Irú Ẹni Wo Ni Baba Wa Ọ̀run Jẹ́?
Irú Ẹni Wo Ni Baba Wa Ọ̀run Jẹ́?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn lónìí ló mọ Àdúrà Olúwa sórí, ìyẹn àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mátíù 6:9-13) Gbogbo ìgbà táwọn èèyàn bá ń gba àdúrà yẹn, wọ́n máa ń pe Ọlọ́run ní “Baba Wa.” Àmọ́, àwọn mélòó ló lè sọ pé àwọn mọ Ọlọ́run dáadáa?
Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ Ọlọ́run dáadáa? Ǹjẹ́ àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán? Ṣé o máa ń bá a sọ̀rọ̀, tó o sì ń jẹ́ kó mọ ohun tó múnú rẹ dùn àtohun tó ń bà ọ́ nínú jẹ́? Kí ni mímọ Ọlọ́run túmọ̀ sí?
“Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ̀”
Ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ kan lè máa pe bàbá rẹ̀ ní Dádì. Àmọ́ bó bá ṣe ń dàgbà, á wá mọ orúkọ tí bàbá rẹ̀ ń jẹ́ àti irú ẹni tí bàbá rẹ̀ jẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó máa fi bàbá rẹ̀ yangàn. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa baba wa ọ̀run tó fún wa ní ìwàláàyè ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ orúkọ rẹ̀ àti ìtumọ̀ orúkọ náà?
Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń gba Àdúrà Olúwa wọ́n máa ń sọ pé, “Ki a bọ̀wọ fun orúkọ rẹ.” (Bibeli Mimọ) Àmọ́, tá a bá bi wọ́n pé “Kí ni orúkọ Ọlọ́run?” Ìdáhùn wọn kì í tọ̀nà. Lára àwọn nǹkan tó ń fi hàn pé Ọlọ́run wà ni: Ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, àwọn òkè àwòyanu, àwọn òkìtì iyùn aláwọ̀ mèremère táwọn nǹkan abẹ̀mí ń gbénú wọn lábẹ́ omi. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìṣẹ̀dá yìí ò sọ orúkọ Ọlọ́run fún wa. Ká lè mọ orúkọ yẹn, a ní láti lọ wo inú Bíbélì. Bíbélì sọ ní pàtó pé: “Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.”—Ẹ́kísódù 15:3.
Ọlọ́run fẹ́ ká mọ orúkọ tí òun ń jẹ́, ìyẹn Jèhófà. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ ká mọ orúkọ òun? Ìdí ni pé orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Orúkọ yẹn túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” A lè sọ ọ́ lọ́nà míì pé, ó lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ láti mú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ṣẹ. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Kí bàbá kan bàa lè bójú tó ìdílé rẹ̀, á di
òṣìṣẹ́ tó ń pa owó wálé fún ìdílé rẹ̀, á di agbaninímọ̀ràn, onídàájọ́, alárinà, aláàbò àti olùkọ́. Ohun tó máa dà sinmi lórí ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Lọ́nà kan náà, orúkọ Jèhófà ń mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ láti bù kún gbogbo àwọn tó ń sìn ín, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la sí.Ẹ jẹ́ ká wo onírúurú ohun tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ lè dà, tó máa ń bá ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mu. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọyì ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, àti ohun tó yẹ kó o ṣe láti lè sún mọ́ ọn.
“Ọlọ́run Ìfẹ́ àti Àlàáfíà”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Ẹlẹ́dàá wa ní “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Kí nìdí tó fi pè é bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jésù Kristi sọ nígbà kan rí pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Nítorí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí ọmọ aráyé, ó fi Ọmọ rẹ̀ àyànfẹ́ ṣe ìràpadà, èyí tó mú kó lè ṣeé ṣe fún ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ náà láti ní ìyè àìnípẹ̀kun, tí kò ní sí ìrora àti ìyà tí ẹ̀ṣẹ̀ fà. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fi sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí sún wa láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká sì sún mọ́ ọn?
