Ọ̀dọ́ Kan Tó Nígboyà
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ọ̀dọ́ Kan Tó Nígboyà
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 1 SÁMÚẸ́LÌ 17:1-11, 26, 32-51.
Ṣàpèjúwe bó o ṣe rò pé Gòláyátì rí àti irú ohùn tó ní.
․․․․․
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì kì í ṣe ọkàn lára àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, kí nìdí tó fi fẹ́ bá Gòláyátì jà? (Wo ẹsẹ 26.)
․․․․․
Kí ló fi Dáfídì lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́? (Tún ka ẹsẹ 34 sí 37.)
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Lo àwọn ìwé míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tó o ní lọ́wọ́ láti ṣèwádìí, kó o sì gbìyànjú láti mọ
(1) Bí Gòláyátì ṣe ga tó. (1 Sámúẹ́lì 17:4)
Ó lé díẹ̀ ní ẹsẹ bàtà mẹ́sàn-án = ․․․․․
(2) Bí ẹ̀wù Gòláyátì tí wọ́n fi àdàrọ irin ṣe ṣe wúwo tó. (1 Sámúẹ́lì 17:5)
Ó wúwo tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ṣékélì bàbà = ․․․․․
(3) Bí ọ̀kọ̀ Gòláyátì ṣe wúwo tó. (1 Sámúẹ́lì 17:7)
Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì irin = ․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìgboyà.
․․․․․
Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà dípò agbára ara rẹ.
․․․․․
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ MÍÌ.
Àwọn ohun ìdènà tó dà bíi Gòláyátì wo lò ń dojú kọ?
․․․․․
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ (tàbí sáwọn ẹlòmíì) tó jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní pa ẹ́ tì?
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․