Ọlọ́run Nìkan Ló Lè Tún Ayé Yìí Ṣe
Ọlọ́run Nìkan Ló Lè Tún Ayé Yìí Ṣe
Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Edgar Mitchell tó máa ń rìnrìn àjò lọ sí gbalasa òfuurufú ń ṣàpèjúwe bí ayé wa yìí ṣe rí nígbà tó wò ó láàárín òfuurufú tó ṣókùnkùn birimùbirimù, ó ní “Ó Ń DÁN LOGÓLOGÓ BÍI PÉÁLÌ IYEBÍYE.”
Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni Ọlọ́run ṣe láti mú kí ayé yìí dùn-ún gbé fáwa èèyàn. Nígbà tí Ọlọ́run dá ayé, àwọn áńgẹ́lì “hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:7) Ó dájú pé táwa náà bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà láyé yìí, a máa fìyìn fún Ọlọ́run. Onírúuru nǹkan àgbàyanu ló wà láyìíká wa tó mú káwọn ẹ̀dá abẹ̀mí lè máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀kan lára irú àwọn nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa ni báwọn ewéko ṣe ń ṣètò oúnjẹ wọn nípa lílo ìtànṣán oòrùn, afẹ́fẹ́ carbon dioxide àti omi. Afẹ́fẹ́ ọ́síjìn, tó ń gbé ìwàláàyè tiwa ró, làwọn ewéko wọ̀nyí sì máa ń tú jáde lẹ́yìn èyí.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti fi ayé yìí síkàáwọ́ àwa èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Kí àjọṣe tó dán mọ́nrán bàa lè wà láàárín àwọn nǹkan alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti àyíká wọn, àwa èèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó tọ́. A gbọ́dọ̀ fẹ́ràn ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ibùgbé wa yìí. Ó gbọ́dọ̀ máa wù wá láti jẹ́ kí ilẹ̀ ayé wa yìí túbọ̀ máa lẹ́wà sí i. Àmọ́, torí pé Ọlọ́run ti fún àwa èèyàn lómìnira láti máa ṣohun tó wù wá, ó ṣeé ṣe ká lo àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ ayé yìí nílòkulò débi tá a fi máa ṣàkóbá fún ilẹ̀ ayé. Ohun tó sì ti ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ìṣòro kékeré kọ́ ni ìwà àìbìkítà àti ìwọra àwa èèyàn ti fà lórí ilẹ̀ ayé yìí.
Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ti jẹ yọ torí pé àwọn èèyàn ti lo àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé yìí nílòkulò rèé: (1) Àwọn igbó táwọn èèyàn ń pa run ti jẹ́ kí afẹ́fẹ́ carbon dioxide pọ̀ lápọ̀jù lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn wà lára àwọn ohun tí kò jẹ́ kí ojú ọjọ́ máa rí bó ṣe yẹ kó rí. (2) Àwọn oògùn tí wọ́n fi ń pa kòkòrò kò jẹ́ káwọn kòkòrò, bí èèrà, pọ̀ tó bó ṣe yẹ mọ́, iṣẹ́ kékeré sì kọ́ làwọn kòkòrò wọ̀nyẹn ń ṣe láti mú kí àyíká àwọn nǹkan alààyè yòókù dùn-ún gbé, ọ̀kan lára iṣẹ́ wọn ni jíjẹ́ kí ìtànná di èso. (3) Pípa táwọn èèyàn ń pa àwọn ẹja inú omi ju bó ṣe yẹ lọ àtàwọn nǹkan olóró tí wọ́n ń dà sínú omi ti jẹ́ káwọn ẹja dín kù gan-an. (4) Bí wọ́n ṣe ń fi ìwàǹwara lo àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ tó wà láyé yìí ti jẹ́ ká rí i pé bóyá làwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la máa lè dé bá nǹkan kan láyé yìí, ìyẹn náà ló sì ń jẹ́ káyé máa móoru ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣàyẹ̀wò àyíká ti jẹ́ ká mọ̀ pé báwọn òkìtì yìnyín ṣe ń yọ́ láwọn apá ibi tó tutù nini lágbàáyé fi hàn pé ayé ń móoru.
Báwọn ìjàǹbá tá ò rò tẹ́lẹ̀ ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i láyé wa yìí ti jẹ́ káwọn kan máa sọ pé ẹ̀san ló ń ké lórí àwa èèyàn. Ọlọ́run ò gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wa, bíi pé a jẹ́ ayálégbé, ọ̀fẹ́ ló fún wa ní gbogbo nǹkan tó wà láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-29) Àmọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí ti jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fẹ́ káyé yìí dùn-ún wò. Dípò káwọn èèyàn máa ṣiṣẹ́ kára láti máa tún ilẹ̀ ayé wa yìí ṣe, ìfẹ́ inú ara wọn ni wọ́n ń bá kiri. Àwọn èèyàn ò fira wọn hàn bí ayálégbé tó ṣeé fọkàn tán, ńṣe ni wọ́n “ń run ilẹ̀ ayé” bí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá 11:18 ṣe sọ.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti fi hàn pé, Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ ti pàṣẹ, àkókò sì ti tó láti “lé” àwọn èèyàn, tó dà bí ayálégbé, tó ń lo ayé yìí nílòkulò “jáde”. (Sefanáyà 1:14; Ìṣípayá 19:11-15) Ọlọ́run ò ní máa wo àwọn èèyàn tó fẹ́ pa ayé yìí run níran o, ńṣe ló máa ṣe wọ́n bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú kó tó pẹ́ jù. a (Mátíù 24:44) Ó dájú pé Ọlọ́run nìkan ló lè tún ayé yìí ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nípa bí kò ṣe yẹ ká fi nǹkan falẹ̀ lákòókò tá a wà yìí wà nínú ìwé pẹlẹbẹ tá a pe àkọlé ẹ̀ ní Ẹ Máa Ṣọ́nà! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.