Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?

Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?

Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?

ÈDÈ Hébérù àti Gíríìkì ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé inú Bíbélì. a Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló darí àwọn oǹkọ̀wé tí wọ́n fi àwọn èdè yìí kọ ọ́. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Torí náà, a lè sọ pé ọ̀rọ̀ tí “Ọlọ́run mí sí” ni wọ́n kọ.—2 Tímótì 3:16, 17.

Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń ka Bíbélì lónìí kò lè ka èdè Hébérù tàbí èdè Gíríìkì. Àfi kí wọ́n ka Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè wọn. Bóyá ohun tí ìwọ náà ní láti ṣe nìyẹn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run kò mí sí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì, o lè máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo lè lóye tó kún nípa Bíbélì, tí mo bá ka Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ àbí ó pọn dandan kí n kọ́ èdè Hébérù àti Gíríìkì?’

Àwọn Ohun Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn

Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ kó o fi àwọn nǹkan kan sọ́kàn. Lákọ̀ọ́kọ́, pé èèyàn kan mọ èdè Hébérù tàbí Gíríìkì ìgbàanì kò sọ pé onítọ̀hún máa lóye ohun tó wà nínú Bíbélì lọ́nà ìyanu. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ̀nyí gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nípa mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ní ìyè.” (Jòhánù 5:39, 40) Kí ni ìṣòro wọn? Ṣé torí pé wọn kò lóye èdè Hébérù ni? Rárá o, wọ́n mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ èdè náà. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Èmi mọ̀ dunjú pé ẹ kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú yín.”—Jòhánù 5:42.

Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó ń sọ èdè Gíríìkì nílùú Kọ́ríńtì ìgbàanì pé: “Àwọn Júù ń béèrè àmì, àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n; ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi tí a kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 1:22, 23) Ó ṣe kedere nígbà náà pé kì í kàn án ṣe sísọ èdè Hébérù tàbí èdè Gíríìkì ló máa mú kí ẹnì kan lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Kókó kejì ni pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń sọ èdè Hébérù tàbí Gíríìkì òde òní, èdè Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n ń sọ báyìí yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì lónìí ló ṣòro fún láti lóye èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ìdí sì ni pé, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti fi kún èdè náà, wọ́n ti yí àwọn ọ̀rọ̀ kan pa dà, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó sì wà títí dòní nínú àwọn èdè náà ló ti ní ìtumọ̀ míì. Bí àpẹẹrẹ, nínú èdè Gíríìkì òde òní, “nǹkan tó ń pani lẹ́rìn-ín” ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ẹwà” nínú ìwé Ìṣe 7:20 àti Hébérù 11:23 túmọ̀ sí. Yàtọ̀ síyẹn, àtúnṣe kékeré kọ́ ni wọ́n ti ṣe sí gírámà àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣètò ọ̀rọ̀ nínú àwọn èdè yìí.

Ká tiẹ̀ wá sọ pé o fẹ́ kọ́ èdè Hébérù tàbí èdè Gíríìkì tí wọ́n ń sọ lóde òní, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wàá lóye tó kún rẹ́rẹ́ tó o bá ka Bíbélì ní èdè Hébérù àti Gíríìkì àtijọ́. Síbẹ̀ náà, wàá ṣì nílò àwọn ìwé atúmọ̀ èdè àti àwọn ìwé tó ṣàlàyé gírámà láti rí bí wọ́n ṣe lo àwọn èdè yìí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ Bíbélì.

Kókó kẹta ni pé kò rọrùn láti kọ́ èdè míì. Lóòótọ́, ó lè kọ́kọ́ dà bíi pé ó rọrùn láti kọ́ bí èèyàn ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ṣókíṣókí ní èdè míì, àmọ́ ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára kí èèyàn tó lè lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ èdè náà. Ààbọ̀ ẹ̀kọ́ sì léwu, gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn ṣe máa ń sọ. Lọ́nà wo?

Kí Ni Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Náà?

Ǹjẹ́ ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè rẹ ti béèrè ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan lọ́wọ́ rẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti dáhùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ kan lè ní onírúurú ìtumọ̀. Ó lè jẹ́ pé ohun tó o máa sọ fún ẹni náà ni pé kó lo ọ̀rọ̀ náà nínú gbólóhùn kan. Torí pé tí kò bá sí àpẹẹrẹ, ó lè ṣòro fún ẹ láti mọ èyí tó máa bá àyíká ọ̀rọ̀ kan mu nínú oríṣiríṣi ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà ní. Nínú èdè Yorùbá, ọ̀rọ̀ náà “ogún” lè ní oríṣi ìtumọ̀ méjì. Bí àpẹẹrẹ, ó lè túmọ̀ sí òǹkà [20], nínú àyíká ọ̀rọ̀ míì sì rèé, ó lè túmọ̀ sí dúkìá tí òbí fi sílẹ̀ fún ọmọ. Torí náà, ó lè má rọrùn láti mọ ohun tó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà gan-an.

