Kí Làwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kú Nílò?—Báwo Lo Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́?
Kí Làwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kú Nílò?—Báwo Lo Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́?
Nínú yàrá kékeré kan tí Jeanne ń gbé, ilé ìdáná kan wà níbẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìmọ́lẹ̀, nínú ilé ìdáná yìí ni Jeanne ti to tábìlì ìjẹun, àmọ́ kò fọkàn sí ohun tó ń ṣe. Ó kúkú yẹ kó wá nǹkan kan jẹ lóòótọ́. Lójijì, ó rí abọ́ méjì níwájú rẹ̀ . . . ló bá bú sẹ́kún. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó ti to tábìlì fún èèyàn méjì! Ọdún kejì sì nìyẹn tí ọkọ rẹ̀ ti ṣaláìsí.
KÒ RỌRÙN fún àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kò tíì kú láti mọ bí ẹ̀dùn ọkàn àwọn tí irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ṣe máa ń pọ̀ tó. Kódà, èèyàn kì í tètè gbà pé nǹkan náà ṣẹlẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Beryl, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin [72], kò gbà nígbà tí ikú pa ọkọ rẹ̀ lójijì. Ó sọ pé, “Ó dà bíi pé kò rí bẹ́ẹ̀. Mi ò gbà pé kò tún ní fẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn wọnú ilé yìí mọ́.”
Àwọn tí wọ́n gé ẹsẹ̀ wọn ṣì máa ń “rò” nígbà míì pé ẹsẹ̀ náà ṣì wà níbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti gé e. Bí ọ̀ràn àwọn tí ọkọ tàbí aya wọ́n kú ṣe máa ń rí nìyẹn, ó máa ń ṣe wọ́n nígbà míì bíi pé wọ́n “rí” ẹnì kejì wọn láàárín àwọn èrò tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa bá wọn sọ̀rọ̀ bíi pé wọ́n jọ wà pa pọ̀!
Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé kì í sábà mọ ohun tí wọ́n lè ṣe fún àwọn tí ọkọ tàbí aya wọ́n kú. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú? Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́? Nǹkan wo ló yẹ kó o mọ̀, kó o bàa lè ran àwọn tí ọkọ tàbí aya wọ́n kú lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ̀fọ̀? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ìgbésí ayé wọn lẹ́ẹ̀kan sí i?
Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Ṣe
Ìbànújẹ́ tí ikú ọkọ tàbí aya ẹnì kan fà bá a lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé rẹ̀, àwọn wọ̀nyí sì lè fẹ́ gbìyànjú láti ran ẹni náà lọ́wọ́ pé kó tètè ṣíwọ́ nínú ṣíṣọ̀fọ̀. Ọkùnrin kan tó ṣèwádìí lọ́wọ́ àwọn ọgọ́rùn-ún méje [700] èèyàn tí ọkọ tàbí aya wọn kú, kọ̀wé pé: “Kò sí iye àkókò kan ‘pàtó’ téèyàn lè fi Jẹ́nẹ́sísì 37:34, 35; Jóòbù 10:1.
ṣọ̀fọ̀.” Nítorí náà, dípò tí ẹ óò fi máa sọ pé kí wọ́n má sunkún mọ́, ńṣe ni kẹ́ ẹ fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n lè fi bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn hàn.—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ṣèrànwọ́ lórí àwọn ètò tó jẹ mọ́ ìsìnkú, a kò gbọ́dọ̀ rò pé àwa la ní láti darí gbogbo ọ̀ràn ìsìnkú náà. Paul tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta [49], tí ìyàwó rẹ̀ kú sọ pé: “Ó dára gan-an pé àwọn tó ràn mí lọ́wọ́ láti ṣètò ìsìnkú aya mi ṣì fún mi láyè láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì. Ìfẹ́ ọkàn mi ni pé kí nǹkan lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ níbi ìsìnkú aya mi. Mo gbà pé ọ̀wọ̀ tó kẹ́yìn tí mo lè fún un nìyẹn.”
Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọrírì àwọn ìrànlọ́wọ́ kan tí wọ́n rí gbà. Opó kan tó ń jẹ́ Eileen, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin [68], sọ pé: “Ṣíṣètò ìsìnkú àti bíbójú tó ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwé tó yẹ ní ṣíṣe lórí ikú ọkọ mi kò rọrùn rárá, torí pé ìrònú mi kò já gaara. Àmọ́, ọmọ mi ọkùnrin àti ọkọ ọmọ mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”
Bákan náà, má bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ nípa olóògbé náà. Beryl, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Àmọ́ mo ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò sọ̀rọ̀ nípa John ọkọ mi. Ńṣe ló dà bíi pé kò gbé láyé rí, ìyẹn sì bà mí nínú jẹ́.” Tó bá yá, ọkọ tàbí aya kan lè fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kejì rẹ̀ tó ti kú. Ǹjẹ́ o rántí ohun rere kan tàbí ohun kan tó pani lẹ́rìn-ín tí olóògbé náà ṣe nígbà kan? Tó o bá rántí, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ẹ́, sọ ọ́ fún ẹni náà. Tó o bá rí i pé ẹni náà máa mọrírì ọ̀rọ̀ rẹ, sọ ohun tó o fẹ́ràn nípa olóògbé náà tàbí ohun tí o kò lè gbàgbé tí ẹni náà ṣe. Èyí lè ran ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà lọ́wọ́ láti rí i pé òun nìkan kọ́ lòun pàdánù olóògbé náà.—Róòmù 12:15.
Má ṣe gba ẹni tí ọ̀ràn kàn ní ìmọ̀ràn tó pọ̀ jù nígbà tó o bá ń ràn án lọ́wọ́. Má ṣe fi dandan mú ẹni náà pé kó tètè ṣe ìpinnu. a Kàkà bẹ́ẹ̀, lo òye, kó o sì bi ara rẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe láti ran ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí kan lọ́wọ́ lákòókò àjálù tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà yìí?’
Ohun Tó O Lè Ṣe
Ó ṣeé ṣe kí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú gba ìrànlọ́wọ́ táwọn èèyàn bá ṣe fún un láwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé ikú ẹnì kejì rẹ̀. Torí náà, ǹjẹ́ o lè se oúnjẹ fún un, kó o gba àwọn ìbátan rẹ̀ tó wá kí i sí ilé rẹ tàbí kó o wà lọ́dọ̀ rẹ̀?
Ó yẹ kó o tún mọ̀ pé, ọ̀nà tí ọkùnrin àti obìnrin máa ń gbà fara da ìdánìkanwà yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ibì kan láyé, ohun tó lé ní ìdajì lára àwọn ọkùnrin tí aya wọn kú ló máa ń tún ìgbéyàwó ṣe láàárín ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn ikú ìyàwó wọn, èyí kì í sábà ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn obìnrin tí ọkọ wọn kú. Kí ló fa ìyàtọ̀ yìí?
Ní ìyàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò, kì í ṣe torí kí àwọn ọkùnrin lè rí ẹni bá wọn ṣe nǹkan tàbí nítorí ìbálòpọ̀ ni wọ́n fi máa ń tún ìgbéyàwó ṣe. Ohun tó jẹ́ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, aya wọn nìkan ni ọ̀pọ̀ jù lọ ọkùnrin máa ń bá sọ̀rọ̀ àṣírí, èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n dá nìkan wà gan-an nígbà tí aya wọn bá kú. Ní ti àwọn obìnrin tí ọkọ wọn kú, wọ́n sábà máa ń rí ẹni tí wọ́n lè fọ̀rọ̀ lọ̀, àní bí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ wọn tiẹ̀ gbàgbé wọn pàápàá. Bí ọ̀ràn àwọn ọkùnrin ṣe rí yìí jẹ́ ká mọ ara ìdí tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin fi ń wo títún ìgbéyàwó ṣe bí ọ̀nà kan tí wọn ò fi ní máa dá nìkan wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè ṣàì ronú dáadáa lórí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gbé níyàwó náà. Àwọn obìnrin tí ọkọ wọ́n kú lè ní okun láti kojú ìṣòro ìdánìkanwà.
Bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin ni ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ tí ẹnì kejì rẹ̀ kú, kí lo lè ṣe fún un tí kò fi ní máa dá wà lọ́pọ̀ ìgbà? Helen, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta [49] tí ọkọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ló ní ẹ̀mí tó dáa, àmọ́ wọn kì í lo ìdánúṣe. Wọ́n sábà máa ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ tí nǹkan kan bá wà tí mo lè bá a yín ṣe.’ Àmọ́, inú mi máa ń dùn tí ẹnì kan bá sọ fún mi pé, ‘mò ń lọ sọ́jà, ṣé kí á jọ lọ?’” Paul, tí àrùn jẹjẹrẹ pa ìyàwó rẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí òun fi mọrírì rẹ̀ táwọn èèyàn bá ní káwọn jọ ṣeré jáde. Ó sọ pé, “Nígbà míì, ó lè má wù ẹ́ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tàbí kó o sọ ìṣòro rẹ fún wọn. Àmọ́, lẹ́yìn tó o bá ti wà láàárín àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ara máa tù ẹ́ gan-an, o kò sì ní fi bẹ́ẹ̀ dá wà mọ́. Wàá rí i pé àwọn èèyàn bìkítà fún ẹ lóòótọ́, ìyẹn á sì túbọ̀ mú kí nǹkan rọrùn.” b
Ìgbà Tí Ẹnì Kan Túbọ̀ Nílò Ìbánikẹ́dùn
Helen rí i pé ìgbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí òun bá ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ wọn gan-an ni òun máa ń nílò ẹni tóun máa bá sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé rẹ á
máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ tó bá yá, wọ́n á pa dà sídìí nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tìrẹ kò tíì lè rí bẹ́ẹ̀.” Torí bí ipò nǹkan ṣe máa ń rí yìí, àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń wà nítòsí ẹni náà, wọ́n á sì máa ràn án lọ́wọ́ nìṣó.Ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú nílò pé káwọn èèyàn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láwọn ọjọ́ pàtàkì kan bí àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wọn tàbí àyájọ́ ọjọ́ tí ẹnì kejì wọn kú. Eileen, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé ọmọkùnrin òun àgbà ló ran òun lọ́wọ́ tí òun fi lè fara da ìdánìkanwà àti ìbànújẹ́ tó máa ń bá òun ní àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó àwọn. Ó sọ pé, “Ọmọ mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Kevin máa ń mú mi jáde lọ́dọọdún ní àyájọ́ ọjọ́ yìí. Èmi àti ọmọ mi yìí sì jọ máa ń jẹun ọ̀sán, a kì í pe ẹlòmíì síbẹ̀.” O ò ṣe kọ déètì ọjọ́ náà sílẹ̀, ìyẹn ọjọ́ tí nǹkan máa ń nira gan-an fún ará ilé rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú. Èyí á lè jẹ́ kó o ṣètò láti wà nítòsí ẹni náà ní àkókò tó le yẹn tàbí kó o ní kí ẹlòmíì wà níbẹ̀.—Òwe 17:17.
Àwọn kan ti rí i pé àwọn kan tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú pàápàá lè tu àwọn míì nínú. Annie, tí ọkọ rẹ̀ kú lọ́dún mẹ́jọ sẹ́yìn sọ nípa opó kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé, “Ìpinnu tó ṣe ní ipa tó dára lórí mi, ó sì fún mi níṣìírí láti máa fara dà á nìṣó.”
Àwọn tó borí ìbànújẹ́ tí wọ́n ní nígbà tí ọkọ tàbí aya wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lè dẹni tó ń fúnni níṣìírí, tí wọ́n á sì máa fọkàn àwọn èèyàn balẹ̀. Àwọn opó méjì kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, ìyẹn Rúùtù tó ṣì kéré àti Náómì tó jẹ́ ìyá ọkọ rẹ̀ jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún ara wọn. Àkọsílẹ̀ tó ń mú orí ẹni wú yìí ṣàlàyé bí ìrànlọ́wọ́ tí àwọn méjèèjì ṣe fún ara wọn ṣe fún wọn lókun láti borí ìbànújẹ́ wọn, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó ìṣòrò tí wọ́n dojú kọ.—Rúùtù 1:15-17; 3:1; 4:14, 15.
Ìgbà Ìmúláradá
Kí àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kú bàa lè máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn ò ní jẹ́ kí àárò ẹnì kejì wọn tó ń sọ wọ́n ṣàkóbá fún ìlera wọn. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé “ìgbà sísunkún” wà. Àmọ́, ó tún sọ pé “ìgbà ìmúláradá” ní láti wà.—Oníwàásù 3:3, 4.
