Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Rí—Ìtùnú Gbà Lẹ́yìn Ìpakúpa Tó Wáyé Lọ́gbà Iléèwé Kan

Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Rí—Ìtùnú Gbà Lẹ́yìn Ìpakúpa Tó Wáyé Lọ́gbà Iléèwé Kan

Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Rí—Ìtùnú Gbà Lẹ́yìn Ìpakúpa Tó Wáyé Lọ́gbà Iléèwé Kan

GÀDÀGBÀ GADAGBA ni ìbéèrè náà, “Kí nìdí?” wà níwájú ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Jámánì. Pípa tí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan fi ìbọn pa àwọn èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], tó sì wá pa ara rẹ̀ nílùú Winnenden ní gúúsù Jámánì ló fa ìbéèrè yìí. Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ìdajì òpó ni wọ́n ta àwọn àsíá sí jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, àwọn èèyàn sì gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yìí yíká ayé.

Ìlú tí àwọn èèyàn ti rí towó ṣe ni ìlú Winnenden, ó lẹ́wà, àwọn igi àti ọgbà tó ní òdòdó sì wà káàkiri ìlú náà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, àwọn ọmọ iléèwé Albertville Secondary School ti wọnú kíláàsì wọn ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2009. Lójijì ni nǹkan dàrú, tí ìwà ipá sì bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án ààbọ̀ àárọ̀.

Kí ló fa sábàbí? Ọmọkùnrin kan ló já wọ ọgbà iléèwé tó ti kàwé jáde pẹ̀lú ìbọn kan tó mú nínú yàrá àwọn òbí rẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti yìnbọn pa ọmọ iléèwé mẹ́sàn-án àti olùkọ́ mẹ́ta nínú kíláàsì mẹ́ta àti ní fàráńdà, ó sì tún ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn léṣe. Ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọlọ́pàá dé. Ni apààyàn yìí bá sá lọ sí inú ọgbà ilé ìwòsàn kan tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ tó wà nítòsí iléèwé náà. Ló bá tún pa òṣìṣẹ́ kan tó ń tún nǹkan ṣe nínú ọgbà ilé ìwòsàn náà. Lẹ́yìn náà, ó wọnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, ó sì fìbọn halẹ̀ mọ́ awakọ̀ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rin nǹkan bí ogójì [40] kìlómítà, awakọ̀ náà dọ́gbọ́n sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ náà, ó sì sá lọ. Nínú ọgbà kan tí wọ́n ti ń ta ọkọ̀, apààyàn yìí pa ọ̀kan lára àwọn tó ń ta ọjà níbẹ̀ àti oníbàárà kan, ó tún ṣe àwọn ọlọ́pàá méjì tí wọ́n ń gbìyànjú láti mú un léṣe gan-an. Nígbà tó sì ku díẹ̀ kí àwọn ọlọ́pàá rí i mú, ńṣe ló yìnbọn mọ́ ara rẹ̀ lórí.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn tó mọ apààyàn yìí sọ, wọ́n ní ọ̀dọ́mọkùnrin yìí jẹ́ ẹnì kan tó fẹ́ kí àwọn èèyàn fẹ́ràn òun, ó sì wù ú láti lọ́rẹ̀ẹ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìrẹ̀wẹ̀sì ló dé bá a, tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó máa ń fìbọn oníke ṣeré, ó sì máa ń ṣeré oníwà ipá orí kọ̀ǹpútà tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa. Àwọn kan sọ pé kì í ṣáà ṣe òun nìkan ló ń ṣe irú eré yìí. Tá a bá wá ní ká wo ti àwọn tó pa ńkọ́? Ṣé àwọn kan ni apààyàn yìí ní lọ́kàn láti pa ni àbí ṣe ló kàn yìnbọn sí àwọn tó rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ìdí tó fi jẹ́ pé obìnrin mẹ́jọ àti ọkùnrin kan ṣoṣo ló pa lára àwọn ọmọ iléèwé tó ti kàwé jáde. Kò sẹ́ni tó lè fi ìdánilójú sọ pé ohun tó fà á nìyí.

Ohun Táwọn Èèyàn Ṣe Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Heike rántí pé, “Mi ò gbà gbọ́ nígbà tí ọmọ wa ọkùnrin pè láti iléèwé pé ẹnì kan ń yìnbọn níléèwé àwọn. Àmọ́ ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo gbọ́ bí ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá àti ọkọ̀ áńbúláǹsì tó ń kọjá ṣe ń pọ̀ sí i.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àwọn ọlọ́pàá ṣe tètè dé ibẹ̀ ni kò jẹ́ kí apààyàn yìí pa èèyàn púpọ̀ nínú ọgbà iléèwé náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti kó àwọn ọmọ iléèwé náà síbi tí kò ti séwu, àwọn oníwòsàn, agbaninímọ̀ràn àti àwọn àlùfáà wá síbẹ̀, wọ́n sì fi taratara ṣiṣẹ́ bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn ọmọ iléèwé náà.

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn oníròyìn ti dé sínú ọgbà iléèwé náà, wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọ iléèwé náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ iléèwé yìí lẹ̀rù ṣì ń bà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà ka ọkọ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] tó wá sínú iléèwé náà. Àwọn oníròyìn ń figagbága láàárín ara wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìròyìn tí wọn kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ jáde. Oníròyìn kan tiẹ̀ lọ bá àwọn èèyàn ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́jọ́ tí nǹkan náà ṣẹlẹ̀, ó ní kí wọ́n fún òun ní fọ́tò ọmọbìnrin náà, nígbà tí àwọn oníròyìn míì fún àwọn ọmọ iléèwé kan lówó pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ya fọ́tò wọn. Àwọn oníròyìn náà hára gàgà débi pé, ó ṣòro fún wọn láti gba tàwọn èèyàn rò kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún wọn bí wọ́n ṣe ń wá àwọn ìsọfúnni tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju ti àwọn oníròyìn ẹlẹ́gbẹ́ wọn lọ.

Bó ṣe sábà máa ń rí nírú ipò yìí, ọ̀dọ̀ àwọn onísìn ni àwọn èèyàn yíjú sí kí wọ́n lè rí ìtùnú àti àlàyé lórí ìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ tí ìpakúpa yìí wáyé, gbogbo àwọn onísìn jọ ṣe ààtò ìsìn kan pa pọ̀. Ọ̀pọ̀ ló mọrírì ohun tí wọ́n ṣe yìí. Àmọ́ ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ fún àwọn tó ń wá ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí tí wọ́n ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń dùn wọ́n lọ́kàn. Ìdílé kan lọ sí ibi tí wọ́n ti sìnkú ọmọbìnrin kan tí òun àti ọmọ wọn jọ wà ní kíláàsì. Ìyá ọmọ tó lọ sí ibi ìsìnkú náà sọ pé, “Bíṣọ́ọ̀bù kan sọ̀rọ̀ nípa ìyà tí Jóòbù jẹ. Mo retí pé kó sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìtàn náà tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀, àmọ́ kò sọ nǹkan kan nípa rẹ̀. Kò sọ ohun tó fa ìyà tí Jóòbù jẹ tàbí àbájáde ọ̀rọ̀ náà.”

Ọkùnrin kan bínú gan-an torí ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání tó gbọ́ yẹn. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ni ọkùnrin yìí ti fi kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó pa ẹ̀kọ́ náà tì. Ní báyìí, ó tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé wọn déédéé.

Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìnlá [14] kan tó ń jẹ́ Valisa tó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà nínú kíláàsì kan nítòsí ibi tí ìpakúpa náà ti wáyé. Nígbà tó gbọ́ ìró ìbọn, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tí wọ́n bi í nípa bó ṣe ń fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, ó sọ pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà fìdí ohun tí òun ti kọ́ nínú Bíbélì múlẹ̀ nípa àkókò òpin tó nira láti bá lò. (2 Tímótì 3:1-5) Lákòókò yìí, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan dí bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn aládùúgbò wọn. Àgbàlagbà obìnrin kan sọ fún wọn pé, “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló yẹ kó máa ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe yìí.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́tí sí ìrètí àti ìtùnú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí bí ìbànújẹ́ àti ìbẹ̀rù tí ìpakúpa náà fà ṣe pọ̀ tó.

