tí Èlíjà ṣì wà nínú ihò náà, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀.
Jèhófà bi í pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín?” Èlíjà wá sọ pé, ‘Èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù tó ń jọ́sìn rẹ.’ Jèhófà wá fi ìfẹ́ tọ́ Èlíjà sọ́nà, ó ní, ‘Mo ṣì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin tó ń jọ́sìn mi.’ Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kó pa dà, ó jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tóun fẹ́ kó ṣe.
Kí lo rò pé a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Èlíjà?— Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà pàápàá lè máa bẹ̀rù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, gbogbo wa lọ́mọdé lágbà, ní láti máa rántí láti bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì ṣèlérí pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”
Ẹ̀kọ́ míì tá a rí kọ́ ni pé: Ibi gbogbo ni a ti ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwa náà. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará [wa] nínú ayé.” Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn pé a kò dá nìkan wà?—
Kà á nínú Bíbélì rẹ
^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.