Ọlọ́run fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo aráyé lápapọ̀, yàtọ̀ sí yẹn, ó tún fi hàn sáwọn olóòótọ́ èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tí wọ́n sábà máa ń ṣàìgbọràn pé: “Ṣé Jèhófà ni ẹ̀yin ń ṣe báyìí sí, ìwọ arìndìn ènìyàn tí kò gbọ́n? Òun ha kọ́ ni Baba rẹ tí ó mú ọ jáde, Ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ, tí ó sì mú ọ dúró gbọn-in gbọn-in?” (Diutarónómì 32:6) Ǹjẹ́ o mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe lágbára tó? Nítorí pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó ń bìkítà fáwọn èèyàn rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ó sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò, ó ń gbọ́ ẹ̀dùn ọkàn wọn, ó sì ń mú kí àjọṣe àárín àwọn àti òun dára sí i.
Gbogbo wa la ń dojú kọ pákáǹleke láyé yìí. Ó máa ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, kódà ó ń mú kínú wa bà jẹ́ nígbà míì. A máa ń fẹ́ kí ẹnì kan tọ́ wa sọ́nà ká lè fojú tó tọ́ wo ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí wa àtàwọn ìṣòro wa. Ta ló máa ràn wá lọ́wọ́? Jèhófà tipasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, fi hàn pé òun ni ẹni tó ń fìfẹ́ tọ́jú wa tó sì ń fún wa nímọ̀ràn. Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tá a fi ń jìyà àti bá a ṣe lè fara dà á. Bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe máa ń ṣèrànwọ́ fọ́mọ rẹ̀ tó ṣubú tó sì fara pa, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà nínú ìfẹ́ rẹ̀ tó tóbi lọ́lá ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ gbé wa sókè láti ràn wá lọ́wọ́. Dájúdájú, ọwọ́ Jèhófà kò kúrú, ó sì ṣe tán láti gba àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Aísáyà 59:1.
Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn ní ti pé ó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Báwo ni gbígbọ́ tó ń gbọ́ àdúrà wa ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Nípa gbígba àdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run àti nípa títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwọ náà lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”
“Ọlọ́run Ìmọ̀”
Bíbélì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni “pípé nínú ìmọ̀.” Nítorí pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìmọ̀,” ó mọ̀ wá dáadáa ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ wá lọ, Jóòbù 36:4; 1 Sámúẹ́lì 2:3) Ó tipasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé, “ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Diutarónómì 8:3; Mátíù 4:4) Èyí túmọ̀ sí pé kéèyàn tó lè láyọ̀, ó nílò ohun tó ju ohun ìní tara lọ.
ó sì tún mọ ohun tá a nílò. (Ẹlẹ́dàá wa ń fún wa ní ìmọ̀ràn àtàtà àti ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò nígbèésí ayé wa, a ó máa jàǹfààní “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” Bí àpẹẹrẹ, obìnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́, Zuzanna, sọ nípa ìdílé rẹ̀, ó ní: “Ìgbéyàwó wa lágbára nítorí a máa ń ka Bíbélì pa pọ̀, a jọ ń lọ sí ìpàdé Kristẹni, a sì máa ń sọ ohun tá a ti kọ́ fáwọn èèyàn. Nítorí pé Ọlọ́run ń tọ́ wa sọ́nà, ohun kan náà la jọ ń lépa, èyí sì mú kí àjọṣe wa túbọ̀ lágbára.”
Báwo nìwọ náà ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run? Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tó o sì ń fàwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀ sílò, wàá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Hébérù 12:9.
“Ọlọ́run Ìgbàlà”
Gbọ́nmisi-omi-ò-to pọ̀ nínú ayé lónìí. Àwọn èèyàn ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Tó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ogun ti bà jẹ́ lò ń gbé, bó o ṣe máa gbé ní àlàáfíà ló máa jẹ ọ́ lógún. Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, àwọn èèyàn ń gbé nínú ìbẹ̀rù nítorí ìwà ipá, ọrọ̀ ajé tó ń bà jẹ́ sí i, àti ìbẹ̀rù táwọn apániláyà ń dá sílẹ̀. Ta ló máa gbà wá lọ́wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Ká sòótọ́, ọmọ aráyé ń fẹ́ ààbò àti ìdáǹdè lóde òní ju ti ìgbàkigbà rí lọ.
