Kí Ni Ìgbàgbọ́?
Kí Ni Ìgbàgbọ́?
K Í LO máa sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́? Àwọn kan sọ pé téèyàn bá ń gbà láìjanpata pé òótọ́ ni gbogbo nǹkan tóun ń gbọ́, onítọ̀hún ti nígbàgbọ́ nìyẹn. Ọ̀gbẹ́ni H. L. Mencken tó jẹ́ gbajúgbajà oníròyìn àti akéwì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nígbà kan pé, “téèyàn bá ti lè máa gbà láìronú jinlẹ̀ pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó tiẹ̀ le má ṣẹlẹ̀,” onítọ̀hún ti nígbàgbọ́ nìyẹn.
Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé níní ìgbàgbọ́ kì í ṣọ̀rọ̀ gbígbà láìjanpata póòótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tí ò mọ́gbọ́n dání. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.”—Hébérù 11:1.
Ní báyìí tá a ti mọ oríṣiríṣi èrò táwọn èèyàn ní nípa ìgbàgbọ́, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí:
• Kí nìyàtọ̀ láàárín ohun tí Bíbélì pè ní ìgbàgbọ́ àtohun tọ́pọ̀ èèyàn sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nírú ìgbàgbọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
• Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára?
Ìfojúsọ́nà àti Ẹ̀rí Tó Dájú
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé Hébérù tó wà nínú Bíbélì, àwọn èèyàn sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú.” Wọ́n máa ń kọ ọ́ sínú àwọn ìwé àdéhùn ọjà, ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé ẹni tí wọ́n ṣèwé yẹn fún ló ni ọjà tí wọ́n kọ sínú ìwé náà. Ìdí nìyẹn tí ìwé kan fi dábàá pé a tún lè tú àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Hébérù 11:1 báyìí pé: “Ìgbàgbọ́ ni rìsíìtì fún ohun tá à ń retí.”
Tó o bá ti sanwó ọjà fún iléeṣẹ́ kan tó lórúkọ rere rí, tó o sì retí pé kí wọ́n gbé ọjà náà wá lẹ́yìn ìgbà náà, irú ìgbàgbọ́ tó o ní yẹn ni Bíbélì ń sọ. Rìsíìtì tí wọ́n fún ẹ pó o ti sanwó ọjà ló jẹ́ kó o nígbàgbọ́ nínú iléeṣẹ́ tó o sanwó fún pé wọ́n máa kó ọjà ẹ wá. Lọ́rọ̀ kan, rìsíìtì yẹn jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wọ́n máa gbé ọjà tó o sanwó ẹ̀ wá fún ẹ. Tí rìsíìtì yẹn bá sọ nù pẹ́nrẹ́n, ẹ̀rí tó o ní pé ìwọ lo lọjà ló ti sọ nù yẹn. Lọ́nà kan náà, àwọn tó nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ ní ìdánilójú pé ohun táwọn ń retí máa tẹ àwọn lọ́wọ́. Àmọ́, àwọn tí kò nígbàgbọ́ tàbí tó ti sọ ìgbàgbọ́ wọn nù ò lè ráwọn ìlérí Ọlọ́run gbà.—Jákọ́bù 1:5-8.
Gbólóhùn kejì tí ìwé Hébérù 11:1 mẹ́nu bà la tú sí “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà,” ìyẹn sì ní í ṣe pẹ̀lú fífi ẹ̀rí tó dájú hàn pé ọ̀rọ̀ kan ò rí bá a ṣe rò pé ó rí. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá rí bí oòrùn ṣe ń yọ ní ìlà-oòrùn tó sì ń wọ̀ ní ìwọ̀-oòrùn, èèyàn lè ronú pé oòrùn ló ń yí ayé po. Àmọ́, àbájáde ìwádìí táwọn onímọ̀ sánmà àtàwọn onímọ̀ ìṣirò ṣe fẹ̀rí tó dájú hàn pé ayé ló ń yí oòrùn po. Téèyàn bá ti mọ ẹ̀rí yìí dáadáa, tó sì gbà póòótọ́ ni, onítọ̀hún á nígbàgbọ́ pé ayé ló ń yí oòrùn po lóòótọ́, bó tiẹ̀ dà bíi pé oòrùn ló ń yí ayé po. Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ kó yé wa pé níní ìgbàgbọ́ kì í ṣọ̀rọ̀ gbígba ohun tí kò yé wa gbọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ ká lóye bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an.
Báwo Nìgbàgbọ́ Tó Lágbára Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó?
Ìgbàgbọ́ tó lágbára ni Bíbélì rọ̀ wá láti ní, ó sì yẹ ká ní ẹ̀rí tó dájú láti fi ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn, kódà ó lè gba pé ká yí ohun tá a ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ pa dà. Irú ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Láìsí ìgbàgbọ́ ènìyàn kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà àti pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá wá a ní èrè.’—Hébérù 11:6, Ìròhìn Ayọ̀.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni kì í jẹ́ kó rọrùn láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àmọ́, tó o bá ṣàwọn nǹkan mẹ́rin tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò báyìí, wàá ṣàṣeyọrí.