Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Kan Di Ẹni Tó Dáńgájíá

Bá A Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Kan Di Ẹni Tó Dáńgájíá

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Bá A Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Kan Di Ẹni Tó Dáńgájíá

George: a “Alaalẹ́ ló máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Michael, ọmọkùnrin mi ọmọ ọdún mẹ́rin, máa ń fọ́n àwọn ohun ìṣeré rẹ̀ káàkiri ilé. Mo máa ń gbìyànjú pé kó palẹ̀ gbogbo wọn mọ́ kó tó lọ sùn. Àmọ́, ara Michael kì í balẹ̀, ńṣe ló máa ń lọgun, táá sì máa ṣe kátikàti. Nígbà míì, tí gbogbo ẹ̀bá ti sú mi, màá kàn jágbe mọ́ ọn ni, àmọ́ ńṣe nìyẹn máa ń mú kí ọ̀ràn náà tún burú sí i fún àwa méjèèjì. Mo fẹ́ kí inú wa máa dùn tá a bá fẹ́ lọ sùn, nítorí náà, èmi fúnra mi ni mo máa ń palẹ̀ àwọn ohun ìṣeré náà mọ́, n kì í sọ fún un mọ́ pé kó ṣe é.”

Emily: “Wàhálà náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jenny ọmọbìnrin mi ọmọ ọdún mẹ́tàlá kò lóye ohun tí olùkọ́ rẹ̀ fẹ́ kó ṣe nípa iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tó gbé fún un. Odindi wákàtí kan ni Jenny fi sunkún nígbà tó dé láti ilé ẹ̀kọ́. Mo sọ fún un pé kó lọ bá olùkọ́ rẹ̀ pé kó ràn án lọ́wọ́, àmọ́ Jenny yarí pé olùkọ́ òun ti le jù, torí náà, kò lè bá a sọ̀rọ̀. Ó ń ṣe mí bíi pé kí n já lọ bá olùkọ́ náà nílé ẹ̀kọ́, kí n sì sọ èrò ọkàn mi fún un. Kò yẹ kí ẹnì kan ba ọmọ mi nínú jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ yẹn!”

ǸJẸ́ ohun tó ṣe George àti Emily yẹn ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí? Bíi tiwọn, ọ̀pọ̀ òbí ni inú wọn kì í dùn nígbà tí wọ́n bá rí ọmọ wọn nínú ìṣòro tàbí tí inú ọmọ wọn bá bà jẹ́. Ohun táwọn òbí máa ń fẹ́ ni pé kí àwọn dáàbò bo ọmọ àwọn. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí fún àwọn òbí yẹn láǹfààní láti kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa bó ṣe lè di ọmọ tó dáńgájíá. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀kọ́ tí ọmọ ọdún mẹ́rin àti ọmọ ọdún mẹ́tàlá máa kọ́ yàtọ̀ síra o.

Ṣùgbọ́n òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn òbí kò lè máa fìgbà gbogbo dáàbò bo ọmọ wọn kó má bàa rí ìṣòro nígbèésí ayé rẹ̀. Nígbà tó bá yá, ọmọ á fi bàbá àti ìyá sílẹ̀, yóò sì máa “ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5; Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Láti lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa dá nǹkan ṣe fúnra wọn, àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ kíkọ́ wọn láti jẹ́ ẹni tí kò mọ ti ara rẹ̀, ẹni tó ń bìkítà fún àwọn ẹlòmíì, tí yóò sì di àgbà tó dáńgájíá. Ìyẹn kì í ṣe iṣẹ́ kékeré o!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò bímọ, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún àwọn òbí pé wọ́n rí àpẹẹrẹ gidi lára Jésù àti nínú ọ̀nà tó gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò. Ìdí tó fi yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó lẹ́yìn tó bá lọ. (Mátíù 28:19, 20) Ohun tí Jésù gbé ṣe yìí jọ ohun táwọn òbí máa ṣe láti tọ́ ọmọ wọn di ọmọ tó dáńgájíá. Jẹ́ ká gbé apá mẹ́ta yẹ̀ wò nínú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fún àwọn òbí.

“Fi Àwòṣe Lélẹ̀ fún” Ọmọ Rẹ Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kúrò ní ayé, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòhánù 13:15) Bákàn náà, ó yẹ kí àwọn òbí máa ṣàlàyé, kí wọ́n sì máa fi hàn nípa àpẹẹrẹ wọn béèyàn ṣe ń di ẹni tó dáńgájíá.

Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń sọ nípa bí mo ṣe lè máa bójú tó ojúṣe mi lọ́nà tó dára? Ṣé mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ́lọ́rùn tí mò ń rí látinú ṣíṣiṣẹ́ kára nítorí kí n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? Tàbí ńṣe ni mo máa ń ṣàròyé tí mo sì máa ń fi ara mi wé àwọn tó ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ?’

Ká sòótọ́, kò sí ẹni pípé. Gbogbo wa ni nǹkan máa ń sú nígbà míì. Àmọ́ àpẹẹrẹ tó o bá fi lélẹ̀ lè jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ tó lè mú kí ọmọ rẹ rí i pé ìwà ọmọlúwàbí ṣe pàtàkì, ó sì gbayì.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Bó bá ṣeé ṣe, mú ọmọ rẹ lọ ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kó o sì fi hàn án bó o ṣe ń wá owó láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé. Kí ìwọ àti ọmọ rẹ ṣèrànwọ́ fún ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, kó o sọ bí inú rẹ ṣe dùn tó nítorí ohun tẹ́ ẹ ṣe yẹn.—Ìṣe 20:35.

Má Ṣe Retí Ohun Tó Pọ̀ Jù Jésù mọ̀ pé ó máa gba àkókò kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó lè ṣe ohun tí òun ń retí lọ́dọ̀ wọn. Nígbà kan, ó sọ fún wọn pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòhánù 16:12) Kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ni Jésù retí pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa dá ṣe nǹkan fúnra wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ wọn ní ohun púpọ̀. Ìgbà tó rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ti kúnjú ìwọ̀n ló tó rán wọn jáde láwọn nìkan.

Bó ṣe yẹ kí ọ̀ràn àwọn òbí rí nìyẹn, kò bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ pé kí wọ́n máa ṣe ojúṣe àwọn àgbàlagbà nígbà tí wọn kò tíì kúnjú ìwọ̀n láti ṣe é. Yàtọ̀ síyẹn, bí àwọn ọmọ bá ṣe ń dàgbà, ó yẹ káwọn òbí mọ irú iṣẹ́ tó yẹ́ kí wọ́n gbé fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí ní láti kọ́ àwọn ọmọ láti máa bójú tó ìmọ́tótó ara wọn, láti tọ́jú yàrá wọn, láti tètè máa dé síbi tí wọ́n bá pè wọ́n sí àti bí wọ́n ṣe lè ṣọ́wó ná. Nígbà tí ọmọ kan bá bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, òbí rẹ̀ ní láti kọ́ ọ láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́.

Yàtọ̀ sí pé kí àwọn òbí pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ wọn, ó tún yẹ kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe é láṣeyọrí. Bàbá tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn George, wá mọ̀ pé ara ìdí tí Michael fi bínú tí kò palẹ̀ àwọn ohun ìṣeré rẹ̀ mọ́ ni pé iṣẹ́ náà ti pọ̀ jù. George sọ pé: “Kàkà kí n máa pariwo mọ́ Michael láti ṣa àwọn ohun ìṣeré náà jọ, ńṣe ni mo sapá láti kọ́ ọ bó ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà.”

Kí ni ohun náà gan-an tó kọ́ ọmọ yìí? George sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, mo sọ iye aago tí a ó máa ṣa àwọn ohun ìṣeré náà jọ lálaalẹ́. Lẹ́yìn náà, èmi pẹ̀lú rẹ̀ la jọ ń ṣe é. A ó ṣe apá kan inú yàrá náà lẹ́ẹ̀kan, mo wá sọ iṣẹ́ náà di eré. Mo sọ ọ́ di ìdíje, pé ta ló lè yára jù nínú àwa méjèèjì láti ṣa àwọn ohun ìṣeré náà jọ. Láìpẹ́, iṣẹ́ náà di ohun tí à ń ṣe ká tó lọ sùn. Mo ṣèlérí fún Michael pé tó bá ṣe iṣẹ́ náà kíákíá màá fi ìtàn kan kún ìtàn tí mo máa ń kà fún un kó tó lọ sùn, àmọ́ tó bá fiṣẹ́ náà falẹ̀, àkókò tí mo máa fi ka ìtàn fún un á kúrú.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ronú lórí ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ rẹ lè ṣe tó máa mú kí nǹkan máa lọ déédéé nínú ilé yín. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ohun kan wà tí mò ń ṣe fún àwọn ọmọ mi tó jẹ́ pé wọ́n lè ṣe fúnra wọn?’ Tó bá wà, kọ́ àwọn ọmọ rẹ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe ohun náà títí dìgbà tí wàá rí i pé wọ́n lè dá a ṣe. Jẹ́ kó yé wọn pé ọwọ́ tí kálukú wọn bá fi mú iṣẹ́ tó o gbé fún wọn ló máa pinnu ohun tí wọ́n máa gbà, bóyá ẹ̀bùn ni o tàbí ìbáwí. Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o fún wọn lẹ́bùn tí wọ́n bá ṣe dáadáa tàbí kí wọ́n jìyà tí wọn ò bá ṣe dáadáa.

Fún Wọn Ní Ìtọ́ni Tó Ṣe Pàtó Bíi ti àwọn olùkọ́ rere, Jésù mọ̀ pé ọ̀nà tó dára jù lọ tẹ́nì kan lè gbà kọ́ nǹkan ni pé kẹ́ni náà fi ohun tó kọ́ dánra wò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù rí i pé àkókò tó, ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ “ní méjìméjì ṣáájú rẹ̀ sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé.” (Lúùkù 10:1) Àmọ́ ṣá o, kò fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Kó tó rán wọn jáde, ó fún wọn láwọn ìtọ́ni pàtó kan. (Lúùkù 10:2-12) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn pa dà, tí wọ́n sì ròyìn àṣeyọrí wọn, Jésù gbóríyìn fún wọn, ó sì fún wọn níṣìírí. (Lúùkù 10:17-24) Ó fi hàn pe òun fọkàn tán wọn àti pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n nídìí iṣẹ́ náà.

Bí àwọn ọmọ rẹ bá ní ohun kan láti ṣe àmọ́ tí wọn kò mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é, kí lo máa ń ṣe? Ṣé o máa ń wá ọ̀nà láti gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nǹkan tó ń bà wọ́n lẹ́rù, ṣé o máa ń dáàbò bò wọ́n kí wọ́n má bàa ní ìjákulẹ̀ àti ìkùnà nínú ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe? Ohun tó lè kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn ni pé kó o “gba” ọmọ rẹ “sílẹ̀” tàbí kó o bá a gbé ẹrù náà.

Àmọ́, rò ó wò ná, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lo máa ń sáré wá “gba” ọmọ rẹ “sílẹ̀,” irú èrò wo lo fẹ́ kí ọmọ yẹn ní? Ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé, ó fọkàn tán an, o sì gbà pé ó kúnjú ìwọ̀n láti dá ṣe nǹkan? Àbí ò ń sọ fún un pé ọmọdé jòjòló tí kò lè dá ṣe nǹkan kan ni, àfi kó o ràn án lọ́wọ́?

Bí àpẹẹrẹ, báwo ni Emily, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ṣe bójú tó ìṣòro ọmọbìnrin rẹ̀? Kàkà kó bá Jenny ọmọ rẹ̀ lọ sílé ìwé, ó pinnu pé kó lọ bá olùkọ́ náà ní tààràtà kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀. Ìyá yìí àti ọmọ rẹ̀ jọ kọ àwọn ìbéèrè kan sílẹ̀, èyí tí ọmọ náà máa mú lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n jíròrò nípa ìgbà tó yẹ kí ọmọ rẹ̀ bá olùkọ́ náà sọ̀rọ̀. Kódà, wọ́n tún ṣe ìfidánrawò bí ọmọ rẹ̀ ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ náà fún olùkọ́ náà. Emily sọ pé: “Jenny ti wá mọ́kàn le báyìí láti bá olùkọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, olùkọ́ ọ̀hún sì yìn ín fún ohun tó ṣe yẹn. Inú Jenny dùn gan-an, inú tèmi náà sì dùn.”

GBÌYÀNJU ÈYÍ WÒ: Kọ ìṣòro kan tí ọmọ rẹ bá pàdé ní lọ́wọ́lọ́wọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, kọ ohun tó o máa ṣe láti ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti borí ìṣòro náà láìjẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ lo “gbà” á “sílẹ̀.” Kí ìwọ àti ọmọ rẹ fi àwọn ohun tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe láti borí ìṣòro náà dánra wò. Mú un dá ọmọ náà lójú pé ó lè ṣàṣeyọrí.

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lò ń gba ọmọ rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro, ìyẹn kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti máa yanjú ìṣòro tó bá ń dojú kọ nígbèésí ayé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọ́ ọmọ rẹ di ẹni tó dáńgájíá. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn tó wúlò jù lọ lo fún ọmọ rẹ yẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ yìí pa dà.

BI ARA RẸ PÉ . . .

▪ Ǹjẹ́ mo máa ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ọmọ mi?

▪ Ǹjẹ́ mo máa ń sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn àti bí wọ́n ṣe lè ṣe é láṣeyọrí?

▪ Ìgbà wo ni mo fún ọmọ mi níṣìírí kẹ́yìn tí mo sì gbóríyìn fún un?