Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Bàlágà
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Bàlágà
“Ó máa ń rọ̀ mí lọ́rùn gan-an láti báwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sóhun tí mo bá sọ fún wọn, wọ́n sì máa ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti ń bàlágà, ọ̀rọ̀ èmi àtiwọn ò wọ̀ mọ́. Wọn ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. Wọ́n á ní: ‘Ṣọ́ràn-anyàn ni ká tiẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì ni?’ Káwọn ọmọ mi tó bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà mi ò ronú pé wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í yọ irú ọwọ́kọ́wọ́ yìí, kódà nígbà tí mo bá rí i táwọn ọmọ míì ń ṣe bẹ́ẹ̀.”—Reggie. a
ṢỌ́MỌ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó fani lọ́kàn mọ́ra jù lọ nínú ìdàgbàsókè ọmọ ẹ lo ń ṣojú ẹ yẹn. Àkókò yẹn sì tún lè jẹ́ ọ̀kan lára ìgbà tọ́mọ ẹ máa fún ẹ ní wàhálà jù lọ. Ṣérú àwọn nǹkan tá a sọ tẹ̀ lé e yìí máa ń ṣẹlẹ̀ nílé yín?
▪ Nígbà tọ́mọkùnrin ẹ ṣì wà ní kékeré, ṣe ló dà bí ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi okùn so mọ́ èbúté, èbúté yẹn sì dúró fún òbí. Àmọ́ ní báyìí tó ti ń bàlágà, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í fa okùn yẹn kíkankíkan, tó sì ń hára gàgà láti bọ́ sójú agbami, o sì wá kíyè sí i pé kò tiẹ̀ fẹ́ kó o dá sọ́rọ̀ òun mọ́.
▪ Nígbà tọ́mọbìnrin ẹ ṣì wà ní kékeré, ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ló máa ń sọ fún ẹ. Àmọ́ ní báyìí tó ti ń bàlágà, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ nìkan ló máa ń sohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún, kì í sì í fọ̀rọ̀ lọ̀ ẹ́ mọ́.
Tírú àwọn nǹkan tá a sọ yìí bá ń ṣẹlẹ̀ nílé yín, má jẹ kíyẹn mú ẹ ronú pé ọmọ ẹ ti di ọlọ̀tẹ̀ tí kò lè yí pa dà. Kí wá lohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ipa pàtàkì tí ìbàlágà ń kó nínú ìdàgbàsókè ọmọ ẹ.
Ìgbà Ìbàlágà Ṣe Pàtàkì
Látìgbà tá a bá ti bímọ, ọ̀pọ̀ nǹkan tọ́mọ náà ń ṣe ló sábà máa ń jẹ́ fúngbà àkọ́kọ́, bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ kan ló bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ọjọ́ kan ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ọjọ́ kan ló bẹ̀rẹ̀ iléèwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Inú àwọn òbí máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn ìyípadà pàtàkì kan ń bá àwọn ọmọ àwọn. Ìyẹn sì ń jẹ́ kó túbọ̀ máa dá wọn lójú pé àwọn ọmọ wọn ń dàgbà sókè báwọn ṣe ń fẹ́.
Ìgbà tó ṣe pàtàkì nìgbà ìbàlágà pàápàá jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàhálà kékeré kọ́ ló máa ń kó àwọn òbí sí. Ó lè jẹ́ pé ìyẹn ló fà á tọ́pọ̀ òbí fi máa ń ṣàníyàn. Abájọ tó fi máa ń ṣòro fáwọn òbí láti gbà pé ọmọ àwọn tó ti máa ń gbọ́ràn dáadáa tẹ́lẹ̀ ti wá dẹni táwọn ò mohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ báyìí. Síbẹ̀ ìgbà ìbàlágà ṣe pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ọmọ. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Bíbélì sọ pé bọ́jọ́ bá ṣe ń gorí ọjọ́, “ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ìdí pàtàkì tọ́mọ ẹ fi ń bàlágà ni kó lè múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ayọ̀ tójú sábà máa ń roni yẹn. Tó bá fi máa dìgbà yẹn, ó yẹ kọ́mọ ẹ lè sọrú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.”—1 Kọ́ríńtì 13:11.
Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tọ́mọ ẹ ń ṣe nígbà tó ń bàlágà nìyẹn, ó ń fìwà ọmọdé sílẹ̀, ó sì ń kọ́ bó ṣe máa dàgbà tó wúlò, tó máa lè dá gbọ́ bùkátà ara ẹ̀, tó sì máa lè dá dúró láyè ara ẹ̀ lẹ́yìn tó bá filé sílẹ̀. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ tiẹ̀ ṣàpèjúwe ìgbà ìbàlágà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, ó ní ṣe ló dà bí ìgbà táwọn ọmọ ń dágbére fáwọn òbí wọn pé “ó dìgbà kan ná.”
