Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń ṣe Ohun Tó Burú?
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń ṣe Ohun Tó Burú?
ṢÀṢÀ èèyàn ló máa sọ pé òun kò gbà pé aláìpé ni gbogbo wa, tí ìyẹn sì máa ń mú ká ṣe àṣìṣe àtàwọn nǹkan tá a máa ń kábàámọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, ṣé ìyẹn ló mú káwọn èèyàn máa hùwà ibi tó burú jáì àtàwọn ìwà ìkà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá a sábà máa ń rí tàbí gbọ́ nínú ìròyìn lójoojúmọ́?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tá a sì máa ń ṣe àṣìṣe, gbogbo èèyàn ló gbà pé àwọn nǹkan kan wà téèyàn kò gbọ́dọ̀ ṣe àti pé èèyàn lè yẹra fún ìwà ìkà. Ọ̀pọ̀ ló tún gbà pé ìyàtọ̀ wà láàárín sísọ ohun kan tí kì í ṣe òótọ́ nípa ẹnì kan láìmọ̀ àti mímọ̀ọ́mọ̀ bani lórúkọ jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn ṣèpalára fúnni láìmọ̀ àti mímọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn. Síbẹ̀, àwọn téèyàn kò rò pé wọ́n lè ṣebi ló sì sábà máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ láabi yìí. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe ohun tó burú?
Bíbélì là wá lóye nípa ọ̀ràn yìí. Ó jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé kò dára. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó sọ.
▪ “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.”—ONÍWÀÁSÙ 7:7.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ipò tí ẹnì kan wà lè mú kó ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe. Àwọn míì tiẹ̀ lè hùwà ọ̀daràn torí kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó máa jẹ́ kí àwọn bọ́ lọ́wọ́ ìnira àti àìṣẹ̀tọ́. Ìwé kan tó sọ nípa àwọn apániláyà, ìyẹn Urban Terrorism, sọ pé, “Ohun tó máa ń mú káwọn apániláyà ṣọṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà ni ìnira tí ìṣèlú, ìṣúnná owó àtàwọn èèyàn láwùjọ máa ń fà.”
▪ “Ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo.”—1 TÍMÓTÌ 6:10, BIBELI MIMỌ.
Àwọn kan sọ pé tí owó tó tówó bá tẹ olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́, ńṣe ló máa pa ìwà ọmọlúwàbí tì. Àwọn kan tó jẹ́ aláàánú èèyàn tó ṣeé sún mọ́ máa ń di ọ̀dájú àti òǹrorò ẹ̀dá nígbà tó bá kan ọ̀ràn owó. Ronú nípa ọ̀pọ̀ ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ti hù nítorí ojúkòkòrò, bíi bíbani lórúkọ jẹ́, jìbìtì, jíjí èèyàn gbé láti gba owó àti ìpànìyàn pàápàá.
▪ “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.”—ONÍWÀÁSÙ 8:11.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń rò pé èèyàn lè ṣe ohun tó bá wù ú tí àwọn aláṣẹ kò bá ti rí i. Ìyẹn ló mú káwọn èèyàn máa fi ọkọ̀ sáré àsápajúdé, tí wọ́n ń jí ìwé wò nígbà ìdánwò, tí wọ́n ń kówó ìlú jẹ, tí wọ́n sì tún ń ṣe àwọn ohun míì tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Níbi tí kò bá ti sí ẹni tó máa fi òfin múni tàbí táwọn èèyàn kò bẹ̀rù pé wọ́n lè mú àwọn, ìyẹn lè mú kí àwọn tó ń tẹ̀ lé òfin pàápàá ṣe ohun tí wọn kò jẹ́ ṣe láéláé. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Arguments and Facts, sọ pé, “Bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń lọ láìjìyà ti mú kí ọ̀pọ̀ ará ìlú máa hùwà ọ̀daràn tó burú jù lọ.”
▪ “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—JÁKỌ́BÙ 1:14, 15.
Gbogbo èèyàn ló máa ń ní èrò tí kò tọ́. Ojoojúmọ́ la máa ń rí àwọn nǹkan àti ìdẹwò tó lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀ náà, ìpinnu tí ẹnì kan ṣe bóyá kó tètè mú èrò búburú náà kúrò lọ́kàn tàbí kó máa ronú lé e lórí ló máa pinnu irú ìwà tí ẹni náà máa hù. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Jákọ́bù láti kọ sílẹ̀ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí kìlọ̀ pé, téèyàn bá jẹ́ kí èrò búburú “lóyún,” lọ́kàn ẹni, ìwà tí kò dára lẹni náà máa hù.
▪ “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò ÒWE 13:20.
gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Ipa kékeré kọ́ làwọn tá à ń bá rìn lè ní lórí wa, ì báà jẹ́ ipa rere tàbí búburú. Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nǹkan tó burú jáì tí wọn kò ní lọ́kàn nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí ẹgbẹ́ wọn ń ṣe. Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa, “àwọn arìndìn,” kì í ṣe àwọn tí kò ní làákàyè ló ń sọ bí kò ṣe àwọn tí kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, bí a kò bá fi ìlànà Bíbélì yan àwọn tí à ń bá rìn, kò sí bá ò ṣe ní “rí láburú.”
Èyí àtàwọn ẹsẹ míì nínú Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn ẹni téèyàn kò rò pé wọ́n lè ṣebi fi máa ń ṣe nǹkan tí kò dára tàbí tó burú jáì pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára láti lóye ohun tó ń mú káwọn èèyàn máa hùwà ibi, ǹjẹ́ ìrètí wà pé nǹkan máa yí pa dà sí rere? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé yàtọ̀ sí pé Bíbélì ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ibi, ó tún ṣèlérí pé àwọn ìwà yìí máa dópin. Kí làwọn ìlérí yìí? Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ láyè máa dópin? Àpilẹ̀kọ tó kàn dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.