Ìbànújẹ́ Tó Gbẹ̀yìn Ìpakúpa Náà

Ó dájú pé kò sí bí ọ̀rọ̀ ìtùnú náà ṣe tọkàn wá tó tó máa lè mú gbogbo ìbànújẹ́ àti àìnírètí àwọn tí àjálù yìí dé bá kúrò. Kò sí ọ̀rọ̀ tó lè mú ẹ̀dùn ọkàn òbí tó pàdánù ọmọ rẹ̀ tàbí ti ìbànújẹ́ tó dé bá ọlọ́pàá tí ìyàwó rẹ̀ kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kúrò pátápátá.

Onírúurú ọ̀nà ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gbà kó ìpayà bá àwọn ọmọ iléèwé tó la ìpakúpa yìí já àti àwọn èèyàn wọn. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Vassilios gba ojú fèrèsé jáde ní gbàrà tí apààyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn. Ó ní: “Nígbà tí mo gba ojú fèrèsé jáde, mo gbàdúrà sí Jèhófà. Mo ronú pé mo máa kú. Ṣe ni mo rò pé àdúrà tí mo máa gbà kẹ́yìn nìyẹn.” Láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó máa ń lá àlá tó máa ń bà á lẹ́rù lóru, kò sì fẹ́ bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ mọ́. Inú bí i gan-an fún bí àwọn oníròyìn ṣe ń figagbága láti gbé ìròyìn jáde àti bí àwọn tí wọ́n ń wá kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ṣe gba tàwọn èèyàn rò. Nígbà tó yá, ó gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ó sì ń bá ìgbésí ayé rẹ̀ nìṣó.

Inú kíláàsì kan náà ni Jonas àti Vassilios wà, ojú Jonas sì ni apààyàn náà ti pa márùn-ún nínú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Ó ní: “Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kò ṣòro fún mi láti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ rárá, ńṣe ló dà bí fídíò oníwà ipá. Àmọ́ ní báyìí, ó ṣòro fún mi láti sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi. Mi ò mọ bó ṣe máa ń ṣe mí, torí nígbà míì, kì í wù mí láti sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, nígbà míì sì rèé, mo máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa rẹ̀.” Òun náà máa ń lá àlá tó ń bani lẹ́rù, kì í sì í lè sùn dáadáa.

Lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n fún àwọn ọmọ iléèwé náà ní àwọn ẹrù wọn tó wà nínú kíláàsì náà. Àwọn oníṣègùn tó ń tọ́jú àwọn tó fara pa kìlọ̀ pé, tí àwọn ọmọ yìí bá ń rí àwọn ẹrù wọ̀nyí, ó lè mú kí wọ́n máa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Jonas kò kọ́kọ́ fẹ́ fọwọ́ kan ẹ̀wù, báàgì iléèwé rẹ̀ àti akoto tó máa ń dé lórí alùpùpù. Ẹ̀rù tún máa ń bà á nígbàkigbà tó bá rí ẹni tó jọ apààyàn náà tàbí tó bá rí ẹni tó gbé irú báàgì tó jọ ti apààyàn náà. Tí àwọn òbí rẹ̀ bá ń wo fídíò, tí wọ́n bá sì yìnbọn nínú fídíò náà, ṣe ni àyà rẹ̀ máa ń já. Àwọn oníṣègùn gbìyànjú láti ran àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbàgbé rẹ̀ kó máa sì máa da ọpọlọ wọn láàmù.

Inú ilé ìwòsàn tí apààyàn náà ti pa òṣìṣẹ́ kan ni Jürgen baba Jonas ti ń ṣiṣẹ́. Ó sọ pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn òbí àti àwọn tí àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé kí nìdí tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀? Wọ́n sì tún ń ronú pé tó bá jẹ́ àwọn ni apààyàn náà yìnbọn fún ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tó rí apààyàn náà láti orí òkè ilé bẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe kí apààyàn náà ti yìnbọn fún òun, èrò yìí sì dà á lọ́kàn rú débi pé ó di dandan kó lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn àwọn alárùn ọpọlọ.

