Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
Kí ló ran ọkùnrin kan tó ń mugbó àti sìgá látìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti fàwọn àṣàkaṣà wọ̀nyí sílẹ̀? Kí ló ran ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ọmọọ̀ta lọ́wọ́ láti kápá ìbínú ẹ̀ kó sì mú ìkórìíra kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kúrò lọ́kàn rẹ̀? Jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn èèyàn náà ní ín sọ.
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ
ORÚKỌ: HEINRICH MAAR
ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MÉJÌDÍNLÓGÓJÌ
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: KAZAKHSTAN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO MÁA Ń MUGBÓ ÀTI SÌGÁ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Gúúsù orílẹ̀-èdè Kazakhstan, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́fà [120] kìlómítà sílùú Tashkent, ni wọ́n ti bí mi. Ibẹ̀ máa ń gbẹ fúrúfúrú, ó sì máa ń gbóná gan-an nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, òtútù ibẹ̀ sì máa ń légbá kan nígbà òtútù, ìyẹn jẹ́ kó rọrùn gan-an láti máa gbin èso àjàrà àti igbó táwọn èèyàn máa ń mu.
Ọmọ ìlú Jámánì làwọn òbí mi. Ajíhìnrere làwọn méjèèjì, àmọ́ wọn kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Síbẹ̀, wọ́n kọ́ mi láti máa ka Àdúrà Olúwa lórí. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, màmá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúngbà díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọjọ́ kan wà tóhun táwọn Ẹlẹ́rìí méjì tó ń kọ́ màmá mi lẹ́kọ̀ọ́ ń sọ ta sí mi létí, wọ́n fi Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run han màmá mi nínú ògbólógbòó Bíbélì tí màmá mi ń lò. Ìyẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Màmá mi dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn dúró, èmi náà ò sì sapá láti mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn tí tíṣà wa níléèwé fi ń sọ àwọn ìtàn èké kan nípa àwọn onísìn tàwọn èèyàn mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí pé mo ti tẹ̀ lé àǹtí mi lọ sáwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà kan rí, mo sọ fún tíṣà wa pé àwọn nǹkan tó ń sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn kì í ṣòótọ́.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], àwọn òbí mi ní kí n lọ kọ́ṣẹ́ ọwọ́ nílùú Leningrad, tí wọ́n ń pè ní St. Petersburg báyìí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Mo máa ń sọ ìwọ̀nba ohun tí mo mọ̀ nípa Jèhófà fáwọn tá a jọ ń gbé nínú yàrá kan náà. Àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Nígbà tí mo bá lọ sílé wa nílùú Kazakhstan, ó máa ń rọrùn fún mi gan-an láti ra igbó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò bófin mu. Mo tún máa ń mu ọtí ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí wọ́n ń pè ní vodka àtàwọn ọtí ìbílẹ̀ míì lámujù.
Nígbà tí mo kọ́ṣẹ́ ọwọ́ tán, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Soviet fún ọdún méjì. Síbẹ̀, mi ò gbàgbé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí mo ti kọ́ látinú Bíbélì látìgbà tí mo ti wà ní kékeré. Láwọn ìgbà
tó bá ṣeé ṣe, mo máa ń bá àwọn sójà ẹlẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, mo sì máa ń gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbàkigbà tí n bá gbọ́ táwọn èèyàn ń parọ́ mọ́ wọn.Nígbà tí mo kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, mo lọ sórílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tí mo wà níbi táwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìlú míì máa ń wà, mo gba ẹ̀dà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Mo fi tọkàntọkàn kà á, mo sì wá mọ̀ pé òótọ́ lohun tó wà ńbẹ̀. Àmọ́, kò rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú sìgá àti igbó mímu tó ti di bárakú fún mi. Nígbà tó yá, mo kó lọ sí tòsí ìlú Karlsruhe. Mo bá Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pàdé níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti máa ń ronú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Lẹ́yìn tí mo wá ka ẹ̀dà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo gbà yẹn, ó wá dá mi lójú pé Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè pàtàkì téèyàn lè ní nígbèésí ayé. Síbẹ̀ ó ṣì gbà mí lákòókò tó pọ̀ kí n tó lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti mọ́ mi lára yẹn. Nígbà tó yá, ìmọ̀ràn inú ìwé 2 Kọ́ríńtì 7:1 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo sì pinnu pé màá wẹ ara mi mọ́ kúrò nínú “gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí,” ìyẹn sì túmọ̀ sí pé mo ní láti jáwọ́ sìgá àti igbó mímu.
Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn tí mo fi jáwọ́ nínú igbó mímu. Àmọ́ ó ṣì tó oṣù mẹ́fà gbáko lẹ́yìn ìgbà náà, kí n tó bọ́ lọ́wọ́ sìgá mímu. Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Kí lo fẹ́ fi ìgbésí ayé ẹ ṣe gan-an?” Ìbéèrè yẹn jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí sìgá mímu tí mo ti sọ di bárakú yìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti gbìyànjú láti jáwọ́ nínú ẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mo pinnu pé ṣe ni màá máa gbàdúrà kí n tó mu sìgá dípò kí n máa bẹ Ọlọ́run fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn tí n bá ti mu ún tán. Lọ́dún 1993, mo mú ọjọ́ kan tí mo máa jáwọ́ nínú sìgá mímu. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mi ò fọwọ́ kan sìgá látìgbà yẹn.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ìlera mi ti sunwọ̀n sí i torí pé mo ti jáwọ́ nínú sìgá àti igbó mímu, àkóbá kékeré kọ́ làwọn nǹkan yìí ti ṣe fún mi nígbà tí mo sọ wọ́n di bárakú. Ní báyìí, mo láǹfààní láti yọ̀ǹda ara mi gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì. Inú mi dùn gan-an pé mo kọ́ láti fìmọ̀ràn Bíbélì sílò nígbèésí ayé mi! Mímọ̀ tí mo mohun tí Bíbélì kọ́ni ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀.
