Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àwọn Ọkọ̀ Òkun Táṣíṣì” Mú Ọ̀làjú Dé

“Àwọn Ọkọ̀ Òkun Táṣíṣì” Mú Ọ̀làjú Dé

“Àwọn Ọkọ̀ Òkun Táṣíṣì” Mú Ọ̀làjú Dé

“Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń la òkun já nítorí òwò rẹ.”—ÌSÍKÍẸ́LÌ 27:25, ÌTÚMỌ̀ THE JERUSALEM BIBLE

ÀWỌN ọkọ̀ òkun Táṣíṣì wà lára àwọn nǹkan tó sọ Sólómọ́nì dọlọ́rọ̀. Àwọn tó ṣe àwọn ọkọ̀ òkun wọ̀nyí wà lára àwọn tó mú kí wọ́n máa kọ èdè Gíríìkì àti Róòmù sílẹ̀. Àwọn náà ni wọ́n tẹ ìlú kan tí wọ́n pè ní Bíbílọ́sì dó, látinú orúkọ ìlú yẹn sì ni orúkọ ìwé tó tíì nípa lórí àwọn èèyàn jù lọ ti wá, ìyẹn Bíbélì.

Àwọn wo ló ṣe ọkọ̀ òkun Táṣíṣì, àwọn wo ló sì ń wà á? Báwo ni wọ́n ṣe fún àwọn ọkọ̀ náà lórúkọ? Báwo sì làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn wọ̀nyẹn àtàwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n ṣe ṣe jẹ́rìí sí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

Òléwájú Lórí Òkun Mẹditaréníà

Àwọn ará Fòníṣíà ló ṣe àwọn ọkọ̀ òkun táwọn èèyàn ń pè ní ọkọ̀ òkun Táṣíṣì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan [1,000] ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn ará Fòníṣíà ti di àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí ká tukọ̀ òkun. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé etíkun tẹ́ẹ́rẹ́ kan báyìí, níbi tí orílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì òde òní wà, ni ìlú ìbílẹ̀ wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè míì wà ní àríwá, ìlà oòrùn àti ní gúúsù ìlú náà. Àmọ́, Òkun Mẹditaréníà ló lọ salalu lápá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà. Àwọn ará Fòníṣíà gbà pé táwọn bá ń ṣòwò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì láwọn etíkun Mẹditaréníà, àwọn máa jèrè gọbọi.

Báwọn ará Fòníṣíà tó máa ń tukọ̀ òkun ṣe fàwọn ọkọ̀ òkun wọn bẹ̀rẹ̀ òwò tó ń búrẹ́kẹ́ nìyẹn. Bówó ṣe túbọ̀ ń wọlé fún wọn, tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sì ń tẹ̀ síwájú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá tó lè rìn jìnnà dáadáa lórí agbami. Lẹ́yìn tí wọ́n dé erékùṣù Kípírọ́sì, Sardinia, àtàwọn erékùṣù Balearic, àwọn ará Fòníṣíà tọ etíkun tó wà ní Àríwá Áfíríkà lọ sápá ìwọ̀ oòrùn títí tí wọ́n fi dé orílẹ̀-èdè Sípéènì. (Wo àwòrán ilẹ̀ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.)

Àwọn káfíńtà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Fòníṣíà, tí wọ́n sì jẹ́ ògbógi nínú kíkan ọkọ̀ òkun, máa ń ṣe ọkọ̀ òkun tó máa gùn ju ọkọ̀ bọ́ọ̀sì mẹ́jọ lọ. Àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní “àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì” torí pé wọ́n lè rin lórí agbami láti Fòníṣíà lọ sí gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì, ibi tó ṣeé ṣe kí ìlú Táṣíṣì wà nígbà yẹn, ìrìn àjò yẹn sì tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] kìlómítà. a

Àwọn ará Fòníṣíà lè má ní in lọ́kàn láti ṣàkóso ayé, wọ́n kàn fẹ́ máa ṣòwò tiwọn ni. Ìdí sì nìyẹn tí wọ́n fi ní ìsọ̀ tí wọ́n ti ń tajà káàkiri àgbáyé. Òwò tí wọ́n ń ṣe ló sọ wọ́n di òléwájú lórí Òkun Mẹditaréníà.

Wọ́n Tún Kọjá Òkun Mẹditaréníà

Àwọn ará Fòníṣíà wọ̀nyí tún lọ ṣòwò lórí Òkun Àtìláńtíìkì kí wọ́n lè túbọ̀ jèrè gọbọi. Àwọn ọkọ̀ òkun wọn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn etíkun tó wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì títí tí wọ́n fi dé agbègbè ibí tó ń jẹ́ Tartessus. Nígbà tó máa fi di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún kan [1100] ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n tẹ ìlú kan tí wọ́n pè ní Gadir dó. Etíkun yìí tí wọ́n wá ń pè ní Cádiz báyìí lórílẹ̀-èdè Sípéènì wà lára àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ dó lápá Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù.

Àwọn ará Fòníṣíà máa ń ṣòwò iyọ̀, wáìnì, ẹja gbígbẹ, igi kédárì, igi ahóyaya, àwọn nǹkan tí wọ́n fi irin ṣe, gíláàsì, àwọn aṣọ aláràbarà, aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, àtàwọn aṣọ tí wọ́n fi àwọ̀ àlùkò tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè Tírè pa láró. Kí ni wọ́n wá máa ń rí lórílẹ̀-èdè Sípéènì ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn ohun tí wọ́n kó lọ síbẹ̀?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fàdákà àtàwọn mẹ́táàlì tó ṣeyebíye míì wà ní Gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì létí Òkun Mẹditaréníà. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìlú Tírè tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn etíkun táwọn ará Fòníṣíà máa ń ná, pé: “O ṣòwò lórílẹ̀-èdè Sípéènì, o sì gba fàdákà, irin, tánńganran àti òjé láti fi rọ́pò owó ọjà rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.”—Ìsíkíẹ́lì 27:12, ìtumọ̀ Today’s English Version.

Àwọn ará Fòníṣíà ṣàwárí ibì kan tí wọ́n ti lè máa wa àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọ̀nyí jáde lọ́pọ̀ yanturu létí odò Guadalquivir, nítòsí Cádiz. Àwọn kan ṣì ń wa àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ wọ̀nyí jáde níbẹ̀ títí dòní olónìí, àmọ́ Río Tinto ni wọ́n ń pe àdúgbò náà báyìí. Ó sì ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún báyìí tí wọ́n ti ń wa ojúlówó àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ jáde níbi tá à ń wí yìí.

Nígbà tí òwò tó da àwọn ará Sípéènì àtàwọn ará Fòníṣíà pọ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa, ló di pé àwọn ará Fòníṣíà nìkan ló ń wa fàdákà lórílẹ̀-èdè Sípéènì, àwọn náà ló sì ń pinnu ibi tí wọ́n máa gbé e lọ. Fàdákà wá pọ̀ gan-an nílùú Fòníṣíà tó fi mọ́ ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n jọ pààlà. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì dòwò pọ̀ pẹ̀lú Hírámù Ọba Fòníṣíà. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn ò fi ka fàdákà sí “nǹkan kan rárá” nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 10:21. b

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òwò àwọn ará Fòníṣíà búrẹ́kẹ́ dáadáa, wọn máa ń hùwà òǹrorò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn èèyàn sọ pé nígbà míì, wọ́n máa ń tan àwọn èèyàn láti wá wọkọ̀ ojú omi wọn, wọ́n á ní kí wọ́n wá wo ọjà táwọn ń tà, àmọ́ ọgbọ́n àtikó wọn lẹ́rú ni wọ́n ń dá. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ti jọ dòwò pọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣòwò ẹrú. Ìdí nìyẹn táwọn wòlíì Hébérù fi sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú Tírè tó wà ní Fòníṣíà. Alẹkisáńdà Ńlá ló wá mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní ọdún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jóẹ́lì 3:6; Ámósì 1:9, 10) Báwọn ará Fòníṣíà ṣe pa run nìyẹn.