Ìwé atúmọ̀ èdè lè sọ gbogbo ìtumọ̀ tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ kan ní. Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè kan tiẹ̀ máa ń sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń lò ó lójoojúmọ́. Àmọ́ àyíká ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ti lo ọ̀rọ̀ kan ló máa jẹ́ kó o mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí. Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé o ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa iṣẹ́ ìṣègùn, o sì fẹ́ mọ ohun tó fà á tí ara rẹ fi ń ṣe bákan-bákan. Ó ṣeé ṣe kó o ka ìwé atúmọ̀ èdè tó dá lórí ìmọ̀ ìṣègùn. Ìwé náà lè jẹ́ kó o mọ̀ pé tírú nǹkan báyìí bá ń ṣe ẹ́, ó dájú pé oríṣi àìsàn kan ló fà á, ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ oríṣi àìsàn míì. Torí náà, ó béèrè pé kó o wádìí dáadáa kó o tó lè mọ ohun tó ń ṣe ẹ́ gan-an. Bákan náà, torí pé ọ̀rọ̀ kan sábà máa ń ní ìtumọ̀ kan kò túmọ̀ sí pé ìtumọ̀ yìí náà ló máa ní níbòmíì. Torí náà, o gbọ́dọ̀ lóye àyíká ọ̀rọ̀ dáadáa kó o tó lè mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀.

Tó o bá ń ṣèwádìí nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì, ó tún ṣe pàtàkì pé kó o lóye inú àwọn àyíká ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sábà máa ń tú sí “ẹ̀mí” lè ní onírúurú ìtumọ̀, ìyẹn sinmi lórí àyíká ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti lò ó. Nígbà míì, ó lè túmọ̀ sí “ẹ̀fúùfù.” (Ẹ́kísódù 10:13; Jòhánù 3:8) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ míì sì rèé, ó lè túmọ̀ sí ohun tó gbé ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn àti ẹranko ró. (Jẹ́nẹ́sísì 7:22; Sáàmù 104:29; Jákọ́bù 2:26) Bíbélì tún ṣàlàyé àwọn ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí. (1 Àwọn Ọba 22:21, 22; Mátíù 8:16) Bíbélì tún pe ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ní ẹ̀mí mímọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Mátíù 12:28) Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni Bíbélì tún lò láti ṣàlàyé ohun tó ń jẹ́ kí èèyàn ní oríṣi ìwà kan, ìrònú kan tàbí oríṣi ìmọ̀lára kan títí kan bí nǹkan ṣe sábà máa ń rí lára àwọn èèyàn.—Jóṣúà 2:11; Gálátíà 6:18.

Lóòótọ́, ìwé atúmọ̀ èdè Hébérù tàbí ti Gíríìkì lè sọ onírúurú ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ kan ní, àmọ́ àyíká ọ̀rọ̀ ló máa jẹ́ kó o mọ èyí tó tọ́ nínú onírúurú ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà ní. b Bó bá jẹ́ Bíbélì tí wọ́n fi èdè Hébérù àti Gíríìkì àtijọ́ kọ lò ń kà tàbí èyí tí wọ́n túmọ̀, ohun kan tó dájú ni pé àyíká ọ̀rọ̀ ló máa jẹ́ kó o lóye ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan pàtó.

Ṣó Burú Kí Èèyàn Lo Bíbélì Tí Wọ́n Tú?

Àwọn kan ti sapá gan-an láti kọ́ èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì tàbí kí wọ́n kọ́ ọ̀kan nínú méjèèjì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà mọ̀ pé ó níbi tí òye àwọ́n mọ, wọ́n láyọ̀ pé àwọn lè ka Bíbélì ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ ọ́, wọ́n sì nímọ̀lára pé ìsapá tí àwọn ṣe tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ṣé ó yẹ kó o juwọ́ sílẹ̀, kó o sì pa kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì tì nítorí pé o kò lè kọ́ àwọn èdè yìí? Rárá o! Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú ká sọ bẹ́ẹ̀.

Àkọ́kọ́ ni pé, kò sí ohun tó burú láti lo Bíbélì tí wọ́n túmọ̀. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun lo ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì nígbà tí wọ́n bá ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. c (Sáàmù 40:6; Hébérù 10:5, 6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Hébérù ni wọ́n ń sọ, tí wọ́n sì lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n fi èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti lo àwọn ẹsẹ tí wọ́n ti tú sí èdè Gíríìkì, tí àwọn tí wọ́n ń kọ̀wé sí mọ̀ dáadáa.—Jẹ́nẹ́sísì 12:3; Gálátíà 3:8.

Ìkejì, ká tiẹ̀ wá sọ pé ẹnì kan lóye àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n ti tú lẹni náà lè rí kà. Ìdí ni pé, èdè Gíríìkì ni àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere fi ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní èdè Hébérù. d Torí náà, tẹ́nì kan bá rò pé kíkà tí òun lè ka ọ̀rọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé àtijọ́ kọ lédè tí wọ́n fi kọ ọ́ ló jẹ́ kí òun ní òye kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kí ló wá máa ṣe sí ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n ti tú yìí? Òtítọ́ náà pé Jèhófà rí sí i pé kò sí nǹkan kan tó ṣe ọ̀rọ̀ Ìránṣẹ́ rẹ̀ atóbilọ́lá tí wọ́n tú sí èdè míì, ìyẹn èdè tí àwọn èèyàn lóye níbi gbogbo nígbà yẹn, jẹ́ ẹ̀rí pé èdè tá a fi ń ka Bíbélì kọ́ ló ṣe pàtàkì. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká ka ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú rẹ̀ ní èdè tá a lóye, tá a sì máa lè fi sílò.

Ẹ̀kẹta ni pé, “ìhìn rere” tó wà nínú Bíbélì gbọ́dọ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6; Lúùkù 10:21; 1 Kọ́ríńtì 1:27-29) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe látinú Bíbélì tí wọ́n ti tú sí èdè wọn, tí wọn ò sì ní láti lọ kọ́ èdè míì. Nínú ọ̀pọ̀ èdè, oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì ló wà, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa wá yan èyí tóun máa kà. e

Báwo lo ṣe lè rí i pé o lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ọ̀nà tó dára jù láti gbà lóye àwọn ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni láti mú àkòrí kan nínú Bíbélì, kí èèyàn sì gbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń mú àkòrí kan, irú bí “Ìgbéyàwó,” wọ́n sì máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa àkòrí yìí. Lọ́nà yìí, wọ́n máa ń jẹ́ kí apá kan Bíbélì ṣàlàyé ohun tí apá míì túmọ̀ sí. O ò ṣe yọ̀ǹda kí wọ́n wá máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìwọ náà nínú ilé rẹ lọ́fẹ̀ẹ́. Èdè yòówù kó o máa sọ, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4; Ìṣípayá 7:9.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ àwọn apá kan Bíbélì, èdè yìí sì jọra pẹ̀lú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Àpẹẹrẹ àwọn apá tí wọ́n fi èdè Árámáíkì kọ ni ìwé Ẹ́sírà 4:8 sí 6:18 àti 7:12-26, Jeremáyà 10:11 àti Dáníẹ́lì 2:4b sí 7:28.

b Ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé dípò tí àwọn kan lára àwọn ìwé atúmọ̀ èdè àti àwọn ìwé tó túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì á fi máa sọ ohun tí ọ̀rọ̀ kan wulẹ̀ túmọ̀ sí, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ ìtumọ̀ tí Bíbélì kan pàtó, irú bíi King James Version, bá lò fún ọ̀rọ̀ náà.

c Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Jésù Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló ti wà lédè Gíríìkì. Ìtumọ̀ yìí ni wọ́n sì ń pè ní Septuagint, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì sì lò ó dáadáa. Inú ìtumọ̀ Septuagint ni wọ́n ti mú ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n fà yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

d Ọ̀pọ̀ ló gbà pé, èdè Hébérù ni àpọ́sítélì Mátíù kọ́kọ́ fi kọ ìwé Ìhìn Rere rẹ̀. Ká tiẹ̀ wá sọ pé bó ṣe rí náà nìyẹn, ẹ̀dà tí wọ́n ti tú sí èdè Gíríìkì ló ṣì wà títí di òní, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Mátíù fúnra rẹ̀ náà ló tú u.

e Fún àlàyé síwájú sí i lórí onírúurú ìtumọ̀ tó wà àti bó o ṣe lè yan ìtumọ̀ Bíbélì tó péye, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí ti May 1, 2008.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìtumọ̀ Septuagint

Àwọn Júù tí wọ́n ń sọ èdè Gíríìkì ní àkókò tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì wà láyé lo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì gan-an ni. Bíbélì yìí ni wọ́n ń pè ní ìtumọ̀ Septuagint. Yàtọ̀ sí pé ìtumọ̀ Septuagint ni Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tú sí èdè míì, ohun míì tó tún gbàfiyèsí nípa rẹ̀ ni àkókò tó gbà kí wọ́n tó ṣètumọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí tán. Ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àwọn atúmọ̀ èdè kan bẹ̀rẹ̀ ìtumọ̀ Septuagint, àwọn míì ló sì parí ìtumọ̀ náà ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà.

Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni lo ìtumọ̀ Septuagint dáadáa láti ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn pé Jésù ni Kristi, ìyẹn Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Wọ́n lo ìtumọ̀ yìí gan-an débi pé àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìtumọ̀ Septuagint gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn “Kristẹni.” Bí ìtumọ̀ yìí kò ṣe gbayì lọ́dọ̀ àwọn Júù mọ́ nìyẹn, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe onírúurú ìtumọ̀ èdè Gíríìkì. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Aquila, tó ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù, náà ṣe ọ̀kan lára àwọn ìtumọ̀ yìí ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bíbélì kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìtumọ̀ yìí, ó ní, “nǹkan kan tí èèyàn kò retí wà nínú rẹ̀.” Nínú ìtumọ̀ èdè Gíríìkì tí Aquila ṣe, gbogbo ibi tí Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà, ló fi sí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní èdè Hébérù.

[Credit Line]

Israel Antiquities Authority

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ó ṣe pàtàkì pé ká ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí ní èdè tá a lóye tá a máa lè fi sílò