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ
ORÚKỌ: TITUS SHANGADI
ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MẸ́TÀLÉLÓGÓJÌ
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: NÀMÍBÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌỌ̀TA
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Abúlé kan lágbègbè Ohangwena ní àríwá orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Nígbà ogun tó jà ní àgbègbè yìí láwọn ọdún 1980, àwọn ọ̀tá lu àwọn ará abúlé wa, wọ́n sì pa wọ́n. Lábúlé wa, ọmọkùnrin tó bá lè jà dáadáa, tó sì lè lu àwọn ọkùnrin míì lálùbolẹ̀ nìkan ni wọ́n kà sí ọkùnrin gidi. Torí náà mo kọ́ béèyàn ṣe lè jà.
Nígbà tí mo parí iléèwé, mo lọ ń gbé lọ́dọ̀ àbúrò màmá mi ní ìlú Swakopmund tó wà ní
etíkun. Kò pẹ́ tí mo débẹ̀ ni mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n máa ń dàgboro rú. A sábà máa ń lọ sáwọn ibi tí wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn dúdú máa wọ̀ nígboro, irú bí òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn ilé ọtí, ká lè lọ dá ìjà sílẹ̀. A máa ń bá àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu ọ̀nà àtàwọn ọlọ́pàá jà nígbà míì. Lálaalẹ́, mo máa ń mú ọ̀bẹ ńlá kan tàbí àdá dání kí n lè fi bá ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbéjà kò mí jà.Díẹ̀ ló kù kí wọ́n pa mí lálẹ́ ọjọ́ kan níbi tá a ti ń jà pẹ̀lú àwọn ọmọ jàǹdùkú míì. Ọ̀kan nínú wọn ti gbé àdá sókè láti fi bẹ́ mi lórí látẹ̀yìn, àmọ́ ẹlòmíì tá a jọ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ kan náà la nǹkan mọ́ ọn, ló bá dá kú. Pẹ̀lú bó ṣe kù díẹ̀ kí n kú yìí, mi ò jáwọ́ nínú ìwà ìpáǹle. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín èmi àtẹnì kan, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, èmi ni mo máa ń kọ́kọ́ gbá onítọ̀hún lẹ́ṣẹ̀ẹ́.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà àkọ́kọ́, tí mo pàdé obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ka àwọn ẹsẹ kan fún mi látinú Sáàmù 37, ó sì wá sọ pé àwọn ìlérí àgbàyanu míì tí Ọlọ́run ṣe wà nínú ìwé Ìṣípayá. Torí pé obìnrin yìí ò sọ ibi táwọn ìlérí wọ̀nyẹn wà nínú ìwé Ìṣípayá, ṣe ni mo ka ìwé Ìṣípayá láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ìlérí tí mo kà nínú ìwé Ìṣípayá 21:3, 4 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni, ó ni: “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí yẹn pa dà wá, mo gbà pé kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kò rọrùn rárá láti yí ìwà àti ìrònú mi pa dà. Àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé Ìṣe 10:34, 35 pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Mo tún sapá gidigidi láti fohun tó wà nínú ìwé Róòmù 12:18 sílò, ó ní: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”
Yàtọ̀ sí pé mo ní láti sapá kí n lè kápá ìbínú, mo tún ní láti jáwọ́ nínú sìgá mímu tó ti di bárakú fún mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bẹ Jèhófà pẹ̀lú omijé lójú pé kó ràn mí lọ́wọ́. Àmọ́ ó ṣe kedere pé ohun tí kò tọ́ lèmi náà ń ṣe, mo sábà máa ń sọ pé mi ò ní mu sìgá míì mọ́ lẹ́yìn èyí tí mò ń mu yìí, màá ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbàdúrà. Ẹlẹ́rìí tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé, ó dáa gan-an láti máa gbàdúrà tí sìgá bá ti ń wù mí mu. Mo tún ní láti jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń mu sìgá. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún gbàmọ̀ràn tó fún mi pé kí n máa bá àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ewu tó wà nínú sìgá mímu. Ìyẹn ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, torí pé kò jẹ́ kí n rí sìgá ọ̀fẹ́ mu mọ́, àwọn tó ń mu sìgá nínú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ kì í ra sìgá fún mi mọ́.
Nígbà tó yá mo jáwọ́ nínú sìgá mímu, mo sì kọ ọ̀nà ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá sílẹ̀ pátápátá. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí mo sì ń fàwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò, mo kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Nígbà tí mo rí bí ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó láìka ẹ̀yà tàbí àwọ̀ wọn sí, ó dá mi lójú pé àwọn ni wọ́n ń ṣe ìsìn tòótọ́. Kódà, kó tó di pé mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹnì kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun nínú ìjọ wa pè mí pé kí n wá jẹun nílé òun. Ṣe ló dà bí àlá lójú mi. Èmi àti aláwọ̀ funfun kankan ò jọ jókòó pa pọ̀ lálàáfíà rí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé ká jọ jẹun nínú ilé wọn. Ní báyìí, mo ti wà lára ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé.
Láwọn ìgbà kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn ọlọ́pàá ti gbìyànjú láti fipá mú mi kí n lè yí ìwà àti ìrònú mi pa dà, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún wọn. Bíbélì nìkan ló jẹ́ kí n lè yíwà mi pa dà kí n sì láyọ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bẹ Jèhófà pẹ̀lú omijé lójú pé kó ràn mí lọ́wọ́”