Ṣé Lóòótọ́ Ni Àwọn Amòye Mẹ́ta Lọ Wo Jésù Nígbà Tó Wà Ní Ọmọ Ọwọ́?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Ṣé Lóòótọ́ Ni Àwọn Amòye Mẹ́ta Lọ Wo Jésù Nígbà Tó Wà Ní Ọmọ Ọwọ́?
Lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe Kérésìmesì ní Amẹ́ríkà ti gúúsù àti ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù títí lọ dé Ilẹ̀ Éṣíà, wọ́n sábà máa ń ya àwòrán ìbí Jésù ní ibùjẹran pẹ̀lú àwọn ọba tàbí amòye mẹ́ta tí wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn iyebíye wá fún Jésù tó jẹ́ ọmọ ọwọ́. Ṣé òótọ́ ni ìtàn yìí? Ǹjẹ́ ó bá àwọn òkodoro òtítọ́ mu? Jẹ́ ká wò ó ná.
Méjì nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn Mátíù àti Lúùkù sọ ìtàn nípa ìbí Jésù. Àwọn ìtàn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ láti àwọn pápá oko tó wà nítòsí nìkan ló wá wo Jésù nígbà tí wọ́n bí i. Awòràwọ̀ ni àwọn ọkùnrin tí àwọn èèyàn ń pè ní ọba tàbí àwọn amòye yìí, Bíbélì kò sì sọ iye wọn. Àwọn awòràwọ̀ yìí kò lọ sọ́dọ̀ Jésù nígbà tó wà ní ọmọ ọwọ́ ní ibùjẹran, àmọ́ ìgbà tí Jésù ti kúrò ní ọmọ ọwọ́, tó sì ti ń gbé ní ilé ni wọ́n wá wò ó. Wíwá wọn tiẹ̀ fi ìwàláàyè Jésù sínú ewu pàápàá!
Tó o bá fara balẹ̀ ka ìtàn tí Lúùkù kọ sínú Bíbélì nípa bí wọ́n ṣe bí Jésù, wàá rí i pé: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú . . . ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru. Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, . . . áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: . . . ‘Ẹ óò rí ọmọdé jòjòló kan tí a fi àwọn ọ̀já wé, ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran‘ . . . Wọ́n sì lọ pẹ̀lú ìṣekánkán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọdé jòjòló tí ó wà ní ìdùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”—Lúùkù 2:8-16.
Jósẹ́fù, Màríà àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn nìkan ni wọ́n wà lọ́dọ̀ Jésù nígbà tó wà ní ọmọ ọwọ́. Àkọsílẹ̀ Lúùkù kò mẹ́nu ba ẹlòmíì.
Wàyí o, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Mátíù 2:1-11 nínú Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀: ‘Nígbà tí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ilẹ̀ Jùdíà, ní ayé ọba Hẹ́rọ́dù, àwọn amòye kan wá láti ilẹ̀ ìlà-oòrùn sí Jerúsálẹ́mù . . . Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹ̀lú Màríà ìyà rẹ̀.’
Kíyè sí pé ‘àwọn amòye’ ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu bà, kì í ṣe ‘àwọn amòye mẹ́ta,’ wọ́n sì ti kọ́kọ́ rìnrìn àjò láti ìlà oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù, kì í ṣe wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú tí wọ́n ti bí Jésù. Nígbà tí wọ́n fi máa dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Jésù ti kúrò ní ọmọ ọwọ́, ó ti di ‘ọmọ’ kékeré, kò sì sí ní ilé ẹran mọ́, àmọ́ ó wà nínú ilé tí àwọn èèyàn ń gbé.
Yàtọ̀ sí ‘àwọn amòye’ tí Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀ pe àwọn àlejò yìí, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pè wọ́n ní “pidánpidán” tàbí “awòràwọ̀.” Ìwé A Handbook on the Gospel of Matthew sọ pé, gbólóhùn náà “àwọn amòye” jẹ́ ìtumọ̀ “ọ̀rọ̀ orúkọ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún àwọn àlùfáà ilẹ̀ Páṣíà tí wọ́n jẹ́ ògbóǹkangí awòràwọ̀.” Ìwé atúmọ̀ èdè The Expanded Vine’s Expository Dictionary of New Testament Words sì túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “àjẹ́, oṣó, pidánpidán, ògbóǹkangí nínú iṣẹ́ òkùnkùn.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ṣì ń wo ìràwọ̀ tí wọ́n sì máa ń lọ́wọ́ nínú onírúurú iṣẹ́ òkùnkùn lóde òní, Bíbélì kìlọ̀ lòdì sí i. (Aísáyà 47:13-15) Wọ́n wà lára oríṣi ìbẹ́mìílò àti àṣà tí Jèhófà Ọlọ́run kórìíra. (Diutarónómì 18:10-12) Ìdí nìyẹn tí àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run kò fi kéde ìbí Jésù fún àwọn awòràwọ̀. Àmọ́, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn lójú àlá pé kí wọ́n má ṣe pa dà lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù tó jẹ́ Ọba búburú, torí pé ó fẹ́ láti pa Jésù. Torí náà, “wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀ gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ilẹ̀ wọn.”—Mátíù 2:11-16.
Ṣé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa fẹ́ láti tan ìtàn èké tí kò jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òótọ́ nípa ìbí Jésù kálẹ̀? Ó dájú pé wọn kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.