Paul, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, jẹ́ ká mọ bó ṣe ṣòro tó láti mú ọkàn kúrò lára ẹni tó kú náà. Ó sọ pé, “Ńṣe lèmi àti ìyàwó mi dà bí igi kékeré méjì tí wọ́n gbìn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n lọ́ mọ́ ara wọn, tí wọ́n sì jọ dàgbà. Àmọ́ nígbà tó yá, igi kan kú, wọ́n yọ ọ́, èkejì sì wá rí gbágungbàgun. Kò bá mi lára mu láti máa dá wà.” Àwọn kan ṣì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí ẹni tó kú náà, torí náà wọ́n kọ̀ láti mú ọkàn kúrò lára ẹni náà. Èrò àwọn míì sì ni pé, ìwà ọ̀dàlẹ̀ ló máa jẹ́ táwọn bá bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ìgbésí ayé àwọn nìṣó, torí náà, wọ́n kọ̀ láti máa jáde tàbí láti bá àwọn èèyàn kẹ́gbẹ́. Báwo la ṣe lè ran àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kú lọ́wọ́ kí ara wọn lè kọ́fẹ pa dà, kí wọ́n sì lè máa bá ìgbésí ayé wọn nìṣó?
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lè jẹ́, láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Herbert, tí ìyàwó rẹ̀ kú lọ́dún mẹ́fà sẹ́yìn sọ pé: “Mo máa ń mọyì rẹ̀ gan-an bí àwọn àlejò bá jókòó tí wọ́n dákẹ́ tí wọ́n sì ń fetí sí bí mo ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn mi lákòókò yẹn. Mo mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni mo máa ń tu àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ mi lára, àmọ́ mo mọrírì ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tí wọ́n ní.” Bí ọ̀rẹ́ Paul kan tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe máa ń béèrè bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ̀ wú u lórí gan-an. Paul sọ pé, “Mo mọrírì bó ṣe máa ń bá mi sọ̀rọ̀ látọkànwá yẹn, mo sì sábà máa ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi lákòókò yẹn fún un.”—Òwe 18:24.
Bí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú bá ń kábàámọ̀, tó ń sọ ẹ̀bi rẹ̀ tàbí tó ń fi ìbínú hàn, èyí fi hàn pé ó ti wá mọ̀ pé nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ nìyẹn. Nínú ọ̀ràn Ọba Dáfídì, bó ṣe sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó ga jù lọ téèyàn lè sọ ìṣòro ọkàn ẹni fún yìí ló fún Dáfídì 2 Sámúẹ́lì 12:19-23.
lókun láti “dìde,” tó sì gbà pé ọmọkùnrin òun ti kú.—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní kọ́kọ́ rọrùn, nígbà tó bá yá, ó yẹ kí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú máa bá ìgbésí ayé ojoojúmọ́ tó ń gbé tẹ́lẹ̀ nìṣó. Ṣé o lè pè é pé kẹ́ ẹ jọ ṣe àwọn ohun kan lára nǹkan tó o máa ń ṣe lójoojúmọ́, bíi lílọ sọ́jà tàbí ṣíṣeré jáde? Ṣé o lè pe ọ̀rẹ́ rẹ yìí pé kó wá kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́? Ọ̀nà míì nìyẹn téèyàn lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má ṣe máa dá wà. Bí àpẹẹrẹ, ṣé opó kan lè bá ẹ tọ́jú àwọn ọmọ rẹ tàbí kó o ní kó kọ́ ẹ bó ṣe máa ń se oúnjẹ tó mọ̀ ọ́n sè dáadáa? Ṣé ẹni tí ìyàwó rẹ̀ kú lè bá ẹ ṣe àwọn àtúnṣe kan nílé rẹ? Yàtọ̀ sí pé èyí á jẹ́ kí wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó lárinrin, á tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé ìgbésí ayé wọn ṣì wúlò.
Bí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú bá tún sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára òun fún àwọn èèyàn, èyí lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ láti pa dà gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì lè ràn án lọ́wọ́ láti máa lépa àwọn ohun míì tó ṣàǹfààní. Bí ọ̀rọ̀ Yonette, ẹni ogójì ọdún ó lé mẹ́rin [44] tó jẹ́ opó, tó sì tún jẹ́ ìyá ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó rántí pé: “Kò rọrùn rárá láti máa pa dà ṣe àwọn nǹkan téèyàn ti ń ṣe tẹ́lẹ̀! Ó máa ń ṣòro fún mi lójoojúmọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, láti bójú tó ọ̀ràn ìnáwó àti láti bójú tó àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.” Àmọ́, nígbà tó yá, Yonette mọ bó ṣe lè ṣètò ara rẹ̀ àti bó ṣe lè bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó tún jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ran òun lọ́wọ́.
