“Ìjọba Rẹ Yóò sì Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Dájúdájú”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ìjọba Rẹ Yóò sì Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Dájúdájú”
NÍNÚ ìtàn ìran èèyàn, ọ̀pọ̀ alákòóso ni wọ́n ti yọ nípò. Wọ́n ti fìbò gbé àwọn kan kúrò nípò, àwọn míì sì rèé, tìpá tìkúùkù ni wọ́n fi lé wọn dà nù. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run ńkọ́? Ǹjẹ́ nǹkan kan lè dí i lọ́wọ́ kó má ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run yàn? A lè rí ìdáhùn náà nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ bó ṣe wà nínú 2 Sámúẹ́lì orí 7.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yẹn, a rí i níbẹ̀ pé ojú ti Dáfídì pé òun èèyàn lásánlàsàn ń gbé ní ààfin tó rẹwà, nígbà tí àpótí Ọlọ́run wà nínú àgọ́ kẹ́jẹ́bú kan. a Dáfídì sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ pé òun fẹ́ kọ́ ilé tó bójú mu, tàbí tẹ́ńpìlì fún Jèhófà. (Ẹsẹ 2) Àmọ́ Dáfídì kọ́ ló máa kọ́ ilé náà. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Nátánì sọ fún Dáfídì pé ọmọkùnrin rẹ̀ kan ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà.—Ẹsẹ 4, 5, 12, 13.
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó wà lọ́kàn Dáfídì yìí. Nítorí ìfọkànsìn Dáfídì àti àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run bá a dá májẹ̀mú pé òun á gbé ẹnì kan dìde nínú ìdílé Dáfídì ọba tí yóò ṣàkóso títí láé. Nátánì sọ ìlérí Ọlọ́run fún Dáfídì pé: “Ilé rẹ àti ìjọba rẹ yóò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dájúdájú fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ pàápàá yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Ẹsẹ 16) Ta ni Ajogún májẹ̀mú yìí tó máa wà títí lọ, tá máa ṣàkóso títí láé?—Sáàmù 89:20, 29, 34-36.
Àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Jésù ará Násárétì. Nígbà tí áńgẹ́lì kan ń kéde ìbí Jésù, ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Nítorí náà, Jésù Kristi ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá ṣẹ sí lára. Kì í ṣe èèyàn ló yàn án sípò láti ṣàkóso, àmọ́ ó ń ṣàkóso nípasẹ̀ ìlérí Ọlọ́run, èyí tó fún un lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso títí láé. Ká má gbàgbé pé ìlérí Ọlọ́run máa ń ṣẹ nígbà gbogbo.—Aísáyà 55:10, 11.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì kan wà tá a lè rí kọ́ nínú 2 Sámúẹ́lì orí 7. Àkọ́kọ́, a lè nífọ̀kànbalẹ̀ pé kò sóhun kan tàbí ẹnì kan tó lè dí Jésù Kristi lọ́wọ́ pé kó má ṣàkóso. Nítorí náà, ó dá wa lójú pé yóò ṣe ohun tí ìṣàkóso rẹ̀ fẹ́ ṣe, ìyẹn láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run.—Mátíù 6:9, 10.
Èkejì ni pé, àkọsílẹ̀ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan tó wọni lọ́kàn nípa Jèhófà. Rántí pé Jèhófà rí ohun tó wà lọ́kàn Dáfídì, ó sì fojú rere wò ó. Èyí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà mọyì ìjọsìn tá à ń ṣe fún un tọkàntọkàn. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn ipò kan wà tí kì í jẹ́ ká lè ṣe tó bí ọkàn wa ṣe ń fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, irú bí ìlera tó ń jó rẹ̀yìn tàbí ọjọ́ ogbó. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà rí ọkàn wa, ó sì mọ bí ọ̀ràn ìjọsìn rẹ̀ ṣe ń jẹ wá lọ́kàn tó.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àpótí májẹ̀mú jẹ́ àpótí mímọ́ kan tí wọ́n ṣe bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n ṣe é. Àpótí náà ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́.—Ẹ́kísódù 25:22.