Ibo La Ti Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Òde Òní?
Àkànṣe Àsọyé Fún Gbogbo Èèyàn
Ibo La Ti Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Òde Òní?
Kò sí ibi téèyàn yíjú sí lóde òní tí kò rí ìmọ̀ràn gbà. Àwọn ìwé àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń gbani nímọ̀ràn lórí béèyàn ṣe lè yanjú ìṣòro ara ẹni wọ́pọ̀ gan-an. Síbẹ̀, àwọn ìṣòro ṣì wà. O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ ibi kankan wà tí mo ti lè rí ìtọ́sọ́nà tí mo lè gbára lé?’ Ìdáhùn náà ni pé, bẹ́ẹ̀ ni!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan ni Bíbélì ti wà, síbẹ̀ ó láwọn ìlànà tó wúlò títí ayé tó dáhùn àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí:
▪ Kí ni mo lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè tí màá sì gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn?
▪ Kí ni mo lè ṣe tí màá fi láyọ̀?
▪ Kí ni mo lè ṣe láti kojú àwọn ìṣòro ìṣúnná owó?
▪ Kí ni mo lè ṣe láti ṣẹ́pá àníyàn?
A máa gbọ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ǹjẹ́ Àwọn Ìlànà Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Òde Òní?” Kárí ayé ní ilẹ̀ tó ju ọgbọ̀n lé ní igba [230] lọ la ti máa sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì yìí. Ní ibi tó pọ̀ jù lọ, ọjọ́ Sunday, May 1, 2011 la máa sọ àsọyé yìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ máa dùn láti sọ fún ẹ nípa àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe é. A pè ẹ́ tìfẹ́tìfẹ́ pé kó o wá.