“Ẹ̀bùn Iyebíye Ṣì Ni Ìwàláàyè”
Tá a bá fẹ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́, ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti ará ilé tó ṣeé fẹ̀yìn tì, a ní láti mọ̀ pé, láàárín àwọn àkókò tí nǹkan dojú rú, tí ìbànújẹ́ sì dorí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú kodò, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ìrètí pé nǹkan máa sunwọ̀n sí i fún ẹni náà fún ọ̀pọ̀ oṣù àti ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá. Ó dájú pé, “ìyọnu àjàkálẹ̀ ọkàn-àyà,” rẹ̀ máa pọ̀ gan-an.—1 Àwọn Ọba 8:38, 39.
Àkókò yìí gan-an lẹni náà nílò pé ká fún un níṣìírí láti mọ̀ pé nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀, kó má sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Irú àwọn ìrànlọ́wọ́ yìí ti mú kí ìgbà ọ̀tun dé bá ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ opó àtàwọn tí ìyàwó wọn kú. Claude, tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún [60] tí ìyàwó rẹ̀ kú, tó sì ti wá di òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ní ilẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Ẹ̀bùn iyebíye ṣì ni ìwàláàyè jẹ́, àní lẹ́yìn ìbànújẹ́ tí ikú ẹnì kejì ẹni mú wá.”
Ìgbésí ayé kì í rí bákan náà lẹ́yìn ikú ọkọ tàbí aya ẹni. Síbẹ̀, àwọn tí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n lè ṣe fún àwọn èèyàn.—Oníwàásù 11:7, 8.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí náà, “Ṣé Ohun Ìrántí Tó Ń Woni Sàn Ni àbí Èyí Tó Ń Múni Ṣàárẹ̀?” lójú ìwé 12.
b Fún àbá síwájú sí i lórí bá a ṣe lè ran ẹni téèyàn rẹ̀ kú lọ́wọ́, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, ojú ìwé 20 sí 25. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń wà nítòsí ẹni náà, wọ́n á sì máa ràn án lọ́wọ́ nìṣó
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ṣé Ohun Ìrántí Tó Ń Woni Sàn Ni àbí Èyí Tó Ń Múni Ṣàárẹ̀?
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Helen tí ọkọ rẹ̀ kú ní nǹkan bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹrù ọkọ mi ni mo tọ́jú. Mo ṣàkíyèsí pé àwọn ẹrù yìí jẹ́ kí n máa rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń fún mi láyọ̀ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Mi ò fẹ́ da èyíkéyìí nù báyìí, torí pé bí nǹkan ṣe rí lára èèyàn lónìí lè yàtọ̀ gan-an bó di ọ̀la.”
Àmọ́ ọ̀rọ̀ Claude, tí ìyàwó rẹ̀ kú lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn yàtọ̀, ó sọ pé: “Ní tèmi o, mi ò fẹ́ máa rí àwọn ẹrù rẹ̀, kí n má bàa máa rántí rẹ̀. Mo rò pé bí mo ṣe kó gbogbo ẹrù rẹ̀ dà nù ràn mí lọ́wọ́ láti gbà pé ó ti ṣẹlẹ̀, kò sì jẹ́ kí ìbànújẹ́ náà pọ̀ jù fún mi.”
Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí jẹ́ ká rí bí ohun tí ẹnì kan máa ṣe sí ẹrù ẹnì kejì rẹ̀ tó kú ṣe yàtọ̀ gan-an sí ohun tí ẹlòmíì máa ṣe. Torí náà, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kò ní gbìyànjú láti sọ fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú pé kó ṣe ohun táwọn fẹ́ nípa ọ̀ràn náà.—Gálátíà 6:2, 5.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ṣé àwọn ọjọ́ kan pàtó wà tí wọ́n máa mọrírì ìrànlọ́wọ́ rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Má gbàgbé láti máa pè wọ́n pé kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ní kí àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kú wá lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe lójoojúmọ́ tàbí sí eré ìnàjú