Ká sòótọ́, bó o ṣe ń ronú pé ọmọ kékeré ọjọ́sí fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀ báyìí lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé:
▪ “Tọ́mọkùnrin mi ò bá lè ronú débi tó fi yẹ kó mọ̀ pé ó yẹ kí yàrá òun máa mọ́ tónítóní, báwo ló ṣe máa lè tọ́jú ilé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé?”
▪ “Tọ́mọbìnrin mi kì í bá wọlé lásìkò tó yẹ báyìí, báwo láá ṣe máa débiṣẹ́ lásìkò nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?”
Tó o bá ń ṣàníyàn nípa irú nǹkan báyìí, ó yẹ kó o rántí pé: A ò lè fi bọ́mọ ṣe fẹ́ dá dúró wé ẹnu ọ̀nà téèyàn kàn lè gbà kọjá, kó sì bọ́ sódìkejì; àmọ́ ṣe ló dà bí ojú ọ̀nà tọ́mọ náà máa fi ọ̀pọ̀ ọdún rìn kó tó lè débi tó ń lọ. Àmọ́ ní báyìí, ìwọ náà lè ti kíyè sí i pé, “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin [tàbí ọmọdébìnrin] ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.”—Òwe 22:15.
Ní báyìí ná, tó o bá ń tọ́ àwọn ọmọ ẹ sọ́nà bó ṣe yẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n di àgbà tó máa wúlò, tí wọ́n á sì lè “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
Bó O Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí
Tó o bá máa tọ́mọ ẹ sọ́nà kó lè wúlò nígbà tó bá dàgbà, o ní láti kọ́kọ́ ràn án lọ́wọ́ láti ní “agbára ìmọnúúrò,” ìyẹn ló sì máa jẹ́ kó lè máa dá ṣàwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Róòmù 12:1, 2) Àwọn ìlànà Bíbélì tó o máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà báyìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tọ́mọ ẹ sọ́nà.
Fílípì 4:5: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” Ọmọ ẹ tó ti ń bàlágà sọ fún ẹ pé òun fẹ́ máa pẹ́ níta ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. O sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé kò sáyè. Ọmọ ẹ wá bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, ó ní: “Kí ló tiẹ̀ dé gan-an, ẹ dẹ̀ ń ṣe mí bí ọmọdé!” Kó o tó sọ fún ọmọ yẹn pé: “Ṣé bí àgbàlagbà ṣe ń ṣe lo wá ń ṣe yìí,” kọ́kọ́ ronú lórí àwọn kókó wọ̀nyí: Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà máa ń fẹ́ òmìnira ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ àwọn òbí náà máa ń háwọ́ òmìnira fáwọn ọmọ wọn láìmọ̀. O ò ṣe rò ó wò dáadáa, bóyá ó máa ṣeé ṣe fún ẹ láti máa gba tọmọ ẹ rò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Tàbí kẹ̀, kó o ronú lórí ìdí tọ́mọ ẹ fi rò póun nílò òmìnira díẹ̀ sí i.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ṣàkọsílẹ̀ ohun kan tàbí méjì tó o lè torí ẹ̀ fún ọmọ ẹ lómìnira púpọ̀ sí i. Ṣàlàyé fún un pé ńṣe lo fẹ́ fún un ní àfikún òmìnira láti mọ bó ṣe máa ṣe sí. Tó bá ṣe dáadáa, o lè fún un lómìnira púpọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ tí kò bá ṣe dáadáa, ńṣe ni kó o dín òmìnira tó o fún un tẹ́lẹ̀ kù.—Mátíù 25:21.
Kólósè 3:21: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò sí àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn.”—Ìròhìn Ayọ̀. Àwọn òbí kan máa ń ṣọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí pé wọn ò fẹ́ kí wọ́n ṣi ẹsẹ̀ gbé. Àwọn ló máa ń yan ọ̀rẹ́ fún wọn, àwọn òbí yìí á sì tún máa dọ́gbọ́n kẹ́tí gbọ́ ohun táwọn ọmọ wọn bá ń bá ẹlòmíì sọ lórí fóònù. Àmọ́, àwọn ọgbọ́n táwọn òbí wọ̀nyí ń dá wọ̀nyẹn lè tún dá kún ìṣòro. Tó o bá ń há àwọn ọmọ ẹ mọ́lé ju bó ṣe yẹ lọ, bí wọ́n ṣe máa ráyè sá jáde nílé ni wọ́n á máa wá; tó o bá ń ba àwọn ọ̀rẹ́ wọn jẹ́ lójú wọn, ńṣe ni wọ́n á túbọ̀ di kòríkòsùn; tó o bá sì ń kẹ́tí sọ́rọ̀ wọn, wọ́n á wá ọ̀nà míì tí wọ́n á gbà máa bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ tíwọ ò sì ní mọ̀. Tó o bá sọ pé gbogbo ohun táwọn ọmọ ẹ ń ṣe lo fẹ́ máa ṣọ́, bóyá lo máa rí wọn mú. Òótọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ ni pé, tó ò bá jẹ́ kí wọ́n kọ́ bí wọ́n á ṣe máa ṣèpinnu fúnra wọn nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ ẹ, wọn ò ní lè dá ṣèpinnu nígbà tí wọ́n bá wà láyè ara wọn.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ìgbà tó o bá tún máa bá ọmọ ẹ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tó kàn án, ńṣe ni kó o ràn án lọ́wọ́ láti ronú lórí bí ìpinnu tó ṣe ṣe máa nípa lórí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa ṣàròyé lórí irú àwọn ọ̀rẹ́ tó ń kó, o lè sọ nípa ọ̀rẹ́ yẹn pé: “Táwọn ọlọ́pàá bá mú lágbájá torí gbogbo ìwàkiwà tó ń hù yìí ńkọ́? Kí lo rò páwọn èèyàn máa sọ nípa ìwọ náà?” Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa jẹ́ kọ́mọ ẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà rí báwọn nǹkan tóun ńṣe ṣe máa Òwe 11:17, 22; 20:11.
