Ṣé Òótọ́ Ni Jésù Kú Lórí Àgbélébùú?
Ṣé Òótọ́ Ni Jésù Kú Lórí Àgbélébùú?
ÌWÉ gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé, “Àgbélébùú jẹ́ ohun kan tí gbogbo àwọn èèyàn fi ń dá àwọn Kristẹni mọ̀.” Wọ́n máa ń ya Jésù nínú ọ̀pọ̀ àwòrán àtàwọn iṣẹ́ ọnà tó jẹ́ ti ẹ̀sìn, pé wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. Kí nìdí tí àmì yìí fi wọ́pọ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? Ṣé òótọ́ ni Jésù kú lórí àgbélébùú?
Ọ̀pọ̀ ló máa sọ pé òótọ́ ni, pé Bíbélì sọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Mimọ sọ pé nígbà tí wọ́n fẹ́ pa Jésù, àwọn tó ń wo Jésù ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń sọ fún un pé “sọkalẹ lati ori agbelebu wá.” (Mátíù 27:40, 42) Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì míì ló sọ ohun kan náà. Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ sọ nípa Símónì ará Kírénè pé: “Wọ́n fi tipá-tipá mú u láti gbé agbelebu Jesu.” (Máàkù 15:21) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, staurosʹ ni wọ́n túmọ̀ sí “àgbélébùú” nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí. Ǹjẹ́ ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà pé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí nìyẹn lóòótọ́? Kí ni staurosʹ túmọ̀ sí gan-an?
Ṣé Àgbélébùú Ni?
Ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ W. E. Vine, sọ pé, “ohun tí [staurosʹ] jẹ́ gangan ni, òpó igi tó dúró ṣánṣán. Orí rẹ̀ ni wọ́n máa ń kan àwọn ọ̀daràn mọ́. Ọ̀rọ̀ náà stauroō, tó jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ ìṣe, túmọ̀ sí kéèyàn kan nǹkan mọ́ òpó igi, kò túmọ̀ sí àgbélébùú ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì rárá.”
Ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí wọ́n ń pè ní, The Imperial Bible-Dictionary sọ pé, ohun tí ọ̀rọ̀ náà, staurosʹ “ń tọ́ka sí gan-an ni, òpó igi, ìyẹn òpó tó dúró ṣánṣán, tí wọ́n lè gbé nǹkan kọ́ tàbí tí wọ́n lè fi ṣe ọgbà yíká ilẹ̀ kan.” Ìwé náà ń bá a nìṣó pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òpó igi tó dúró ṣánṣán làwọn ará Róòmù pàápàá ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mọ crux sí (Ọ̀rọ̀ Látìn náà, crux ni wọ́n túmọ̀ sí àgbélébùú tá a mọ̀ lónìí).” Nítorí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti Kátólíìkì náà, The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Bó ti wù kó rí, kò sí àní-àní pé, ohun táwọn èèyàn mọ̀ sí àgbélébùú lónìí kì í ṣe àgbélébùú tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ òpó tó dúró ṣánṣán, tí wọ́n gbẹ́ orí rẹ̀ ṣóṣóró.”
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì míì tún wà tó ń jẹ́ xyʹlon, àwọn tí wọ́n kọ Bíbélì lò ó láti fi ṣàlàyé ohun tí wọ́n fi pa Jésù. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, A Critical Lexicon and Concordance to the English and Greek New Testament túmọ̀ xyʹlon sí “ẹ̀là igi gẹdú, ìyẹn òpó igi.” Ìwé náà ń bá a nìṣó pé, bíi ti staurosʹ, ọ̀rọ̀ náà, xyʹlon “jẹ́ òpó igi tó dúró ṣánṣán, orí rẹ̀ làwọn ará Róòmù máa ń kan èèyàn tí wọ́n fẹ́ pa mọ́.”
Èyí ló mú kí Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ sọ nínú ìwé Ìṣe 5:30 pé: “Jesu ẹni tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi [xyʹlon], Ọlọ́run àwọn baba wá jí i dìde.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àgbélébùú,” ni àwọn Bíbélì kan túmọ̀ staurosʹ sí, síbẹ̀ “igi” ni wọ́n túmọ̀ xyʹlon sí. Bibeli Mimọ sọ nípa Jésù nínú ìwé Ìṣe 13:29 pé: “Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi [xyʹlon], nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì.”
