Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Gan-an Sẹ́ni Tó Bá Kú?
Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Gan-an Sẹ́ni Tó Bá Kú?
“Ẹ̀mí èèyàn kì í kú, títí kan tàwọn aṣebi pàápàá . . . Wọ́n máa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ nínú iná tí kò lè kú, síbẹ̀ wọn ò ní kú, wọn ò sì ní lè [fòpin] sí ìyà tó ń jẹ wọ́n.”—Ọ̀gbẹ́ni Clement, ọmọ ìlú Alẹkisáńdíríà, òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Kristẹni ló sọ bẹ́ẹ̀.
BÍI ti Ọ̀gbẹ́ni Clement, àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn pé ibi ìdálóró ni ọ̀run àpáàdì gbà pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú. Ṣé ẹ̀kọ́ yìí wà nínú Bíbélì? Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí.
Ṣé Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ní ẹ̀mí tí kò lè kú? Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù tán, ó pàṣẹ fún un pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Èyí fi hàn pé Ádámù ò ní ẹ̀mí tí kò lè kú.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà tó dẹ́ṣẹ̀? Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run sọ pé ó máa jẹ kì í ṣe ìdálóró ayérayé nínú ọ̀run àpáàdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bibeli Ajuwe sọ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run kéde báyìí pé: ‘Ní òógùn ojú rẹ ni ìwọ ó máa jẹun, títí ìwọ ó fi pa dà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ ó sì pa dà di erùpẹ̀.’ (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ohun tí Ọlọ́run sọ yìí ò túmọ̀ sí pé nǹkan kan wà lára Ádámù tí kò kú nígbà tí Ádámù kú.
Ṣé ẹ̀mí èèyàn máa ń kú lóòótọ́? Kò sí ẹ̀mí èèyàn kankan tí kò lè kú. Ìwé Oníwàásù 3:20 sọ pé: “Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ [Ádámù] wọ inú ayé, tí ikú sì bá ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló ṣẹ̀.’ (Róòmù 5:12, Ìròhìn Ayọ̀) Gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀, torí náà gbogbo èèyàn ló ń kú.
Ṣẹ́ni tó ti kú lè mọ nǹkan kan tàbí kó ronú ohunkóhun? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.’ (Oníwàásù 9:5, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá ti kú, ó ní: ‘Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.’ (Orin Dáfídì [Sáàmù, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun] 146:4, Bibeli Mimọ) Táwọn òkú ‘kò [bá] mọ ohun kan’ tí ‘ìrò inú’ wọn sì ti “run,” báwo ni wọ́n ṣe lè mọ̀ pé àwọn ń joró ní ọ̀run àpáàdì?
Jésù Kristi ò fi ikú wé ìgbà téèyàn mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó fi ikú wé oorun. a (Jòhánù 11:11-14) Àwọn kan lè sọ pé Jésù kọ́ni pé ọ̀run àpáàdì gbóná àti pé Ọlọ́run á ju àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sínú iná ọ̀run àpáàdì. Jẹ́ ká wá jíròrò ohun tí Jésù sọ nípa ọ̀run àpáàdì.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé ẹ̀ ní, “Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù—Nípa Ìrètí Tó Wà Fáwọn Òkú” lójú ìwé 16 àti 17.