Kí Ni Ìhìn Rere?
Kí Ni Ìhìn Rere?
“Ìhìn rere ìjọba yìí . . . ”—MÁTÍÙ 24:14.
ÀWỌN Kristẹni ní láti wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” fún àwọn èèyàn, kí wọ́n sọ fún wọn pé Ìjọba yìí ló máa ṣàkóso gbogbo ayé nínú òdodo lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, a tún lo ọ̀rọ̀ náà, “ìhìn rere” lọ́nà míì nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì tọ́ka sí “ìhìn rere ìgbàlà” (Sáàmù 96:2); “ìhìn rere Ọlọ́run” (Róòmù 15:16); àti “ìhìn rere nípa Jésù Kristi.”—Máàkù 1:1.
Ní kúkúrú, ìhìn rere ni gbogbo òtítọ́ tí Jésù sọ àtàwọn èyí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ sílẹ̀. Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti sọ nípa Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn, wọ́n tún gbọ́dọ̀ sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
Kí làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe nípa ọ̀ràn yìí? Ọ̀pọ̀ ni kò mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, kò sì ní ṣeé ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ìjọba náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó máa mú ara tu àwọn èèyàn nìkan ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń wàásù, irú bí, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Wọ́n tún ń gbìyànjú láti fa àwọn èèyàn sínú ẹ̀sìn wọn nípa ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn èèyàn tàbí nípa kíkọ́ ilé ìwòsàn, iléèwé àti ilé fún àwọn tálákà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn nǹkan yìí lè mú kí àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ sí i, àmọ́ kò lè mú káwọn èèyàn jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tó ń fi gbogbo ọkàn fẹ́ láti mú kí ìgbé ayé wọn bá ẹ̀kọ́ Jésù mu.
Ọkùnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀sìn sọ pé: “Ṣàṣà làwọn ọ̀mọ̀wé tàbí aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni tó máa sọ pé kò yẹ ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tàbí pé kó yẹ ká ṣe iṣẹ́ tí Jésù ṣe, ká sì kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo ohun tí Jésù sọ. . . . Ó ṣe tán, ìtọ́ni Jésù lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere. Àwa la ò kan ṣe ohun tó ní ká ṣe. A ò fọwọ́ pàtàkì mú un rárá. Ká sòótọ́, ó hàn pé a ò mọ bó ṣe yẹ ká ṣe iṣẹ́ náà.”
Bákan náà, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, èèyàn mọ́kàndínlógún nínú ogún ló gbà pé ó yẹ káwọn wàásù ìhìn rere nítorí pé, ó wà lára ohun tó fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbàgbọ́. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló gbà pé, ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbà ṣe é ni pé, kí ìgbésí ayé àwọn jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn èèyàn, kì í ṣe pé kí àwọn máa wàásù ohun tí àwọn gbà gbọ́. Obìnrin kan lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé: “Iṣẹ́ ìhìn rere kì í ṣe ọ̀ràn kéèyàn kàn máa wàásù ṣáá. Àwa fúnra wa la ní láti jẹ́ Ìhìn Rere.” Ìwé ìròyìn U.S. Catholic, tó ṣe ìwádìí yìí sọ pé, ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ wàásù ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nítorí “ẹ̀bi ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì wọn jẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí àti nítorí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí kò yéni.”
Bíṣọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kan tún kédàárò pé, ohùn àwọn tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kò ṣọ̀kan, wọn kò sì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọn kò ní ìgboyà láti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ọ̀nà ìgbésí ayé wọn kò sì yàtọ̀ sí táwọn èèyàn tí kò mọ Ọlọ́run. Ó wá fi ìbànújẹ́ béèrè pé: “Àwọn wo gan-an ló kúnjú ìwọ̀n láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà báyìí?”
Bíṣọ́ọ̀bù yìí kò dáhùn ìbéèrè tó béèrè yẹn. Àmọ́ ìdáhùn wà. Wàá rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ìhìn rere jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi