Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó pé o wà níbi tí ohun tó ò ń kà náà ti ṣẹlẹ̀, kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA LÚÙKÙ 2:41-47.
Tó o bá fojú inú wo ohun tí ẹsẹ kẹrìndínláàádọ́ta sọ, ọ̀rọ̀ kí lo rò pé Jésù àtàwọn olùkọ́ yẹn jọ ń sọ?
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Kí lo rò pé ó jẹ́ kí Jésù lè bá àwọn olórí ẹ̀sìn yẹn sọ̀rọ̀ pa pọ̀ bó ṣe jẹ́ ọmọdé tó yẹn? Ṣé torí pé ó jẹ́ ẹni pípé ni, àbí ó tún nídìí míì tó fi rí bẹ́ẹ̀?
․․․․․
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA LÚÙKÙ 2:48-52.
Irú ìwà wo lo rò pé Jésù hù sáwọn òbí ẹ̀ nígbà tó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi?”
․․․․․
Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jésù kò fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn òbí ẹ̀ àti pé ó bọ̀wọ̀ fún wọn?
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Kí nìdí tá a fi gbà pé Jósẹ́fù àti Màríà máa dààmú lóòótọ́?
․․․․․
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, kí nìdí tó fi ń bá a lọ láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu?
․․․․․
Ǹjẹ́ o ronú pé ó ṣeé ṣe kí ojú ti Jésù bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe bá a wí lójú àwọn èèyàn tó fẹ́ràn rẹ̀?
․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Jíjẹ́ ẹni tó ń tẹrí ba.
․․․․․
Bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó wà lọ́mọdé.
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ NÍNÚ ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․