Bí Àwọn Kan Ṣe Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

Kí ló ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tó le koko yìí? Jürgen sọ pé: “Lóòótọ́, kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn, àmọ́ ó máa ń dáa kí èèyàn wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Ọkàn èèyàn máa ń balẹ̀ tí èèyàn bá kíyè sí pé, àwọn ẹlòmíì bìkítà nípa òun àti pé òun kò dá nìkan wà.”

Inú Jonas náà dùn pé àwọn èèyàn bìkítà, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ló fi káàdì ìkíni ránṣẹ́, wọ́n sì tún fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù. Mo sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí àwọn kan kọ ránṣẹ́. Èyí dára gan-an ni.” Kí ló tún ràn án lọ́wọ́? Ó ní: “Tí mo bá jí lóru, tí gbogbo nǹkan sì tojú sú mi, mo máa ń gbàdúrà. Nígbà míì, mo máa ń tẹ́tí sí orin tàbí ìwé ìròyìn Jí! tí wọ́n ti kà sórí àwo CD.” a Ó sọ síwájú sí i pé Bíbélì ti jẹ́ ká mọ ìdí tí gbogbo nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé: Sátánì ló ń ṣàkóso gbogbo ayé àti pé àkókò òpin là ń gbé. Baba Jonas sọ pé àwọn nǹkan tí àwọn mọ̀ yìí ló ran àwọn lọ́wọ́ láti fara dà á.

Ìjìyà Máa Tó Dópin

Láàárín ọjọ́ mélòó kan, ńṣe ni àbẹ́là, òdòdó àti lẹ́tà kún ibì kan ní iwájú iléèwé náà. Kerstin kíyè sí pé àwọn èèyàn kọ ìwé lóríṣiríṣi tí wọ́n fi ń béèrè pé, ‘Kí nìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ àti pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á?’ Ó rí i pé ó yẹ kí ìdáhùn wà fún àwọn ìbéèrè náà, torí náà òun àti Ẹlẹ́rìí méjì míì kọ lẹ́tà kan, wọ́n sì fi sí àárín àwọn ìwé tó wà níbẹ̀.

Nígbà tí wọ́n ń ṣe ààtò ìsìnkú fún àwọn tó kú náà, ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan ṣàfihàn lẹ́tà tí Kerstin kọ, wọ́n sì fa ọ̀rọ̀ tó wà nílà àkọ́kọ́ níbẹ̀ yọ pé: “Kí nìdí? Ní àkókò òpin yìí, àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ìbéèrè yìí lọ́pọ̀ ìgbà, èyí tí wọ́n tiẹ̀ máa ń béèrè jù ni: Ibo ni Ọlọ́run wà? Kì sì nìdí tó fi fàyè gba èyí?” Ó ṣeni láàánú pé ìwọ̀nba ohun tí wọ́n fà yọ nínú ọ̀rọ̀ náà nìyí.

Kí nìdí tó fi ṣeni láàánú? Ìdí ni pé lẹ́tà náà ń bá a nìṣó láti ṣàlàyé ohun tó jẹ́ orísun gbogbo ìwà ibi àti pé Ọlọ́run “máa rí sí i pé gbogbo nǹkan búburú tí èèyàn ti fà kásẹ̀ nílẹ̀.” Ó tún ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Ọlọ́run sọ nínú ìwé tó gbẹ̀yìn Bíbélì pé òun máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn, ikú kò ní sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Jèhófà Ọlọ́run tún máa jí àwọn òkú dìde. Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó máa tó dé, kò ní sí àjálù, ìpakúpa tàbí ìrora mọ́. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń ṣe ìwé ìròyìn Jí! sórí ìwé àti sórí àwo CD.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jonas gba káàdì ìkíni kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ yìí sí pé, “À ń ronú nípa rẹ”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Focus Agency/WPN

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

© imagebroker/Alamy

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwòrán: picture alliance

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwòrán: picture alliance