nípa lórí irú ojú táwọn èèyàn á máa fi wo òun.—Éfésù 6:4: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” Láti kọ́mọ ní “ìlànà èrò orí” kọjá kéèyàn kàn máa rọ̀jò òótọ́ ọ̀rọ̀ lé e lórí. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn bá ọmọ yẹn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi máa ronú jinlẹ̀ lórí ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí, tíyẹn á sì mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà rere. Èyí ṣe pàtàkì gan-an pàápàá nígbà tọ́mọ ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Bàbá kan tó ń jẹ́ Andre sọ pé: “Báwọn ọmọ ẹ bá ṣe ń dàgbà sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe máa yí bo o ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ pa dà, kó o sì túbọ̀ máa ronú pa pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—2 Tímótì 3:14.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tọ́rọ̀ kan bá délẹ̀ tẹ́ ẹ jọ fẹ́ yanjú, jẹ́ kí ọmọ ẹ ṣe bí òbí kíwọ sì ṣe bí ọmọ. Béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé, ìmọ̀ràn wo ló máa fún ẹ, tó bá jẹ́ pé òun ni òbí. Ní kó lọ ṣèwádìí dáadáa, kó lè ní ẹ̀rí tó máa fi ti ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn, kó sì tún lè ronú dáadáa lórí àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé torí ìpinnu tó bá ṣe. Kẹ́ ẹ jọ wá tún ọ̀rọ̀ yẹn sọ kí ọ̀sẹ̀ yẹn tó délẹ̀.
Gálátíà 6:7: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Èèyàn lè fi nǹkan kan du ọmọdé láti bá a wí, bóyá kéèyàn ní kò gbọ́dọ̀ jáde nínú yàrá tàbí kéèyàn máà jẹ́ kó ṣeré kan tó máa ń fẹ́ láti ṣe. Àmọ́ tọ́mọ bá ti ń bàlágà, àwọn ibi tí ìwà tó ń hù lè yọrí sí lẹ máa jẹ́ kó mọ̀.—Òwe 6:27.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Má ṣe bá a san gbèsè tó bá jẹ, má sì ṣe gbè lẹ́yìn ẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò gba iye máàkì tó yẹ kó gbà níléèwé. Jẹ́ kóun náà mọ bó ṣe máa ń rí lára tí nǹkan ò bá rí bó ṣe yẹ kó rí, ìyẹn ò ní jẹ́ kó tètè gbàgbé ohun tó bá kọ́.
Torí pé o jẹ́ òbí, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kò yẹ kọ́mọ ẹ níṣòro kankan nígbà tó ń bàlágà, ó sì yẹ kó rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti di àgbàlagbà tó máa wúlò. Àmọ́, o ní láti fi sọ́kàn pé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà láti mọ gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, bọ́mọ ẹ ṣe ń bàlágà yìí jẹ́ kó o láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti “tọ́ [ọmọ rẹ] ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” (Òwe 22:6) Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, wàá lè fi ìpìlẹ̀ tó lágbára lélẹ̀ fún ìdílé aláyọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
BI ARA Ẹ PÉ . . .
Tọ́mọ mi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé, ṣó ó máa lè . . .
▪ máa ṣàwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé
▪ máa ṣàwọn ìpinnu tó tọ́
▪ báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ọmọlúwàbí
▪ bójú tó ìlera ara ẹ̀
▪ mọ bó ṣe yẹ kó máa ṣọ́wó ná
▪ mọ bó ṣe máa máa túnlé ṣe
▪ máa lo ìdánúṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Tọ́mọ ẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà àgbà, o ò ṣe fún un lómìnira díẹ̀ sí i láti ṣohun tó bá fẹ́?