Sínágọ́gù—Ibi Tí Jésù àti Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Ti Wàásù
Sínágọ́gù—Ibi Tí Jésù àti Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Ti Wàásù
“Lẹ́yìn náà, ó lọ yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.”—MÁTÍÙ 4:23.
ÀKỌSÍLẸ̀ inú ìwé Ìhìn Rere sọ ọ́ léraléra pé Jésù máa ń wà nínú sínágọ́gù. Jésù sábà máa ń lo sínágọ́gù bí ibi tó ti ń wàásù tó sì ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ ní Násárétì, ìyẹn ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, tàbí ní Kápánáúmù, ìlú tó fi ṣe ilé tàbí ní ìlú àti abúlé èyíkéyìí tó ṣèbẹ̀wò sí nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó mú kí ọwọ́ rẹ̀ dí jọjọ lọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀. Kódà, nígbà tí Jésù wo ohun tó ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọpọ̀ sí.”—Jòhánù 18:20.
Bákan náà, àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn Kristẹni yòókù nígbà ìjímìjí sábà máa ń kọ́ni ní àwọn sínágọ́gù Júù. Àmọ́ báwo ló ṣe jẹ́ pé inú sínágọ́gù làwọn Júù ti ń jọ́sìn? Báwo sì ni ilé ìjọsìn wọ̀nyẹn ṣe rí nígbà ayé Jésù? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò kínníkínní.
Ohun Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Àwọn Júù Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Júù máa ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ tó
wà níbẹ̀. Àmọ́ tó bá di ọ̀ràn ìjọsìn wọn ojoojúmọ́, sínágọ́gù àdúgbò ni wọ́n máa ń lò, bóyá wọ́n ń gbé ní Palẹ́sìnì tàbí wọ́n ń gbé ní ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìlú tí àwọn Júù tẹ̀dó sí nílẹ̀ òkèèrè.Ìgbà wo ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo sínágọ́gù? Àwọn kan gbà pé àkókò tí àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì (ní ọdún 607 sí 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lò ó, ìyẹn ìgbà tí tẹ́ńpìlì Jèhófà ti wó palẹ̀. Tàbí kó jẹ́ kété lẹ́yìn tí àwọn Júù pa dà láti ìgbèkùn, nígbà tí Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n túbọ̀ ní ìmọ̀ àti òye tó pọ̀ sí i nípa Òfin Ọlọ́run.—Ẹ́sírà 7:10; 8:1-8; 10:3.
Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ náà, “sínágọ́gù” túmọ̀ sí “àpéjọ” tàbí “ìjọ.” Bí wọ́n ṣe lò ó nìyẹn nínú Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ náà wá túmọ̀ sí ilé táwọn èèyàn ti ń péjọ fún ìjọsìn. Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú tí Jésù lọ ló ti ní sínágọ́gù tiẹ̀, àwọn ìlú ńlá ní àwọn sínágọ́gù mélòó kan, Jerúsálẹ́mù sì ní ọ̀pọ̀ sínágọ́gù. Báwo ni àwọn ilé náà ṣe rí?
Ilé Ìjọsìn Tó Mọ Níwọ̀n Nígbà táwọn Júù bá fẹ́ kọ́ sínágọ́gù, wọ́n máa ń wá ibi tó ga, wọ́n á sì ṣètò láti kọ́ ilé náà lọ́nà tí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ (1) á fi dojú kọ́ Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, ó jọ pé wọ́n ṣì lè kọ́ ilé náà lọ́nà míì torí pé kì í fìgbà gbogbo bọ́ sí ibi tí wọ́n fẹ́.
Nígbà tí wọ́n bá kọ́ sínágọ́gù parí, ó sábà máa ń jẹ́ ilé tó mọ níwọ̀n, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀. Nǹkan pàtàkì tó máa ń wà níbẹ̀ ni àpótí (2), tàbí ibi tí wọ́n máa ń tọ́jú ohun tó ṣeyebíye jù lọ lágbègbè kan pa mọ́ sí, ìyẹn àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣèpàdé, wọ́n á gbé àpótí tí kò tóbi jù náà sí àyè rẹ̀, tí ìpàdé bá sì parí, wọ́n á wá gbé e lọ síbi tí wọ́n máa ń tọ́jú rẹ̀ sí (3).
Àwọn ìjókòó iwájú wà nítòsí àpótí náà, wọ́n sì dojú kọ ìjọ, (4) wọ́n wà fún àwọn alága sínágọ́gù àtàwọn àlejò pàtàkì. (Mátíù 23:5, 6) Pèpéle, àga ìsọ̀rọ̀ àti ìjókòó olùbánisọ̀rọ̀ wà nítòsí àárín gbọ̀ngàn náà (5). Àwọn bẹ́ǹṣì tí wọ́n tò sí apá mẹ́ta fún ìjọ dojú kọ pèpéle náà (6).
Ìjọ àdúgbò ló sábà máa ń lo sínágọ́gù, àwọn ló sì máa ń bójú tó o. Ọrẹ àtinúwá tí àwọn olówó àti tálákà ń mú wá ni wọ́n fi ń ṣètọ́jú ilé náà. Àmọ́ báwo ni àwọn ìpàdé inú sínágọ́gù ṣe máa ń rí?
Ìjọsìn Inú Sínágọ́gù Ohun tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìjọsìn inú sínágọ́gù ni, ìyìn, àdúrà, kíka Ìwé Mímọ́, kíkọ́ni àti wíwàásù. Bí ìjọ ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ìsìn ni pé wọ́n á ka Ṣémà, ìyẹn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Júù. Látinú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń kà ni wọ́n ti mú orúkọ yẹn jáde, ẹsẹ náà sọ pé: “Fetí sílẹ̀ [Shema], ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.”—Diutarónómì 6:4.
Lẹ́yìn náà, wọ́n á ka Tórà, ìyẹn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì tí Mósè kọ, wọ́n á sì ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa rẹ̀. (Ìṣe 15:21) Wọ́n á tún ka ìwé míì tẹ̀ lé e, ìyẹn àyọkà látinú ìwé àwọn wòlíì (haftarah), wọ́n á sì ṣàlàyé rẹ̀, wọ́n á sì tún sọ béèyàn ṣe lè fi sílò. Nígbà míì, àwọn àlejò olùbánisọ̀rọ̀ ló máa ń ṣe apá yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ìwé Lúùkù 4:16-21 sọ nípa èyí tí Jésù ṣe nígbà kan.
Àmọ́ ṣá o, àkájọ ìwé tí wọ́n fi lé Jésù lọ́wọ́ ní ìpàdé yẹn kò ní orí àti ẹsẹ bíi tàwọn Bíbélì tá à ń lò lóde òní. Nítorí náà, a lè fojú inú wo bí Jésù ṣe ń fi ọwọ́ òsì rẹ̀ tú àkájọ ìwé náà tó sì ń fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ká a títí tó fi rí ibi tó ń wá nínú ìwé náà. Lẹ́yìn tó ka ibi tó fẹ́ kà náà, ó ká ìwé náà jọ pa dà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ka àwọn ìwé tí wọ́n fi èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ yìí, wọ́n á sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Árámáíkì. Nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Gíríìkì, Bíbélì Septuagint ni wọ́n máa ń lò.
Ibi Pàtàkì Tí Wọ́n Ń Lò Lójoojúmọ́ Sínágọ́gù jẹ́ ibi tí àwọn Júù máa ń lò lójoojúmọ́ fún onírúurú nǹkan, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń lo àwọn ilé míì tí wọ́n kọ́ mọ́ ọn tàbí àwọn ilé tí wọ́n jọ wà lórí ilẹ̀ kan náà. Nígbà míì, wọ́n máa ń gbọ́ ẹjọ́ níbẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn ìpàdé ìlú níbẹ̀, kódà wọ́n ń ṣe àpéjọ níbẹ̀, tí wọ́n sì máa ń pèsè oúnjẹ fún wọn nínú yàrá ìjẹun tó wà níbẹ̀. Àwọn arìnrìn-àjò máa ń sùn nínu àwọn ilé ibùwọ̀ tó wà ní ibi tí sínágọ́gù wà.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ìlú ni sínágọ́gù tún ti ní ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n sábà máa ń kọ́ mọ́ ọn. A lè fojú inú wo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ka àwọn lẹ́tà ńlá tí olùkọ́ kọ sórí wàláà tí wọ́n fi ìda kùn. Irú ilé ẹ̀kọ́ yìí ló mú kí àwọn Júù ayé àtijọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, kódà ohun ló jẹ́ káwọn gbáàtúù èèyàn mọ Ìwé Mímọ́ kà.
Àmọ́ ìdí pàtàkì tí wọ́n fi kọ́ sínágọ́gù ni pé kí wọ́n lè máa rí ibi ṣe ìjọsìn déédéé. Nígbà náà kò yani lẹ́nu pé ìpàdé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jọ ìpàdé táwọn Júù máa ń ṣe nínú sínágọ́gù. Ìdí táwọn Kristẹni náà fi máa ń ṣe ìpàdé ni láti jọ́sìn Jèhófà nípa gbígbàdúrà, kíkọ orin ìyìn àti kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì jíròrò rẹ̀. Ìjọra yẹn kò tán síbẹ̀ o. Ní ilé ìjọsìn méjèèjì yìí, ọrẹ àtinúwá ni wọ́n máa fi ń bójú tó àwọn nǹkan tó bá yẹ ní ṣíṣe. Kì í ṣe àwọn àlùfáà nìkan ló ní àǹfààní láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbẹ̀ kí wọ́n sì jíròrò rẹ̀; nínú ilé ìjọsìn méjèèjì yìí, àwọn àgbà ọkùnrin ló máa ń ṣètò ìpàdé, àwọn ló sì máa ń darí rẹ̀.
Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi lélẹ̀. Láwọn ọ̀nà kan, ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba jọ àwọn ìpàdé táwọn Júù ń ṣe láyé àtijọ́ nínú sínágọ́gù. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwa Ẹlẹ́rìí ń péjọ fún ìdí kan náà tí gbogbo àwọn olùfẹ́ òtítọ́ fi ń péjọ, ìyẹn láti “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Jákọ́bù 4:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwòrán ìkọ́lé Sínágọ́gù Gamla ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni wọ́n wò fi kọ́ àtúnkọ́ yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ọmọdékùnrin ọmọ ọdún mẹ́fà sí mẹ́tàlá ni wọ́n máa ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ inú sínágọ́gù