Lójú ohun tí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà staurosʹ àti xyʹlon jẹ́ yìí, ìwé Critical Lexicon and Concordance tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí kò túmọ̀ sí ohun táwọn èèyàn lóde òní pè ní àgbélébùú, èyí tá a máa ń rí nínú àwòrán.” A tún lè sọ ọ́ báyìí pé, ohun tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ń sọ nígbà tí wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà, staurosʹ kì í ṣe ohun tí àwọn èèyàn òde òní ń pè ní àgbélébùú. Nítorí ìdí yìí ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi lo “òpó igi oró” nínú Mátíù 27:40-42 àti láwọn ibòmíì tí ọ̀rọ̀ náà, staurosʹ ti fara hàn. Bákan náà, “òpó igi ikú” ni Bíbélì Complete Jewish Bible lò.
Ibi Tí Àgbélébùú Ti Wá
Tí Bíbélì kò bá sọ pé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí, kí wá nìdí tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Pùròtẹ́sítáǹtì àti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí wọ́n sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé Bíbélì, pé àwọn sì fi ń ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ́ni ṣe ń fi àgbélébùú ṣe ọ̀ṣọ́ sára ilé ìjọsìn wọn tí wọ́n sì ń lo àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí àmì ìgbàgbọ́ wọn? Báwo ni àgbélébùú ṣe di àmì tàwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mọ owó báyìí?
Ìdáhùn náà ni pé, kì í ṣe àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nìkan ló ka àgbélébùú sí ohun ọlọ́wọ̀, àwọn tí ẹ̀sìn wọn kò jẹ mọ́ Bíbélì pàápàá kà á sí ohun ọlọ́wọ̀, ẹ̀sìn wọn sì ti wà ṣáájú kí ṣọ́ọ̀ṣì tó dé. Ọ̀pọ̀ ìwé ìwádìí tó jẹ́ ti ìsìn ló jẹ́rìí sí i pé, kí Kristi tó dé ni wọ́n ti ń lo onírúurú àgbélébùú. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwòrán tí wọ́n yà nílẹ̀ Íjíbítì àtàwọn àwòrán àwọn ọlọ́run àtàwọn abo ọlọ́run wọn, wọ́n sábà máa ń ya àgbélébùú tó dà bíi lẹ́tà T, tí wọ́n á sì wá ṣe ohun kan tó rí roboto sórí rẹ̀. Ó jẹ́ àgbélébùú tó ní ibi tí èèyàn lè dì mú, wọ́n sì kà á sí ohun tó ṣàpẹẹrẹ ìwàláàyè. Nígbà tó yá, Ṣọ́ọ̀ṣì Coptic nílẹ̀ Íjíbítì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù bẹ̀rẹ̀ sí í lo irú àgbélébùú yìí gan-an.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Catholic Encyclopedia, ṣe sọ, “ó jọ pé irú àgbélébùú tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni wọ́n ń pè ni àgbélébùú ‘gámà’ (crux gammata), àwọn onímọ̀ nípa ìlà oòrùn ayé àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwalẹ̀pìtàn ayé àtijọ́ mọ̀ ọ́n dáadáa sí àgbélébùú swastika, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pè é ní èdè àwọn ará Íńdíà láyé àtijọ́.” Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ilẹ̀ Íńdíà àtàwọn ẹlẹ́sìn Búdà káàkiri ilẹ̀ Éṣíà lo àmì yìí gan-an, èèyàn ṣì lè rí àmì yìí nínú ohun ọ̀ṣọ́ ilé lágbègbè yẹn.
A ò mọ̀ ìgbà náà gan-an tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í lo àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí àmì ìjọsìn wọn. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Vine’s
Expository Dictionary of New Testament Words sọ pé: “Nígbà tó fi máa di àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta lẹ́yìn ikú Olúwa Wa, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti fi àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni kan sílẹ̀ tàbí kí wọ́n sọ àwọn ẹ̀kọ́ náà dìdàkudà. Kí ṣọ́ọ̀ṣì bàa lè mú kí ìpẹ̀yìndà tí wọ́n dáwọ́ lé yìí níyì sí i, wọ́n gba àwọn abọ̀rìṣà tí kò gba àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni gbọ́ pé kí wọ́n di ara wọn, wọ́n sì fàyè gbà wọ́n láti máa lo àwọn àmì ìbọ̀rìṣà wọn nìṣó,” títí kan àgbélébùú.Àwọn òǹkọ̀wé kan tọ́ka sí ohun tí Kọnsitatáìnì tó jẹ́ olùjọsìn ọlọ́run oòrùn sọ lọ́dún 312 Sànmánì Kristẹni lákòókò kan tó ń jagun, ó rí ìran kan tí àgbélébùú wà lórí oòrùn pẹ̀lú àkọlé kan lédè Látìn pé, “in hoc vince” (nípasẹ̀ aṣẹ́gun yìí). Nígbà tó yá, wọ́n fi àmì yìí sára àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò, wọ́n fi sára àwọn apata àti ìhámọ́ra àwọn ọmọ ogun rẹ̀. (Àwòrán apá òsì.) Kọnsitatáìnì sọ pé òun ti di Kristẹni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló tó ṣe ìrìbọmi, nígbà tó kù díẹ̀ kó kú. Àwọn kan tiẹ̀ kọminú sí ohun tó ṣe yìí. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àgbélébùú, ìyẹn The Non-Christian Cross sọ pé, “Kàkà kí Kọnsitatáìnì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ará Násárétì, ńṣe ló ń gbìyànjú láti yí ẹ̀sìn Kristẹni sí nǹkan míì kí àwọn abọ̀rìṣà bàa lè ṣe é.”