Bíbélì sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” (Òwe 18:10) Mímọ orúkọ Ọlọ́run àti gbígbẹ́kẹ̀lé e ń mú ká máa ronú nípa ohun tó ti ṣe àtohun tó máa ṣe láti gba àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ là. Jèhófà Ọlọ́run ti fi hàn láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé òun lè dá àwọn èèyàn òun nídè. Bí àpẹẹrẹ, ó gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là nípa pípa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun jẹ́ Ọlọ́run ìṣòtítọ́, Ọlọ́run tó máa ń rántí àwọn tójú ń pọ́n tó sì ṣe tán láti gbà wọ́n.—Ẹ́kísódù 15:1-4.
Tá a bá fẹ́ wà láàyè títí láé, àfi ká nígbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run pé ó jẹ́ Olùgbàlà. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì tó fara da ọ̀pọ̀ ìnira, fi irú ìgbàgbọ́ yẹn hàn nígbà tó sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Sáàmù 25:5) Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 Pétérù 2:9.
Ọlọ́run ṣèlérí fún ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pé: “Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.” (Sáàmù 91:14) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ti rí i pé ìlérí yẹn ń ṣẹ. Arákùnrin Henryk tó ń gbé ní ilẹ̀ Poland ti sin Jèhófà fún àádọ́rin ọdún, láìfi ìpọ́njú àti inúnibíni pè. Nígbà tí Henryk wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, wọ́n mú bàbá rẹ̀ lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Auschwitz. Wọ́n sọ Henryk àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin sílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìgbọràn ti ìjọba Násì. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Henryk lọ sí onírúurú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nígbà tí Henryk rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó ní: “Ní gbogbo àkókò àdánwò wọ̀nyẹn, Jèhófà kò fi mí sílẹ̀. Ó ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí mi wà nínú ewu.” Ó dájú pé Jèhófà máa ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì ń fún wọn lókun láti fara da àdánwò.
Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò jẹ́ Olùgbàlà àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ àtàwọn tó ń wojú rẹ̀ fún ìdáǹdè. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan.” (Aísáyà 43:11) Nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” Ọlọ́run yóò pa àwọn èèyàn burúkú run kúrò lórí ilẹ̀ ayé yóò sì gba àwọn adúróṣinṣin là. (Ìṣípayá 16:14, 16; Òwe 2:21, 22) Jèhófà mú un dá wa lójú pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.
Bá A Ṣe Lè Di “Ọmọ Ọlọ́run”
Nígbà ayé wòlíì Málákì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé Jèhófà ni Bàbá àwọn. Síbẹ̀, nígbà tó bá di ọ̀rọ̀ bíbu ọlá fún Ọlọ́run àti fífọkàn sìn ín, àwọn ohun tí kò ní láárí ni wọ́n fi ń rúbọ sí Ọlọ́run, irú bíi búrẹ́dì tí kò dára àti ẹran tó fọ́jú tó sì yarọ. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bi wọ́n pé: “Bí mo bá jẹ́ baba, ọlá mi dà?”—Málákì 1:6.
Má ṣe irú àṣìṣe táwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ yẹn ṣe o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run kó o sì sún mọ́ ọn. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Baba wa gbé iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́. Tó o bá ń sapá láti bọlá fún Ọlọ́run nípa títẹ̀lé ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn nínú gbogbo ìgbésí ayé rẹ, kò ní gbàgbé ìsapá rẹ láé. Ńṣe ni yóò máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà títọ́ tó lọ sí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí ‘kò ti ní sí ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4) Ní ìgbà yẹn, gbogbo aráyé tó jẹ́ onígbọràn ni a óò ti ‘dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.’—Róòmù 8:21.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ọlọ́run fẹ́ ká mọ orúkọ òun, ìyẹn Jèhófà. Orúkọ yẹn túmọ̀ sí “Alèwílèṣe”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ní gbogbo àkókò àdánwò wọ̀nyẹn, Jèhófà kò fi mí sílẹ̀.”—HENRYK
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Ìgbéyàwó wa lágbára nítorí a máa ń ka Bíbélì pa pọ̀, a jọ ń lọ sí ìpàdé Kristẹni, a sì máa ń sọ ohun tá a ti kọ́ fáwọn èèyàn.”—ZUZANNA