“Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”
ÌRÍSÍ òde ara lè tanni jẹ. Ìrísí ẹnì kan lè má fi ohun tó jẹ́ nínú hàn, ìyẹn bí ọkàn rẹ̀ ṣe rí. Àwa èèyàn sábà máa ń fi ìrísí ṣèdájọ́ nǹkan. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run kì í wo ohun tí èèyàn jẹ́ lóde nìkan. Ọ̀rọ̀ tó wà ní 1 Sámúẹ́lì 16:1-12 jẹ́ ká mọ èyí.
Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Jèhófà fẹ́ fòróró yan ọba tuntun fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ó sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé: “Èmi yóò rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí pé mo ti pèsè ọba fún ara mi lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.” (Ẹsẹ 1) Jèhófà kò sọ orúkọ ẹni náà, àmọ́ ó sọ pé ẹni tóun máa yàn náà wà lára àwọn ọmọkùnrin Jésè. Bí Sámúẹ́lì ṣe forí lé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni mo ṣe máa mọ ẹni tí Jèhófà yàn lára àwọn ọmọkùnrin Jésè?’
Nígbà tí Sámúẹ́lì dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó ṣètò fún Jésè àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ lára oúnjẹ ìrúbọ. Nígbà tí Élíábù, èyí tó dàgbà jù, wọlé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ìrísí rẹ̀ jọ Sámúẹ́lì lójú gan-an. Èrò Sámúẹ́lì ni pé ìrísí Élíábù jọ ẹni tó lè di ọba, ó ní: “Dájúdájú, ẹni àmì òróró rẹ̀ wà níwájú Jèhófà.”—Ẹsẹ 6.
Àmọ́ ṣá o, ojú tí Jèhófà fi wo ọ̀ràn náà yàtọ̀. Ó sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́.” (Ẹsẹ 7) Bí Élíábù ṣe ga tó, tó sì rẹwà kò jọ Jèhófà lójú. Ojú Jèhófà tó ń rí ohun gbogbo ti ríran ré kọjá ẹwà òde, ó ríran dé ibi tí ẹwà tòótọ́ wà.
Jèhófà ṣàlàyé fún Sámúẹ́lì pé: “Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan [ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan], nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (Ẹsẹ 7) Bẹ́ẹ̀ ni, ọkàn, ìyẹn ohun téèyàn jẹ́ nínú, ibi tí èrò, ìṣesí àti ìmọ̀lára èèyàn ti ń wá, ló ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. “Olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” kò fọwọ́ sí Élíábù àtàwọn ọmọ Jésè mẹ́fà yòókù tí wọ́n wá síwájú Sámúẹ́lì.—Òwe 17:3.
Jésè ṣì ní ọmọkùnrin kan, ìyẹn Dáfídì, òun ló kéré jù, ó “ń kó àwọn àgùntàn jẹ koríko.” (Ẹsẹ 11) Nítorí náà, wọ́n lọ pe Dáfídì wá látinú pápá, ó sì wá síwájú Sámúẹ́lì. Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Dìde, fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!” (Ẹsẹ 12) Lóòótọ́, Dáfídì jẹ́ “ọ̀dọ́kùnrin kan tí ojú rẹ̀ lẹ́wà, ó sì rẹwà ní ìrísí.” Àmọ́ ọkàn rẹ̀ ló mú kó jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.—1 Sámúẹ́lì 13:14.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tó nífẹ̀ẹ́ ẹwà òde ara gan-an la wà yìí, inú wa dùn láti mọ̀ pé ẹwà òde ara kò jọ Jèhófà Ọlọ́run lójú. Kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀ bóyá o ga tàbí àwọn èèyàn kà ẹ́ sí arẹwà. Ohun tó o jẹ́ nínú, ìyẹn nínú ọkàn rẹ ló ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Ǹjẹ́ ohun tó o mọ̀ yìí mú kó o fẹ́ ní irú àwọn ànímọ́ tó máa mú kó o lẹ́wà lójú Ọlọ́run?