Látìgbà yẹn, ni wọ́n ti ń lo onírúurú àgbélébùú. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì, ìyẹn The Illustrated Bible Dictionary sọ bí àgbélébùú tí wọ́n ń pè ní St. Anthony ṣe rí, ó ní, “wọ́n ṣe é bíi lẹ́tà T gàdàgbà, àwọn kan sọ pé, látinú ọ̀rọ̀ náà, tau tó jẹ́ àmì ọlọ́run Támúsì [ti àwọn ará Bábílónì], ni wọ́n ti mú àmì yìí jáde.” Àgbélébùú míì tún wà tí wọ́n ń pè ní àgbélébùú St. Andrew, ó rí bíi lẹ́tà X àti àgbélébùú tá a mọ̀ dáadáa, tí wọ́n kàn sún igi tí wọ́n fi dábùú rẹ̀ wálẹ̀ díẹ̀, ìyẹn àgbélébùú ilẹ̀ Látìn. Èyí tá a sọ gbẹ̀yìn yìí, ìyẹn àgbélébùú ilẹ̀ Látìn, làwọn èèyàn “gbà pé orí àgbélébùú yìí ni Olúwa wa kú sí.”
Ohun Táwọn Kristẹni Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní Gbà Gbọ́
Bíbélì sọ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ tó gbọ́rọ̀ Jésù ló di onígbàgbọ́, wọ́n sì gbà pé ikú ìrúbọ tó kú lágbára láti dá àwọn nídè. Bíbélì sọ pé, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù fún àwọn Júù tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì, tó sì fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ní Kristi náà, “Kírípọ́sì tí ó jẹ́ alága sínágọ́gù di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n sì gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́, a sì ń batisí wọn.” (Ìṣe 18:5-8) Kàkà kí àwọn Kristẹni fàyè gba lílo àwọn àmì ìjọsìn kan tàbí ère nínú ìjọsìn wọn, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé, “ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà” àti fún àṣà èyíkéyìí tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà.—1 Kọ́ríńtì 10:14.
Àwọn òpìtàn àtàwọn tó ń ṣèwádìí kò rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni lo àgbélébùú. Ó dùn mọ́ni nínú láti gbọ́ ohun tí ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa àgbélébùú, ìyẹn ìwé History of the Cross sọ, ìwé yìí fa ọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé kan tó gbé láyé lọ́gọ́rùn-ún ọdún kẹtàdínlógún yọ, pé: “Ǹjẹ́ inú Jésù tá a ti ṣe lógo á dùn láti rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n ń bọlá tàbí jọ́sìn ohun tí [wọ́n sọ pé] wọ́n fi ṣìkà pa Òun?” Báwo lo ṣe máa dáhùn?
Ìjọsìn tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú lílo àmì tàbí ère ìjọsìn. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà?” (2 Kọ́ríńtì 6:14-16) Kò sí ibì kankan tí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé kí àwọn Kristẹni nínú ìjọsìn wọn máa lo ohun tí wọ́n kan Jésù mọ́.—Fi wé ohun tó wà nínú Mátíù 15:3; Máàkù 7:13.
Kí la fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀? Kì í ṣe àgbélébùú tàbí àmì èyíkéyìí, àmọ́ ìfẹ́ ni. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Ohun tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ń ṣàlàyé kì í ṣe ohun tí àwọn èèyàn òde òní ń pè ní àgbélébùú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwòrán ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàdínlógún nípa bí wọ́n ṣe ń pa èèyàn lórí Staurosʹ, ó wá láti Lipsius’ “De Cruce”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwòrán ara ògiri ilẹ̀ íjíbítì (nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni) nípa àgbélébùú tó ní ibi tí èèyànlè dì mú, tó ṣàpẹẹrẹ ìwàláàyè
[Credit Line]
© DeA Picture Library / Art Resource, NY
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àgbélébùú gámà tó wà lára Tẹ́ńpìlì Híńdù ti Laxmi Narayan
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Látinú ìwé náà, The Cross in Tradition, History, and Art (1897)