Ìlànà Àwọn Ará Fòníṣíà

Bíi tàwọn oníṣòwò tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́, àwọn oníṣòwò ará Fòníṣíà máa ń kọ àdéhùn tó bá ní í ṣe pẹ̀lú òwò wọn sílẹ̀. Bí wọ́n sì ṣe máa ń kọ àwọn lẹ́tà wọn sílẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti èdè Hébérù àtijọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè míì rí i pé àǹfààní wà nínú báwọn ará Fòníṣíà ṣe ń kọ̀rọ̀ sílẹ̀. Ìlànà táwọn ará Fòníṣíà fi ń kọ̀rọ̀ sílẹ̀ làwọn Gíríìkì ṣàtúnṣe díẹ̀ sí táwọn náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀rọ̀ tiwọn náà sílẹ̀, látinú èdè Gíríìkì sì làwọn ará Róòmù ti mú ìlànà táwọn náà fi ń kọ lẹ́tà wọn sílẹ̀, àwọn lẹ́tà tàwọn ará Róòmù yìí sì lọ̀pọ̀ èèyàn wá ń lò jù lọ lóde òní.

Yàtọ̀ síyẹn, ìlú Bíbílọ́sì, tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlú tó wà ní Fòníṣíà ni òrépèté tí wọ́n ń kọ̀wé sí nígbà yẹn pọ̀ sí, káwọn èèyàn tó máa wá ṣe bébà tá à ń kọ̀wé sí lóde òní. Òrépèté yìí ló jẹ́ káwọn èèyàn ronú àtimáa ṣèwé jáde. Kódà, látinú Bíbílọ́sì ni orúkọ tá à ń pe ìwé táwọn èèyàn tíì pín kiri jù lọ ti wá, ìyẹn Bíbélì. Kò sí àníàní pé, àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn ará Fòníṣíà, àtàwọn ọkọ̀ òkun wọn jẹ́rìí sí i pé òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro làwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe oríṣi ọkọ̀ òkun tó bá ti lè rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn lórí agbami ní “àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì.”

b Sólómọ́nì ní “ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun láti Táṣíṣì,” ó sì dòwò pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ó ṣeé ṣe káwọn ọkọ̀ òkun wọ̀nyí máa lọ jìnnà kọjá Esioni-gébérì, kí wọ́n sì máa ṣòwò dé etí Òkun Pupa àtàwọn ibi tó tún jìnnà jù bẹ́ẹ̀ lọ.—1 Àwọn Ọba 10:22.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 27]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

OJÚ Ọ̀NÀ TÁWỌN ARÁ FÒNÍṢÍÀ MÁA Ń GBÀ LỌ ṢÒWÒ

SÍPÉÈNÌ

TARTESSUS

Odò Guadalquivir

Gadir

Corsica

Etíkun Balearic

Sardinia

Sísílì

Kírétè

Kípírọ́sì

Bíbílọ́sì

Tírè

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

Esioni-gébérì

Òkun Pupa

ÁFÍRÍKÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Owó ẹyọ tí wọ́n ya ọkọ̀ òkun àwọn ará Fòníṣíà sí ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹta sí ìkẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwókù ibi táwọn ará Fòníṣíà tẹ̀ dó sí ní Cádiz lórílẹ̀-èdè Sípéènì

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Museo Naval, Madrid

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Owó Ẹyọ: Museo Arqueológico Municipal. Puerto de Sta. María, Cádiz; àwókù: Yacimiento Arqueológico de Doña Blanca, Pto. de Sta. María, Cádiz, España